Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí “Ìrètí Ìgbàlà” Wà Lọ́kàn Rẹ Digbí!

Jẹ́ Kí “Ìrètí Ìgbàlà” Wà Lọ́kàn Rẹ Digbí!

Jẹ́ Kí “Ìrètí Ìgbàlà” Wà Lọ́kàn Rẹ Digbí!

“Gbé . . . ìrètí ìgbàlà [wọ̀] gẹ́gẹ́ bí àṣíborí.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:8.

1. Báwo ni “ìrètí ìgbàlà” ṣe ń jẹ́ kéèyàn ní ìfaradà?

 ÌRÈTÍ ìgbàlà lè jẹ́ kéèyàn mọ́kàn le kódà nígbà tíná bá jó dóríi kókó pàápàá. Ẹni tí ọkọ̀ rì, tó jàjà rí igi kan tó léfòó dìrọ̀ mọ́ lójú agbami, kò ní jọ̀gọ̀ nù bó bá mọ̀ pé ìrànwọ́ ń bọ̀ lọ́nà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni ìrètí “ìgbàlà Jèhófà” ti máa ń mẹ́sẹ̀ àwọn ọkùnrin àtobìnrin onígbàgbọ́ dúró nígbà tí wàhálà bá dójú ẹ̀, ìrètí yìí kò sì ṣákìí rí. (Ẹ́kísódù 14:13; Sáàmù 3:8; Róòmù 5:5; 9:33) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi “ìrètí ìgbàlà” wé “àṣíborí” tó jẹ́ ara ìhámọ́ra tẹ̀mí fún Kristẹni. (1 Tẹsalóníkà 5:8; Éfésù 6:17) Ó dájú pé ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní pé Ọlọ́run yóò gbà wá, ń dáàbò bo agbára ìrònú wa, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa agbára ìmòye wa mọ́, láìfi ìpọ́njú, àtakò, àti ìdẹwò pè.

2. Ní àwọn ọ̀nà wo ni “ìrètí ìgbàlà” fi jẹ́ òpómúléró ìjọsìn tòótọ́?

2 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé: “Àwọn kèfèrí kò ní ìrètí pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa,” àwọn kèfèrí yìí ló sì yí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ká. (Éfésù 2:12; 1 Tẹsalóníkà 4:13) Bẹ́ẹ̀ rèé, “ìrètí ìgbàlà” ni òpómúléró ìjọsìn tòótọ́. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìgbàlà àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tan mọ́ orúkọ òun fúnra rẹ̀. Ásáfù onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Ràn wá lọ́wọ́, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa, nítorí ògo orúkọ rẹ; kí o sì dá wa nídè.” (Sáàmù 79:9; Ìsíkíẹ́lì 20:9) Síwájú sí i, níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí pọndandan bí a óò bá ní ìbátan rere pẹ̀lú rẹ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ rèé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Láfikún sí i, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ìgbàlà àwọn onírònúpìwàdà ni ìdí pàtàkì tí Jésù fi wá sáyé. Ó polongo pé: “Ṣíṣeégbíyèlé àti yíyẹ fún ìtẹ́wọ́gbà kíkún ni àsọjáde náà pé Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.” (1 Tímótì 1:15) Àpọ́sítélì Pétérù sì pe ìgbàlà ní ‘òpin [tàbí, àtúbọ̀tán] ìgbàgbọ́ wa.’ (1 Pétérù 1:9) Fún ìdí yìí, kò sóhun tó burú ńbẹ̀ táa bá fọkàn sí rírí ìgbàlà. Àmọ́ kí tiẹ̀ ni ìgbàlà ná? Kí sì la gbọ́dọ̀ ṣe kọ́wọ́ wa tó lè tẹ̀ ẹ́?

Kí Ni Ìgbàlà?

3. Irú ìgbàlà wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé ọjọ́un rí?

3 Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, “ìgbàlà” sábà máa ń túmọ̀ sí ìtúsílẹ̀ tàbí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ìfojú-ẹni-gbolẹ̀ tàbí kúrò lọ́wọ́ ikú gbígbóná àti ikú àìtọ́jọ́. Bí àpẹẹrẹ, láti fi hàn pé Jèhófà ni “Olùpèsè àsálà,” Dáfídì sọ pé: “Ọlọ́run mi ni àpáta mi. . . . Ibi ìsásí mi, Olùgbàlà mi; ìwọ gbà mí là kúrò nínú ìwà ipá. Jèhófà, ẹni tí ó yẹ fún ìyìn, ni èmi yóò ké pè, a ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.” (2 Sámúẹ́lì 22:2-4) Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà máa ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ bá ń ké gbàjarè fún ìrànlọ́wọ́.—Sáàmù 31:22, 23; 145:19.

4. Ìrètí wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé ní nípa ìwàláàyè ọjọ́ iwájú?

4 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé tún ní ìrètí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú. (Jóòbù 14:13-15; Aísáyà 25:8; Dáníẹ́lì 12:13) Ohun tó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ìlérí ìdáǹdè tí ń bẹ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbàlà ńlá kan—èyíinì ni ìgbàlà tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Aísáyà 49:6, 8; Ìṣe 13:47; 2 Kọ́ríńtì 6:2) Nígbà ayé Jésù, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ń retí ìyè àìnípẹ̀kun, àmọ́ wọ́n kọ̀ láti gbà pé ipasẹ̀ Jésù lohun táwọn ń retí fi lè tẹ àwọn lọ́wọ́. Jésù sọ fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ ń wá inú àwọn Ìwé Mímọ́ kiri, nítorí ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; ìwọ̀nyí gan-an sì ni ó ń jẹ́rìí nípa mi.”—Jòhánù 5:39.

5. Paríparí rẹ̀, kí ni ìgbàlà túmọ̀ sí?

5 Nípasẹ̀ Jésù, Ọlọ́run jẹ́ kí a rí ibi tí ọ̀rọ̀ náà, ìgbàlà, nasẹ̀ dé. Ó kan ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìjẹgàba ẹ̀ṣẹ̀, kúrò lọ́wọ́ oko ẹrú ẹ̀sìn èké, kúrò lọ́wọ́ ayé tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì, kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù èèyàn, àti kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú pàápàá. (Jòhánù 17:16; Róòmù 8:2; Kólósè 1:13; Ìṣípayá 18:2, 4) Paríparí rẹ̀, ní ti àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ìgbàlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kò mọ sórí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ìfojú-ẹni-gbolẹ̀ àti hílàhílo nìkan, ó tún nasẹ̀ dórí àǹfààní níní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 6:40; 17:3) Jésù kọ́ni pé ohun tí ìgbàlà “agbo kékeré” túmọ̀ sí ni pé a óò jí wọn dìde sí ìyè ti ọ̀run láti bá Kristi ṣàkóso nínú Ìjọba náà. (Lúùkù 12:32) Ní ti ìyókù aráyé, ìgbàlà túmọ̀ sí ìmúbọ̀sípò ìwàláàyè pípé àti ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run, irú èyí tí Ádámù àti Éfà gbádùn nínú ọgbà Édẹ́nì kí wọ́n tó ṣẹ̀. (Ìṣe 3:21; Éfésù 1:10) Ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ irú ipò párádísè bẹ́ẹ̀ ni ète Ọlọ́run fún aráyé ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Máàkù 10:30) Àmọ́ báwo ni a ó ṣe mú irú ipò wọ̀nyẹn padà wá?

Ìràpadà Ló Jẹ́ Ká Ní Ìrètí Ìgbàlà

6, 7. Kí ni ipa tí Jésù kó nínú ìgbàlà wa?

6 Ipasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi nìkan ni ìgbàlà àìnípẹ̀kun fi ṣeé ṣe. Èé ṣe? Bíbélì ṣàlàyé pé nígbà tí Ádámù ṣẹ̀, ó “ta” ara rẹ̀ àti gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀, títí kan àwa náà, sínú ẹ̀ṣẹ̀—ìyẹn ni ìràpadà fi pọndandan bí ìrètí gúnmọ́ kankan yóò bá wà fọ́mọ aráyé. (Róòmù 5:14, 15; 7:14) Ti pé Ọlọ́run yóò pèsè ìràpadà fún gbogbo aráyé ni a rí àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú àwọn ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ lábẹ́ Òfin Mósè. (Hébérù 10:1-10; 1 Jòhánù 2:2) Jésù ni ẹni tí ẹbọ rẹ̀ mú àwọn àpẹẹrẹ alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn ṣẹ. Áńgẹ́lì Jèhófà kéde ṣáájú ìbí Jésù pé: “Òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”—Mátíù 1:21; Hébérù 2:10.

7 Màríà wúńdíá ló bí Jésù lọ́nà ìyanu, níwọ̀n bí Jésù sì ti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, kò jogún ikú látọ̀dọ̀ Ádámù. Òtítọ́ yìí, àti ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ pípé tí ó tọ̀, ló jẹ́ kí ìwàláàyè rẹ̀ ní ìtóye táa nílò láti fi ra aráyé padà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 8:36; 1 Kọ́ríńtì 15:22) Láìdà bíi gbogbo èèyàn yòókù, ikú tí Jésù kú kì í ṣe ikú ẹ̀ṣẹ̀. Ó dìídì wá sáyé ni, láti “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Lẹ́yìn tó ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù tó ti jíǹde, tó sì ti wà lórí ìtẹ́ báyìí, ní agbára láti fún gbogbo àwọn tó bá dójú ìlà ohun tí Ọlọ́run ń béèrè ní ìgbàlà.—Ìṣípayá 12:10.

Kí La Gbọ́dọ̀ Ṣe Ká Tó Lè Rí Ìgbàlà?

8, 9. (a) Báwo ni Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè tí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ olùṣàkóso béèrè nípa ìgbàlà? (b) Báwo ni Jésù ṣe lo àǹfààní yìí láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́?

8 Nígbà kan, ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan, tó tún jẹ́ olùṣàkóso ní Ísírẹ́lì, béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” (Máàkù 10:17) Ó lè jẹ́ èrò tó gbòde kan láàárín àwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀ ló fa ìbéèrè rẹ̀—èrò ọ̀hún ni pé Ọlọ́run ti la àwọn iṣẹ́ rere kan sílẹ̀ téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe, ẹni tó bá sì ṣe iṣẹ́ wọ̀nyẹn dójú ìlà nìkan ló lè rí ìgbàlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ìmọtara-ẹni-nìkan lè sún èèyàn máa ṣe irú ìjọsìn tí ò dénú bẹ́ẹ̀. Irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ kò lè fúnni ní ìrètí tó dájú nípa ìgbàlà, nítorí pé, kò sẹ́dàá aláìpé tó lè tẹ̀ lé gbogbo ìlànà Ọlọ́run fínnífínní.

9 Nígbà tí Jésù máa dáhùn ìbéèrè ọkùnrin yìí, ńṣe ló kàn rán an létí pé kí ó lọ máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Ọlọ́run. Párá tí ọ̀dọ́ olùṣàkóso yìí máa dá Jésù lóhùn, ó ní tó bá jẹ́ tìyẹn ni, àtikékeré òun lòun ti ń pa wọ́n mọ́. Ìdáhùn rẹ̀ yìí wá jẹ́ kí ọkàn Jésù fà sí i tìfẹ́tìfẹ́. Jésù wá sọ fún un pé: “Ohun kan ni ó kù nípa rẹ: Lọ, ta àwọn ohun tí o ní, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” Ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ lọkùnrin náà bá kúrò níbẹ̀, “nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.” Lẹ́yìn náà ni Jésù wá fi yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé béèyàn bá wa dúkìá ayé yìí máyà, kò sí bí ọ̀nà àtirí ìgbàlà kò ṣe ní há fún onítọ̀hún. Ó fi kún un pé kò sẹ́ni tó lè jèrè ìgbàlà nípasẹ̀ ìsapá tara rẹ̀ nìkan. Àmọ́ Jésù tún wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Fún ènìyàn, kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:18-27; Lúùkù 18:18-23) Báwo ni ìgbàlà ṣe ṣeé ṣe?

10. Kí làwọn ohun táa gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè rí ìgbàlà?

10 Ìgbàlà jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ kì í ṣe ohun táa lè rí gbà láìsapá. (Róòmù 6:23) Àwọn ohun pàtàkì kan wà tí kálukú gbọ́dọ̀ ṣe kí ẹ̀bùn yẹn tó lè tọ́ sí i. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Àpọ́sítélì Jòhánù sì fi kún un pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè.” (Jòhánù 3:16, 36) Láìsí àní-àní, Ọlọ́run ń béèrè ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn lọ́wọ́ olúkúlùkù tó bá fẹ́ jèrè ìgbàlà àìnípẹ̀kun. Olúkúlùkù gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu láti tẹ́wọ́ gba ìràpadà náà, kí ó sì máa tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù.

11. Báwo ni ẹ̀dá aláìpé ṣe lè jèrè ojú rere Jèhófà?

11 Níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, ṣíṣe ìgbọràn kò mọ́ wa lára, kò sì ṣeé ṣe fún wa láti ṣègbọràn lọ́nà pípé. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pèsè ìràpadà kan láti bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n o, a gbọ́dọ̀ máa làkàkà láti gbé ìgbé-ayé tó bá ọ̀nà Ọlọ́run mu. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ fún ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso náà, a gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí ojú rere Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ní àfikún, yóò tún yọrí sí ayọ̀ ńláǹlà, nítorí pé “àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira”; “ìtura” ni wọ́n jẹ́. (1 Jòhánù 5:3; Òwe 3:1, 8) Síbẹ̀, kò rọrùn láti rọ̀ mọ́ ìrètí ìgbàlà.

“Máa Ja Ìjà Líle fún Ìgbàgbọ́”

12. Báwo ni ìrètí ìgbàlà ṣe lè fún Kristẹni kan lókun láti dènà ìdẹwò ṣíṣe ìṣekúṣe?

12 Ọmọ ẹ̀yìn náà Júúdà kọ́kọ́ fẹ́ kọ̀wé sáwọn Kristẹni ìjímìjí nípa “ìgbàlà tí gbogbo [wọ́n] jọ dì mú.” Ṣùgbọ́n, ìwàkiwà tó gbòde kan wá jẹ́ kó di dandan fún un láti gba àwọn ará níyànjú láti “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.” Ní tòdodo, báa bá fẹ́ jèrè ìgbàlà, níní ìgbàgbọ́, fífaramọ́ ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́, àti ṣíṣègbọràn nígbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ déédéé nìkan kò tó. Ìfọkànsìn táa ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ jinlẹ̀ débi tí yóò fi lè ràn wá lọ́wọ́ láti dènà ìdẹwò àti ìwà ìṣekúṣe. Àmọ́, ìwà ìṣekúṣe tó burú jáì tó sì gbòdì, àìfọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ, ìyapa, àti iyèméjì ti fẹ́ ba ẹ̀mí tó wà nínú ìjọ ọ̀rúndún kìíní jẹ́. Láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dojúùjà kọ irú àwọn ìtẹ̀sí bẹ́ẹ̀, Júúdà rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n má gbàgbé góńgó wọn, ó ní: “Ẹ̀yin, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” (Júúdà 3, 4, 8, 19-21) Ìrètí jíjèrè ìgbàlà lè fún wọn lókun bí wọ́n ti ń jà raburabu láti jẹ́ oníwà mímọ́.

13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kò tíì tàsé ète inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run?

13 Jèhófà Ọlọ́run retí pé kí ìwà gbogbo àwọn tí òun yóò fún ní ìgbàlà jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Àmọ́ o, rírọ̀mọ́ ìlànà ìwà híhù tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ò wá túmọ̀ sí pé ká máa ṣòfíntótó àwọn ẹlòmíì o. Àwa kọ́ ni yóò pinnu ohun tí yóò jẹ́ ìpín àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ni yóò pinnu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ fún àwọn Gíríìkì ní Áténì, pé: “Ó ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò,” ìyẹn Jésù Kristi. (Ìṣe 17:31; Jòhánù 5:22) Báa bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù nínú ìgbésí ayé wa, kò sídìí láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí pé ọjọ́ ìdájọ́ kan ń bọ̀. (Hébérù 10:38, 39) Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé a ò gbọ́dọ̀ “tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run [ìpadàrẹ́ wa pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà] kí [a] sì tàsé ète rẹ̀” nípa jíjẹ́ kí a dẹ wá lọ sínú èrò òdì àti ìwà àìtọ́. (2 Kọ́ríńtì 6:1) Ní àfikún sí i, nípa ríran àwọn míì lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàlà, a ń fi hàn pé a kò tàsé ète àánú Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

Nínawọ́ Ìrètí Ìgbàlà Sáwọn Ẹlòmíì

14, 15. Àwọn wo ni Jésù yan iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere ìgbàlà fún?

14 Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ Jóẹ́lì yọ nígbà tó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́ ṣá o, báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” Nínú àwọn ẹsẹ mélòó kan lẹ́yìn èyí, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìgbàgbọ́ kì í ṣàdédé wá fúnra rẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa “ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́,” ìyẹn ni, “ọ̀rọ̀ nípa Kristi.”—Róòmù 10:13, 14, 17; Jóẹ́lì 2:32.

15 Ta ni yóò mú “ọ̀rọ̀ nípa Kristi” tọ àwọn orílẹ̀-èdè lọ? Jésù yan iṣẹ́ yẹn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ìyẹn àwọn táa ti fi “ọ̀rọ̀” náà kọ́. (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Jòhánù 17:20) Nígbà táa bá ń lọ́wọ́ nínú wíwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa rẹ̀ gan-an là ń ṣe, lọ́tẹ̀ yìí ọ̀rọ̀ Aísáyà ló fà yọ, pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere mà dára rèǹtè-rente o!” Kódà bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò tiẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìhìn rere táa mú tọ̀ wọ́n lọ, ẹsẹ̀ wa ṣì “dára rèǹtè-rente” lójú Jèhófà.—Róòmù 10:15; Aísáyà 52:7.

16, 17. Ète alápá méjì wo ni iṣẹ́ ìwàásù ń ṣiṣẹ́ fún?

16 Ṣíṣe iṣẹ́ táa gbé lé wa lọ́wọ́ yìí ń mú ète pàtàkì méjì ṣẹ. Èkíní, a gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere náà fún ìgbéga orúkọ Ọlọ́run, àti kí àwọn tó fẹ́ ìgbàlà lè mọ ibi tó yẹ káwọn yíjú sí. Pọ́ọ̀lù lóye apá yìí lára iṣẹ́ náà. Ó sọ pé: “Ní ti tòótọ́, Jèhófà ti pàṣẹ fún wa ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé, ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, fún ọ láti jẹ́ ìgbàlà títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.’” Fún ìdí yìí, gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi, olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ nípìn-ín nínú mímú ìhìn ìgbàlà tọ àwọn èèyàn lọ.—Ìṣe 13:47; Aísáyà 49:6.

17 Èkejì, wíwàásù ìhìn rere náà ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ yẹn, ó sọ pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dìgbà “tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀” kí ìdájọ́ àti ìyàsọ́tọ̀ tó wáyé, síbẹ̀ lọ́wọ́ táa wà yìí, iṣẹ́ ìwàásù náà ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti mọ ẹni tí àwọn arákùnrin Kristi nípa tẹ̀mí jẹ́, kí wọ́n sì tipa báyìí gbárùkù tì wọ́n fún ìgbàlà ayérayé àwọn alára.—Mátíù 25:31-46.

Rọ̀ Mọ́ “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìdánilójú Ìrètí Náà”

18. Báwo la ṣe lè mú kí “ìrètí ìgbàlà” wa wà lọ́kàn wa digbí?

18 Jíjẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìwàásù tún jẹ́ ọ̀nà kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìrètí wa wà lọ́kàn wa digbí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.” (Hébérù 6:11) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa gbé “ìrètí ìgbàlà [wọ̀] gẹ́gẹ́ bí àṣíborí,” ká sì máa rántí pé “Ọlọ́run kò yàn wá fún ìrunú, bí kò ṣe fún rírí ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.” (1 Tẹsalóníkà 5:8, 9) Ká má sì gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú Pétérù, tó sọ pé: “Ẹ mú èrò inú yín gbára dì fún ìgbòkègbodò, ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré; ẹ gbé ìrètí yín ka inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a óò mú wá fún yín.” (1 Pétérù 1:13) Gbogbo àwọn tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni “ìrètí ìgbàlà” wọn yóò ṣẹ délẹ̀délẹ̀!

19. Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

19 Ní báyìí ná, ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àkókò tó ṣẹ́ kù fún ètò yìí? Báwo la ṣe lè lo àkókò yẹn láti jèrè ìgbàlà fún ara wa àti àwọn ẹlòmíì? Ìbéèrè wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Èé ṣe tó fi yẹ kí “ìrètí ìgbàlà” wa wà lọ́kàn wa digbí?

• Kí ni ìgbàlà wé mọ́?

• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti lè rí ẹ̀bùn ìgbàlà gbà?

• Kí ni iṣẹ́ ìwàásù wa ń ṣe láṣeyọrí níbàámu pẹ̀lú ète Ọlọ́run?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìgbàlà kò mọ sórí ìdáǹdè kúrò nínú ìparun nìkan