Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orin Tí Ń Múnú Ọlọ́run Dùn

Orin Tí Ń Múnú Ọlọ́run Dùn

Orin Tí Ń Múnú Ọlọ́run Dùn

A ti ṣàpèjúwe orin gẹ́gẹ́ bí “ohun tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tó sì tún ń wọ̀ wá lọ́kàn jù lọ nínú gbogbo ohun àkọ́mọ̀ọ́ṣe.” Gẹ́gẹ́ bí èdè, orin jẹ́ àgbàyanu ẹ̀bùn kan tó mú kéèyàn yàtọ̀ sí àwọn ẹranko. Orin máa ń ru ìmọ̀lára sókè. Ó máa ń dùn-ún gbọ́ létí, kì í tètè kúrò lọ́kàn ẹni. Lékè gbogbo rẹ̀, orin lè múnú Ọlọ́run dùn.

BÍ BÍBÉLÌ ṣe fi hàn, kọrinkọrin làwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Unger’s Bible Dictionary, sọ pé orin jẹ́ “ohun àkọ́mọ̀ọ́ṣe tí tẹrú tọmọ mọ̀ nípa rẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ohun tí wọ́n ń ṣe lójoojúmọ́, orin jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wọn, yálà èyí tí a fẹnu kọ tàbí èyí tí wọ́n fi ohun èlò kọ. Àmọ́, èyí tí wọ́n ń lò jù lọ ni orin tí àwọn èèyàn fẹnu ara wọn kọ.

Dáfídì Ọba yan àwọn aṣojú láàárín àwọn ọmọ Léfì “láti máa darí orin kíkọ” níbi àgọ́ ìjọsìn, ṣáájú ìfilọ́lẹ̀ tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ kọ́. (1 Kíróníkà 6:31, 32) Nígbà tí àpótí májẹ̀mú, tó ń ṣojú fún Jèhófà dé sí Jerúsálẹ́mù, Dáfídì ṣètò àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì “láti máa rántí àti láti máa dúpẹ́ àti láti máa yin Jèhófà.” Wọ́n ń kọ orin ìyìn “pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin tí í ṣe olókùn tín-ín-rín àti pẹ̀lú háàpù, . . . pẹ̀lú aro tí ń dún sókè, . . . pẹ̀lú kàkàkí.” Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni “a yàn sọ́tọ̀ nípa orúkọ láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, nítorí tí ‘inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin’”—1 Kíróníkà 16:4-6, 41; 25:1.

Ègbè náà “inú rere onífẹ̀ẹ́ [Jèhófà] wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Sáàmù, ìyẹn ìwé Bíbélì tó ní orin nínú jù lọ. Fún àpẹẹrẹ, òun ló wà ní apá kejì ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n inú Sáàmù kẹrìndínlógóje. Ọ̀mọ̀wé kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lórí Bíbélì sọ pé: “Ègbè náà ṣe ṣókí, èyí sì jẹ́ kí ó mọ́ àwọn èèyàn lẹ́nu. Ẹnikẹ́ni tó bá sáà ti gbọ́ ọ ló ń rántí rẹ̀.”

Àkọlé tó wà lókè àwọn sáàmù fi hàn pé wọ́n fi ohun èlò orin dárà síbẹ̀. Sáàmù àádọ́jọ sọ̀rọ̀ nípa ìwo, háàpù, ìlù tanboríìnì, àti fèrè ape, àti aro, pẹ̀lú ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Síbẹ̀síbẹ̀, ohùn ènìyàn la fi sípò kìíní. Ẹsẹ ìkẹfà gbani níyànjú pé: “Gbogbo ohun ẹlẹ́mìí—kí ó yin Jáà. Ẹ yin Jáà!”

Níwọ̀n bí orin tí máa ń fi ìmọ̀lára wa hàn, ìròbìnújẹ́ ló máa ń mú kí àwọn èèyàn kọrin arò tàbí sun rárà láwọn àkókò táa kọ Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, irú orin yìí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nínú àkójọ orin Ísírẹ́lì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bíbélì náà, Insight on the Scriptures a sọ pé: “Inú kìkì orin arò tàbí ìdárò nìkan ni wọ́n ti máa ń yàn láti sun rárà dípò kíkọ orin adùnyùngbà tàbí yíyí ohùn padà àti fífi ìtẹnumọ́ ṣe àlàyé lọ́rọ̀ ẹnu pọ́nbélé.”

Láìsí àní-àní, orin ìyìn tí Jésù àti àwọn olóòótọ́ àpọ́sítélì rẹ̀ kọ sí Jèhófà ní alẹ́ tí ó ṣáájú ikú Jésù ní àwọn ọ̀rọ̀ Hálẹ́lì inú Sáàmù nínú. (Sáàmù 113-118) Ẹ wo bí èyí yóò ti fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lókun tó láti má ṣe bara jẹ́ jù nítorí fífi tí Ọ̀gá wọn ń fi wọ́n sílẹ̀ lọ! Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìpinnu tí wọ́n ti ṣe láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Gíga Jù Lọ lágbàáyé, yóò túbọ̀ jinlẹ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń gbe orin náà nígbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé “inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 118:1-4, 29.

Àwọn Kristẹni ìjímìjí ní Éfésù àti Kólósè kọ “àwọn sáàmù àti ìyìn sí Ọlọ́run” (ní ṣangiliti, “orin ìyìn”). Wọ́n wá fi “àwọn orin ẹ̀mí” tí wọn ń kọ nínú ọkàn-àyà wọn kún un. (Éfésù 5:19; Kólósè 3:16) Nípa orin àti ọ̀rọ̀ ẹnu, wọ́n fi ẹnu wọn bu ìyìn lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú. Ǹjẹ́ Jésù ò ti sọ ọ́ pé “lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ”?—Mátíù 12:34.

Orin Tí Kò Mú Inú Ọlọ́run Dùn

Kì í ṣe gbogbo orin táa mẹ́nu kàn nínú Bíbélì ló mú inú Ọlọ́run dùn. Gbé ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Òkè Sínáì yẹ̀ wò, níbi tí Mósè ti ń gba Òfin, tó ní Àṣẹ Mẹ́wàá nínú. Nígbà tí Mósè sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè náà, kí ló gbọ́? “Kì í ṣe ìró orin nítorí iṣẹ́ agbára ńlá, kì í sì í ṣe ìró orin àwọn tí a ṣẹ́gun,” bí kò ṣe “ìró orin mìíràn.” Èyí jẹ́ orin tí ó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà, ìyẹn àṣà tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú rárá, tí ó sì yọrí sí ikú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àwọn tí ó kọ orin yẹn.—Ẹ́kísódù 32:18, 25-28.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn lè ronú, kí wọ́n sì kọ onírúurú orin, kí wọ́n sì gbádùn wọn, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé gbogbo rẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí. Èé ṣe? Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Àwọn ààtò ìbímọlémọ ti kèfèrí, ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ènìyàn, àti jíjúbà Màríà gẹ́gẹ́ bí “ìyá Ọlọ́run” ló sábà máa ń fara hàn gẹ́gẹ́ bí àkọlé àwọn àkójọ orin. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ìgbàgbọ́ àti àṣà wọ̀nyí ń tàbùkù sí Ọlọ́run òtítọ́, nítorí pé wọ́n tako ohun tó ṣí payá nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí.—Diutarónómì 18:10-12; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Lúùkù 1:35, 38.

Fífi Ọgbọ́n Yan Orin

Ṣíṣe àṣàyàn àwọn orin tó wà máa ń dani lọ́kàn rú. Ète àwòrán àti ọ̀rọ̀ tó wà lẹ́yìn kásẹ́ẹ̀tì orin ni láti fi fajú àwọn oníbàárà mọ́ra kí wọ́n lè ra gbogbo rẹ́kọ́ọ̀dù orin wọn láìku ẹyọ kan. Àmọ́ bí ẹnì kan tí ó ń jọ́sìn Ọlọ́run bá fẹ́ mú inú Rẹ̀ dùn, ó yẹ kónítọ̀hún kíyè sára, kó sì fi ọgbọ́n yan orin àti ìlù kí ó lè yẹra fún àwọn èyí tí ó tan mọ́ ìgbàgbọ́ ìsìn èké tàbí tí ó pe àfiyèsí sórí ìwà pálapàla àti bíbá ẹ̀mí èṣù lò.

Albert, tí ó ti fìgbà kan sìn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní Áfíríkà, sọ pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní láti máa tẹ dùùrù níbẹ̀. Ohun tó wá ṣe ni pé àwọn àwo tí orin wọn máa ń pẹ́ kó tó tán, tó kó dání lọ síbẹ̀ ló ń gbọ́ ní àgbọ́túngbọ́. Albert ti wá padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ báyìí, ó sì ń bẹ àwọn ìjọ Kristẹni wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Ìwọ̀nba àkókò ló ní fún orin báyìí. Ó sọ pé: “Orin tí mo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ ní orin Beethoven. Jálẹ̀ àwọn ọdún yìí wá, mo ti ní àwọn onírúurú àwo orin rẹ̀.” Ó sì máa ń gbádùn àwọn orin wọ̀nyí gan-an ni. Àmọ́ ṣá o, èyí wù mí ò wù ọ́ ni ọ̀rọ̀ orin, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.

Orin àti Ìfọkànsìn

Ohun tí Susie fẹ́ràn jù lọ ni orin. Ó ṣàlàyé pé: “Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí tẹ dùùrù, mo bẹ̀rẹ̀ sí ta gòjé lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, níkẹyìn mo wá ń ta háàpù lọ́mọ ọdún méjìlá.” Lẹ́yìn náà ni Susie wá lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Orin ti Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nílùú London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa háàpù. Ó fi ọdún mẹ́rin kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ olókìkí ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó ń ta háàpù, ó tún fi ọdún kan mìíràn kẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Orin ní Paris, ó gba oyè nínú orin kíkọ, ó sì gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà nínú títa háàpù àti kíkọ́ni ní dùùrù.

Susie wá bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní London. Ibẹ̀ ló ti wá rí ojúlówó aájò àti ìfẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ fún Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i, ìtara tó ní fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sì sún un láti wá ọ̀nà tí òun lè gbà sìn ín. Èyí ló mú kó ya ara rẹ̀ sí mímọ́, kó sì ṣe ìrìbọmi. Susie sọ pé: “Èmi tí mo ti fi orin ṣiṣẹ́ ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ tó ń gba gbogbo ọkàn èèyàn ni iṣẹ́ orin kíkọ, nítorí náà gbígbé ìgbésí ayé ìfọkànsìn ti mọ́ mi lára.” Ó dín àkókò tó fi ń lọ ṣeré lórí ìtàgé kù kí ó lè rí àyè láti máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láti ṣe ìgbọràn sí ìtọ́ni Jésù.—Mátíù 24:14; Máàkù 13:10.

Nísinsìnyí tó jẹ́ pé ìwọ̀nba àkókò ló fi ń ṣiṣẹ́ orin kíkọ, kí ni èrò rẹ̀? Ó sọ pé: “Ó máa ń dùn mí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé n kò rí àkókò tó pọ̀ láti fi orin dánra wò, àmọ́ mo ṣì máa ń wá àyè lo àwọn ohun èlò ìkọrin mi, mo sì ń gbádùn orin pẹ̀lú. Orin jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ìsinsìnyí tí mo wá fi iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé mi ni mo wá ń gbádùn orin jù lọ.”—Mátíù 6:33.

Orin Tí Ó Ń Yin Ọlọ́run

Albert àti Susie pẹ̀lú àwọn bíi mílíọ̀nù mẹ́fà mìíràn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ń fi orin yin Jèhófà Ọlọ́run lógo déédéé. Ní àwọn ìpàdé Kristẹni tí wọ́n ń ṣe láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀, wọ́n máa ń fi orin kíkọ sí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé wọn, wọ́n sì máa ń fi parí rẹ̀ láwọn ibi tí ó bá ti ṣeé ṣe. Àwọn orin atunilára wọ̀nyẹn máa ń ní àwọn ọ̀rọ̀ orin tó bá Ìwé Mímọ́ mu nínú, èyí tí a fi ń yin Jèhófà Ọlọ́run lógo.

Gbogbo àwọn tó wà láwùjọ ló ń gbé ohùn wọn sókè láti fi ìtara kọ orin pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó bìkítà. (Orin 44) Wọ́n ń kọ orin ìyìn sí Jèhófà (Orin 190). Àwọn orin wọn máa ń fi ìdùnnú àti ojúṣe ẹgbẹ́ ará Kristẹni hàn, ó tún ń fi ìgbé ayé Kristẹni àti àwọn ànímọ́ Kristẹni hàn. Ara ohun tó tún fi kún ayọ̀ wọn ni àwọn onírúurú ọ̀nà tí àwọn Ẹlẹ́rìí láti Éṣíà, Ọsirélíà, Yúróòpù, àti Ilẹ̀ Àríwá òun Gúúsù Amẹ́ríkà ń gbà kọ àwọn orin atunilára wọ̀nyẹn. b

“Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà. Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé. Ẹ kọrin sí Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀,” ni àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọyọyọ kan tí a kọ sílẹ̀ nígbà ayé onísáàmù. “Ẹ máa sọ ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́. Ẹ máa polongo ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn.” (Sáàmù 96:1-3) Ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lágbègbè rẹ nìyí, wọ́n sì ń ké sí ọ láti wá bá wọn kọ orin ìyìn yìí. Wọn ó fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gbà ọ́ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, níbi tóo ti lè kọ́ bí a ṣe ń yin Jèhófà pẹ̀lú orin tó ń múnú rẹ̀ dùn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.

b Àwọn orin wọ̀nyí wà nínú ìwé Kọrin Ìyìn sí Jehofah, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Kíkọrin ìyìn sí Jèhófà