Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Borí Ẹ̀mí Ìṣefínnífínní Dóríi Bíńtín?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Borí Ẹ̀mí Ìṣefínnífínní Dóríi Bíńtín?
Ǹjẹ́ o máa ń sa gbogbo ipá rẹ dé góńgó? Kò sí ni, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣàǹfààní fún ìwọ àtàwọn tó yí ẹ ká lóríṣiríṣi ọ̀nà. Àmọ́ àwọn kan tún ti ṣe é ní àṣejù baba àṣetẹ́, wọ́n ti sọ ara wọn di aṣefínnífínní dóríi bíńtín. Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
Ọ̀KAN lára ìtumọ̀ gbólóhùn náà “ìṣefínnífínní dóríi bíńtín” ni “ẹ̀mí kíka ohunkóhun tó bá yingin, tó kù díẹ̀ káàtó, sí ohun tí kò dáa.” Ó ṣeé ṣe kí o ti rí àwọn èèyàn tó nírú ẹ̀mí yẹn. O lè rí i pé ohun tí apá ò lè ká ni wọ́n ń retí látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì, èyí sì lè fa wàhálà rẹpẹtẹ, kó ṣokùnfà gbúngbùngbún, kó sì fayé sú àwọn ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì èèyàn ló mọ̀ pé ìṣefínnífínní dóríi bíńtín, èyíinì ni ṣíṣe ọ̀rínkinniwín ré kọjá ààlà àti rírinkinkin jù nínú gbogbo ìgbòkègbodò ẹ̀dá, kì í ṣe ẹ̀mí tó dáa. Èèyàn gbọ́dọ̀ dẹ̀yìn lẹ́yìn irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìṣòro kan rèé o, táa bá wo ìwà tàbí ìṣesí ti àwa alára, a lè jẹ́ arítẹnimọ̀ọ́wí afàpáàdì bo tiẹ̀ mọ́lẹ̀, a lè má gbà pé àwa náà ń ṣe fínnífínní dóríi bíńtín, ìyẹn ló fi máa ń nira gan-an láti borí ẹ̀mí yìí.
Iṣẹ́ tó wà lọ́rùn Nelson, àtàwọn ìṣòro tó ń bá yí pọ̀ lọ jàraa. Ìgbà gbogbo ló máa ń jókòó ti àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò, tí á máa ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ wọn, iṣẹ́ ò sì gbọ́dọ̀ dúró ìṣẹ́jú kan. Àwọn èèyàn sì gbà pé a gbọ́dọ̀ lè ṣe fínnífínní dóríi bíńtín, táa bá fẹ́ ríṣẹ́ ṣe, nítorí pé iṣẹ́ ṣòroó rí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè mọyì ọ̀rínkinniwín Nelson, àmọ́ ìṣefínnífínní dóríi bíńtín rẹ̀ ti ń di wàhálà sí i lọ́rùn báyìí o, àwọn nǹkan bí ẹ̀fọ́rí àti másùnmáwo ò jẹ́ kó gbádùn mọ́. Ṣé ìwọ náà kì í ṣe irú èèyàn bíi Nelson ṣá?
Ìṣefínnífínní dóríi bíńtín tún ń yọ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́nu. Rita, ọmọ kékeré, láti Rio de Janeiro, kò fi iléèwé ṣeré rárá. Kò bá ẹnikẹ́ni dupò o, ṣùgbọ́n ó máa ń banú jẹ́ gan-an tí kò bá gba ipò kìíní. Rita sọ pé: “Láti kékeré ni mo ti máa ń rò ó pé tèmi ṣe wá yàtọ̀, ṣebí àwọn èèyàn rèé tí wọ́n rójú ráyè, àmọ́ súré-n-bájà ni tèmi ṣáá, kòókòó jàn-ánjàn-án ni lọ́jọ́ gbogbo. Mi ò mọ̀gbà tí mo ráyè sinmi rí, torí pé ìgbà gbogbo ni mo sáà máa ń rí nǹkan ṣe.”
Ńṣe ni Maria ọmọbìnrin kékeré á máa
sunkún, tí á máa fẹsẹ̀ janlẹ̀ nígbà tí kò bá mọ àwòrán yà bíi tàwọn yòókù. Síwájú sí i, bó ṣe ń ṣe fínnífínní dóríi bíńtín, tó fẹ́ rí i pé òun mọ iṣẹ́ orin débi tí wọ́n ń mọ̀ ọ́n dé, ọ̀pọ̀ ìgbà lèyí máa ń kó o lọ́kàn sókè, tí ìdààmú á dé bá a, kàkà tí ì bá fi máa gbádùn gìtá tó ń ta tàbí orin tó ń kọ. Ọmọbìnrin ará Brazil mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tânia, tó rọra ń dọ́gbọ́n sọ́ràn ara ẹ̀, tí kò sì gbé ara rẹ̀ lẹ́mìí gbóná nínú ẹ̀mí ìdíje, jẹ́wọ́ pé òun ṣì máa ń nàgà síbi tọ́wọ́ òun ò lè tó, níléèwé àti nínú ilé. Ó gbà pé iṣẹ́ òun gbọ́dọ̀ gún régé ṣáá ni, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ àwọn èèyàn ò ní gba tòun. Láfikún sí i, nígbà míì Tânia máa ń retí káwọn èèyàn ṣe kọjá agbára wọn, èyí sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ bá a.Òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn tóótun, kó jẹ́ aláápọn, kí iṣẹ́ ọwọ́ ẹni sì tẹ́ni lọ́rùn, ṣùgbọ́n àwọn èrò òdì, bíi ìbẹ̀rù pé kéèyàn má lọ fìdí rẹmi, lè jẹ́ kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn góńgó àléèbá kalẹ̀. Àwọn òbí tàbí àwọn mìíràn lè gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé kalẹ̀ nínú iṣẹ́ iléèwé tàbí nínú eré ìdárayá tó máa nira fún àwọn ọ̀dọ́ láti lé bá. Fún àpẹẹrẹ, màmá Ricardo fẹ́ kó di ọ̀kan ṣoṣo àràbà, ó fẹ́ kó di dókítà, kó mọ dùùrù tẹ̀, ó tún fẹ́ kó lè sọ èdè púpọ̀. Ǹjẹ́ ìwọ náà ò rí i pé ó lè di ìṣòro ńlá, tàbí kó yọrí sí ìjákulẹ̀, tó bá jẹ́ pé ohun àléèbá ni wọ́n ní kéèyàn máa sáré lé?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Yàgò fún Ẹ̀mí Ìṣefínnífínní Dóríi Bíńtín?
Àgbà iṣẹ́, tó gún régé, tó ti lọ wà jù, làwọn èèyàn ń fẹ́. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kò lè ṣe kí ìbára-ẹni-díje máà sí lẹ́nu iṣẹ́. Nǹkan míì tó tún ń fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń forí fọrùn ṣe ni kí ọ̀nà àtijẹ-àtimu wọn má bàa dí. Àwọn òṣìṣẹ́ kan dà bí eléré ìdárayá tó ń tiraka kí òun lè ṣe ohun tuntun tí eléré mìíràn ò ṣe rí. Fún ìdí yìí, nígbà tí ìdíje ọ̀hún bá wá le dójú ẹ̀, á túbọ̀ máa dára yá, ó tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn oògùn olóró táa mú kí iṣan rẹ̀ le tantan, kí agbára rẹ̀ lè pọ̀ sí i, kí ó sì lè borí. Dípò kí ó jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn ń sapá lọ́nà tó tọ́ láti gbégbá orókè, ó lè wá jẹ́ pé ẹ̀mí ìṣefínnífínní dóríi bíńtín ló ń mú kí wọ́n di ẹni tí “ìbẹ̀rù fífìdírẹmi ń sún ṣiṣẹ́” tàbí nítorí “fífẹ́ láti di ọ̀kan ṣoṣo àràbà.”—The Feeling Good Handbook.
Àwọn kan sọ pé ìtẹ̀síwájú ò lópin nínú iṣẹ́ ọwọ́ tàbí nínú eré ìdárayá, a ò sì jiyàn ìyẹn. Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bí Dókítà Robert S. Elliot ti wí, “àlá tí kò lè ṣẹ láéláé ni pé kéèyàn máa retí pé òun lè ṣe fínnífínní dóríi bíńtín.” Ó fi kún un pé: “Ohun tó wà nínú rẹ̀ ò ju ẹ̀bi, àwíjàre, àti àìfẹ́ dẹni tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́.” Àbí ẹ ò wá rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì, pé: “Èmi alára sì ti rí gbogbo iṣẹ́ àṣekára àti gbogbo ìgbóṣáṣá nínú iṣẹ́, pé ó túmọ̀ sí bíbá ẹnì kìíní-kejì díje; asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:4.
Kí lo lè ṣe tó bá jọ pé ìwọ náà ti fẹ́ di aṣefínnífínní dóríi bíńtín? Ǹjẹ́ o ò gbà pé ká ṣiṣẹ́ bí ẹrú ò da nǹkan? Ǹjẹ́ o lè dín bí o ṣe ń rinkinkin kù, kí o sì yéé fi ayé ni ara rẹ lára? Kí ni ìjẹ́pípé túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ o máa ń yán hànhàn láti lo agbára rẹ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, láìṣe fínnífínní dóríi bíńtín? Bí ẹ̀dá aláìpé bá lè lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi ṣàwárí àwọn nǹkan tó lè ṣàǹfààní fún àwọn ẹlòmíì, sáà ronú ohun tọ́mọ aráyé yóò gbé ṣe lábẹ́ ipò pípé àti lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn òbí àtàwọn mìíràn lè máa béèrè kéèyàn ṣe nǹkan fínnífínní dóríi bíńtín, èyí tí apá àwọn ọ̀dọ́ ò lè ká