Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba oògùn èyíkéyìí tí a mú jáde láti inú ẹ̀jẹ̀?

Ìdáhùn rẹ̀ gan-an ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba ẹ̀jẹ̀. A gbà gbọ́ tọkàntọkàn pé òfin Ọlọ́run lórí ẹ̀jẹ̀ kì í ṣe èyí tí à ń yí padà kó lè bá àwọn èrò tó ń yí padà mu. Àmọ́, àwọn kókó tuntun ti ń yọjú nítorí pé wọ́n ti ń ṣe àtúpalẹ̀ ẹ̀jẹ̀ sí àwọn èròjà ìpìlẹ̀ mẹ́rin àti sí àwọn apá kéékèèké tí èròjà wọ̀nyẹn ní báyìí. Nígbà tí Kristẹni kan bá ń ronú lórí bóyá kí òun gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó ní láti wò ré kọjá àwọn àǹfààní àti ewu tó lè wà nínú gbígba irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀. Ohun tó gbọ́dọ̀ ká a lára jù lọ ni ohun tí Bíbélì sọ àti ipa tó lè ní lórí ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Olódùmarè.

Àwọn kókó pàtàkì wọ̀nyí ò fi bẹ́ẹ̀ le. Ká lè rí ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì yẹ̀ wò, ká tún yẹ ìtàn wò àti ọ̀rọ̀ lórí ìṣègùn pẹ̀lú.

Jèhófà Ọlọ́run sọ fún Nóà tó jẹ́ baba ńlá gbogbo wa pé ó gbọ́dọ̀ ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun pàtàkì. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Lẹ́yìn náà, òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi bí ẹ̀jẹ̀ ṣe jẹ́ mímọ́ tó hàn: “Ní ti ọkùnrin èyíkéyìí ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àtìpó kan . . . tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí, dájúdájú, èmi yóò dojú mi kọ ọkàn tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀.” Bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá kọ òfin Ọlọ́run sílẹ̀, ó lè kó àbàwọ́n bá àwọn tó kù; ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi fi kún un pé: “Ní tòótọ́, èmi yóò sì ké e kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Léfítíkù 17:10) Lẹ́yìn náà, ní ìpàdé kan ní Jerúsálẹ́mù, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin pàṣẹ pé a gbọ́dọ̀ ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an bíi yíyẹra fún ìwà pálapàla takọtabo àti ìbọ̀rìṣà ṣe ṣe pàtàkì.—Ìṣe 15:28, 29.

Kí ni ‘títa kété’ ì bá ti túmọ̀ sí nígbà yẹn lọ́hùn-ún? Àwọn Kristẹni kì í jẹ ẹ̀jẹ̀, yálà ẹ̀jẹ̀ tútù tàbí ẹ̀jẹ̀ dídì; bẹ́ẹ̀ náà ni wọn kì í jẹ ẹran tó wá láti ara ẹranko tí a kò da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde. Ohun mìíràn tí wọ́n gbọ́dọ̀ sá fún ni àwọn oúnjẹ tó ní ẹ̀jẹ̀ nínú, bíi sọ́séèjì ẹlẹ́jẹ̀. Gbígba ẹ̀jẹ̀ sára ní èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà wọ̀nyẹn yóò rú òfin Ọlọ́run.—1 Sámúẹ́lì 14:32, 33.

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ìgbàanì ni kò ní kọminú sí ọ̀ràn jíjẹ ẹ̀jẹ̀, báa ṣe lè rí i nínú àwọn ohun tí Tertullian kọ (ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Tiwa). Nígbà tí Tertullian ń fèsì ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kan àwọn Kristẹni pé wọ́n ń jẹ ẹ̀jẹ̀, ó mẹ́nu kan àwọn ẹ̀yà tó máa ń tọ́ ẹ̀jẹ̀ lá nígbà tí wọ́n bá ń mulẹ̀. Ó tún kíyè sí i pé “nígbà tí eré bá ń lọ lọ́wọ́ nínú pápá ìwòran, [àwọn kan] tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ máa ń sáré gba ẹ̀jẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dà jáde lára àwọn ọ̀daràn . . . láti fi wo àrùn wárápá tó ń ṣe wọ́n sàn.”

Irú àwọn àṣà wọ̀nyẹn (kódà bí àwọn ará Róòmù tiẹ̀ lò ó fún ìlera) lòdì lójú àwọn Kristẹni, Tertullian kọ̀wé pé: “A kì í fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko pàápàá sínú oúnjẹ wa.” Àwọn ará Róòmù lo oúnjẹ tó ní ẹ̀jẹ̀ nínú láti dán ìwà títọ́ àwọn ojúlówó Kristẹni wò. Tertullian fi kún un pé: “Wàyí o, mò ń bi yín pé, kí ló mú kí ẹ ronú pé [àwọn Kristẹni] á kù gìrì mọ́ ẹ̀jẹ̀ ènìyàn, nígbà tó dá yín lójú pé wọn ò tiẹ̀ lè gbà láé kí ẹ̀jẹ̀ ẹranko kàn wọ́n lẹ́nu?”

Lónìí, àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa ronú pé ó kan òfin Ọlọ́run Olódùmarè nígbà tí oníṣègùn kan bá dámọ̀ràn pé kí wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ sára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fẹ́ kú, síbẹ̀ ó di dandan fún wa láti ṣègbọràn sí òfin Jèhófà lórí ẹ̀jẹ̀. Kí ni èyí wá túmọ̀ sí tí a bá fojú iṣẹ́ ìṣègùn ti lọ́ọ́lọ́ọ́ wò ó?

Bí fífa gbogbo èròjà inú ẹ̀jẹ̀ síni lára ṣe wá di ohun tó wọ́pọ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé èyí lòdì sí òfin Ọlọ́run—ìgbàgbọ́ wa sì nìyẹn títí di ìsinsìnyí. Àmọ́, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ ni iṣẹ́ ìṣègùn ń yí padà. Lónìí, kì í ṣe ògidì ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń fà síni lára, bí kò ṣe ọ̀kan lára àwọn èròjà tó pilẹ̀ rẹ̀: ìyẹn ni (1) sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀; (2) sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀; (3) sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀; (4) omi inú ẹ̀jẹ̀ (aporó), apá tó jẹ́ omi. Nípa wíwo ipò tí aláìsàn náà wà, àwọn oníṣègùn lè yan sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pẹlẹbẹ, tàbí omi inú ẹ̀jẹ̀. Fífa àwọn èròjà pàtàkì inú ẹ̀jẹ̀ wọ̀nyí síni lára ń fàyè gba kí wọ́n pín àpò ẹ̀jẹ̀ kan ṣoṣo sára àwọn aláìsàn púpọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé gbígba ògidì ẹ̀jẹ̀ tàbí èyíkéyìí lára àwọn èròjà ìpìlẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyẹn sára jẹ́ rírú òfin Ọlọ́run. Ní pàtàkì, pípa àṣẹ inú Bíbélì yìí mọ́ ti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ewu púpọ̀, títí kan àwọn àrùn bí àrùn mẹ́dọ̀wú àti àrùn éèdì, tí àwọn èèyàn máa ń kó látinú ẹ̀jẹ̀.

Àmọ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé wọ́n lè ya àwọn èròjà tó pilẹ̀ ẹ̀jẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn ìbéèrè wá dìde lórí àwọn èròjà kéékèèké tí wọ́n wá mú jáde látinú àwọn èròjà tó pilẹ̀ ẹ̀jẹ̀. Kí ni wọ́n ń lo àwọn èròjà kéékèèké wọ̀nyẹn fún, kí ló sì yẹ kí Kristẹni gbé yẹ̀ wò nígbà tó bá ń ṣe ìpinnu?

Èròjà inú ẹ̀jẹ̀ pọ̀ gan an. Kódà omi inú ẹ̀jẹ̀—tó jẹ́ pé ìpín àádọ́rùn-ún rẹ̀ ló jẹ́ omi—ní àìmọye àwọn omi ìsúnniṣe inú ara, àwọn iyọ̀ oníkẹ́míkà, àwọn èròjà tí ń mú kí oúnjẹ dà, àti àwọn èròjà aṣaralóore, títí kan èròjà mineral àti ṣúgà. Omi inú ẹ̀jẹ̀ tún ní àwọn èròjà protein bíi albumin, àwọn èròjà tí ń mú kí ẹ̀jẹ̀ dì, àti èròjà agbógunti àrùn. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti ya ọ̀pọ̀ èròjà protein tó wà nínú omi inú ẹ̀jẹ̀ sọ́tọ̀, wọ́n sì ti lò ó. Fún àpẹẹrẹ, àwọn èròjà tí ń mú kí ẹ̀jẹ̀ dì tí a ń pè ní factor V111 ni wọ́n ti lò fún àwọn alárùn àsun-ùndá-ẹ̀jẹ̀, tí ẹ̀jẹ̀ kì í pẹ́ dà lára wọn. Tàbí tí ẹnì kan bá wà níbi tí àwọn àrùn kan pọ̀ sí, dókítà lè sọ pé kí wọ́n gún wọ́n lábẹ́rẹ́ gamma globulin, tí wọ́n gbà láti inú omi inú ẹ̀jẹ̀ àwọn tó ní èròjà tí ń gbógun ti àrùn náà. Wọ́n tún máa ń lo àwọn protein omi inú ẹ̀jẹ̀ mìíràn fún ìṣègùn, àmọ́ ohun tí a sọ lókè yìí ń ṣàpèjúwe bí àwọn èròjà tó pilẹ̀ ẹ̀jẹ̀ (omi inú ẹ̀jẹ̀) ṣe lè di ohun tí a tú palẹ̀ láti mú àwọn èròjà kéékèèké jáde látinú wọn. a

Bó ṣe jẹ́ pé omi inú ẹ̀jẹ̀ lè jẹ́ orísun onírúurú èròjà kéékèèké tó wà nínú ẹ̀jẹ̀, wọ́n tún lè ṣe àtúpalẹ̀ àwọn èròjà ìpìlẹ̀ mìíràn (bíi sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pẹlẹbẹ) láti mú àwọn èròjà kéékèèké mìíràn jáde. Fún àpẹẹrẹ, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ lè jẹ́ orísun interferons àti interleukins, tí wọ́n fi ń tọ́jú àwọn àrùn tí fáírọ́ọ̀sì ń kó ranni àti àrùn jẹjẹrẹ. Wọ́n lè ṣe àtúpalẹ̀ àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pẹlẹbẹ láti mú àwọn èròjà tó ń wo egbò sàn jáde. Wọ́n tún ti ń ṣe àwọn egbòogi mìíràn tó ní (ó kéré tán níbẹ̀rẹ̀) àwọn ohun tí a yọ láti inú àwọn èròjà inú ẹ̀jẹ̀ nínú. Irú àwọn ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ kì í ṣe fífa àwọn èròjà ìpìlẹ̀ síni lára; kìkì àwọn apá kan tàbí àwọn ìpín kéékèèké àwọn èròjà wọ̀nyẹn ni wọ́n sábà máa ń lò. Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn Kristẹni gba àwọn ìpín kéékèèké wọ̀nyí nínú ìtọ́jú ìṣègùn? A ò lè sọ. Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀, nítorí ìdí èyí, Kristẹni kan ni yóò ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu níwájú Ọlọ́run.

Àwọn kan lè kọ ohunkóhun tí wọ́n bá mú jáde láti inú ẹ̀jẹ̀ (kódà àwọn ìpín kéékèèké tó wà fún pípèsè ìgbógunti àrùn fún ìgbà kúkúrú). Bí wọ́n ṣe lóye àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé kí á ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀’ nìyẹn. Wọ́n ronú pé òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì béèrè pé ẹ̀jẹ̀ ẹranko èyíkéyìí tí wọ́n bá pa ni wọ́n gbọ́dọ̀ ‘dà jáde sórí ilẹ̀.’ (Diutarónómì 12:22-24) Èé ṣe tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Ó dára, tí wọ́n bá fẹ́ ṣe gamma globulin, àwọn èròjà amẹ́jẹ̀dì tí wọ́n mú jáde láti inú ẹ̀jẹ̀, àti àwọn bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, yóò béèrè pé kí wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ kí wọ́n sì tú u palẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àwọn Kristẹni kan fi kọ̀ láti gba irú àwọn ìtọ́jú bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe kọ̀ láti gba ògidì ẹ̀jẹ̀ tàbí àwọn èròjà mẹ́rin tó pilẹ̀ rẹ̀ sára. Ó yẹ kí a bọ̀wọ̀ fún ìdúró àìlábòsí tí ẹ̀rí ọkàn wọn jẹ́ kí wọ́n mú yìí.

Àwọn Kristẹni mìíràn ń ṣe ìpinnu tó yàtọ̀. Àwọn náà ń kọ̀ láti gba ògidì ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀, tàbí omi inú ẹ̀jẹ̀ sára. Àmọ́, wọ́n lè gbà kí oníṣègùn fi àwọn èròjà kéékèèké tí a yọ lára àwọn èròjà ìpìlẹ̀ ṣe ìtọ́jú wọn. Kódà ìyàtọ̀ tún lè wà níhìn-ín pàápàá. Kristẹni kan lè gba abẹ́rẹ́ gamma globulin, ṣùgbọ́n ó lè gbà tàbí kí ó kọ̀ láti gba abẹ́rẹ́ tí ó ní ohun kan tí a yọ láti inú sẹ́ẹ̀lì pupa tàbí sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ nínú. Àmọ́ ṣá o, ní paríparí rẹ̀, kí ló lè sún àwọn Kristẹni kan parí èrò sí pé àwọn lè gba àwọn èròjà kéékèèké tó wá látinú ẹ̀jẹ̀?

“Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́nà ti June 1, 1990, ṣàlàyé pé èròjà protein (àwọn ìpín kéékèèké) máa ń ti inú ẹ̀jẹ̀ aboyún lọ sínú ẹ̀jẹ̀ ọlẹ̀ inú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ìyá ló máa ń tàtaré àwọn èròjà immunoglobulin sínú ọmọ rẹ̀, tí yóò jẹ́ kí ọmọ náà ní èròjà tí ń gbógun ti àrùn lára. Ní àyè ọ̀tọ̀ pátápátá, bí àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ọmọ inú ọlẹ̀ ṣe ń lo àkókò rẹ̀ tán ni apá ibi tó ń gbé afẹ́fẹ́ oxygen kiri á wá di àtúpalẹ̀. Apá kan lára rẹ̀ yóò di èròjà bilirubin, tí yóò gba inú ibi ọmọ lọ sára ìyá rẹ̀ tí yóò sì wá bá ìdọ̀tí ara ìyá náà jáde. Àwọn Kristẹni kan lè parí èrò sí pé níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwọn èròjà kéékèèké inú ẹ̀jẹ̀ lè ti ara ẹnì kan lọ sí ti ẹnì kejì lọ́nà àdánidá bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn lè gba àwọn èròjà kéékèèké inú ẹ̀jẹ̀ tí a mú jáde látinú omi inú ẹ̀jẹ̀ tàbí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ nìyẹn.

Ǹjẹ́ kókó náà pé èrò àti àwọn ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù mu lè yàtọ̀ síra túmọ̀ sí pé kókó náà ò ṣe pàtàkì? Rárá o. Ó ṣe pàtàkì. Síbẹ̀, kókó kan fara hàn kedere. Ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbà kí a fa ògidì ẹ̀jẹ̀ tàbí àwọn èròjà tó pilẹ̀ rẹ̀ sí wọn lára. Bíbélì pàṣẹ fún àwọn Kristẹni láti ‘ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí àgbèrè.’ (Ìṣe 15:29) Yàtọ̀ sí ìyẹn, nígbà tó bá di ọ̀ràn èyíkéyìí lára àwọn ìpín kéékèèké àwọn èròjà tó pilẹ̀ ẹ̀jẹ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló gbọ́dọ̀ fúnra rẹ̀ ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu lẹ́yìn tó bá ti fi ìṣọ́ra gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò fẹ́ gba ìtọ́jú èyíkéyìí tó bá lè ṣe wọ́n láǹfààní ojú ẹsẹ̀, kódà àwọn ìtọ́jú táa mọ̀ pé wọ́n lè fa àìsàn síni lára pàápàá, bíi lílo àwọn ohun tí a mú jáde láti inú ẹ̀jẹ̀. Kristẹni olóòótọ́ inú yóò tiraka láti ní èrò tó gbòòrò, tó sì túbọ̀ jẹ́ èyí tí kò fì síbì kan, tó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ju ìlera ara nìkan lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọrírì ìtọ́jú ìṣègùn tó jẹ́ ojúlówó, wọ́n sì máa ń gbé ewu àti àǹfààní tó wà nínú ìtọ́jú èyíkéyìí yẹ̀ wò. Àmọ́ ṣá o, nígbà tó bá di ọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a mú jáde láti inú ẹ̀jẹ̀, wọ́n máa ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra gbé ohun tí Ọlọ́run sọ àti ìbátan tiwọn fúnra wọn pẹ̀lú Olùfúnni-Ní-Ìyè wa yẹ̀ wò.—Sáàmù 36:9.

Ẹ wo irú ìbùkún ńlá tí ó jẹ́ fún Kristẹni kan láti ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé tí onísáàmù náà ní, ẹni tó kọ̀wé pé: “Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ oòrùn àti apata; ojú rere àti ògo ni ó ń fi fúnni. Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù. Jèhófà . . . , aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ”!—Sáàmù 84:11, 12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ile-Iṣọ Na January 1, 1979, àti ti October 1, 1994. Àwọn ilé iṣẹ́ ìpoògùn ti mú àwọn èròjà àtọwọ́dá kan jáde báyìí tí wọn kò fi ẹ̀jẹ̀ ṣe, wọ́n sì lè sọ pé kéèyàn lo ìyẹn dípò àwọn èròjà kéékèèké látinú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÍ O LÈ BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ DÓKÍTÀ

Bí o bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ tàbí tí o fẹ́ gba ìtọ́jú tó lè ní èròjà inú ẹ̀jẹ̀ nínú, béèrè pé:

Ǹjẹ́ gbogbo àwọn oníṣègùn tí ọ̀ràn kàn ló mọ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sọ pé kí a má ṣe fa ẹ̀jẹ̀ sí mi lára (ì báà jẹ́ ògidì ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀, tàbí omi inú ẹ̀jẹ̀) nínú ipòkípò tí mo bá wà?

Bí oògùn èyíkéyìí tí wọ́n bá sọ pé kí o lò yóò bá jẹ́ èyí tí a mú jáde láti inú omi inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pupa tàbí funfun inú ẹ̀jẹ̀, béèrè pé:

Ṣé inú ọ̀kan lára àwọn èròjà mẹ́rin tí ó pilẹ̀ ẹ̀jẹ̀ la ti mú oògùn náà jáde? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ṣe é?

Báwo ni èyí tí ẹ fẹ́ kí n lò nínú oògùn tí a mú jáde láti inú ẹ̀jẹ̀ yìí ṣe pọ̀ tó, báwo sì ni màá ṣe lò ó?

Bí ẹ̀rí ọkàn mi bá gbà mí láyè láti lo ìpín yìí, kí ni àwọn ewu tó wà níbẹ̀?

Bí ẹ̀rí ọkàn mí bá mú kí n kọ ìpín yìí, ìtọ́jú mìíràn wo ni mo lè rí gbà?

Lẹ́yìn tí mo bá túbọ̀ gbé ọ̀ràn yìí yẹ̀ wò, ìgbà wo ni mo lè wá sọ ìpinnu mi fún ọ?