Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwàláàyè Pípé Kì Í Màá Ṣe Àlá Lásán!

Ìwàláàyè Pípé Kì Í Màá Ṣe Àlá Lásán!

Ìwàláàyè Pípé Kì Í Màá Ṣe Àlá Lásán!

Ayé kan tí ó jẹ́ pípé—kí ló túmọ̀ sí fún ọ? Sáà fojú inú wo àwùjọ kan tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn, ìjoògùnyó, ìyàn, ipò òṣì, tàbí ìwà ìrẹ́nijẹ. Ara gbogbo èèyàn le, orí wọ́n sì pé. Kò sí ìsoríkọ́ tàbí ìbànújẹ́ nítorí a ti mú ikú pàápàá kúrò. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti yán hànhàn fún irú ayé bẹ́ẹ̀?

BÓ TIẸ̀ jẹ́ pé a ò lè gbójú fo onírúurú itú táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti onímọ̀ ẹ̀rọ ń pa, síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ni kò gbà gbọ́ pé lóòótọ́ ni làákàyè àti ìmọ̀ ẹ̀dá lè mú ayé kan tí ó jẹ́ pípé wá, ayé tí gbogbo ẹ̀dá yóò ti máa gbé ní àlàáfíà àti ayọ̀. Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, kò ṣeé sẹ́ pé ìtẹ̀sí ẹ̀dá ni láti mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i, kí wọ́n sì tún àwọn ohun tí kò dúró déédéé ṣe. Àmọ́ ṣá o, wíwulẹ̀ máa lé góńgó tó jẹ́ àléèbá kò lè ṣàǹfààní fáwọn tí kò rílé gbé, àtàwọn òtòṣì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè yanjú ìṣòro àwọn aláàbọ̀ ara àtàwọn aláìsàn, tí wọ́n ń fẹ́ ìtura kúrò nínú ìroragógó wọn. Ayé tó jẹ́ pípé kò tiẹ̀ lè tọwọ́ ènìyàn wá ni. Ṣùgbọ́n, láìka ìṣẹ́ àti ìnira òde òní sí, ìdí gúnmọ́ wà láti gbà gbọ́ pé ayé kan tí o lè pè ní pípé ti sún mọ́lé lóòótọ́.

Tóo bá ronú nípa ìwàláàyè pípé, ìwàláàyè Jésù Kristi lè wá sí ẹ lọ́kàn. Jésù nìkan kọ́ ni ènìyàn pípé tó tíì gbé ilẹ̀ ayé rí. Ádámù àti Éfà, táa dá ní àwòrán Ọlọ́run, gbádùn ìwàláàyè pípé nínú párádísè kan. Ṣùgbọ́n wọ́n pàdánù ipò tó pinmirin yẹn nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Baba wọn ọ̀run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Síbẹ̀síbẹ̀, Ẹlẹ́dàá fi ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sínú ọkàn ènìyàn. Oníwàásù 3:11 jẹ́rìí sí èyí, ó ní: “Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀. Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ sọ ìwàláàyè aráyé di “ìmúlẹ̀mófo,” tó sì fa “ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,” síbẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, ó ní: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:19-21) Bíbélì mú un ṣe kedere pé àwọn ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe fún mímú ìwàláàyè pípé ènìyàn bọ̀ sípò yóò dé nípasẹ̀ Jésù Kristi.—Jòhánù 3:16; 17:3.

Láfikún sí ìrètí àgbàyanu yìí fún ọjọ́ iwájú, gbogbo wa la ní àǹfààní láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ìtẹ̀síwájú ọ̀hún sì ṣeé ṣe, kódà lákòókò táa wà yìí.

Gbìyànjú Láti Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì

Jésù Kristi ka ọ̀ràn ìjẹ́pípé sí pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi sọ fún àwùjọ ńlá kan pé: “Kí ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.” (Mátíù 5:48) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìní àléébù kankan nínú ètò burúkú ìsinsìnyí? Rárá o. Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ làkàkà láti ní àwọn ànímọ́ bí ìwà ọ̀làwọ́, inú rere, àti ìfẹ́ fún ọmọnìkejì wa, síbẹ̀síbẹ̀ àìmọye ìgbà la máa ń kùnà láti ṣe ohun tó tọ́. Kódà, ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù kọ̀wé pé: “Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tí yóò sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo. Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Àwa kò dẹ́ṣẹ̀,’ a ń sọ ọ́ di òpùrọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa.”—1 Jòhánù 1:9, 10.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a lè tún ojú táa fi ń wo ara wa àti ìṣesí wa sáwọn ẹlòmíì ṣe, ká máa yẹra fún àṣejù. Ta ló mọ ọ̀nà mìíràn tó tún dáa ju èyí tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, táa lè gbà ní àkópọ̀ ìwà tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó sì bọ́gbọ́n mu? Mímú irú àwọn ànímọ́ bí ayọ̀ àti wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì dàgbà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn níbi iṣẹ́, pẹ̀lú ọkọ tàbí aya wa, àti pẹ̀lú àwọn òbí àtàwọn ọmọ wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀! Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”—Fílípì 4:4, 5.

Àwọn Àǹfààní Wíwà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì

Nígbà tóo bá wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ohun tóo ń retí látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, tóo sì yàgò fún ẹ̀mí ìṣefínnífínní dóríi bíńtín tó máa ń fa ìdára-ẹni-lóró àti ìpara-ẹni-láyò, wàá ṣe ara rẹ àtàwọn ẹlòmíì láǹfààní. Mímọ̀wọ̀n ara rẹ wé mọ́ ṣíṣàì tan ara rẹ jẹ àti wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ohun tóo bá fẹ́ ṣe. Rántí pé Ọlọ́run dá wa kí a lè máa gbé orí ilẹ̀ ayé, kí a sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ tó gbámúṣé tí yóò ṣàǹfààní fún àwa àtàwọn ẹlòmíràn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9.

Bóo bá ti ń fi ayé ni ara rẹ lára tẹ́lẹ̀, kí ló dé tí o ò tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà? Rírí ojú rere Ọlọ́run yóò fún ẹ ní ìtura ńláǹlà. Jèhófà mọ ẹ̀dá wa àti ipò àìpé wa, nítorí náà kì í ṣe aláìgbatẹnirò, kò sì ṣòroó tẹ́ lọ́rùn. Onísáàmù náà mú un dá wa lójú pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:13, 14) A mà láyọ̀ o, pé Ọlọ́run ń ṣíjú àánú rẹ̀ wò wá! Ó mọ ibi tágbára wa mọ, síbẹ̀síbẹ̀ a ṣeyebíye lójú rẹ̀, bí ọmọ ọ̀wọ́n.

Dípò ṣíṣe fínnífínní dóríi bíńtín, ẹ wo bó ti lọ́gbọ́n nínú tó láti mú ìfòyemọ̀ tẹ̀mí dàgbà, ká sì ní ojú ìwòye tó wà déédéé! Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó dá wa lójú pé kò sẹ́ni tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti má ṣe mú ète rẹ̀ ṣẹ láti gbé aráyé ga dé ipò ìjẹ́pípé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kí ni ìjẹ́pípé ènìyàn túmọ̀ sí?

Ìwàláàyè Pípé Dára Ju Ìṣefínnífínní Dóríi Bíńtín

Ìjẹ́pípé kò túmọ̀ sí ìṣefínnífínní dóríi bíńtín. Ó dájú pé àwọn tó máa láǹfààní láti gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kò ní jẹ́ àwọn tí kò ṣeé tẹ́ lọ́rùn, àwọn olódodo àṣelékè. Ọ̀kan lára ohun táa gbọ́dọ̀ ṣe táa bá fẹ́ la ìpọ́njú ńlá já ni pé ká ní ìmọrírì àtọkànwá fún ẹbọ ìràpadà náà, kí ó jẹ́ irú ìmọrírì tí ogunlọ́gọ̀ ńlá tó wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè fi hàn, èyí tí àpọ́sítélì Jòhánù ṣàpèjúwe rẹ̀ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.” (Ìṣípayá 7:9, 10, 14) Gbogbo àwọn tó bá la ìpọ́njú ńlá yìí já yóò dúpẹ́ pé Kristi yọ̀ǹda ẹ̀mí rẹ̀ fún wọn àti fún gbogbo àwọn tó gbà á gbọ́. Ẹbọ tó fìfẹ́ rú ló jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ní ìrètí ìtura títí láé kúrò lọ́wọ́ àìpé àti àìlera wọn.—Jòhánù 3:16; Róòmù 8:21, 22.

Báwo ni ìwàláàyè pípé yóò ṣe rí? Dípò ìdíje àti ìwà ànìkànjọpọ́n, ìfẹ́ àti inú rere láàárín ọmọ aráyé yóò jẹ́ kí ayé dùn-ún gbé, kò ní sí hílàhílo àti ríro ara ẹni pin mọ́. Ṣùgbọ́n ìwàláàyè pípé kò ní súni, kò ní gọ́ni. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Párádísè, ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé irú ìgbésí ayé táa lè máa retí, ó ní: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu.”—Aísáyà 65:21-23.

Kàkà tí à bá fi máa ronú nípa irú eré ìnàjú, ohun èlò, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, tàbí ohun ìrìnnà tí a óò máa lò nínú Ìjọba náà, fojú inú wo ara rẹ bí o ti ń gbádùn ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “‘Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn pàápàá yóò máa jùmọ̀ jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù; àti ní ti ejò, oúnjẹ rẹ̀ yóò jẹ́ ekuru. Wọn kì yóò ṣe ìpalára kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi,’ ni Jèhófà wí.” (Aísáyà 65:25) Ẹ wo bí ìwàláàyè pípé yóò ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ìwàláàyè tó wà lónìí! Bí o bá wà lára àwọn tí a ó kà sẹ́ni yíyẹ láti wà láàyè ní àkókò yẹn, ọkàn rẹ yóò balẹ̀ dáadáa pé Baba rẹ ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò máa wá ire tìrẹ àti ti ìdílé rẹ. “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”—Sáàmù 37:4.

Ìwàláàyè pípé kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ. Ète onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní fún aráyé yóò ṣẹ délẹ̀délẹ̀. Ìwọ àti ìdílé rẹ lè wà lára àwọn tí a óò gbé ga dé ìjẹ́pípé, tí wọn yóò sì wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

A lè tún ojú ìwòye wa nípa ara wa àtàwọn ẹlòmíì ṣe, nípa yíyàgò fún ṣíṣefínnífínní dóríi bíńtín tàbí ṣíṣe ọ̀rínkinniwín

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

O ò ṣe máa fojú inú wò ara rẹ bíi pé o ti ń gbádùn àwọn ipò àlàáfíà àti òdodo inú Párádísè ná?