Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Rọ Kíláàsì Kejìdínláàádọ́fà Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead Láti Máa Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀

A Rọ Kíláàsì Kejìdínláàádọ́fà Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead Láti Máa Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀

A Rọ Kíláàsì Kejìdínláàádọ́fà Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead Láti Máa Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀

BÍBÉLÌ máa ń lo gbólóhùn náà “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” fún ìjọsìn Ọlọ́run. Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó tọ́ka sí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọ́run. (Róòmù 9:4) Àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìlélọ́gọ́ta [5,562] tó fetí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kejìdínláàádọ́fà ti Watchtower Bible School of Gilead gbọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu àwọn alásọyé tó pèsè ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tí yóò ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Jèhófà Ọlọ́run. a

Theodore Jaracz, tí í ṣe mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ni alága. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin ìkejìléláàádọ́ta, “Orukọ Baba Wa.” Ìlà kejì orin náà sọ pé: “Ka bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ ailẹgbẹ l’awa nlepa.” Èyí gan-an sì ni ìfẹ́ àtọkànwá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà (àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́wàá), wọ́n fẹ́ lọ lo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí gbà nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn fún wọn, èyí tí wọn ó ṣe ní ilẹ̀ mẹ́tàdínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a yàn wọ́n sí.

Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, Arákùnrin Jaracz pe àfiyèsí sí ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti gbà fún oṣù márùn-ún gbáko, èyí tó múra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “wádìí ohun gbogbo dájú,” èyíinì ni, láti fi ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe àyẹ̀wò ohun tí wọ́n ti kọ́ tẹ́lẹ̀ fínnífínní, kí wọ́n sì wá “di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti iṣẹ́ tí a tìtorí rẹ̀ dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Kí ni yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo èyí?

Ìmọ̀ràn Tó Gbéṣẹ́ fún Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀

Lon Schilling, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ìlọgeere Iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì, sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Ìwọ Yóò Ha Yege Nínú Ìdánwò Ìfòyebánilò Bí?” Ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ afòyebánilò, èyí tí ń fi hàn pé èèyàn ní ọgbọ́n tí ó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 3:17) Ìfòyebánilò wé mọ́ ṣíṣàìrinkinkin jù, àìṣe ojúsàájú, wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, gbígbatẹnirò, àti níní ìforítì. Arákùnrin Schilling sọ pé: “Àwọn èèyàn tí ń fòye báni lò máa ń wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Wọn kì í ṣàṣejù.” Kí ló lè ran míṣọ́nnárì kan lọ́wọ́ láti jẹ́ afòyebánilò? Níní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ara ẹni, lílo àǹfààní tí a ní láti fetí sí àwọn ẹlòmíràn àti láti kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn lọ́nà rere, àti mímúra tán láti gbé èrò àwọn ẹlòmíràn yẹ̀ wò láìfi àwọn ìlànà Ọlọ́run báni dọ́rẹ̀ẹ́.—1 Kọ́ríńtì 9:19-23.

“Ẹ Má Ṣe Gbàgbé Láti Máa Jẹun!” ni àkòrí gbígbàfiyèsí tó tẹ̀ lé e nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, Samuel Herd, tí òun náà jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ló sọ àsọyé yìí. Ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì jíjẹun tó dáa nípa tẹ̀mí déédéé, kí èèyàn lè lókun láti máa bá iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nìṣó. Arákùnrin Herd sọ pé: “Ìgbòkègbodò yín nípa tẹ̀mí yóò pọ̀ sí i láìpẹ́ bí ẹ ti kó wọnú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí a yàn fún yín. Nítorí náà, yóò pọndandan pé kí ẹ fi kún iye oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹ̀ ń jẹ, kí okun yín lè wà ní ìwọ̀n déédéé, kí ó má sì dín kù.” Jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé lè ran míṣọ́nnárì lọ́wọ́ láti yẹra fún ìsoríkọ́ nípa tẹ̀mí, kí àárò ilé má sì máa sọ ọ́. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn àti ìpinnu láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ tí a yàn fún olúwarẹ̀ lọ láìjáwọ́ ńbẹ̀.—Fílípì 4:13.

Lawrence Bowen, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead, rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ yege pé kí wọ́n “Padà sí Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” Kí ló ní lọ́kàn? Ó ní kí gbogbo àwùjọ ṣí ìwé Òwe orí kìíní ẹsẹ keje, tó kà pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé: “Ohunkóhun tó bá tàbùkù sí òtítọ́ àtayébáyé náà nípa wíwà Jèhófà kì í ṣe ojúlówó ìmọ̀ rárá, kò sì lè yọrí sí òye tí ó tọ́.” Arákùnrin Bowen fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wé àwòrán tí a gé kélekèle tó dà bí àdììtú. Nígbà táa bá tò wọ́n pa pọ̀ tán, á wá di odindi àwòrán kan. Bí àwọn ẹ̀yà rẹ̀ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni àwòrán náà yóò ṣe tóbi tó, tí yóò sì ṣe kedere tó, bẹ́ẹ̀ náà tún ni èèyàn ṣe máa mọyì rẹ̀ tó. Èyí lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ sí Ọlọ́run.

Wallace Liverance, tó ń forúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, ló kásẹ̀ ọ̀wọ́ àwọn àsọyé wọ̀nyí nílẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí òun sọ̀rọ̀ lé lórí ni “Ẹ Máa Rú Ẹbọ Ọpẹ́ sí Ọlọ́run.” Ó pe àfiyèsí sí ìtàn àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá tí Jésù wò sàn. (Lúùkù 17:11-19) Ẹnì kan ṣoṣo ló padà wá fògo fún Ọlọ́run, tí ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù. Arákùnrin Liverance ṣàlàyé pé: “Láìsí àní-àní, inú àwọn yòókù dùn gan-an pé àwọn di mímọ́. Ó wú wọn lórí gan-an ni, ṣùgbọ́n ó jọ pé gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn ni pé kí àlùfáà sáà ti polongo àwọn ní ẹni mímọ́.” Ìwẹ̀mọ́ tẹ̀mí tí ń wá látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àti ẹ̀mí ìdúpẹ́, yẹ kó sún èèyàn láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore rẹ̀. A rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì kejìdínláàádọ́fà pé kí wọ́n máa ṣàṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ àti oore Ọlọ́run kí iṣẹ́ ìsìn àti ẹbọ wọn lè máa fọpẹ́ fún Ọlọ́run.—Sáàmù 50:14, 23; 116:12, 17.

Àwọn Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Nípa Bí Wọ́n Ṣe Lè Ṣe É

Mark Noumair, tí òun náà jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead, ló darí apá tó tẹ̀ lé e nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ó dá lórí àwọn ìrírí tí kíláàsì náà ní nínú iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn. Ní ìpíndọ́gba, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti lo nǹkan bí ọdún méjìlá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kí wọ́n tó wá sí ilé ẹ̀kọ́ Gilead. Nígbà tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú onírúurú èèyàn, tó fi hàn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ bí a ṣe ń “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.”—1 Kọ́ríńtì 9:22.

Lẹ́yìn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ ìrírí wọn tán, Charles Molohan àti William Samuelson fọ̀rọ̀ wá àwọn kan lára mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tó ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gilead lẹ́nu wò. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, ìyẹn, Robert Pevy, lọ sìn ní Philippines lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkànléláàádọ́ta ti Gilead. Ó rán kíláàsì náà létí pé: “Nígbàkigbà tí ìṣòro bá yọjú, olúkúlùkù ló máa ń mú àbá tirẹ̀ wá nípa ọ̀nà àtiyanjú ìṣòro náà. O ò ní ṣàìrí ẹni tó gbọ́n jù ọ́ lọ, nítorí náà ẹnì kan máa mú àbá kan wá tó sàn ju tìẹ lọ. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé Bíbélì lo yíjú sí, tí o sì gbìyànjú láti ṣàwárí ojú tí Ọlọ́run fi wo ọ̀ràn náà, ìgbà yẹn lo máa rí ọgbọ́n tó ju gbogbo ọgbọ́n lọ. Ìyẹn ni yóò jẹ́ ìdáhùn tó tọ́.”

Kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó gún régé náà lè wá síparí, John Barr, tí í ṣe mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Máa Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ṣe Ìtẹ́wọ́gbà sí Jèhófà.” Ó ṣàlàyé nípa bí a ṣe lè fi hàn pé a ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, láti ran àwọn ọlọ́kàn títọ́ lọ́wọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Lẹ́yìn tó ka ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù orí kẹrin, ẹsẹ ìkẹwàá, Arákùnrin Barr sọ pé, “Bí a óò bá sin Jèhófà nìkan, a gbọ́dọ̀ yàgò fún gbogbo ọ̀nà àyínìke téèyàn fi lè lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, irú bí ojúkòkòrò, ìfẹ́ ọrọ̀, àti ìgbéra-ẹni-ga. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó pé àwọn míṣọ́nnárì wa láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, àní láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940 títí dòní, ti pa ara wọn mọ́ pátápátá kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí! A sì mọ̀ dájú pé ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kejìdínláàádọ́fà ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead yóò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere wọn. Ẹ óò máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ sí Jèhófà, ẹnì kan ṣoṣo tí irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ tọ́ sí.”

Èyí jẹ́ ọ̀nà tó dáa láti dé ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń gbéni ró náà ládé. Àkókò wá tó wàyí láti gbọ́ àwọn ìkíni a-báa-yín-yọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà, àti láti ka lẹ́tà tí kíláàsì náà kọ, tí wọ́n fi dúpẹ́ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí gbà. A gba kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà níyànjú láti ní ẹ̀mí ìdúróṣinṣin nínú iṣẹ́ tí a yàn fún wọn àti nínú sísin Jèhófà. Gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbi ayẹyẹ yìí, títí kan àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, dara pọ̀ nínú orin àti àdúrà tí a fi mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wá sópin.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní Patterson, New York, ni a ti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní March 11, 2000.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

ÌSỌFÚNNI ONÍṢIRÒ NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 10

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 17

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 46

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 34

Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 16

Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kíláàsì Kejìdínláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Ní ti ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Amadori, E.; Cook, O.; Byrne, M.; Lee, A. (2) Newsome, D.; Pederzolli, A.; Bigras, H.; Kato, T.; Gatewood, D. (3) Eade, D.; Eade, J.; Wells, S.; Jamison, J.; Gonzales, M.; Gonzales, J. (4) Kato, T.; Lohn, D.; Niklaus, Y.; Preiss, S.; Foster, P.; Ibarra, J. (5) Amadori, M.; Manning, M.; James, M.; Boström, A.; Gatewood, B.; Newsome, D. (6) Foster, B.; Jamison, R.; Hifinger, A.; Koffel, C.; Koffel, T.; Byrne, G. (7) Hifinger, K.; Manning, C.; Cook, J.; Boström, J.; Lohn, E.; Pederzolli, A. (8) James, A.; Wells, L.; Preiss, D.; Niklaus, E.; Lee, M.; Ibarra, P.; Bigras, Y.