Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Arákùnrin Ni Gbogbo Yín”

“Arákùnrin Ni Gbogbo Yín”

“Arákùnrin Ni Gbogbo Yín”

“Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.”—MÁTÍÙ 23:8.

1. Ọ̀ràn wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?

 “TA LÓ yẹ ká bọlá fún jù, ṣé míṣọ́nnárì ni tàbí ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì?” Ìbéèrè àtọkànwá tí Kristẹni obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè kan tó wà níhà Ìlà Oòrùn ayé béèrè lọ́wọ́ míṣọ́nnárì kan tó wá láti Ọsirélíà nìyẹn. Ó fẹ́ mọ ẹni tó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún jù nínú míṣọ́nnárì tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn àti òjíṣẹ́ kan tó ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Ìbéèrè àtọkànwá yẹn, tó fi hàn pé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà yẹn ka ipò sí nǹkan bàbàrà, bá míṣọ́nnárì náà lábo. Bó ti wù kó rí, àbọ̀rọ̀ fẹ́ mọ bí agbára táwọn èèyàn ní ṣe tó àti bí wọ́n ṣe lókìkí tó ló ń múni béèrè ìbéèrè nípa ẹni tó tóbi jù.

2. Ojú wo ló yẹ ká fi wo àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa?

2 Irú àníyàn yìí kì í ṣe ohun tuntun rárá. Kódà, lemọ́lemọ́ làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ń jiyàn lórí ẹni tó tóbi jù lọ. (Mátíù 20:20-24; Máàkù 9:33-37; Lúùkù 22:24-27) Inú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí wọ́n ti ka ipò sí bàbàrà làwọn náà ti wá, ìyẹn ni ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ìsìn àwọn Júù ti ọ̀rúndún kìíní. Irú àwùjọ yẹn ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.” (Mátíù 23:8) Albert Barnes tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì sọ pé, orúkọ oyè ẹ̀sìn bíi “Rábì,” tó túmọ̀ sí “Olùkọ́,” “máa ń fa ìgbéraga, ó sì máa ń jẹ́ kí àwọn tí wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀ lérò pé àwọn lọ́lá ju àwọn mìíràn lọ, àwọn tí wọn ò sì ní orúkọ oyè yẹn máa ń jowú, wọ́n sì máa ń gbà pé àwọn kéré sí àwọn tó wà nípò yẹn; gbogbo ẹ̀mí àti èrò tó ń gbé yọ ló lòdì pátápátá sí ‘ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Kristi.’” Láìṣe àní-àní, àwọn Kristẹni máa ń yẹra fún pípe àwọn alábòójútó tó wà láàárín wọn ní “Alàgbà tibí àti alàgbà tọ̀hún,” kí wọ́n máa lo “alàgbà” bí orúkọ oyè kan fún àpọ́nlé. (Jóòbù 32:21, 22) Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn alàgbà tó ní irú ẹ̀mí tí Jésù dámọ̀ràn rẹ̀ máa ń bọlá fún àwọn mẹ́ńbà yòókù nínú ìjọ, bí Jèhófà ṣe ń bọlá fún àwọn adúróṣinṣin olùjọsìn rẹ̀ àti bí Jésù Kristi ṣe ń bọlá fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó dúró ṣinṣin.

Àpẹẹrẹ Jèhófà àti ti Jésù

3. Báwo ni Jèhófà ṣe bọlá fún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rẹ̀?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni “Ẹni Gíga Jù Lọ,” àtìbẹ̀rẹ̀ pàá ló ti ń bọlá fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ nípa pípè wọ́n láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀. (Sáàmù 83:18) Nígbà tí Jèhófà dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, ó pe Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sídìí iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:27-30; Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Jèhófà tilẹ̀ ké sí àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ọ̀run láti lóhùn sí bí àwọn ó ṣe pa Áhábù Ọba búburú nì run nígbà tí Ó ti pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Àwọn Ọba 22:19-23.

4, 5. Báwo ni Jèhófà ṣe bọlá fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀ tí ó jẹ́ ènìyàn?

4 Jèhófà ló ń ṣàkóso bí Ọba Aláṣẹ Gíga Jù Lọ ní gbogbo àgbáálá ayé. (Diutarónómì 3:24) Kò tiẹ̀ yẹ kó sọ pé òun tún ń bá àwọn ènìyàn fikùnlukùn rára. Síbẹ̀ ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó kà wọ́n sí. Onísáàmù kan kọ ọ́ lórin pé: “Ta ní dà bí Jèhófà Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fi ibi gíga lókè ṣe ibùgbé rẹ̀? Ó ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, ó ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde àní láti inú ekuru.”—Sáàmù 113:5-8.

5 Ṣáájú kí Jèhófà tó pa Sódómù àti Gòmórà run, ó fetí sílẹ̀ sí àwọn ìbéèrè Ábúráhámù, ó sì tẹ́ ìfẹ́ ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lọ́rùn. (Jẹ́nẹ́sísì 18:23-33) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti mọ ohun tí yóò jẹ́ àbájáde àwọn ìbéèrè Ábúráhámù, síbẹ̀ ó fi sùúrù fetí sí Ábúráhámù, ó sì tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tí ó gbà ronú.

6. Kí ni àbájáde ọ̀wọ̀ tí Jèhófà fi hàn nígbà tí Hábákúkù bi í ní ìbéèrè kan?

6 Jèhófà tún fetí sílẹ̀ sí Hábákúkù, ẹni tó béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́?” Ǹjẹ́ Jèhófà ka ìbéèrè yẹn sí èyí tí a fi pe ọlá àṣẹ òun níjà? Rárá o, lójú rẹ̀, kò sí ohun tó burú nínú àwọn ìwádìí tí Hábákúkù ṣe, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣí ète rẹ̀ payá pé òun óò gbé àwọn ará Kálídíà dìde láti mú ìdájọ́ ṣẹ. Ó fi wòlíì náà lọ́kàn balẹ̀ pé, ‘ìdájọ́ tí a sọ tẹ́lẹ̀ yìí yóò ṣẹ láìkùnà.’ (Hábákúkù 1:1, 2, 5, 6, 13, 14; 2:2, 3) Bí Jèhófà ṣe fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ Hábákúkù, tó sì dá a lóhùn fi hàn pé ó bọlá fún wòlíì náà. Àbájáde rẹ̀ ni pé wòlíì tí ọkàn rẹ̀ dà rú náà wá túra ká, inú rẹ̀ dùn, ó sì wá ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀. Èyí la rí kedere nínú ìwé Hábákúkù onímìísí náà tó fún ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà lókun lóde òní.—Hábákúkù 3:18, 19.

7. Èé ṣe tí ipa tí Pétérù kó ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa fi ṣe pàtàkì?

7 Jésù Kristi tún jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà mìíràn nínú fífi ọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Jésù ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé “ẹnì yòówù tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú Baba mi.” (Mátíù 10:32, 33) Àmọ́, ní òru ọjọ́ tí wọ́n dà á, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló sá fi í sílẹ̀ lọ, àpọ́sítélì Pétérù sì sẹ́ ẹ nígbà mẹ́ta. (Mátíù 26:34, 35, 69-75) Jésù wò ré kọjá ìrísí òde, ó kíyè sí irú ẹni tí Pétérù jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, àti ìrònúpìwàdà jíjinlẹ̀ tó fi hàn. (Lúùkù 22:61, 62) Ọjọ́ mọ́kànléláàádọ́ta péré lẹ́yìn ìyẹn ni Kristi gbé àpọ́sítélì náà níyì, nípa jíjẹ́ kó ṣojú fún ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, tí ó sì lo ìkíní nínú “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba.” ( Mátíù 16:19; Ìṣe 2:14-40) A tún fún Pétérù láǹfààní láti ‘padà, kí ó sì fún àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun.’—Lúùkù 22:31-33.

Bíbọlá fún Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé

8, 9. Báwo ní ọkọ kan ṣe lè fara wé Jèhófà àti Jésù ní bíbọlá fún aya rẹ̀?

8 Ì bá dára tí àwọn ọkọ àtàwọn òbí bá lè fara wé Jèhófà àti Jésù Kristi nínú lílo ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn. Pétérù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá [àwọn aya yín] gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Pétérù 3:7) Fojú inú wo bóo ṣe máa gbé àwo tán-ń-ganran, tó dájú pé ó ṣe ẹlẹgẹ́ ju abọ́ tí a figi ṣe lọ. Ǹjẹ́ o ò ní gbé e tìṣọ́ratìṣọ́ra? Ọkọ kan lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe àfarawé Jèhófà, kí ó máa fetí sí àwọn èrò aya rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ ti ìdílé. Rántí pé Jèhófà wá àyè láti gbọ́ èrò Ábúráhámù. Nítorí àìpé ẹ̀dá, ọkọ kan lè máà rí gbogbo ibi tí ọ̀ràn náà nasẹ̀ dé. Nítorí náà, ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìwà ọgbọ́n fún un láti bọlá fún aya rẹ̀ nípa fífi tòótọ́tòótọ́ gbé àwọn èrò tirẹ̀ náà yẹ̀ wò?

9 Ní àwọn ilẹ̀ kan tó jẹ́ pé ohun tí àwọn ọkùnrin bá sọ labẹ́ gé, ó yẹ kí ọkọ kan ní in lọ́kàn pé aya òun lè ní láti borí ìdènà ńlá kí ó tó lè sọ tinú rẹ̀ jáde. Fara wé ọ̀nà tí Jésù Kristi gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn tí wọ́n jẹ́ apá kan ẹgbẹ́ ìyàwó rẹ̀ ọjọ́ iwájú. Ó ṣìkẹ́ wọn, ó ń gba ti ipò tara àti tẹ̀mí wọn tó láàlà rò, kódà kí wọ́n tiẹ̀ tó sọ ohun tó jẹ́ àìní wọn jáde. (Máàkù 6:31; Jòhánù 16:12, 13; Éfésù 5:28-30) Láfikún sí i, fara balẹ̀, kí o kíyè sí ohun tí aya rẹ ń ṣe fún ìwọ àti ìdílé rẹ, kí o sì fi ìmọrírì hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Jèhófà àti Jésù mọyì àwọn ẹni yíyẹ, wọ́n ń yìn wọ́n, wọ́n sì ń bù kún wọn. (1 Àwọn Ọba 3:10-14; Jóòbù 42:12-15; Máàkù 12:41-44; Jòhánù 12:3-8) Lẹ́yìn tí ọkọ Kristẹni obìnrin kan láti Ìlà Oòrùn ayé di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tán, obìnrin náà sọ pé: “Ọkọ mi máa ń fi ìṣísẹ̀ mẹ́ta tàbí mẹ́rin ṣáájú mi tẹ́lẹ̀, tó máa ń jẹ́ kí n nìkan gbé gbogbo nǹkan. Àmọ́, nísinsìnyí, òun ló ń gbé àpò, ó sì máa ń fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ ilé tí mò ń ṣe!” Ọ̀rọ̀ ìmọrírì tí ó ti ọkàn wá máa ń ṣèrànwọ́ gan-an láti jẹ́ kí aya rẹ mọ̀ pé o mọyì òun.—Òwe 31:28.

10, 11. Kí ni àwọn òbí lè kọ́ nínú àpẹẹrẹ àtàtà tí Jèhófà fi lélẹ̀ nínú bí ó ṣe bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ lò?

10 Nígbà tó bá kan ọ̀ràn àbójútó àwọn ọmọ, àgàgà tó bá di ọ̀ràn ìbáwí, àwọn òbí gbọ́dọ̀ fara wé àpẹẹrẹ ti Ọlọ́run. “Jèhófà sì ń kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà ṣáá” láti yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn, ṣùgbọ́n wọ́n “ń bá a nìṣó ní mímú ọrùn wọn le.” (2 Àwọn Ọba 17:13-15) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tiẹ̀ “gbìyànjú láti fi ẹnu wọn tàn án; wọ́n sì gbìyànjú láti fi ahọ́n wọn purọ́ fún un.” Ọ̀pọ̀ òbí ló lè rí i pé àwọn ọmọ wọn ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “ń dán Ọlọ́run wò,” wọ́n ṣe ohun tó dùn ún, wọ́n sì bà á nínú jẹ́. Síbẹ̀ Jèhófà “jẹ́ aláàánú; òun a sì bo ìṣìnà náà, kì yóò sì mú ìparun wá.”—Sáàmù 78:36-41.

11 Jèhófà tiẹ̀ bẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa . . . Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.” (Aísáyà 1:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kọ́ ló jẹ̀bi, síbẹ̀ ó pe orílẹ̀-èdè ọlọ̀tẹ̀ náà láti wá, kí wọ́n sì mú ọ̀ràn tọ́. Àpẹẹrẹ àtàtà mà lèyí jẹ́ o, fún àwọn òbí láti fara wé, nínú bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ọmọ wọn lò! Nígbà tí ipò nǹkan bá gbà bẹ́ẹ̀, fi ọ̀wọ̀ tiwọn wọ̀ wọ́n nípa fífetí sí ohun tí wọ́n ní í sọ, kí o sì fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú wọn lórí ìdí tí wọ́n fi ní láti ṣe àtúnṣe.

12. (a) Èé ṣe tí a fi ní láti yẹra fún bíbọlá fún àwọn ọmọ wa ju Jèhófà lọ? (b) Kí ló yẹ ní ṣíṣe tí a óò bá fi ọ̀wọ̀ àwọn ọmọ wa wọ̀ wọ́n nígbà táa bá ń bá wọn wí?

12 Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà míì wà táwọn ọmọ nílò ìbáwí líle koko. Àwọn òbí ò ní fẹ́ rí bí Élì, ẹni ‘tó ń bọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ju Jèhófà lọ.’ (1 Sámúẹ́lì 2:29) Síbẹ̀, ó yẹ kí àwọn ọmọ rí i pé ìfẹ́ ló mú kí a báwọn wí. Ó yẹ kí wọ́n rí i pé àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ àwọn. Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn baba létí pé: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Nígbà tó jẹ́ pé bàbá ní láti lo ọlá àṣẹ rẹ̀, ohun tí a ń wí ni pé bàbá náà ní láti fún àwọn ọmọ ní ọ̀wọ̀ tiwọn nípa ṣíṣàì mú wọn bínú nípa fífi ọwọ́ tó le jù mú wọn. Dájúdájú, ó gba àkókò àti ìsapá àwọn òbí láti fi ọ̀wọ̀ àwọn ọmọ wọ̀ wọ́n, ṣùgbọ́n àbájáde rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

13. Ojú wo ni Bíbélì fi ń wo àwọn àgbàlagbà nínú ìdílé?

13 Bíbọlá fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé ẹni kò mọ sórí bíbu iyì fún aya àti àwọn ọmọ wa. Òwe àwọn ará Japan kan sọ pé: “Nígbà tóo bá darúgbó, gbọ́ràn sí àwọn ọmọ rẹ lẹ́nu.” Kókó tó wà nínú òwe yẹn ni pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ yẹra fún lílo ọlá àṣẹ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí ré kọjá ibi tí ọlá àṣẹ ọ̀hún mọ, wọ́n gbọ́dọ̀ kọbi ara sí ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà bá sọ. Nígbà tó jẹ́ pé ó bá Ìwé Mímọ́ mu kí àwọn òbí bọlá fún àwọn ọmọ wọn nípa fífetí sí wọn, àwọn ọmọ náà kò gbọ́dọ̀ fi ìwà àìlọ́wọ̀ hàn sí àwọn tó dàgbà nínú ìdílé. Òwe orí kẹtàlélógún, ẹsẹ ìkejìlélógún sọ pé: “Má . . . tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.” Ohun tó wà nínú òwe yìí gan-an ni Sólómọ́nì Ọba ṣe, ó bọlá fún ìyá rẹ̀ nígbà tó wá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀. Sólómọ́nì mú kí wọ́n gbé ìtẹ́ kan kalẹ̀ ní apá ọ̀tún ìtẹ́ tirẹ̀, ó sì fetí sí ohun tí Bátí-ṣébà, ìyá rẹ̀ tó ti di àgbàlagbà fẹ́ bá a sọ.—1 Àwọn Ọba 2:19, 20.

14. Báwo la ṣe lè bọlá fún àwọn àgbàlagbà nínú ìjọ?

14 Nínú ìdílé wa tẹ̀mí tó gbòòrò, a ní àǹfààní láti “mú ipò iwájú” nínú bíbu ọlá fún àwọn tó jẹ́ àgbàlagbà nínú ìjọ. (Róòmù 12:10) Wọ́n lè má lè ṣe tó bí wọ́n ti ń ṣe látijọ́, ìyẹn sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. (Oníwàásù 12:1-7) Àgbàlagbà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ẹni àmì òróró, tí kò lè rìn lọ rìn bọ̀ mọ́, tí wọ́n sì ti dá dúró sí ibi ìtọ́jú aláìsàn fìgbà kan sọ irú ìrẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀ jáde pé: “Ó wù mí kí n tètè kú kí n lè padà sẹ́nu iṣẹ́.” Kíka irú àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀ sí àti bíbọlá fún wọn lè ṣèrànwọ́ fún wọn. A pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.” (Léfítíkù 19:32) Fi ìgbatẹnirò hàn nípa jíjẹ́ kí àwọn àgbàlagbà rí i pé a nílò wọn, a sì mọyì wọn. ‘Dídìde dúró’ lè ní jíjókòó, kí a sì fetí sí wọn bí wọ́n ti ń sọ àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn nínú. Ìyẹn yóò buyì fún àwọn àgbàlagbà, yóò sì fún ìgbésí ayé tiwa lókun nípa tẹ̀mí.

‘Nínú Bíbu Ọlá, Ẹ Mú Ipò Iwájú’

15. Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti buyì fún àwọn mẹ́ńbà ìjọ?

15 Àwọn mẹ́ńbà ìjọ máa ń ṣe dáadáa nígbà tí àwọn alàgbà bá fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wọn. (1 Pétérù 5:2, 3) Láìka bí ọwọ́ wọn ṣe dí tó sí, àwọn alàgbà tó bìkítà máa ń lo ìdánúṣe láti lọ bá àwọn ọ̀dọ́, àwọn olórí ìdílé, àwọn ìyá adánìkantọ́mọ, àwọn ìyàwó ilé, àti àwọn àgbàlagbà, yálà irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìṣòro tàbí wọn ò ní. Àwọn alàgbà máa ń fetí sí ohun tí àwọn mẹ́ńbà ìjọ ní í sọ, wọ́n sì máa ń yìn wọ́n fún ohun tí agbára wọ́n bá gbé láti ṣe. Alàgbà kan tí ó máa ń kíyè sí nǹkan, tó sì ń sọ̀rọ̀ ìmọrírì nípa ohun tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan ṣe ń fara wé Jèhófà, ẹni tó mọyì àwọn ẹ̀dá rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé.

16. Èé ṣe tó fi yẹ kí á ka àwọn alàgbà sí ẹni tó yẹ ká bọlá fún papọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn nínú ìjọ?

16 Nípa fífara wé Jèhófà, àwọn alàgbà ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní títẹ̀lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Èyí lè má rọrùn fún àwọn alàgbà tí wọ́n ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ka ipò sí bàbàrà. Fún àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan ní Ìlà Oòrùn ayé, àwọn ọ̀rọ̀ méjì ni wọ́n ń lò fún “arákùnrin,” wọ́n ń lo ọ̀kan fún ẹni tó wà ní ipò ọ̀gá, wọ́n sì ń lo èkejì fún àwọn gbáàtúù. Títí di ẹnu àìpẹ́ yìí, àwọn mẹ́ńbà ìjọ máa ń fi èyí tí wọ́n ń lo fún ẹni tó wà ní ipò ọ̀gá pe àwọn alàgbà àtàwọn tó dàgbà, wọ́n sì ń lo èyí tó wà fún àwọn gbáàtúù fún àwọn tó kù. Àmọ́ ṣá o, wọ́n ti gbà wọ́n níyànjú láti máa lo èyí tí ó wà fún èèyàn lásán ní gbogbo ìgbà nítorí pé Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “arákùnrin ní gbogbo yín jẹ́.” (Mátíù 23:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ yẹn lè máà hàn tó báyẹn láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa ìwà ẹ̀dá láti máa ka ipò sí bàbàrà.—Jákọ́bù 2:4.

17. (a) Èé ṣe tó fi yẹ kí àwọn alàgbà jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà fi lè fara wé Jèhófà nínú bí wọ́n ṣe ń bá àwọn mẹ́ńbà ìjọ lò?

17 Lóòótọ́, Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti ka àwọn alàgbà kan sí ẹni tí “ọlá ìlọ́po méjì” tọ́ sí, àmọ́ síbẹ̀ arákùnrin ṣì ni wọ́n. (1 Tímótì 5:17) Bí ó bá ṣeé ṣe fún wa láti “sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” ti Ọba Aláṣẹ Àgbáyé “pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ,” ṣé kò wá yẹ kí a lè sún mọ́ àwọn alàgbà, tó yẹ kí wọ́n máa fara wé Jèhófà ni? (Hébérù 4:16; Éfésù 5:1) Àwọn alábòójútó lè mọ bí àwọn ṣe jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ tó nípa wíwo iye ìgbà tí àwọn èèyàn máa ń wá sọ́dọ̀ wọn láti wá gbàmọ̀ràn tàbí àbá. Kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń pe àwọn mìíràn láti lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tó ń ṣe. Ó ń buyì fún àwọn ẹlòmíràn nípa gbígbé ẹrù iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́. Kódà bí àwọn àbá tí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn dá kò bá tilẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ bójú mu, ó yẹ kí àwọn alàgbà mọrírì àníyàn wọn. Rántí bí Jèhófà ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè olófìn-ín-tótó tí Ábúráhámù béèrè àti igbe ìrora ọkàn tí Hábákúkù ké.

18. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè fara wé Jèhófà nínú títọ́ àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ sọ́nà padà?

18 Àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan nílò ìtọ́sọ́nàpadà. (Gálátíà 6:1) Síbẹ̀, wọ́n ṣeyebíye lójú Jèhófà, wọ́n sì yẹ lẹ́ni tí à ń buyì fún. Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan tó ń fún mi nímọ̀ràn bá fi ọ̀wọ̀ tèmi wọ̀ mí, ọkàn mi máa ń balẹ̀ láti sún mọ́ ọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló máa ń gba ìmọ̀ràn nígbà táa bá fún wọn ní iyì tó tọ́ sí wọn. Ó lè gba àkókò o, àmọ́ jíjẹ́ kí àwọn tó ṣi ẹsẹ̀ gbé sọ tinú wọn jáde máa ń jẹ́ kí ó rọrùn fún wọn láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tí wọ́n nílò. Rántí bí Jèhófà ṣe fèrò wérò pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì léraléra, nítorí pé ó ní ìyọ́nú sí wọn. (2 Kíróníkà 36:15; Títù 3:2) Ìmọ̀ràn tí a bá fúnni pẹ̀lú ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò àti ìbánikẹ́dùn yóò wọ àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́kàn.—Òwe 17:17; Fílípì 2:2, 3; 1 Pétérù 3:8.

19. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tí ìgbàgbọ́ tiwọn yàtọ̀ sí ti Kristẹni?

19 Bíbọlá fún àwọn ẹlòmíràn tún nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n di arákùnrin wa tẹ̀mí lọ́jọ́ ọ̀la. Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ lè máa fi nǹkan falẹ̀ báyìí, kí wọ́n má tètè tẹ́wọ́ gba ìwàásù wa, síbẹ̀ a ní láti ní sùúrù fún wọn, kí a sì fún wọn ní iyì tiwọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan kọ́ ló yẹ kí a máa fi wo nǹkan ni? Ní ti àwọn ènìyàn ní gbogbo gbòò, ọ̀nà àtijẹ́rìí fún wọn lè ṣí sílẹ̀, tí a bá gbìyànjú nígbà gbogbo láti ṣe bí ọ̀rẹ́. Àmọ́ ṣá o, a ó yẹra fún àjọṣe tó lè pa ipò tẹ̀mí wa lára. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Síbẹ̀, a ń fi “inú rere ẹ̀dá ènìyàn” hàn, a kì í tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwa.—Ìṣe 27:3.

20. Kí ló yẹ kí àpẹẹrẹ Jèhófà àti ti Jésù Kristi sún wa láti ṣe?

20 Dájúdájú, Jèhófà àti Jésù Kristi ka ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sí ẹni tó yẹ ní bíbọ̀wọ̀ fún. Ǹjẹ́ kí a máa fìgbà gbogbo rántí ìṣarasíhùwà wọn, kí a sì máa mú ipò iwájú bákan náà nínú bíbọlá fún àwọn ẹlòmíràn. Kí a sì máa fi àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa wa Jésù Kristi sọ́kàn ní gbogbo ìgbà pé: “Arákùnrin ní gbogbo yín.”—Mátíù 23:8.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ojú wo ló yẹ kóo máa fi wo olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ?

• Báwo ni àpẹẹrẹ Jèhófà àti ti Jésù ṣe sún ẹ láti bọlá fún àwọn ẹlòmíràn?

• Báwo ni àwọn ọkọ àtàwọn òbí ṣe lè bọlá fún àwọn ẹlòmíràn?

• Kíka àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn sí àwọn arákùnrin wọn ń sún àwọn alàgbà gbégbèésẹ̀ lọ́nà wo?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Fi ọ̀rọ̀ ìmọrírì bọlá fún aya rẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Buyì fún àwọn ọmọ rẹ nípa fífetí sí wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Fi ọ̀wọ̀ àwọn mẹ́ńbà ìjọ wọ̀ wọ́n