Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ìgbanilà Ní Erékùṣù Robinson Crusoe

Iṣẹ́ Ìgbanilà Ní Erékùṣù Robinson Crusoe

Iṣẹ́ Ìgbanilà Ní Erékùṣù Robinson Crusoe

ROBINSON CRUSOE jẹ́ ọ̀kan lára àwọn erékùṣù mẹ́ta tó wà ní Òkun Pàsífíìkì tó para pọ̀ jẹ́ erékùṣù òkun tí a ń pè ní Juan Fernández, tó wà ní nǹkan bí òjìlélẹ́gbẹ̀ta [640] kìlómítà sí etíkun orílẹ̀-èdè Chile. a Robinson Crusoe, ìwé ìtàn àròsọ olókìkí kan tí Daniel Defoe, gbajúmọ̀ òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì kọ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ni orúkọ tí a fi sọ erékùṣù náà tó jẹ́ kìlómítà mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún níbùú lóròó. Ìtàn ìrìnkèrindò ará Scotland náà, Alexander Selkirk, tó dá nìkan gbé ní erékùṣù náà fún nǹkan bí ọdún mẹ́rin, ló jọ pé wọ́n kọ sínú ìwé ìtàn àròsọ náà.

Ẹ jẹ́ ká fa díẹ̀ yọ lára ọ̀rọ̀ tó wà lára pátákó ìsọfúnni kan ní erékùṣù náà tó kà pé: “Ọ̀gangan ibí yìí ni Alexander Selkirk, atukọ̀ ará Scotland nì, ti ń fi ojoojúmọ́ garùn ṣáá, fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́rin gbáko, tó ń wọ̀nà fún ọkọ̀ ìgbàlà tó máa wá gbé òun kúrò ní àdádó tóun wà.” Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n gba Selkirk là, wọ́n gbé e padà sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, sí ìlú tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn mọ́ lẹ́yìn tó ti gbé nínú párádísè kékeré tirẹ̀. Wọ́n ní ó sọ lẹ́yìn náà pé: “Áà, ìwọ erékùṣù mi ọ̀wọ́n! Ǹ bá mọ̀, ǹ bá má fi ẹ́ sílẹ̀ rárá!”

Bọ́dún ti ń gorí ọdún, wọ́n wá sọ erékùṣù náà di ibi ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ó di ibi tí àwọn tó “tàpá sí ìlànà ẹ̀sìn” Ìjọ Kátólíìkì ń gbé. Págà, erékùṣù tó dà bíi párádísè, èyí tí Selkirk ń gbé nígbà kan rí ló wá dà báyìí! Àmọ́ àwọn tó ń gbé erékùṣù yìí lóde òní ń gbádùn ìbàlẹ̀ ọkàn tó ṣọ̀wọ́n láyé táa wà yìí. Ìgbésí ayé gbẹ̀fẹ́, tó ti mọ́ àwọn ará erékùṣù lára, máa ń jẹ́ kó rọrùn láti bá wọn fọ̀rọ̀wérọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àkọọ́lẹ̀ ti fi hàn, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn ló ń gbé ní Robinson Crusoe, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà láàárín ọdún, kìkì nǹkan bí irínwó [400] èèyàn ló máa ń gbé ní erékùṣù náà. Ara ohun tó fà á ni pé àwọn ìyá kan àtàwọn ọmọ wọ́n máa ń kúrò létíkun láti lọ gbé ní Chile nígbà táwọn ọmọ bá wà níléèwé, àwọn oṣù tí wọ́n bá wà lọ́lidé nìkan ni wọ́n máa ń padà wá sí erékùṣù wá bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé yòókù.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgboro Robinson Crusoe ló lẹ́wà mèremère, tó rí bí ọgbà ìtura, síbẹ̀síbẹ̀ ó ń ká àwọn èèyàn kan ní erékùṣù náà lára pé inú àwọn ṣófo nípa tẹ̀mí, wọ́n sì fẹ́ wá nǹkan ṣe sí i. Àwọn mìíràn rí i pé ipò àwọn nípa tẹ̀mí ń béèrè pé kí wọ́n gbà wọ́n là.

Gbígbà Wọ́n Là Nípa Tẹ̀mí

Irú iṣẹ́ ìgbàlà nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1979. Obìnrin kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nílùú Santiago, Chile, ṣí wá sí erékùṣù yìí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ẹlòmíì ní ohun tó ti kọ́. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni alàgbà ìjọ kan wá ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ní erékùṣù náà, ó sì yà á lẹ́nu láti rí àwùjọ kéréje àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ obìnrin náà. Ìgbà tí alàgbà náà tún padà wá sí erékùṣù yìí lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, obìnrin tó ń dá kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí àti méjì lára àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe tán láti ṣe ìrìbọmi, nítorí náà, alàgbà náà ṣètò fún ìrìbọmi wọn. Lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwọn Kristẹni yìí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí ṣègbéyàwó, òun àti ọkọ rẹ̀ sì ń bá a lọ ní wíwá àwọn míì tó yẹ fún ìgbàlà nípa tẹ̀mí. Ọkọ rẹ̀ mú ipò iwájú nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́ńbé kan, tí àwùjọ kéréje tó wà ní erékùṣù yìí ṣì ń lò. Nígbà tó yá, nítorí ìṣòro ìṣúnná owó, wọ́n ṣí kúrò ní Robinson Crusoe lọ sí ìjọ kan tó wà ní àárín gbùngbùn Chile, níbi tí wọ́n ti ń bá a nìṣó ní fífi ìtara sin Jèhófà.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwùjọ kéréje tó wà ní erékùṣù náà ń pọ̀ sí i bí wọ́n ti ń gba àwọn míì kúrò lọ́wọ́ ẹ̀sìn èké. Ṣùgbọ́n o, níwọ̀n bí ó ti pọndandan pé káwọn ọmọléèwé ṣí lọ sílùú nítorí iléèwé girama tí wọ́n ń lọ, àwùjọ náà ti dín kù, àwọn arábìnrin méjì tó ti ṣèrìbọmi àti ọ̀dọ́mọbìnrin kan ló kù síbẹ̀. Ìgbà ọlidé ni àwùjọ náà máa ń pọ̀ sí i, nígbà táwọn ìyá bá padà wá sí erékùṣù náà. Ìgbà ọlidé yìí ló máa ń fún àwọn Kristẹni mẹ́ta tó máa ń wà ní àdádó níbẹ̀ jálẹ̀ ọdún lókun. Àwọn èèyàn mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ẹní mowó ní Robinson Crusoe nítorí iṣẹ́ takuntakun táwọn arábìnrin yìí ń ṣe. Òótọ́ ni pé àwọn kan ní erékùṣù náà ń tako iṣẹ́ wọn, wọ́n sì ń gbìyànjú láti fagbára mú káwọn ẹlòmíì kọ etí ikún sí ìhìn Ìjọba náà. Síbẹ̀síbẹ̀, irúgbìn òtítọ́ Bíbélì táa gbìn sọ́kàn àwọn olóòótọ́ kàn ń gbèrú ṣáá ni.

Fífún Àwọn Táa Ti Gbà Sílẹ̀ Lókun

Alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń bẹ erékùṣù náà wò lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Báwo ló ṣe ń rí láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí kéréje tó ń gbé ní erékùṣù jíjìnnà náà? Alábòójútó àyíká kan ṣàpèjúwe ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ tó ṣe sí Robinson Crusoe, ó ní:

“Ìrìn àjò yìí kẹjẹgbẹ. Ó bẹ̀rẹ̀ ní aago méje àárọ̀, nígbà táa kúrò ní Valparaiso láti wakọ̀ lọ́ sí Pápákọ̀ Òfuurufú Cerrillos tó wà nílùú Santiago. Ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan tí kò lè gbà ju èrò méje la wọ̀. Lẹ́yìn tí ọkọ̀ náà ti ń gbé wa lọ fún wákàtí mẹ́ta ó dín ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, a rí ṣóńṣó orí òkè kan lọ́ọ̀ọ́kán tó yọrí láàárín àwọsánmà. Bí a ti túbọ̀ ń sún mọ́ ọn, la bẹ̀rẹ̀ sí rí erékùṣù náà—àpáta ràbàtà kan tí ń bẹ láàárín òkun ni. Ńṣe ló jọ bíi pé ó léfòó sórí alagbalúgbú omi, bí ọkọ̀ tó tàn sójú òkun.

“Lẹ́yìn táa gúnlẹ̀, ọkọ̀ ojú omi kan ló gbé wa lọ sí abúlé náà. Lọ́tùn-ún lósì là ń rí àwọn àpáta ràbàtà-ràbàtà tó yọrí látinú òkun, tó sì jẹ́ àwọn erékùṣù kéékèèké níbi táwọn ẹranko séálì onírun lára ti ń rẹjú ní àwọn erékùṣù Juan Fernández. Wọn ò gbà kí ẹnikẹ́ni pa àwọn séálì onírun wọ̀nyí nítorí pé iye wọ́n ti dín kù gan-an ni. Lójijì, kiní kan ṣàdédé fò kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ ojú omi wa kó tó di pé ó tún rá sínú òkun. Ẹja tí ń fò ni, tí lẹbẹ rẹ̀ aláwẹ́ dà bí ìyẹ́ tí ẹyẹ fi ń fò. Ó jọ pé ó máa ń gbádùn fífò jáde látinú omi láti wá hán àwọn kòkòrò. Àmọ́, nígbà mìíràn, ẹni tó ń wá ohun tí yóò jẹ tún máa ń pàdé ẹni tí yóò jẹ òun náà o; fífò tó fò jáde lè pe àfiyèsí àwọn panipani mìíràn tó ti lanu sílẹ̀ dè é bó ṣe ń padà sínú omi.

“Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a dé abúlé San Juan Bautista (St. John the Baptist). Ọ̀pọ̀ àwọn ará erékùṣù náà ló dúró ní èbúté, bóyá tí wọ́n ń dúró de àlejò wọn tàbí tí wọ́n kàn fẹ́ mọ àwọn àlejò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dé. Ẹwà ibẹ̀ yẹn ti lọ wà jùòkè apatapìtì tí wọ́n ń pè ní El Yunque (Orí Ibi Tí Alágbẹ̀dẹ Ti Ń Lu Irin), dà bí ibi tí a fi aṣọ àrán aláwọ̀ ewé bò, àti ní àyíká rẹ̀, èèyàn á rí ojú sánmà aláwọ̀ aró, tó mọ́ roro, tí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ àwọsánmà funfun-funfun sì wà ní eteetí rẹ̀.

“Kò pẹ́ tí a fi rí àwùjọ àwọn Kristẹni arábìnrin wa àtàwọn ọmọ wọn tí wọ́n ti ń dúró dè wá ní èbúté. Àsìkò ọlidé ni, òun ló jẹ́ kí wọ́n pọ̀ ju báa ṣe fọkàn sí. Lẹ́yìn táa kíra wa tán tọ̀yàyà-tọ̀yàyà, wọ́n mú wa lọ sínú ilé mọ́ńbé kan tó fani mọ́ra tí a gbé jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ yẹn.

“Ọ̀sẹ̀ alárinrin gbáà ni, a sì mọ̀ pé àkókò ò dúró dẹnì kan. Nítorí náà, bíṣẹ́ ò pẹ́ni a kì í pẹ́ṣẹ́. Lọ́jọ́ yẹn gan-an, báa ṣe jẹun ọ̀sán tán báyìí, la gbéra ó di ọ̀dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó máa tóó di arábìnrin wa nípa tẹ̀mí àti ara párádísè tẹ̀mí tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀. Ńṣe ni inú rẹ̀ kàn ń dùn ṣìnkìn, àmọ́ àyà rẹ̀ tún ń já díẹ̀díẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tẹ góńgó ìrìbọmi tó ti ń lé láti ọjọ́ yìí wá. A jíròrò àwọn ìsọfúnni pàtàkì kan pẹ̀lú rẹ̀ kí ó bàa lè tóótun láti di akéde ìhìn rere náà. Lọ́jọ́ kejì, ó kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà fúngbà àkọ́kọ́. Lọ́jọ́ kẹta, a bẹ̀rẹ̀ sí bá a jíròrò àwọn ohun téèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ kó tó lè ṣe batisí. Kí ọ̀sẹ̀ náà tó jálẹ̀, ó ti ṣe batisí.

“Ẹni púpọ̀ ló wá sí àwọn ìpàdé tí a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀, nígbà míì a tiẹ̀ pọ̀ tó mẹ́rìnlá. Ojoojúmọ́ ni ètò wà fún jíjáde iṣẹ́ ìsìn pápá, ìpadàbẹ̀wò, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Ìṣírí ńláǹlà mà lèyí o, fún àwọn arábìnrin tó ń dá ṣiṣẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ọdún!”

Ó nira gan-an fáwọn ọkùnrin tó wà ní erékùṣù yìí láti wá sínú òtítọ́, bóyá nítorí iṣẹ́ àṣekúdórógbó tí wọ́n ń ṣe ni. Olórí iṣẹ́ wọn ni edé pípa, iṣẹ́ náà sì máa ń gbà wọ́n lọ́kàn. Ẹ̀tanú tún wà lára ìdí tí ọ̀pọ̀ fi ń ṣàtakò. Síbẹ̀síbẹ̀, ìrètí wa ni pé púpọ̀ sí i àwọn ará erékùṣù yìí, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, yóò yí ọkàn padà lọ́jọ́ iwájú.

Ní báa ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èèyàn mẹ́wàá la ti gbà sílẹ̀ kúrò nínú ewu ní erékùṣù yìí, ní ti pé wọ́n ti wá mọ òtítọ́ àtàwọn ète Jèhófà Ọlọ́run. Àwọn kan nínú wọn ti kúrò ní erékùṣù yìí lẹ́yìn náà nítorí ìdí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́, yálà wọ́n ṣì wà níbẹ̀ tàbí wọ́n ti kúrò níbẹ̀, gbígbà tí a gbà wọ́n là nípa tẹ̀mí ṣe pàtàkì gidigidi ju gbígbà tí wọ́n gba Alexander Selkirk là. Wọ́n ń gbádùn párádísè tẹ̀mí báyìí níbikíbi tí wọ́n bá ń gbé. Àwọn arábìnrin tó ṣì ń gbé erékùṣù yìí àtàwọn ọmọ wọn ń gbádùn àyíká tó rí bí ọgbà ìtura, ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá, wọ́n ní ìrètí gbígbé nígbà tí gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di párádísè tòótọ́ ní gbogbo ọ̀nà.

Iṣẹ́ Ìgbanilà Ń Bá A Nìṣó

Ní ti àwòrán ilẹ̀, àwùjọ kéréje àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ní Robinson Crusoe ń gbé ní ibi tó jìnnà réré sí ìyókù àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí. Àmọ́, wọn ò dá wà bíi ti Selkirk ará Scotland. Nípasẹ̀ ìwé ìṣàkóso Ọlọ́run tí kì í wọ́n wọn, àtàwọn fídíò ìpàdé àyíká àti ti àgbègbè tí ẹ̀ka Watch Tower Society tó wà ní Chile ń fi ránṣẹ́ sí wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, àti ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, pẹ́kípẹ́kí ni wọ́n wà pẹ̀lú ètò Jèhófà. Fún ìdí yìí, wọ́n ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ ara ògbóṣáṣá “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará nínú ayé.”—1 Pétérù 5:9.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ tí wọ́n mọ erékùṣù náà sí gan-an ni Más a Tierra.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

CHILE

Santiago

ERÉKÙṢÙ ROBINSON CRUSOE

San Juan Bautista

El Yunque

ÒKUN PÀSÍFÍÌKÌ

ERÉKÙṢÙ SANTA CLARA

[Àwòrán]

Ìgbà téèyàn bá ń wo erékùṣù náà lọ́ọ̀ọ́kán, àpáta ràbàtà ní àárín gbùngbùn òkun lèèyàn máa rí

[Credit Line]

Àwòrán ilẹ̀ Chile: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Òkè apatapìtì tí wọ́n ń pè ní El Yunque (Orí Ibi Tí Alágbẹ̀dẹ Ti Ń Lu Irin)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Abúlé San Juan Bautista (St. John the Baptist)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn erékùṣù kéékèèké tí onírúurú ẹ̀yà àwọn ẹranko séálì onírun lára ti ń rẹjú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

A lo ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan láti ìlú Santiago, Chile

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Etíkun tí kò tẹ́jú tí ń bẹ ní Erékùṣù Robinson Crusoe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́ńbé tó wà ní erékùṣù náà