Ǹjẹ́ O Máa Ń Gba Ohun Tí O Kò Lè Rí Gbọ́?
Ǹjẹ́ O Máa Ń Gba Ohun Tí O Kò Lè Rí Gbọ́?
TÍ ẸNÌ kan bá sọ pé, ‘Ohun tí mo bá fojú rí nìkan ni mo lè gbà gbọ́,’ kì í ṣe ohun tí ó fi ojúyòójú rí ló ń sọ. Ká sòótọ́, gbogbo wa la máa ń gba ohun tí a ò lè rí gbọ́.
Bí àpẹẹrẹ, nígbà tóo wà níléèwé, o lè ti ṣe àṣeyẹ̀wò kan tó ń fi hàn pé agbára òòfà wà. Wọ́n lè ṣe àṣeyẹ̀wò ọ̀hún lọ́nà yìí: Da egunrín irin sórí abala bébà kan. Wá fi bébà náà sórí mágínẹ́ẹ̀tì. Nígbà táa bá mi bébà náà, àfi bí ẹní pidán ló máa rí, kíá ni àwọn egunrín irin náà máa ṣù
pọ̀ síbi tí mágínẹ́ẹ̀tì náà wà, á wá gbé bátànì mágínẹ́ẹ̀tì tó wà nísàlẹ̀ yọ. Bóo bá ṣe àṣeyẹ̀wò yìí, ǹjẹ́ o lè rí agbára òòfà náà ní ti gidi? Rárá o, ṣùgbọ́n ìyọrísí rẹ̀ lára àwọn egunrín irin náà hàn kedere, ìyẹn ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé agbára òòfà wà.Àwọn nǹkan mìíràn wà tí a ò lè rí, àmọ́ táa máa ń gbà pé wọ́n wà láìjanpata. Nígbà táa bá wo àwòrán mèremère kan tàbí tí a gba ti ère gbígbẹ́ kan tó dáa gan-an, a kì í jiyàn bóyá ayàwòrán tàbí gbẹ́nàgbẹ́nà kan wà tàbí kò sí. Fún ìdí yìí, nígbà tí a bá fara balẹ̀ ṣàkíyèsí ìtàkìtì omi tàbí tí a bá ń wo wíwọ̀ oòrùn, ó kéré tán, ǹjẹ́ kò yẹ ká ronú pé nǹkan wọ̀nyí ní láti jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Àgbà Oníṣẹ́ Ọnà tàbí Gbẹ́nàgbẹ́nà kan?
Ìdí Táwọn Kan Ò Fi Gbà Gbọ́
Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ò gbà pé Ọlọ́run wà mọ́ nítorí ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ará Norway kan nìyí nígbà tí wọ́n sọ fún un pé Ọlọ́run máa ń sun àwọn olubi nínú iná ọ̀run àpáàdì. Ó kàn sáà ń ya ọkùnrin náà lẹ́nu ni, pé irú Ọlọ́run wo rèé tó ń dá àwọn èèyàn lóró lọ́nà yẹn, bó ṣe di ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà nìyẹn.
Àmọ́, lẹ́yìn náà, ọkùnrin yìí gbà pé kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú Bíbélì. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un nígbà tó rí i pé Bíbélì kò kọ́ni pé Ọlọ́run ń dá àwọn olubi lóró nínú ọ̀run àpáàdì. Bíbélì fi ikú wé oorun. Kò sí ìrora nínú sàréè; a ò mọ nǹkan kan rárá. (Oníwàásù 9:5, 10) Ọkùnrin náà tún kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn tí Ọlọ́run rí i pé wọ́n ti jingíri sínú ìwà ibi kò ní jáde láé nínú sàréè. (Mátíù 12:31, 32) Àwọn òkú yòókù yóò jíǹde nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, wọn yóò sì ní ìrètí ìwàláàyè títí láé nínú Párádísè. (Jòhánù 5:28, 29; 17:3) Àlàyé yìí mọ́gbọ́n dání. Ó bá gbólóhùn Bíbélì náà mu pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ọkùnrin olóòótọ́ ọkàn yìí ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó, nígbà tó sì yá, ó wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Bíbélì.
Àwọn ẹlòmíràn kì í gbà pé Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ kan wà nítorí pákáǹleke àti ìwà ìrẹ́nijẹ tó gbòde kan. Wọ́n fara mọ́ ohun tí ọkùnrin ará Sweden kan sọ, ẹni tó nawọ́ sókè ọ̀run nígbà kan rí, tó sì béèrè pé: “Báwo ni Ọlọ́run olódùmarè, oníbú ọrẹ kan, ṣe lè wà lókè lọ́hùn-ún yẹn nígbà tí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ibi pọ̀ tó báyìí láyé ńbí?” Nígbà tí kò rí ẹnikẹ́ni tó lè dáhùn ìbéèrè rẹ̀, lòun náà bá sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Nígbà tó ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnni ní ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn a
sí ìbéèrè àtọdúnmọ́dún náà pe, Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi?Ọkùnrin olóòótọ́ inú yìí kẹ́kọ̀ọ́ pé wíwà tí ìwà ibi wà kì í ṣe ẹ̀rí pé Ọlọ́run ò sí. Àpèjúwe kan rèé: Ẹnì kan lè ṣe ọ̀bẹ kan pé kí wọ́n máa fi gé ẹran. Ẹnì kan lè lọ ra ọ̀bẹ yẹn, kí ó máa fi pànìyàn dípò kí ó máa fi gé ẹran. Òtítọ́ náà pé ó lo ọ̀bẹ yìí lọ́nà tí kò yẹ kò wá túmọ̀ sí pé kò sẹ́ni tó ṣe ọ̀bẹ yìí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, òtítọ́ náà pé a ò lo ilẹ̀ ayé ní ìbámu pẹ̀lú ète táa tìtorí rẹ̀ dá a kò túmọ̀ sí pé ilẹ̀ ayé kò ní Ẹlẹ́dàá.
Bíbélì kọ́ wa pé pípé ni iṣẹ́ Ọlọ́run. “Kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Ọlọ́run máa ń fún èèyàn ní ẹ̀bùn rere, ṣùgbọ́n èèyàn ti ṣi ọ̀pọ̀ lára ẹ̀bùn náà lò, èyí sì ti fa ìjìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ. (Jákọ́bù 1:17) Àmọ́ o, Ọlọ́run yóò mú òpin dé bá ìjìyà. Lẹ́yìn ìyẹn, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, . . . wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:11, 29.
Ó máa ń ká ọkùnrin ará Sweden táa mẹ́nu kàn ní ìṣáájú yìí lára nígbà tó bá rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn bíi tirẹ̀. Ní tòótọ́, àníyàn oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó ní fún àwọn mìíràn mú un dáni lójú pé Ọlọ́run wà. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Ní ti ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn, ohun mìíràn tí wọ́n máa ń gbà gbọ́ bí wọn kò bá gba Ọlọ́run gbọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì máa ń fi kọ́ni ni ẹ̀kọ́ “ìlàájá ẹni tó lágbára jù”—ìyẹn ni pé àwọn èèyàn àti ẹranko ń bá irú tiwọn díje fún lílàájá. Èyí tó bá lágbára jù á yè é; èyí tó bá jẹ́ ahẹrẹpẹ á kú. Wọ́n ní ètò àbáláyé nìyẹn. Àmọ́ bó bá jẹ́ ètò “àbáláyé” ni pé kí èyí tó jẹ́ ahẹrẹpẹ kú, kí èyí tó lágbára lè máa wà láàyè nìṣó, báwo la ṣe wá fẹ́ ṣàlàyé ìdí tó fi máa ń dun àwọn alágbára, irú àwọn bí ọkùnrin ará Sweden yẹn, nígbà tí wọ́n bá rí ìyà tó ń jẹ ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn?
Mímọ Ọlọ́run
A ò lè rí Ọlọ́run nítorí pé kò ní ẹran ara bíi tèèyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ kí a mọ òun. Ọ̀nà kan tí a fi lè mọ̀ ọ́n ni nípa ṣíṣàkíyèsí iṣẹ́ àrà rẹ̀—“àwọn àwòrán” àti “àwọn ohun gbígbẹ́” inú ìṣẹ̀dá. Nínú ìwé Róòmù 1:20, Bíbélì sọ pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” Òdodo ọ̀rọ̀, gan-an bí fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwòrán tàbí ohun gbígbẹ́ kan ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni tí oníṣẹ́ ọnà náà jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ṣíṣàṣàrò nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́.
Àmọ́ ṣá o, a ò lè dáhùn gbogbo ìbéèrè tí ń kọni lóminú nínú ìgbésí ayé kìkì nípa wíwo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n a lè rí ìdáhùn sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ nípa wíwá inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kíka Bíbélì láìsí ẹ̀tanú ló jẹ́ káwọn ọkùnrin méjì tí a mẹ́nu kàn ní ìṣáájú lè wá dórí ìparí èrò náà pé Ọlọ́run wà àti pé ó bìkítà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, jọ̀wọ́ wo ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You, orí kẹwàá tàbí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, orí kẹjọ. Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. ló tẹ àwọn ìwé yìí jáde.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
J. Hester and P. Scowen (AZ State Univ.), NASA