Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Yóò Fòpin Sí Ìwà Ipá?

Ta Ni Yóò Fòpin Sí Ìwà Ipá?

Ta Ni Yóò Fòpin Sí Ìwà Ipá?

Ní September 1999, Kofi Annan, tó jẹ́ Ọ̀gá Àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kí àwọn aṣojú káàbọ̀ sí ìpàdé kẹrìnléláàádọ́ta nínú ìpàdé ọdọọdún ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Toronto Star ṣe ròyìn rẹ̀, ó gbé ìpèníjà kan dìde síwájú àwọn aṣáájú ayé, ní sísọ pé: “Ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn ló wà tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń fẹ́ látọ̀dọ̀ àwùjọ àgbáyé kọjá ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn lásán. Wọ́n nílò ojúlówó àdéhùn tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fòpin sí ìwà ipá tí kò dáwọ́ dúró, kí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn lé ọ̀nà kan tó láàbò tó lè sọ wọ́n di ẹni tó ní láárí.”

Ǹjẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀ lè ṣe “ojúlówó àdéhùn tó fẹsẹ̀ múlẹ̀” láti fòpin sí ìwà ipá? Ìwé ìròyìn Star kan náà ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tí Bill Clinton, Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Lẹ́yìn gbogbo ìtàjẹ̀sílẹ̀ ọ̀rúndún yìí, a mọ̀ pé ó rọrùn láti sọ pé ‘ó tó gẹ́ẹ́,’ àmọ́ ẹnú dùn-ún ròfọ́, agada ọwọ́ ṣeé bẹ́ gẹdú lọ̀rọ̀ náà.” Ó fi kún un pé: “Ṣíṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlérí tí kò ṣeé mú ṣẹ àti ṣíṣàìbìkítà, ìwà ìkà ni méjèèjì jẹ́.”

Ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn, wòlíì Jeremáyà sọ nípa ìsapá ẹ̀dá ènìyàn pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ìrètí wo ló wá wà pé ìwà ipá yóò dópin?

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kà á nínú Aísáyà 60:18, Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “A kì yóò gbọ́ ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ, a kì yóò gbọ́ ìfiṣèjẹ tàbí ìwópalẹ̀ ní ààlà rẹ.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn nímùúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ènìyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ó tún máa ní ìmúṣẹ títóbi lọ́lá tí a lè gbádùn. Jèhófà Ọlọ́run kò ṣe “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlérí tí kò ṣeé mú ṣẹ.” Gẹ́gẹ́ bí Ẹni Gíga Jù Lọ àti Ẹlẹ́dàá ènìyàn, òun lẹni tó wà nípò tó dára jù lọ láti fòpin sí “ìwà ipá tí kò dáwọ́ dúró.” Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àlàáfíà yóò gbilẹ̀. Ìwà ipá yóò kásẹ̀ nílẹ̀ títí láé!—Dáníẹ́lì 2:44.