Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àpẹẹrẹ Rere Ṣé O Ń Jàǹfààní Lára Wọn?

Àwọn Àpẹẹrẹ Rere Ṣé O Ń Jàǹfààní Lára Wọn?

Àwọn Àpẹẹrẹ Rere Ṣé O Ń Jàǹfààní Lára Wọn?

“Ẹ WÁ di àpẹẹrẹ fún gbogbo onígbàgbọ́ ní Makedóníà àti ní Ákáyà.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí àwọn Kristẹni tòótọ́ tí ń gbé ní Tẹsalóníkà. Àpẹẹrẹ tí wọ́n fi lélẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn yẹ ní gbígbóríyìn fún lóòótọ́. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti fi lélẹ̀ làwọn ará Tẹsalóníkà fúnra wọn ń tẹ̀ lé. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ irú ènìyàn tí a wá jẹ́ sí yín nítorí yín; ẹ sì di aláfarawé wa.”—1 Tẹsalóníkà 1:5-7.

Dájúdájú, Pọ́ọ̀lù ṣe ju kó kàn máa wàásù nìkan lọ. Ìgbésí ayé rẹ̀ gan-an, ìwàásù ni—ó jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́, ìfaradà, àti ìfara-ẹni-rúbọ. Nítorí ìdí èyí, Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ wá di ẹni tó ní ipa tó lágbára lórí ìgbésí ayé àwọn ará Tẹsalóníkà, tí ó mú kí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ “lábẹ́ ìpọ́njú púpọ̀.” Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù àti ti àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ nìkan ló ní ipa rere lórí àwọn onígbàgbọ́ wọ̀nyẹn. Àpẹẹrẹ àwọn mìíràn tí wọ́n lo ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú tún jẹ́ ìṣírí fún wọn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Tẹsalóníkà pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ di aláfarawé àwọn ìjọ Ọlọ́run tí ń bẹ ní Jùdíà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, nítorí ẹ̀yin pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí jìyà lọ́wọ́ àwọn ará ilẹ̀ ìbílẹ̀ tiyín àwọn ohun kan náà gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti ń jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù.”—1 Tẹsalóníkà 2:14.

Kristi Jésù—Àpẹẹrẹ Àkọ́kọ́ Pàá

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ti fi àpẹẹrẹ kan tó yẹ ní fífarawé lélẹ̀, síbẹ̀ kò ṣàìtọ́ka sí Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ tí àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ fara wé. (1 Tẹsalóníkà 1:6) Kristi ni Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ fún wa. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pétérù 2:21.

Àmọ́ o, ó ti ń lọ sí nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn báyìí tí Jésù ti dágbére fáyé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ẹlẹ́ran ara. Nísinsìnyí, ó “ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́,” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú. Nípa bẹ́ẹ̀, “kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.” (1 Tímótì 6:16) Báwo la ṣe wá lè fara wé e? Ọ̀nà kan ni pé kí a ka àwọn ìwé Bíbélì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó sọ nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù dáadáa. Àwọn Ìwé Ìhìn Rere náà fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa irú ẹni tó jẹ́, ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀, àti “ẹ̀mí ìrònú” rẹ̀. (Fílípì 2:5-8) A tún lè lóye síwájú sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, tó ṣàlàyé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jésù lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ àti bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀léra ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀ lé. a

Àpẹẹrẹ ìfara-ẹni-rúbọ Jésù ní ipa tó lágbára gan-an lórí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá fún ọkàn yín.” (2 Kọ́ríńtì 12:15) Ìwà bíi ti Kristi gan-an mà lèyí! Bí a ṣe ń ronú nípa àpẹẹrẹ pípé ti Kristi, ó yẹ kí àpẹẹrẹ rẹ̀ sún àwa náà láti ṣàfarawé rẹ̀ nínú ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìgbésí ayé tiwa.

Fún àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ wa pé a gbọ́dọ̀ fọkàn tán ìlérí Ọlọ́run láti pèsè fún wa nípa ti ara. Ṣùgbọ́n ó tún ṣe ju ìyẹn lọ. Ojoojúmọ́ ló ń fi hàn pé òun ní irú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà. Ó sọ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀ sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Mátíù 6:25; 8:20) Ṣé àníyàn nípa ohun ti ara ló máa ń gba gbogbo ìrònú àti ìṣesí rẹ? Tàbí, ṣé ìgbésí ayé rẹ ń fi hàn pé ò ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́? Irú ẹ̀mí wo lo sì ní sí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣé irú ti Jésù tó jẹ́ Àpẹẹrẹ wa ni? Bíbélì fi hàn pé kì í ṣe pé Jésù kàn ń wàásù nípa ìtara nìkan ni, àmọ́ ó tún fi ìtara mímúná hàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà. (Jòhánù 2:14-17) Síwájú sí i, ẹ wo àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù tún fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́! Àní, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀! (Jòhánù 15:13) Ǹjẹ́ o máa ń fara wé Jésù nípa fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ? Àbí o máa ń jẹ́ kí àìpé àwọn kan ṣèdíwọ́ fún ìfẹ́ tó yẹ kóo ni sí wọn?

Kò sí bí a ò ṣe ní máa ṣisẹ̀ gbé báa ti ń tiraka láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Àmọ́, ó dájú pé inú Jèhófà dùn sí bí a ṣe ń sapá láti “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀.”—Róòmù 13:14.

“Àpẹẹrẹ fún Agbo”

Ǹjẹ́ àwọn kan tiẹ̀ wà nínú ìjọ lónìí tí wọ́n lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa? Dájúdájú, wọ́n wà! Àwọn arákùnrin, àgàgà àwọn tí a yàn sípò ẹrù iṣẹ́ gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù, tó ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní Kírétè wò, tó sì ń yan àwọn alábòójútó, pé olúkúlùkù tí ó bá yàn sípò alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘ọkùnrin tí ó wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn.’ (Títù 1:5, 6) Bákan náà ni àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn “àgbà ọkùnrin” níyànjú pé kí wọ́n di “àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pétérù 5:1-3) Àwọn tó wá ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ńkọ́? Àwọn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ “àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—1 Tímótì 3:13.

Àmọ́ ṣá o, kò bọ́gbọ́n mu láti máa retí pé gbogbo alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni yóò já fáfá lọ́nà títayọ lọ́lá nínú gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Àwa . . . ní àwọn ẹ̀bùn tí ó yàtọ̀ síra ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún wa.” (Róòmù 12:6) Onírúurú ọ̀nà ni àwọn arákùnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ń ta yọ. Kò yẹ ká máa retí pé àwọn alàgbà yóò máa ṣe gbogbo nǹkan tàbí sọ gbogbo nǹkan lọ́nà pípé. Bíbélì sọ nínú Jákọ́bù 3:2 pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” Àmọ́, láìfi gbogbo àìpé wọn pè, àwọn alàgbà ṣì lè ṣe bíi ti Tímótì, kí wọ́n sì “di àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.” (1 Tímótì 4:12) Nígbà tí àwọn alàgbà bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn tó wà nínú agbo yóò ṣe tán láti fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Hébérù 13:7 sílò, pé: “Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.”

Àwọn Àpẹẹrẹ Mìíràn Lóde Òní

Láti àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, àìmọye àwọn mìíràn ló ti fi ara wọn hàn bí àpẹẹrẹ rere. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn míṣọ́nnárì tó fara wọn rúbọ ńkọ́, ìyẹn àwọn tó ti “fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀” kí wọ́n lè mú ohun tí a pa láṣẹ fún Kristẹni ṣẹ nílẹ̀ òkèèrè? (Mátíù 19:29) Tún ronú nípa àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn aya wọn, àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni ní àwọn iléeṣẹ́ Watch Tower Society, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n ń sìn láwọn ìjọ. Ǹjẹ́ irú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyẹn lè sún àwọn mìíràn gbégbèésẹ̀? Kristẹni ajíhìnrere kan ní Éṣíà rántí míṣọ́nnárì kan tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹjọ ti Watchtower Bible School of Gilead. Ó ní arákùnrin adúróṣinṣin yìí “ṣe tán láti kojú àwọn yànmùyánmú tó pọ̀ bíi rẹ́rẹ àti ooru tó mú gan-an. . . . Èyí tó wúni lórí jù lọ ni bó ṣe lè ń wàásù ní èdè Chinese àti èdè Malay nígbà tó sì jẹ́ pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ti wá.” Ipa wo ni àpẹẹrẹ àtàtà yìí ní? Arákùnrin náà sọ pé: “Ìwà pẹ̀lẹ́ àti ìgboyà rẹ̀ ló wú mi lórí tó fi wù mí kí n di míṣọ́nnárì nígbà tí mo bá dàgbà.” Abájọ tí arákùnrin yìí fi di míṣọ́nnárì lóòótọ́.

Àìmọye àwọn ìtàn ìgbésí ayé tó ti fara hàn nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la lè rí nínú Watch Tower Publications Index. Àwọn ìtàn wọ̀nyí ń sọ nípa àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti pa àwọn iṣẹ́ àti góńgó wọn nínú ayé tì, tí wọ́n ti kojú àìlera, tí wọ́n ti yí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ padà lọ́nà yíyanilẹ́nu, àwọn tí wọ́n tújú ká nígbà ìpọ́njú, tí wọ́n sì ti fi akitiyan, ìfaradà, ìdúróṣinṣin, ìrẹ̀lẹ̀, àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn. Òǹkàwé kan kọ̀wé nípa àwọn ìtàn wọ̀nyí pé: “Bí mo ṣe ń ka ohun tí àwọn ẹlòmíràn là kọjá, ó ń jẹ́ kí n túbọ̀ di Kristẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tó kún fún ìmoore, ó sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ tàbí kí n di onímọtara-ẹni-nìkan.”

Láfikún sí i, má ṣe gbàgbé àwọn àpẹẹrẹ àtàtà tó wà nínú ìjọ tìrẹ: ìyẹn àwọn olórí ìdílé tí wọn kì í kùnà láti bójú tó àwọn àìní ti ara àti ti ẹ̀mí àwọn ìdílé wọn; àwọn arábìnrin—títí kan àwọn ìyá anìkantọ́mọ—tí wọ́n ń kojú wàhálà ọmọ títọ́ tí wọ́n sì tún ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà déédéé; àwọn arúgbó àtàwọn aláìlera tí wọ́n ń bá jíjẹ́ olóòótọ́ nìṣó láìka ọjọ́ ogbó àti àìsàn tó ń yọ wọ́n lẹ́nu sí. Ṣé irú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyẹn ò wú ọ lórí ni?

Lóòótọ́, àwọn àpẹẹrẹ búburú tún pọ̀ lọ súà nínú ayé. (2 Tímótì 3:13) Síbẹ̀, ronú nípa ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó ń gbé ní Jùdíà. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ̀rọ̀ lórí ìwà àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́ ìgbàanì tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, ó wá gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Nípa báyìí, nítorí tí a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú . . . fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa, bí a ti tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” ( Hébérù 12:1, 2) Bákan náà ni àwọn Kristẹni tòde òní ní ‘àwọsánmà’ àwọn àpẹẹrẹ rere ‘púpọ̀’ tó yí wọn ká—àwọn ti ayé ìgbàanì àti ti òde òní. Ṣé ní ti tòótọ́ lò ń jàǹfààní lára wọn? O lè jàǹfààní lára wọn tóo bá ti pinnu láti “má ṣe jẹ́ aláfarawé ohun búburú, bí kò ṣe ohun rere.”—3 Jòhánù 11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. ló tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

Kò bọ́gbọ́n mu láti máa retí pé gbogbo alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni yóò já fáfá lọ́nà títayọ lọ́lá nínú gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn alàgbà ní láti jẹ́ “àpẹẹrẹ fún agbo”