Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Dárí Jini?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Dárí Jini?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Dárí Jini?

“ÌWÉ ìròyìn The Toronto Star ti Kánádà ròyìn pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti gbé ìwádìí kan jáde tó ti bẹ̀rẹ̀ sí fi hàn pé ìdáríjì lè nípa tó dára lórí ìmọ̀lára ẹni—ó sì tún ṣeé ṣe kó nípa lórí ìlera—ara ẹni.” Síbẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Carl Thoresen ti Yunifásítì Stanford, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tó jẹ́ olùwádìí àgbà fún Iṣẹ́ Ìwádìí Nípa Ìdáríjini ti Stanford ṣàkíyèsí pé “àwọn ènìyàn díẹ̀ kéréje ló lóye ohun tí ìdáríjì jẹ́ àti iṣẹ́ tó ń ṣe.”

Ojúlówó ìdáríjì jẹ́ apá pàtàkì nínú ìsìn Kristẹni. Ìwé ìròyìn The Toronto Star túmọ̀ rẹ̀ sí “mímọ̀ pé ẹnì kan ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n tí o fọwọ́ wọ́nú, tí o tún wá ń fi ìyọ́nú àti ìfẹ́ bá ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ náà lò lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Èyí yàtọ̀ pátápátá sí gbígbọ̀jẹ̀gẹ́, ṣíṣàwáwí, gbígbàgbé, tàbí sísẹ́ pé wọn ò ṣe ẹ́ ní láìfí; bẹ́ẹ̀ náà ni kò sì túmọ̀ sí fífi ara rẹ wọ́lẹ̀. Ìròyìn náà sọ pé kọ́kọ́rọ́ ìdáríjì tòótọ́ ni “yíyẹra fún ìbínú àti èrò òdì.”

Àwọn olùwádìí sọ pé títúbọ̀ ṣàyẹ̀wò kínníkínní lórí àwọn àǹfààní ti ara tí a lè rí nínú ìdáríjì ṣe pàtàkì. Àmọ́, wọ́n tún ròyìn àwọn àǹfààní tó ń ṣe fún ìrònú òun ìhùwà ẹni, títí kan “díndín tó ń dín másùnmáwo, hílàhílo àti ìsoríkọ́ kù.”

Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa dárí jini ni èyí tó wà nínú Éfésù 4:32, tó sọ pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ìdáríjì, títí kan ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn, a gbà wá níyànjú láti máa fara wé Ọlọ́run.— Éfésù 5:1.

Kíkọ̀ láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn, nígbà tí a bá ní ìdí pàtàkì láti fi àánú hàn lè ba ìbátan àwa fúnra wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Jèhófà ń fẹ́ kí a máa dárí ji ara wa. Ìgbà yẹn la tó lè gbàdúrà pé kí ó dárí jì wá.—Mátíù 6:14; Máàkù 11:25; 1 Jòhánù 4:11.