Ẹ̀yin Kristẹni Olùṣọ́ Àgùntàn,—‘Ẹ Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Yín Gbòòrò’!
Ẹ̀yin Kristẹni Olùṣọ́ Àgùntàn,—‘Ẹ Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Yín Gbòòrò’!
“JÈHÓFÀ ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni Dáfídì lò láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún tó ní nínú Ọlọ́run hàn. Jèhófà ṣamọ̀nà rẹ̀, nípa tẹ̀mí, lọ sí “pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko” àti “ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa,” ó ń darí rẹ̀ kí ó lè máa rìn “ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo.” Nígbà tí àwọn alátakò yí Dáfídì ká, ó rí ìtìlẹyìn àti ìṣírí gbà, èyí tí ó sún un láti sọ fún Jèhófà pé: “Èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi.” Nítorí Olùṣọ́ Àgùntàn Gíga Jù Lọ tí Dáfídì ní, ó pinnu láti “máa gbé inú ilé Jèhófà fún gígùn ọjọ́.”—Sáàmù 23:1-6.
Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run náà tún gbádùn àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà, bó sì ṣe bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi pè é ní “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà,” “olùṣọ́ àgùntàn ńlá,” àti “olórí olùṣọ́ àgùntàn.”—Jòhánù 10:11; Hébérù 13:20; 1 Pétérù 5:2-4.
Jèhófà àti Jésù Kristi ń bá ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn nìṣó. Ara jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn la rí kedere nínú bí wọ́n ṣe fìfẹ́ pèsè àwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí ni Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.”—Ìṣe 20:28.
Ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí Jèhófà àti Kristi Jésù là sílẹ̀ kì í ṣe iṣẹ́ tí ó rọrùn rárá, àmọ́ ó wá ṣe pàtàkì nísinsìnyí ju tí ìgbàkígbà rí lọ. Ronú nípa iye tí ó lé ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ṣe batisí láàárín ọdún mẹ́ta sẹ́yìn! Irú àwọn ẹni tuntun bẹ́ẹ̀ kò ní òye kíkún nípa tẹ̀mí, èyí táwọn tó ti pẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn máa ń ní. Tún ronú nípa àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣì jẹ́ ọmọdé tàbí ọ̀dọ́langba. Kì í ṣe ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn nìkan ni wọ́n ti nílò àfiyèsí, wọ́n tún nílò àfiyèsí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà nínú ìjọ pẹ̀lú.
Ní tòótọ́, gbogbo Kristẹni ni àwọn nǹkan ayé ń fẹjú mọ́, títí kan ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ làkàkà láti dènà òòfà líle tó lè máa fà wá láti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ ti ayé. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn akéde Ìjọba náà lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé àwọn èèyàn ò fetí sí ìwàásù wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ni àìsàn ńlá ń ṣe. Ọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu lè máà jẹ́ kí orí àwọn kan yá láti máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Ká sòótọ́, gbogbo wa—títí kan àwọn tó ti pẹ́ nínú òtítọ́—ló nílò ìrànlọ́wọ́ yíyẹ látọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́.
Ẹ̀mí Tó Yẹ Kí Wọ́n Máa Fi Ṣiṣẹ́
A gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní níyànjú pé: ‘Ẹ jẹ́ kí ọkàn-àyà yín gbòòrò’! (2 Kọ́ríńtì 6:11-13) Ì bá dára tí àwọn Kristẹni alàgbà bá lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí nínú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn wọn. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ńkọ́, àwọn tí ọ̀pọ̀ nínú wọn máa di olùṣọ́ àgùntàn lọ́la?
Bí àwọn Kristẹni alàgbà bá fẹ́ jẹ́ ìbùkún fún agbo, wọn ò gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ yìí bí ẹni pé ńṣe ni wọ́n ń fagbára mú wọn ṣe é. A gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.” (1 Pétérù 5:2) Nítorí náà, ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn lọ́nà tó gbéṣẹ́ ní ẹ̀mí ìmúratán àti ìháragàgà láti sin àwọn ẹlòmíràn nínú. (Jòhánù 21:15-17) Ó túmọ̀ sí rírí àìní àwọn àgùntàn kí wọ́n sì yára kánkán láti bójú tó àìní náà. Ó túmọ̀ sí fífi àwọn ànímọ́ àtàtà ti Kristẹni tí a mọ̀ sí èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run hàn nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—Gálátíà 5:22, 23.
Nígbà mìíràn, ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn kan bíbẹ àwọn arákùnrin wò nínú ilé wọn. a Àmọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ‘jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn gbòòrò’ máa ń lo ara wọn dé góńgó. Ìyẹn ni pé wọ́n máa ń ṣe ju kí wọ́n kàn máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ ni wọ́n máa ń lò láti fi ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn mìíràn nínú agbo.
Kíkọ́ Àwọn Mìíràn Láti Di Olùṣọ́ Àgùntàn
Arákùnrin èyíkéyìí, láìfi ọjọ́ orí pè, tí ó “bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.” (1 Tímótì 3:1) Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló ti fi hàn pé àwọn ti múra tán láti tẹ́wọ́ gba àwọn àǹfààní púpọ̀ sí i. Nítorí ìdí èyí, inú àwọn alàgbà máa ń dùn láti ran àwọn arákùnrin tó múra tán wọ̀nyí lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí ní ‘nínàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó.’ Ìyẹn túmọ̀ sí kíkọ́ wọn láti di olùṣọ́ àgùntàn tó gbéṣẹ́.
Nítorí tí ìjọ Kristẹni ti Jèhófà rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ọ̀pá ìdíwọ̀n gíga ti Ọlọ́run, kò ṣeé ṣe fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn èké láti dá wọn lágara bíi ti àwọn táa ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Ìsíkíẹ́lì 34:2-6. Èèyànkéèyàn làwọn wọ̀nyí jẹ́ lójú Jèhófà, bó sì ṣe yẹ kó rí gan-an nìyẹn. Dípò tí wọn ì bá fi máa bọ́ agbo, ara wọn ni wọ́n ń bọ́. Wọn ò fún àwọn tí ń ṣàìsàn lókun, wọn ò wo àwọn aláìlera sàn, wọn ò di ọgbẹ́ àwọn tí ó fara pa, wọn ò sì mú àwọn tí ó fọ́n ká tàbí tí ó ti sọnù padà. Ìṣe àwọn tí wọ́n pera wọn ní olùṣọ́ àgùntàn ò yàtọ̀ sí ìkookò rárá, gbígbo ni wọ́n ń gbo àwọn àgùntàn mọ́lẹ̀. Àwọn àgùntàn tí wọ́n pa tì fọ́n ká, wọ́n ń rìn káàkiri láìmọ ibi tí wọ́n ń lọ, kò sì sí ẹni tó máa bójú tó wọn.—Jeremáyà 23:1, 2; Náhúmù 3:18; Mátíù 9:36.
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn aláìṣòótọ́ wọ̀nyẹn, àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà. Wọ́n ń ṣèrànwọ́ láti darí àwọn àgùntàn lọ sí “pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko” àti “sí ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa” nípa tẹ̀mí. Wọ́n ń sapá láti darí wọn sí “àwọn òpó ọ̀nà òdodo” nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Jèhófà dáradára, kí wọ́n sì fi í sílò. Wọ́n lè ṣe èyí dáradára, nítorí pé wọ́n “tóótun láti kọ́ni.”—1 Tímótì 3:2.
Orí pèpéle làwọn alàgbà ti sábà máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Síbẹ̀, wọ́n tún ń kọ́ni láyè ara wọn. Lóòótọ́, àwọn kan lè pegedé nínú kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, nígbà tó jẹ́ pé sísọ àsọyé lórí pèpéle lẹ̀bùn títayọ ti àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́ ṣá o, pé ẹnì kan ò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́bùn àtikọ́ni lápá ibì kan ò túmọ̀ sí pé kò tóótun láti jẹ́ olùkọ́. Gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ làwọn alàgbà máa ń lò láti kọ́ni, títí kan ṣíṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn kan wà tí wọ́n máa ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà, àpẹẹrẹ kan ni ìbẹ̀wò tí a ṣètò rẹ̀. Àmọ́ ọ̀pọ̀ iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn la lè ṣe lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, èyí sì tún máa ń ṣeni láǹfààní púpọ̀.
Olùṣọ́ Àgùntàn àti Olùkọ́ ní Gbogbo Ìgbà
Dókítà kan gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ àti ìrírí kó tó lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn aláìsàn tún máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an nígbà tó bá fi inú rere, ìyọ́nú, àníyàn àti ìfẹ́ tòótọ́ hàn sí wọn. Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ jẹ́ ara àkópọ̀ ìwà rẹ̀. Àwọn ànímọ́ kan náà ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ara àkópọ̀ ìwà olùkọ́ àti olùṣọ́ àgùntàn rere, kó di apá kan ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ ojoojúmọ́. Olùkọ́ gidi yóò wà ní sẹpẹ́ láti fún àwọn tó bá wà láyìíká rẹ̀ nítọ̀ọ́ni nígbàkigbà tó bá yẹ. Òwe 15:23 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí ó . . . bọ́ sí àkókò mà dára o! ‘Àkókò tí ó bọ́ sí i’ lè jẹ́ ìgbà tó bá ń sọ̀rọ̀ láti orí pèpéle, ó lè jẹ́ ìgbà tó bá ń wàásù láti ilé dé ilé, tàbí ìgbà tó bá ń báni jíròrò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lórí tẹlifóònù. Bákan náà ni olùṣọ́ àgùntàn rere máa ń làkàkà láti fi àwọn ànímọ́ àtàtà, tó jẹ́ ti ẹni tó bìkítà hàn ní gbogbo ìgbà, kì í ṣe kìkì ìgbà tó bá ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn nìkan. Nígbà tó sì jẹ́ pé ó ti ‘jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ̀ gbòòrò,’ yóò máa lo gbogbo àǹfààní tó bá rí láti ṣe olùṣọ́ àwọn àgùntàn, nípa fífún wọn ní àbójútó tí wọ́n nílò ní àkókò tí ó tọ́. Èyí ni yóò sọ ọ́ di ẹni ọ̀wọ́n lójú àwọn àgùntàn.—Máàkù 10:43.
Wolfgang, tí ó ti di alàgbà báyìí, rántí ìbẹ̀wò ọlọ́rẹ̀ẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́ tí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan àti ìyàwó rẹ̀ ṣe sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀. Ó ní: “Inú àwọn ọmọ wa dùn púpọ̀ sí àfiyèsí tí wọ́n fún wọn àti àkókò alárinrin tí a gbádùn. Wọ́n ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ di òní olónìí.” Dájúdájú, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí fi hàn pé òun bìkítà; ó ‘jẹ́ kí ọkàn-àyà òun gbòòrò.’
Àǹfààní mìíràn láti ‘jẹ́ kí ọkàn-àyà ẹni gbòòrò’ ni nípa ṣíṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aláìsàn, kíkọ ọ̀rọ̀ ìṣírí ṣókí ránṣẹ́ sí wọn, tàbí kí o tẹ̀ wọ́n láago lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù—ṣáà ṣe ohunkóhun tóo bá lè ṣe kí wọ́n fi lè mọ̀ pé o bìkítà! Ṣèrànwọ́ nígbà tó bá yẹ. Bí wọ́n bá fẹ́ sọ̀rọ̀, tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbòkègbodò tó dára, tó sì wúni lórí nínú ìjọ yín àti láwọn ibòmíràn. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ọjọ́ ọ̀la ológo tó wà nípamọ́ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.—2 Kọ́ríńtì 4:16-18.
Ní Àfikún sí Ìbẹ̀wò Olùṣọ́ Àgùntàn
Tí a bá fi ète iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn sọ́kàn, a óò rí i kedere pé bí ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn gẹ́gẹ́ bí àṣà sí ilé àwọn ará ti ṣe pàtàkì tó, ó wulẹ̀ jẹ́ apá kan lára ohun tó ní nínú ni. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ máa ‘ń jẹ́ kí ọkàn-àyà òun gbòòrò’ nípa jíjẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ lábẹ́ ipòkípò tó bá dìde àti ní gbogbo ìgbà. Ìbátan ọlọ́yàyà tó mú dàgbà pẹ̀lú àwọn ará mú un dá wọn lójú pé ní àkókò Sáàmù 23:4.
ìṣòro, àwọn ò ní láti bẹ̀rù ohun búburú kankan, ní mímọ̀ pé àwọn arákùnrin wọn onífẹ̀ẹ́, ìyẹn àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn, bìkítà fún wọn.—Àní sẹ́, gbogbo ẹ̀yin Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn, ‘ẹ jẹ́ kí ọkàn-àyà yín gbòòrò.’ Ẹ fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sí àwọn ará—ẹ fún wọn níṣìírí, ẹ fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ẹ gbé wọn ró nípa tẹ̀mí ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ bá ti lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́. (Kólósè 1:23) Nítorí fífi tí a fi àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ‘jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn gbòòrò,’ jíǹkí àwọn àgùntàn, àwọn àgùntàn kò ní ṣe aláìní ohunkóhun. Wọn ó pinnu bíi ti Dáfídì láti máa gbé inú ilé Jèhófà fún gígùn ọjọ́. (Sáàmù 23:1, 6) Ṣebí ohun tí olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ ń wá nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A lè rí àwọn ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti September 15, 1993, ojú ìwé 20 sí 23, àti ti March 15, 1996, ojú ìwé 24 sí 27.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn Kristẹni Olùṣọ́ Àgùntàn
• Ń fi ìháragàgà sìn tinútinú
• Ń bọ́ agbo, wọ́n sì ń ṣàníyàn nípa wọn
• Ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti nàgà sí dídi olùṣọ́ àgùntàn
• Ń bẹ àwọn aláìsàn wò, wọ́n sì ń tọ́jú wọn
• Ń wà lójúfò láti ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ ní gbogbo ìgba
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Yálà nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, tàbí láwọn ìpàdé, tàbí níbi àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́, gbogbo ìgbà làwọn alàgbà máa ń jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn