Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Atànmọ́lẹ̀ fún Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

Atànmọ́lẹ̀ fún Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Atànmọ́lẹ̀ fún Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

ÌTÀN NÍPA GEORGE YOUNG GẸ́GẸ́ BÍ RUTH YOUNG NICHOLSON ṢE SỌ Ọ́

“Kí ló wá fà á táa fi dákẹ́, tá ò sọ̀rọ̀ láti orí àga ìwàásù wa? . . . Irú èèyàn wo la fẹ́ sọ ara wa dà, táa bá dákẹ́ lẹ́yìn táa ti rí ẹ̀rí tó dájú pé òótọ́ ni nǹkan tí mo kọ wọ̀nyí? Ẹ má wulẹ̀ jẹ́ ká máa fi òtítọ́ pa mọ́ fáwọn èèyàn, ẹ jẹ́ ká pòkìkí rẹ̀, ká la òótọ́ ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ láìfibọpo bọyọ̀.”

Ọ̀RỌ̀ wọ̀nyí wá látinú lẹ́tà olójú ìwé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tí bàbá mi kọ, tó fi sọ fún wọn pé kí wọ́n yọ orúkọ òun kúrò nínú ìwé ọmọ ẹgbẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Ọdún 1913 nìyẹn ṣẹlẹ̀. Látìgbà yẹn títí lọ, ló ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tó kún fún ìgbòkègbodò, èyí tó jẹ́ kí ó sìn gẹ́gẹ́ bí atànmọ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. (Fílípì 2:15) Láti kékeré ni mo ti ń ṣàkójọ àwọn ìtàn nípa àwọn ìrírí bàbá mi látẹnu àwọn ẹbí àti látinú àwọn ìwé ìtàn, àwọn ọ̀rẹ́ mi sì ràn mí lọ́wọ́ láti kó ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ jọ. Lọ́pọ̀ ọ̀nà ni ìgbésí ayé bàbá mi gbà rán mi létí ìgbésí ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Gẹ́gẹ́ bíi ti àpọ́sítélì yẹn tó jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” bàbá mi máa ń múra tán nígbà gbogbo láti rin ìrìn àjò lọ síbi tí yóò ti lọ jẹ́ iṣẹ́ Jèhófà fáwọn èèyàn gbogbo ilẹ̀ àti erékùṣù. (Róòmù 11:13; Sáàmù 107:1-3) Ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín nípa bàbá mi tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ George Young.

Àwọn Ọdún Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

Bàbá mi ni ọmọkùnrin tí John àti Margaret Young bí kẹ́yìn, wọ́n jẹ́ ará Scotland, onísìn Presbyterian sì ni wọ́n. September 8, 1886, ni wọ́n bí i, kété lẹ́yìn tí ìdílé wọ́n ṣí láti Edinburgh, Scotland, lọ sí British Columbia ní ìwọ̀ oòrùn Kánádà. Wọ́n ti bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—ìyẹn Alexander, John, àti Malcolm—ní Scotland ní àwọn ọdún díẹ̀ ṣáájú. Bàbá mi gba ọdún méjì lọ́wọ́ Marion, èyí obìnrin tó jẹ́ àbúrò àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyẹn, orúkọ àpọ́nlé tí wọ́n sì sọ àbúrò wọn yìí ni Nellie.

Oko kan tó wà nílùú Saanich, tí kò jìnnà sí Victoria, British Columbia, la ti tọ́ wọn dàgbà, àwọn ọmọ náà sì gbádùn ara wọn gan-an. Lákòókò kan náà, wọ́n kọ́ bí a ṣe ń tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́. Fún ìdí yìí, kí àwọn òbí wọn tó ti ìrìn àjò wọn sí Victoria dé, wọ́n á ti ṣe gbogbo iṣẹ́ àyíká ilé, gbogbo ilé á sì ti mọ́ tónítóní.

Bí ọjọ́ ti ń lọ, bàbá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwakùsà àti iṣẹ́ gígé gẹdú. Àwọn ọmọkùnrin Young wá gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí onígẹdú (ìyẹn, àwọn ọkùnrin tí ń yẹ ilẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ó dáa fún igi gẹdú), wọ́n sì tún mọ̀ nípa káràkátà òwò gẹdú. Bàbá mi ló wà nídìí káràkátà.

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìfẹ́ tí bàbá mi ní sí àwọn ohun tẹ̀mí jẹ́ kó pinnu pé òun fẹ́ di òjíṣẹ́ àwọn onísìn Presbyterian. Àmọ́ láàárín àkókò yẹn, Charles Taze Russell, tí í ṣe ààrẹ àkọ́kọ́ ti Zion’s Watch Tower Tract Society, máa ń ṣe àwọn ìwàásù kan tó máa ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn, ìwọ̀nyí sì nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà jíjinlẹ̀. Àwọn ohun tí bàbá mi kọ́ ló wá sún un tó fi kọ lẹ́tà táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀, tó ní kí wọ́n yọ orúkọ òun kúrò nínú ìwé ọmọ ẹgbẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì.

Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, àmọ́ lọ́nà tó ṣe kedere ni Bàbá fi lo àwọn ẹsẹ Bíbélì láti já irọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì pé ọkàn ènìyàn kì í kú àti pé Ọlọ́run yóò máa dá ọkàn àwọn ènìyàn lóró títí láé nínú iná ọ̀run àpáàdì. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó tú ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan fó, ó fi hàn gbangba pé kì í ṣe inú ẹ̀sìn Kristẹni ló ti wá, ó sì fi Ìwé Mímọ́ ti gbogbo rẹ̀ lẹ́yìn. Láti ìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ti ṣe é, tó ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ lo gbogbo agbára àti okun rẹ̀ fún ògo Jèhófà.

Ní 1917, lábẹ́ ìdarí Watch Tower Society, Bàbá bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí àwọn arìnrìn-àjò onísìn, ìyẹn lorúkọ tí wọ́n ń pe àwọn aṣojú arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Ní àwọn ìlú ńláńlá àti ìlú kéékèèké jákèjádò Kánádà ló ti ń sọ àsọyé, tó sì ń fi sinimá àti àwòrán ara ògiri táa mọ̀ sí “Photo-Drama of Creation” [“Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá”] hàn. Ńṣe ni àwọn gbọ̀ngàn ìwòran máa ń kún fọ́fọ́ nígbà ìbẹ̀wò Bàbá. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìbẹ̀wò ìrìn àjò onísìn rẹ̀ máa ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì títí fi di ọdún 1921.

Ìwé ìròyìn Winnipeg kan sọ pé Ajíhìnrere Young sọ̀rọ̀ níwájú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ènìyàn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò sì ráyè wọlé nítorí pé gbọ̀ngàn náà kún fọ́fọ́. Ní Ottawa, ó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Lílọ sí Ọ̀run Àpáàdì Bọ̀.” Níbẹ̀, ọkùnrin àgbàlagbà kan ròyìn pé: “Nígbà tí George Young parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ké sí agbo àwọn àlùfáà kan wá sórí pèpéle kí wọ́n wá bá òun jíròrò kókó náà, ṣùgbọ́n kò sí ìkankan lára wọn tó ṣísẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kí n mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́.”

Kò sí ìṣẹ́jú kan tí Bàbá kì í gbìyànjú láti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí nígbà àwọn ìbẹ̀wò ìrìn àjò onísìn rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, á wá sáré gìdìgìdì lọ wọ ọkọ ojú irin lọ sí ibùdó tó kàn. Nígbà tó jẹ́ pé ọkọ̀ ló ń wọ̀ kiri, àárọ̀ kùtù kí oúnjẹ àárọ̀ tó délẹ̀ ló ti máa tẹkọ̀ létí lọ sí ibùdó tó kàn. Ní àfikún sí jíjẹ́ tí Bàbá jẹ́ onítara, wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí olùgbatẹnirò, òkìkí rẹ̀ sì kàn nítorí àwọn iṣẹ́ Kristẹni tó ń ṣe àti nítorí ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀.

Lára ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀ tó kọ́kọ́ lọ, ọ̀kan tó jẹ́ mánigbàgbé ni èyí tó wáyé ní Edmonton, Alberta, ní 1918. Gbogbo mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ ló wà níbẹ̀ nítorí ìrìbọmi Nellie. Èyí sì ni ìgbà ìkẹyìn táwọn ọmọkùnrin inú ìdílé náà jọ wà pa pọ̀. Ọdún méjì lẹ́yìn náà ni otútù àyà pa Malcolm. Ìrètí ìyè ti ọ̀run ni Malcolm àti àwọn arákùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pẹ̀lú Bàbá jùmọ̀ ní, gbogbo wọ́n sì ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí dójú ikú.—Fílípì 3:14.

Ó Gbéra Lọ Sẹ́nu Iṣẹ́ ní Ilẹ̀ Òkèèrè

Lẹ́yìn tí Bàbá parí iṣẹ́ ìwàásù jákèjádò Kánádà ní September 1921, Joseph F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, sọ pé kí ó forí lé àwọn erékùṣù Caribbean. Kò sí ibi tí Bàbá ti fi “Photo-Drama of Creation” hàn tí àwọn èrò kò ti kóra jọ pìtìmù. Láti Trinidad, ó kọ̀wé pé: “Ibẹ̀ kún fọ́fọ́, ọ̀pọ̀ èrò la sì dá padà. Ní alẹ́ ọjọ́ kejì, ńṣe làwọn èèyàn ya bo ilé náà pìtìmù.”

Nígbà tó wá di 1923, wọ́n ní kí Bàbá kọjá sí ilẹ̀ Brazil. Níbẹ̀, ó bá àwọn àwùjọ ńláńlá sọ̀rọ̀, nígbà míì ó máa ń háyà àwọn ògbufọ̀. Ilé Ìṣọ́ December 15, 1923, lédè Gẹ̀ẹ́sì ròyìn pé: “Láti June 1 sí September 30, Arákùnrin Young ṣe ìpàdé ìta gbangba mọ́kànlélógún, àròpọ̀ àwọn tó pésẹ̀ sí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ egbèjìdínlógún [3,600]; ó ṣe ìpàdé ìjọ méjìdínláàádọ́ta, àwọn tó pésẹ̀ sí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100]; ó sì pín àròpọ̀ ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Potogí lọ́fẹ̀ẹ́.” Ọ̀pọ̀ ló fìfẹ́ hàn nígbà tí Bàbá sọ àsọyé náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.”

Nígbà tí wọ́n ya àwọn ilé tuntun sí mímọ́ ní Brazil ní March 8, 1997, ìwé pẹlẹbẹ tó ròyìn nípa ìyàsímímọ́ náà sọ pé: 1923: George Young dé sí Brazil. Ó ṣètò ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní àárín gbùngbùn ìlú Rio de Janeiro.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lédè Spanish, a tún nílò rẹ̀ lédè Potogí, ìyẹn, lájorí èdè tí wọ́n ń sọ ní Brazil. Fún ìdí yìí, ní October 1, 1923, a bẹ̀rẹ̀ sí tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde lédè Potogí.

Bàbá bá àwọn èèyàn kan tí kò ṣeé gbàgbé pàdé ní Brazil. Ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin ará Potogí kan tó rí já jẹ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jacintho Pimentel Cabral, tó ní kí wọ́n wá máa lo ilé òun fún ìpàdé. Kò pẹ́ tí Jacintho tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, ó sì di mẹ́ńbà iléeṣẹ́ ẹ̀ka lẹ́yìn ìgbà náà. Ẹlòmíì tún ni Manuel da Silva Jordão, ọ̀dọ́kùnrin ará Potogí tó jẹ́ olùṣọ́gbà. Ó gbọ́ àsọyé ìta gbangba kan tí Bàbá sọ, èyí sì sún un láti padà sí ilẹ̀ Potogí láti lọ sìn gẹ́gẹ́ bí apínwèé-ìsìn-kiri, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn.

Bàbá wọ ọkọ̀ ojú irin lọ jákèjádò Brazil gan-an ni, ó sì bá ọ̀pọ̀ olùfìfẹ́hàn pàdé. Lẹ́nu ọ̀kan lára àwọn ìrìn àjò rẹ̀, ó pàdé Bony àti Catarina Green, ó sì wọ̀ sílé wọn fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì, ó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wọn. Ó kéré tán, bí ẹni méje nínú ìdílé náà ló fàmì ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìbatisí nínú omi lẹ́yìn náà.

Ẹlòmíì tí Bàbá tún pàdé ni Sarah Bellona Ferguson ní 1923. Ní 1867, ọ̀dọ́bìnrin yìí àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin, ìyẹn, Erasmus Fulton Smith àti ìyókù ìdílé wọn, ṣí wá sí Brazil láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Láti 1899 ló ti ń rí Ilé Ìṣọ́ gbà déédéé nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́. Àbẹ̀wò Bàbá ni àǹfààní tí Sarah àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti ìbátan wọn kan tí Bàbá pè ní Àǹtí Sallie, ti ń dúró dè tipẹ́tipẹ́ láti ṣe batisí. Ìyẹn wáyé ní March 11, 1924.

Kò pẹ́ kò jìnnà, Bàbá ti ń wàásù ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà. Ní November 8, 1924, ó kọ̀wé láti Peru pé: “Ṣe ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí pípín ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] ìwé àṣàrò kúkúrú nílùú Lima àti Callao.” Lẹ́yìn èyí ó gbéra, ó di Bolivia láti lọ pín ìwé àṣàrò kúkúrú níbẹ̀. Nípa ìbẹ̀wò yẹn, ohun tó sọ ni pé: “Baba wa ń bù kún ìgbòkègbodò náà. Ará Íńdíà kan ló ràn mí lọ́wọ́. Ibi àwọn orísun odò Amazon ló ń gbé. Ó kó ẹgbẹ̀rún ìwé àṣàrò kúkúrú dání padà lọ sílé.”

Nípasẹ̀ àwọn ìsapá bàbá mi, a fúnrúgbìn òtítọ́ Bíbélì sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní àwọn Ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà. Ilé Ìṣọ́ ti December 1, 1924, lédè Gẹ̀ẹ́sì ròyìn pé: “Ó ti tó ọdún méjì báyìí tí George Young ti wà ní Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà. . . . Àǹfààní ló jẹ́ fún arákùnrin ọ̀wọ́n yìí láti gbé ìhìn rere òtítọ́ dé ìlú Punta Arenas, ní àgbègbè Ọrùn Omi Magellan.” Bàbá tún mú ipò iwájú nínú títan iṣẹ́ ìwàásù dé àwọn orílẹ̀-èdè bíi Costa Rica, Panama, àti Venezuela. Ó ń wàásù nìṣó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibà ti kọlù ú, tí ara rẹ̀ kò sì yá.

Ó Tún Gbéra, Ó Di Yúróòpù

Ní March 1925, Bàbá kó sínú ọkọ̀ òkun, ó di Yúróòpù, níbi tó ti nírètí àtipín ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì ní Sípéènì àti ilẹ̀ Potogí, kí ó sì ṣètò bí Arákùnrin Rutherford ṣe máa sọ àwon àsọyé fún gbogbo èèyàn. Àmọ́ lẹ́yìn tí Bàbá gúnlẹ̀ ní Sípéènì, ó ní ominú ń kọ òun pé bóyá ló máa ṣeé ṣe fún Arákùnrin Rutherford láti sọ irú àwọn àsọyé bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ̀mí ẹ̀tanú tó gbòde kan nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn.

Nínú èsì Arákùnrin Rutherford, ó fa ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà 51:16 yọ, tó kà pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ, mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́ mọ́lẹ̀, kí n lè gbin àwọn ọ̀run, kí n sì lè fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, kí n sì lè wí fún Síónì pé, Ìwọ ni ènìyàn mi.” (King James Version) Pẹ̀lú ìyẹn, Bàbá parí èrò sí pé: “Láìsí àní-àní, ìfẹ́ Olúwa ni pé kí n máa bá ètò nìṣó, kí n sì jẹ́ kí Olúwa pinnu ohun tí ìyọrísí rẹ̀ yóò jẹ́.”

Ní May 10, 1925, Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé nípasẹ̀ lílo ògbufọ̀ kan ní Gbọ̀ngàn Ìwòran Novedades nílùú Barcelona. Àwọn tó wá lé ní ẹgbẹ̀rún méjì, títí kan ọkùnrin onípò gíga kan nínú iṣẹ́ ìjọba àti ẹ̀ṣọ́ pàtàkì kan tó wà lórí ìtàgé. Ètò kan náà ló wáyé nílùú Madrid, ẹgbẹ̀fà [1,200] ló sì wá. Ìfẹ́ táwọn èèyàn fi hàn lẹ́yìn fífetísí àsọyé wọ̀nyí ló jẹ́ kí wọ́n dá ẹ̀ka iléeṣẹ́ sílẹ̀ ní Sípéènì, èyí tí a fi “sábẹ́ àbójútó George Young,” gẹ́gẹ́ bí 1978 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ti sọ.

Ní May 13, 1925, Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé nílùú Lisbon, nílẹ̀ Potogí. Àbẹ̀wò tó ṣe sí ibẹ̀ sì kẹ́sẹ járí gan-an ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà gbìyànjú láti da ìpàdé náà rú nípa fífariwobọnu àti nípa wíwó àwọn àga mọ́lẹ̀. Lẹ́yìn àwọn àsọyé Arákùnrin Rutherford ní Sípéènì àti ilẹ̀ Potogí, bàbá mi ń bá a lọ ní fífi “Photo-Drama” náà hàn, ó sì tún ṣètò títẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí a sì pín wọn ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn. Ní 1927, ó ròyìn pé “a ti polongo ìhìn rere náà jákèjádò gbogbo ìlú ńlá àti ìlú kékeré tó wà ní Sípéènì.”

Wíwàásù ní Soviet Union

Ibi tó kàn tí Bàbá tún ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ni Soviet Union, ó gúnlẹ̀ síbẹ̀ ní August 28, 1928. Lẹ́tà kan tó kọ ní October 10, 1928, kà lápá kan pé:

“Látìgbà tí mo ti dé Rọ́ṣíà, mo lè fi tọkàntọkàn gbàdúrà ní tòótọ́ pé, ‘Kí ìjọba rẹ dé.’ Mo ti ń kọ́ èdè wọn, ṣùgbọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ yá. Irú ògbufọ̀ tí mo ní ṣọ̀wọ́n, Júù ni, ṣùgbọ́n ó gba Kristi gbọ́, ó sì fẹ́ràn Bíbélì. Mo ti ní àwọn ìrírí tó wúni lórí ṣùgbọ́n mi ò mọ bí wọ́n ṣe máa jẹ́ kí n dúró pẹ́ tó níbí. Lọ́sẹ̀ tó kọjá, wọ́n ní kí n kẹ́rù mi kí n máa lọ láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún, ṣùgbọ́n mo tètè rìn ín, ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n sọ pé kí n ṣì dúró ná.”

Ó kàn sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ní Kharkov, tó jẹ́ ìlú pàtàkì kan nísinsìnyí ní Ukraine, ìfararora ọlọ́yàyà tó wáyé sì mú kí omijé ayọ̀ bọ́ lójú wọn. Wọ́n máa ń ṣe àpéjọpọ̀ kékeré lálaalẹ́ títí di ọ̀gànjọ́ òru. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Bàbá ń kọ̀wé nípa ìpàdé tó bá àwọn ará ṣe yìí, ó sọ pé: “Àwọn ẹni ẹlẹ́ni, wọ́n ti gba ìwọ̀nba àwọn ìwé díẹ̀ tí wọ́n ní, ìjọba sì ń fojú wọn rí màbo, àmọ́ wọ́n láyọ̀.”

Àkànṣe ìwé pẹlẹbẹ tí wọ́n pín fún àwọn tó wá sí ìyàsímímọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tuntun tó wáyé ní June 21, 1997, ní St. Petersburg, Rọ́ṣíà, pe àfiyèsí pàtàkì sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ bàbá mi ní Soviet Union. Ìwé pẹlẹbẹ náà sọ pé wọ́n rán bàbá mi lọ sílùú Moscow, ó sì ròyìn pé bàbá mi gba àṣẹ “láti tẹ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ẹ̀dà àwọn ìwé kékeré náà Freedom for the Peoples àti Where Are the Dead? kí wọ́n lè pín wọn kiri ní Rọ́ṣíà.”

Nígbà tí Bàbá padà dé láti Rọ́ṣíà, wọ́n yàn án sí iṣẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ní South Dakota, ó bẹ Nellena àti Verda Pool wò nínú ilé wọn, àwọn obìnrin tẹ̀gbọ́n tàbúrò yìí sì di míṣọ́nnárì ní Peru ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Wọ́n fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Bàbá ṣe láìṣàárẹ̀, wọ́n sì wí pé: “Dájúdájú, àwọn ará láyé ìgbà yẹn ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà bí wọ́n ti ń jáde lọ sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè wọ̀nyẹn, bí wọn ò tiẹ̀ ní ọ̀pọ̀ nǹkan ìní ti ayé yìí, síbẹ̀ wọ́n ní ọkàn tó kún fún ìfẹ́ fún Jèhófà. Ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n ṣe àṣeyọrí tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.”

Ìgbéyàwó àti Ìrìn Àjò Ẹlẹ́ẹ̀kejì

Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ni Bàbá àti Clara Hubbert tó wá láti Erékùṣù Manitoulin, Ontario, ti ń kọ lẹ́tà síra wọn. Ṣe ni wọ́n jọ ṣe àpéjọpọ̀ Columbus, Ohio, ní July 26, 1931, nígbà tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́wọ́ gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísáyà 43:10-12) Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣègbéyàwó. Kíá, Bàbá tún mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, ó sì rin àwọn erékùṣù Caribbean já. Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ níbẹ̀ láti ṣètò àwọn ìpàdé, ó sì kọ́ àwọn mìíràn nípa bí wọ́n ṣe lè máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtilé-délé.

Màmá rí àwọn àwòrán, káàdì ìkíni, àti lẹ́tà gbà láti Suriname, St. Kitts, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibòmíràn. Àwọn lẹ́tà náà ń ròyìn ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ nígbà míì wọ́n tún ń ṣàlàyé nípa àwọn ẹyẹ, ẹranko, àtàwọn ohun ọ̀gbìn tó wà ní orílẹ̀-èdè náà gan-an tí Bàbá wà. Ní June 1932, Bàbá parí iṣẹ́ rẹ̀ ní Caribbean, ó sì padà sí Kánádà, gbogbo bó sì ṣe ń rin ìrìn àjò rẹ̀, àyè àwọn mẹ̀kúnnù ló máa ń jókòó sí nínú ọkọ̀ òkun. Lẹ́yìn náà, òun àti Màmá jọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún pa pọ̀, wọ́n lo ìgbà òtútù ọdún 1932 sí 1933 ní àgbègbè Ottawa, pẹ̀lú àwùjọ ńlá àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mìíràn.

Ìgbésí Ayé Ìdílé Ráńpẹ́

Ní ọdún 1934, wọ́n bí David, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin. Nígbà tó wà ní kékeré, á dúró lórí ibi tí Màmá ń fi fìlà sí, á sì sọ pé òun ń sọ “àsọyé.” Gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ó ń fi hàn pé òun ní ìtara fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi ti bàbá rẹ̀. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kiri, pẹ̀lú ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lókè ọkọ̀, bí wọ́n ti ń bẹ àwọn ìjọ wò láti etíkun ìlà oòrùn Kánádà títí dé etíkun ìwọ̀ oòrùn. Ọdún 1938 ni wọ́n bí mi, nígbà tí Bàbá ń sìn ní British Columbia. David rántí bíi Bàbá ṣe gbé mi sórí bẹ́ẹ̀dì, tí Bàbá, Màmá, àti David sì kúnlẹ̀ yí bẹ́ẹ̀dì náà ká, bí Bàbá ti ń gba àdúrà ìdúpẹ́ nítorí mi.

Ní ìgbà òtútù 1939, a ń gbé ní Vancouver nígbà tí Bàbá ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní àgbègbè yẹn wò. Ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà táa ti rí ṣà jọ láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ni èyí tí Bàbá kọ ní January 14, 1939, nígbà tó wà ní Vernon, British Columbia. Clara, David, àti Ruth ni Bàbá kọ ọ́ sí, pẹ̀lú àkọlé náà: “Èyí jẹ́ ìfẹnukonu àti ìgbánimọ́ra díẹ̀.” Ìsọfúnni wà nínú rẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ó sọ pé ìkórè pọ̀ níbẹ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan.—Mátíù 9:37, 38.

Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tó padà sí Vancouver látẹnu iṣẹ́ rẹ̀, Bàbá dìgbò lulẹ̀ nínú ìpàdé kan. Àyẹ̀wò ìṣègùn tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé kókó ọlọ́yún kan wà nínú ọpọlọ rẹ̀. May 1, 1939, ló dágbére fáyé. Ọmọ oṣù mẹ́sàn-án ni mí, David sì ti ń sún mọ́ ọmọ ọdún márùn-ún nígbà yẹn. Ìyá wa ọ̀wọ́n, tí òun náà ní ìrètí ti ọ̀run, ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí ó fi kú ní June 19, 1963.

Ojú tí Bàbá fi wo àǹfààní tó ní láti mú ìhìn rere dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè hàn kedere nínú ọ̀kan lára lẹ́tà tó kọ sí Màmá. Ó sọ lápá kan pé: “Jèhófà fi inú rere yọ̀ǹda fún mi láti lọ sí ilẹ̀ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ láti mú ìhìn Ìjọba náà tọ̀ wọ́n lọ. Ìyìn ni fún orúkọ mímọ́ rẹ̀. Ńṣe ni ògo rẹ̀ ń tàn nìṣó nínú àìlera àti àìkúnjú ìwọ̀n àti àìlókun.”

Nísinsìnyí, àwọn ọmọ, ọmọ ọmọ, àti àtọmọdọ́mọ George àti Clara Young pẹ̀lú ń sin Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Wọ́n sọ fún mi pé bàbá mi kò lè ṣe kí ó má lo ọ̀rọ̀ inú Hébérù orí kẹfà, ẹsẹ ìkẹwàá, tó sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” Àwa náà ò jẹ́ gbàgbé iṣẹ́ tí bàbá wa ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Bàbá rèé lápá ọ̀tún, pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Bàbá rèé (tó dúró) pẹ̀lú Arákùnrin Woodworth, Rutherford, àti Macmillan

Nísàlẹ̀: Bàbá nìyẹn (lápá òsì pátápátá) láàárín àwùjọ kan, pẹ̀lú Arákùnrin Russell

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bàbá àti Màmá

Nísàlẹ̀: Lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Èmi, David àti Màmá ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ikú Bàbá