Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Àwọn Alárìíwísí Ò Tíì Kó Èèràn Ràn ọ́?

Ṣé Àwọn Alárìíwísí Ò Tíì Kó Èèràn Ràn ọ́?

Ṣé Àwọn Alárìíwísí Ò Tíì Kó Èèràn Ràn ọ́?

“ALÁRÌÍWÍSÍ lẹni tí kì í rí ànímọ́ dáadáa téèyàn ní, àfi kìkì àléébù. Òwìwí èèyàn ni, tí í ríran lókùnkùn, àmọ́ tí ìmọ́lẹ̀ ń fọ́ lójú, adọdẹ eṣinṣin níbi tí ẹran gidi wà.” Wọ́n ní àlùfáà ọmọ Amẹ́ríkà nì, Henry Ward Beecher, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ló sọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà pé ọ̀rọ̀ yìí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ẹ̀mí táwọn alárìíwísí òde òní ní. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ táwọn eléèbó ń pè ní “cynic,” tí a tú sí alárìíwísí yìí, ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì ló ti pilẹ̀, nígbà yẹn sì rèé, kò wulẹ̀ túmọ̀ sí ẹnì kan tó ní irú ẹ̀mí yẹn. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, agbo àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí kan ni wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ yẹn fún.

Báwo ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Alárìíwísí ṣe bẹ̀rẹ̀? Kí ni wọ́n ń fi kọ́ni? Ǹjẹ́ èrò Alárìíwísí yẹ Kristẹni?

Àwọn Alárìíwísí Ìgbàanì —Ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti Ìgbàgbọ́ Wọn

Àwọn ará Gíríìsì ìgbàanì kúndùn fífọ̀rọ̀ jomi-toro ọ̀rọ̀ àti fífèrò wérò. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn títí ó fi di Sànmánì Tiwa, àwọn èèyàn bíi Socrates, Plato, àti Aristotle ti gbé àwọn ìmọ̀ ọgbọ́n orí kan kalẹ̀ tó sọ wọ́n di olókìkí. Ẹ̀kọ́ wọn ní ipa jíjinlẹ̀ lórí àwọn èèyàn, irú àwọn èròǹgbà bẹ́ẹ̀ ṣì wà nínú àṣà àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé títí dòní.

Socrates (470 sí 399 ṣááju Sànmánì Tiwa) sọ pé lílépa àwọn nǹkan ti ara tàbí gbígbádùn afẹ́ ayé kò lè fúnni ní ayọ̀ pípẹ́ títí. Ó tẹnu mọ́ ọn pé ìgbésí ayé tó dá lórí lílépa ìwà funfun nìkan ló lè fúnni láyọ̀ tòótọ́. Socrates ka ìwà funfun sí ọba ìwà. Láti lè ní ìwà funfun, ó kórìíra afẹ́ ayé àti gbogbo kìràkìtà tí kò láyọ̀lé, nítorí ó gbà pé nǹkan wọ̀nyí á pín ọkàn òun níyà. Ó ṣalágbàwí ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìsẹ́ra-ẹni, èyíinì ni àìwa-ilé-ayé-máyà, ìgbé ayé tí kì í ṣe ti afẹfẹyẹ̀yẹ̀.

Socrates gbé ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan kalẹ̀ tí wọ́n ń pè ní ìlànà Socrates. Nígbà tó jẹ́ pé ṣe ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn amòye máa ń gbé èròǹgbà tiwọn kalẹ̀, tí wọ́n á sì fẹ̀rí tì í lẹ́yìn, òdìkejì pátápátá ni ọ̀nà tí Socrates gbé tiẹ̀ gbà. Ńṣe lòun ń tẹ́tí sí àbá èrò orí àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí yòókù, tó sì wá ń tọ́ka àléébù tó wà nínú àwọn èròǹgbà tiwọn. Ọ̀nà yìí ń jẹ́ kéèyàn máa ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn, kí ó sì máa tẹ́ńbẹ́lú wọn.

Onímọ̀ ọgbọ́n orí kan wà lára àwọn ọmọlẹ́yìn Socrates tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Antisthenes (ní nǹkan bí 445 sí 365 ṣááju Sànmánì Tiwa). Òun àtàwọn mélòó kan mìíràn tún fi tiwọn kún ẹ̀kọ́ tí Socrates gbé kalẹ̀, nípa sísọ pé ìwà funfun nìkan ni ìwà rere. Lójú tiwọn, kì í kàn-án ṣe pé lílépa fàájì ń pín ọkàn níyà nìkan ni, ṣùgbọ́n nǹkan ibi ni fàájì. Ni wọ́n bá ya ara wọn láṣo pátápátá, débi pé àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn kò yàtọ̀ sí ìgbẹ́ lójú wọn. Bí àwọn èèyàn ṣe wá ń pè wọ́n ní Alárìíwísí nìyẹn o. Alárìíwísí tí wọ́n ń pè wọ́n yìí, ó jọ pé ó wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì kan (ky·ni·kosʹ) tó ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe ń dijú mágbárí kiri, tí wọ́n sì ń fojú pani rẹ́. Ó túmọ̀ sí “oníwà bí ajá.” a

Ohun Tí Ẹ̀kọ́ Yìí Sọ Ìgbésí Ayé Wọn Dà

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tó jọ pé ó dáa nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Alárìíwísí, irú bí wọ́n ṣe kórìíra ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́, síbẹ̀ náà, àwọn Alárìíwísí ti àṣejù bọ àwọn èròǹgbà wọn. Àṣejù yìí hàn kedere nínú ìgbésí ayé Alárìíwísí tó gbajúmọ̀ jù lọ—ìyẹn onímọ̀ ọgbọ́n orí nì, Diogenes.

Ọdún 412 ṣááju Sànmánì Tiwa ni a bí Diogenes ní Sinope, ìlú ńlá kan tó wà létíkun Òkun Dúdú. Tòun ti bàbá rẹ̀ ni wọ́n jọ ṣí wá sílùú Áténì, níbi tó ti kọ́kọ́ gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ àwọn Alárìíwísí. Antisthenes ló kọ́ Diogenes, ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Alárìíwísí sì kó sí i lórí. Ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ni Socrates gbé nígbà tí Antisthenes gbé ìgbésí ayé ìráre ní tirẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìgbésí ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ni Diogenes wá gbé. Láti fi hàn pé òun kórìíra àwọn ohun amáyédẹrùn sẹ́ẹ̀, wọ́n ní Diogenes fìgbà kan lọ gbé inú ọpọ́n kan fúngbà kúkúrú!

Níbi tí Diogenes ti ń wá ìwà rere gíga jù lọ kiri, a gbọ́ pé ńṣe ló tan àtùpà lọ́sàn-án gangan, tó rin ìgboro ìlú Áténì já, ó lóun ń wá èèyàn tó níwà funfun kiri! Irú ìwà bẹ́ẹ̀ pe àfiyèsí àwọn èèyàn, ọ̀nà yìí sì ni Diogenes àtàwọn Alárìíwísí mìíràn gbà ń kọ́ni. Wọ́n ní nígbà kan rí, Alẹkisáńdà Ńlá béèrè ohun tí Diogenes ń fẹ́ jù lọ. Èsì tí a gbọ́ pé Diogenes fún un ni pé kí Alẹkisáńdà sáà jọ̀ọ́ bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kí ó má bàa dí oòrùn lójú!

Agbe ni Diogenes àtàwọn Alárìíwísí mìíràn ń ṣe kiri. Wọn ò ráyè fún àjọṣepọ̀ ẹ̀dá, wọn kì í sì í lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìlú. A ò mọ̀ bóyá torí ọ̀nà tí Socrates gbà ń jiyàn ló kó sí wọn lórí, àwọn táà ń wí yìí ò tiẹ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹnikẹ́ni. Diogenes wá di ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí pẹ̀gànpẹ̀gàn. “Oníwà bí ajá” làwọn èèyàn ń pe àwọn Alárìíwísí, ṣùgbọ́n Ajá ni orúkọ tí wọ́n sọ Diogenes ní tirẹ̀. Ó kú ní nǹkan bí ọdún 320 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tó jẹ́ ẹni nǹkan bí àádọ́rùn-ún ọdún. Wọ́n fi mábìlì yàwòrán ajá sójú oórì rẹ̀.

Àwọn èròǹgbà kan nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Alárìíwísí tàn kálẹ̀ wọnú àwọn èròǹgbà mìíràn. Àmọ́, nígbà tó yá ìwà àṣejù tí Diogenes àtàwọn tó tẹ̀ lé e hù, mú kí èròǹgbà àwọn Alárìíwísí kan àbùkù. Ńṣe ló pòórá nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Àwọn Alárìíwísí Tòní —Ṣé Ó Yẹ Kí O Fìwà Jọ Wọ́n?

Ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Oxford English Dictionary, pe “cynic [alárìíwísí]” òde òní ní “pẹ̀gànpẹ̀gàn tàbí olùwá-àléébù. . . . Ẹni tó lẹ́mìí àtimáa kọminú sí gbogbo èrò àti ìṣesí onínúure tó tọkàn àwọn èèyàn wá, tó sì ti mọ́ ọn lára láti máa fi ìmọ̀lára yìí hàn nípa pípẹ̀gàn àti títẹ́ni; olùwá-àléébù tí ń wá bóun ṣe máa fi àbùkù kanni.” Ìwà wọ̀nyí pọ̀ nínú ayé tó yí wa ká, ṣùgbọ́n, àwa náà kúkú mọ̀ pé kò bá àkópọ̀ ìwà Kristẹni mu. Gbé àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà Bíbélì tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò.

“Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 103:8, 9) A sọ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfésù 5:1) Bí Ọlọ́run Olódùmarè bá yàn láti fi àánú àti ọ̀pọ̀ yanturu inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn, dípò kí ó jẹ́ “pẹ̀gànpẹ̀gàn tàbí olùwá-àléébù,” ó dájú pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti ṣe bákan náà.

Jésù Kristi, tó jẹ́ àwòrán Jèhófà gẹ́lẹ́, ‘fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún wa kí a lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.’ (1 Pétérù 2:21; Hébérù 1:3) Nígbà míì, Jésù tú irọ́ àwọn ẹ̀sìn fó, ó sì tú àṣírí àwọn iṣẹ́ burúkú táyé ń ṣe. (Jòhánù 7:7) Àmọ́, ó sọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́ ọ̀kan ní rere. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ nípa Nàtáníẹ́lì pé: “Wò ó, ọmọ Ísírẹ́lì kan dájúdájú, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.” (Jòhánù 1:47) Nígbà míì tí Jésù bá ṣe iṣẹ́ ìyanu féèyàn, ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tí onítọ̀hún ní. (Mátíù 9:22) Nígbà táwọn kan sì ronú pé ẹ̀bùn ọpẹ́ tóbìnrin kan mú wá ti pọ̀ jù, Jésù kò bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àríwísí pé ọ̀tọ̀ lohun tó wà lọ́kàn obìnrin náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Ibikíbi tí a bá ti wàásù ìhìn rere yìí ní gbogbo ayé, ohun tí obìnrin yìí ṣe ni a ó sọ pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.” (Mátíù 26:6-13) Jésù jẹ́ adùn-únbárìn àti ọ̀rẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fọkàn tán, àní “ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.”—Jòhánù 13:1.

Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ ẹni pípé, ketekete ni àléébù àwọn aláìpé ì bá máa hàn sí i. Àmọ́, kàkà tí ì bá fi ní ẹ̀mí àìnígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú àwọn èèyàn àti ẹ̀mí àléébù wíwá, ṣe ni ó ń wá ọ̀nà láti tù wọ́n lára.—Mátíù 11:29, 30.

“[Ìfẹ́] a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Òdìkejì gbáà lèrò yìí jẹ́ sí ti ẹ̀mí àwọn alárìíwísí, nítorí wọ́n máa ń fura sí èrò ọkàn àti ìṣesí àwọn ẹlòmíì ni. Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀rẹ́-ò-dénú pọ̀ láyé o; fún ìdí yìí, ó gbàṣọ́ra. (Òwe 14:15) Síbẹ̀síbẹ̀, ìfẹ́ máa ń múra tán láti gba nǹkan gbọ́ nítorí pé ó ń fọkàn tánni, kì í sì í fura láìyẹ.

Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fọkàn tán wọn. Ó mọ ibi tágbára wọn mọ, ju bí àwọn alára ti mọ̀ ọ́n. Ṣùgbọ́n o, Jèhófà kì í fura sáwọn èèyàn rẹ̀ rárá, kì í sì í retí pé kí wọ́n ṣe ohun tágbára wọn ò ká. (Sáàmù 103:13, 14) Síwájú sí i, ànímọ́ rere táwọn èèyàn ní ni Ọlọ́run máa ń wò mọ́ wọn lára, ìyẹn ló fi ń fọkàn tán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin, tó sì máa ń nawọ́ àwọn àǹfààní àti ọlá àṣẹ sí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé.—1 Àwọn Ọba 14:13; Sáàmù 82:6.

“Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn-àyà, mo sì ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín, àní láti fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú èso ìbálò rẹ̀.” (Jeremáyà 17:10) Jèhófà lè mọ ohun náà gan-an tó wà lọ́kàn èèyàn. Ṣùgbọ́n àwa ò lè mọ̀ ọ́n. Fún ìdí yìí, ó yẹ ká yẹra fún níní èrò òdì nípa àwọn ìgbésẹ̀ kan táwọn èèyàn bá gbé.

Bí a bá jẹ́ kí ẹ̀mí àìkìígbára-lénìyàn ta gbòǹgbò nínú wa, kí ó sì wá jẹ gàba lórí ìrònú wa ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, kò sígbà tí ẹ̀mí yìí ò ní pín wa níyà sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ó lè dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tí kì í dawọ́ bo òtítọ́ mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tó ní ẹ̀mí tó dáa nínú bó ṣe ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò. Ó di ọ̀rẹ́ tí wọ́n lè finú hàn.—Jòhánù 15:11-15.

“Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà fi ìmọ̀ràn Jésù Kristi yìí sílò. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo wa la máa ń fẹ́ káwọn èèyàn bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí wọ́n sì máa fi ọ̀wọ̀ wa wọ̀ wá. Dájúdájú, nígbà náà, ó yẹ kí àwa náà máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí a sì máa fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n. Kódà nígbà tí Jésù tú ẹ̀kọ́ èké àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fó láìgba gbẹ̀rẹ́, kò ṣe é lọ́nà àríwísí.—Mátíù 23:13-36.

Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Ẹ̀mí Àríwísí

Bí a bá ní ìjákulẹ̀, èyí lè tètè kó ẹ̀mí àríwísí ràn wá. A lè gbógun ti ẹ̀mí yìí nípa rírántí pé Jèhófà fọkàn tán àwọn èèyàn rẹ̀ aláìpé. Èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlòmíràn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run nínú ipò tí wọ́n wà—gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dá aláìpé tí ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́.

Àwọn ìrírí lílekoko lè sún àwọn kan láti má lè fọkàn tán àwọn èèyàn. Òtítọ́ ni pé kò bọ́gbọ́n mu láti gbé gbogbo ọkàn wa lé ẹ̀dá aláìpé. (Sáàmù 146:3, 4) Àmọ́ nínú ìjọ Kristẹni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń fi tọkàntọkàn sapá láti jẹ́ orísun ìṣírí. Sáà ronú nípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún tó ń ṣe bí ìyá, bàbá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, lọ́kùnrin lóbìnrin, àtàwọn tó ń ṣe bí ọmọ sí àwọn tí kò ní ẹbí mọ́. (Máàkù 10:30) Ronú nípa ọ̀pọ̀ àwọn tó ti jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ lákòókò ìpọ́njú. bÒwe 18:24.

Kì í ṣe ẹ̀mí àríwísí, bí kò ṣe ìfẹ́ ará la fi ń dá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀, nítorí ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn, ẹ sì jẹ́ kí a máa wo àwọn ànímọ́ rere táwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa ní. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ká yàgò fún dídi Alárìíwísí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó tún lè jẹ́ pé orúkọ náà Alárìíwísí wá látinú orúkọ gbọ̀ngàn ìṣeré kan tó wà nílùú Áténì tí wọ́n ń pè ní Ky·noʹsar·ges, níbi tí ọ̀gbẹ́ni Antisthenes ti ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

b Wo àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí náà “Ìjọ Kristẹni—Orísun Àrànṣe Afúnnilókun” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 1999.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Diogenes ni Alárìíwísí tó gbajúmọ̀ jù lọ

[Credit Line]

Látinú ìwé Great Men and Famous Women