Inúnibíni Mú Kí Ìbísí Ya Wọlé ní Áńtíókù
Inúnibíni Mú Kí Ìbísí Ya Wọlé ní Áńtíókù
NÍGBÀ tí inúnibíni peléke lẹ́yìn tí Sítéfánù kú ikú ajẹ́rìíkú, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Ọ̀kan lára àwọn ibi tí wọ́n sá lọ fún ààbò ni Áńtíókù, ní Síríà, tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [550] kìlómítà ní ìhà àríwá. (Ìṣe 11:19) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé níbẹ̀ tẹ̀ lé èyí wá nípa lórí gbogbo ìtàn Kristẹni lápapọ̀. Láti lóye ohun tó ṣẹlẹ̀, yóò dára láti mọ díẹ̀ nípa Áńtíókù.
Tó bá kan ọ̀rọ̀ nípa Ilẹ̀ Ọba Róòmù, yálà ní títóbi ni o, ní ti aásìkí ni o, tàbí ní ti bó ṣe ṣe pàtàkì tó, Róòmù àti Alẹkisáńdíríà nìkan ló yọrí ọlá ju Áńtíókù lọ. Olú ìlú Síríà yìí ló jọba lórí ìhà àríwá ìlà oòrùn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Mẹditaréníà. Áńtíókù (òun nìlú tí a ń pè ní Antakya, Turkey lóde òní) wà lórí Odò Orontes tí ọkọ̀ ojú omi ń rìn kọjá, tó so ó mọ́ èbúté òkun, Seleucia Pieria, tó wà ní nǹkan bí kìlómítà mejìlélọ́gbọ̀n sí odò náà. Òun ni ojúkò ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ tí àwọn oníṣòwò máa ń gbà láàárín Róòmù sí Àfonífojì tí ń bẹ láàárín Odò Tígírísì àti Yúfírétì. Nítorí pé ó jẹ́ ibùdó ìṣòwò, gbogbo ilẹ̀ ọba náà ló ń bá ṣòwò pọ̀, ó sì ń rí lílọ àti bíbọ̀ onírúurú ènìyàn, tó ń mú ìròyìn nípa ìgbòkègbodò ìsìn wá láti gbogbo ilẹ̀ Róòmù.
Ẹ̀sìn àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Hélénì ti gbilẹ̀ ní Áńtíókù. Àmọ́, òpìtàn Glanville Downey sọ pé: “Ní àkókò Kristi, ẹ̀sìn ẹgbẹ́ awo ti ayé àtijọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti ń di ọ̀ràn kí olúkúlùkù di ìgbàgbọ́ tirẹ̀ mú, bí àwọn èèyàn ṣe ń fúnra wọn wá ẹ̀sìn tó tẹ́ wọn lọ́rùn kiri láti yanjú àwọn ìṣòro wọn, kí wọ́n sì lè lé àwọn góńgó wọn bá.” (A History of Antioch in Syria) Ọ̀pọ̀ ló rí ìtẹ́lọ́rùn nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run kan ṣoṣo, nínú ayẹyẹ ìsìn, àti nínú ìlànà ìsìn àwọn Júù.
Àwùjọ ńlá àwọn Júù ti dá dó sí Áńtíókù látìgbà tí wọ́n ti tẹ ìlú ńlá náà dó ní ọdún 300 ṣááju Sànmánì Tiwa. A fojú bù ú pé iye wọn jẹ́ láti ọ̀kẹ́ kan [20,000] sí ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000], èyí tó lé ní ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ibẹ̀. Òpìtàn náà, Josephus, sọ pé àwọn ọba tó jẹ ní ìlà ìdílé Seleucid fún àwọn Júù níṣìírí láti tẹ̀ dó sí ìlú ńlá náà, wọ́n sì fún wọn ní ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ọmọ onílẹ̀. Ní àkókò yẹn, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tún wà lédè Gíríìkì pẹ̀lú. Èyí sì ru ìfẹ́ àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìrètí àwọn Júù nípa Mèsáyà sókè. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn Gíríìkì ni wọ́n ti sọ di aláwọ̀ṣe. Gbogbo èyí ló fà á tí Áńtíókù fi jẹ́ ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú fún àwọn Kristẹni láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn.
Jíjẹ́rìí fún Àwọn Kèfèrí
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí, tí wọ́n sì fọ́n káàkiri láti Jerúsálẹ́mù ló ń bá àwọn tó jẹ́ Júù sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan, tí wọ́n wá láti Kípírọ́sì àti Kírénè Ìṣe 11:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wíwàásù fún àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì àti àwọn aláwọ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, síbẹ̀ wíwàásù ní Áńtíókù dà bí ohun tó jẹ́ tuntun. Kì í ṣe kìkì àwọn Júù ni wọn ń bá sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, Kọ̀nílíù, tó jẹ́ Kèfèrí àti ìdílé rẹ̀ ti di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́, Jèhófà ní láti fi ìran kan han àpọ́sítélì Pétérù kó tó lè yí i lérò padà láti gbà pé kò sí ohun tó burú nínú wíwàásù fún àwọn Kèfèrí, tàbí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè.—Ìṣe 10:1-48.
bá “àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Gíríìkì” sọ̀rọ̀ ní Áńtíókù. (Ní ìlú kan tó gba àwùjọ ńlá àwọn Júù ìgbàanì láyè láti máa bá wọn gbé, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí gbọ́nmisi-omi-ò-to láàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí, àwọn tí kì í ṣe Júù bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ìwàásù, wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà. Ìdí nìyẹn tí Áńtíókù fi jẹ́ ibi tó dára fún irú ìdàgbàsókè bẹ́ẹ̀, ‘iye púpọ̀ sì di onígbàgbọ́.’ (Ìṣe 11:21) Nígbà tí àwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n ń bọ̀rìṣà tẹ́lẹ̀ rí di Kristẹni, a mú wọn gbára dì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láti jẹ́rìí fún àwọn Kèfèrí tí wọ́n ṣì ń bọ̀rìṣà.
Bí ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Áńtíókù, kíá ni wọ́n rán Bánábà síbẹ̀ láti wádìí bí ọ̀ràn ṣe rí. Yíyàn tí wọ́n ṣe yẹn mọ́gbọ́n dání, ó sì fìfẹ́ hàn. Nítorí ará Kípírọ́sì ni, bíi tàwọn tó ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún àwọn tí kì í ṣe Júù. Ọkàn Bánábà yóò balẹ̀ láàárín àwọn Kèfèrí tó wà ní Áńtíókù. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn náà á rí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ àdúgbò itòsí àwọn. a Ẹnì kan tó mọyì iṣẹ́ tí wọ́n ṣe ni. Nítorí náà, “nígbà tí ó dé, tí ó sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún gbogbo wọn ní ìṣírí láti máa bá a lọ nínú Olúwa pẹ̀lú ète àtọkànwá,” “ogunlọ́gọ̀ tí ó pọ̀ ni a sì fi kún Olúwa.”—Ìṣe 11:22-24.
Òpìtàn Downey sọ pé: “Ohun tó mú kí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe ní Áńtíókù ní ìjímìjí yọrí sí rere lè jẹ́ nítorí pé àwọn míṣọ́nnárì ò ní láti bẹ̀rù àwọn Júù agbawèrèmẹ́sìn, irú àwọn tí wọ́n bá pàdé ní Jerúsálẹ́mù; àti pé bó ṣe jẹ́ olú ìlú Síríà yẹn, àwọn ọ̀gágun ló ń ṣàkóso rẹ̀, ìdí nìyẹn tí àlàáfíà fi wà nílùú títí dé àyè kan, tó sì jẹ́ pé kì í sábà sí àyè fún àwọn oníwà ipá tó ń da ìlú rú bí irú èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, níbi tó ti dà bí ẹni pé (ó kéré tán, lákòókò yìí) àwọn ajẹ́lẹ̀ Jùdíà kò káwọ́ àwọn Júù agbawèrèmẹ́sìn.”
Ní irú ipò tó wọ̀ bẹ́ẹ̀ àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó wà láti ṣe, ó ṣeé ṣe kí Bánábà wá rí i pé òun nílò ìrànlọ́wọ́, ó sì wá rántí Sọ́ọ̀lù ọ̀rẹ́ rẹ̀. Èé ṣe tó fi jẹ́ Sọ́ọ̀lù, tàbí Pọ́ọ̀lù ló ronú kàn? Ó ní láti jẹ́ nítorí pé Pọ́ọ̀lù ti gba iṣẹ́ àpọ́sítélì sí àwọn orílẹ̀-èdè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn méjìlá náà. (Ìṣe 9:15, 27; Róòmù 1:5; Ìṣípayá 21:14) Nítorí ìdí èyí, Pọ́ọ̀lù á jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ tó yẹ wẹ́kú nínú pípolongo ìhìn rere náà ní Áńtíókù tó jẹ́ ìlú àwọn Kèfèrí. (Gálátíà 1:16) Bí Bánábà ṣe kọrí sí Tásù nìyẹn, ó rí Sọ́ọ̀lù, ó sì mú un wá sí Áńtíókù.—Ìṣe 11:25, 26; wo àpótí tó wà lójú ìwé 26 sí 27.
A Pè Wọ́n Ní Kristẹni Nípasẹ̀ Ìdarí Àtọ̀runwá
Fún odindi ọdún kan, Bánábà àti Sọ́ọ̀lù “kọ́ ogunlọ́gọ̀ tí ó jọjú, Áńtíókù sì ni a ti kọ́kọ́ tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.” Kò dà bí ẹni pé àwọn Júù ló kọ́kọ́ pe àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní Kristẹni (lédè Gíríìkì) tàbí àwọn ọmọlẹ́yìn Mèsáyà (lédè Hébérù) nítorí pé wọ́n kọ Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà tàbí Kristi, wọn ò sì ní fẹ́ pè é bẹ́ẹ̀ nípa pípe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní Kristẹni. Àwọn kan rò pé ó lè jẹ́ àwọn abọgibọ̀pẹ̀ ló sọ wọ́n ní Kristẹni gẹ́gẹ́ bí orúkọ ìnagijẹ kan láti fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí láti pẹ̀gàn wọn. Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ló fún wọn ní orúkọ náà Kristẹni.—Ìṣe 11:26.
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ ìṣe náà tí a lò pẹ̀lú orúkọ tuntun náà, èyí tí gbogbo gbòò túmọ̀ sí ‘a pè,’ sábà máa ń jẹ mọ́ ohun kan
tó ní agbára tó kọjá ti ẹ̀dá, ohun tó jẹ́ ti òrìṣà, tàbí tó jẹ́ àtọ̀runwá. Ìdí nìyẹn táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fi ń túmọ̀ rẹ̀ sí “láti sọ̀rọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ òrìṣà,” “ṣíṣe ìkéde àtọ̀runwá,” tàbí “láti fúnni ní àṣẹ tàbí ìṣílétí àtọ̀runwá, láti kọ́ni láti ọ̀run.” Níwọ̀n bí wọ́n ti pe àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní Kristẹni ‘nípasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá,’ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ń ṣe ni Jèhófà darí Sọ́ọ̀lù àti Bánábà láti fún wọn ní orúkọ náà.Orúkọ tuntun yìí wá di èyí tí a fi ń pè wọ́n. Àwọn èèyàn ò lè fi àṣìṣe pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ẹ̀ya ìsìn àwọn Júù mọ́, nítorí pé ẹ̀sìn tiwọn yàtọ̀ pátápátá. Ní nǹkan bí ọdún 58 Sànmánì Tiwa, àwọn aláṣẹ Róòmù ti mọ irú ẹni tí àwọn Kristẹni jẹ́ dáadáa. (Ìṣe 26:28) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òpìtàn Tacitus sọ, ní ọdún 64 Sànmánì Tiwa, orúkọ náà ti di èyí tí tẹrú tọmọ mọ̀ ní Róòmù.
Jèhófà Ń Lo Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Olùṣòtítọ́
Ìhìn rere náà tẹ̀ síwájú gan-an ní Áńtíókù. Pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, àti bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe pinnu pé àwọn ó máa bá iṣẹ́ wíwàásù wọn nìṣó, Áńtíókù wá di ibùdó ìsìn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní. Ọlọ́run lo ìjọ tó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gbohùngbohùn láti fi tan ìhìn rere náà dé àwọn ilẹ̀ jíjìn réré. Fún àpẹẹrẹ, Áńtíókù ni ibi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ń gbéra nígbà tó ń lọ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ tó fakíki.
Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lóde òní, ìtara àti ìpinnu àtọkànwá lójú àtakò ti ṣèrànwọ́ láti tan ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ kálẹ̀, ó ti mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere náà, kí wọ́n sì mọrírì rẹ̀. b Nítorí náà, bí o bá dojú kọ àtakò nítorí pé o ń ti ìjọsìn mímọ́ gaara lẹ́yìn, ní in lọ́kàn pé ó nídìí tí Jèhófà fi fàyè gbà á. Bó ṣe wà ní ọ̀rúndún kìíní, a gbọ́dọ̀ fún àwọn èèyàn òde òní láǹfààní àtigbọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì mú ìdúró wọn sí ìhà ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ìpinnu rẹ láti máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà nìṣó lè jẹ́ ohun náà gan-an tí yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti wá sí ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí ojú ọjọ́ bá mọ́lẹ̀ kedere, a lè rí erékùṣù Kípírọ́sì láti Òkè Casius, tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Áńtíókù.
b Wo Ilé Ìṣọ́, August 1, 1999, ojú ìwé 9; Jí!, May 8, 1999, ojú ìwé 17 sí 18; 1999 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 250 sí 252.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
“Àwọn Ọdún Tí A Kò Gbúròó” Sọ́ọ̀lù
Ìgbà tí a mẹ́nu kan Sọ́ọ̀lù kẹ́yìn nínú ìwé Ìṣe kó tó di pé ó lọ sí Áńtíókù ní nǹkan bí ọdún 45 Sànmánì Tiwa ni ìgbà tí àṣírí ọ̀tẹ̀ tí wọ́n dì láti pa á ní Jerúsálẹ́mù tú, tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sì rán an lọ sí Tásù. (Ìṣe 9:28-30; 11:25) Àmọ́ ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn ni ìyẹn ṣẹlẹ̀, ní nǹkan bí ọdún 36 Sànmánì Tiwa. Kí ló wá ń ṣe lákòókò yẹn—ìyẹn ní sáà táwọn kan ń pè ní àwọn ọdún tí a kò gbúròó Sọ́ọ̀lù?
Láti Jerúsálẹ́mù, Sọ́ọ̀lù lọ sí àwọn àgbègbè Síríà àti Sìlíṣíà, àwọn ìjọ tó wà ní Jùdíà sì gbọ́ pé: “Ọkùnrin tí ó ṣe inúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń polongo ìhìn rere nísinsìnyí nípa ìgbàgbọ́ náà tí ó pa run tẹ́lẹ̀ rí.” (Gálátíà 1:21-23) Ó lè jẹ́ pé ìgbòkègbodò rẹ̀ pẹ̀lú Bánábà ní Áńtíókù ni ìròyìn yẹn ń tọ́ka sí, àmọ́ ṣáájú ìyẹn pàápàá, ó dájú pé ọwọ́ Sọ́ọ̀lù ò dilẹ̀. Ní ọdún 49 Sànmánì Tiwa, àwọn ìjọ bíi mélòó kan ti wà ní Síríà àti Sìlíṣíà. Ọ̀kan wà ní Áńtíókù, ṣùgbọ́n àwọn kan rò pé àwọn tó kù ní láti jẹ́ àbájáde ìgbòkègbodò Sọ́ọ̀lù láwọn àkókò tí wọ́n ń pè ní àwọn ọdún tí a kò gbúròó rẹ̀.—Ìṣe 11:26; 15:23, 41.
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà gbọ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbígbàfiyèsí tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Sọ́ọ̀lù ní láti ṣẹlẹ̀ ní àárín àkókò kan náà. Bí kì í bá ṣe àkókò yìí ni, a jẹ́ pé á nira láti mọ àkókò mìíràn tó jẹ ọ̀pọ̀ ìyà gẹ́gẹ́ bí ‘òjíṣẹ́ Kristi’ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Ìgbà wo ni àwọn Júù na Sọ́ọ̀lù ní ẹgba mọ́kàndínlógójì nígbà márùn-ún? Ibo ni wọ́n ti fi ọ̀pá nà án nígbà mẹ́ta? Ibo ló ti ṣe ẹ̀wọ̀n “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ”? Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n fi í sí àhámọ́ ní Róòmù. A mọ àkókò kan tí wọ́n lù ú, tí wọ́n sì fi í sí túbú—ní ìlú Fílípì. Àmọ́, àwọn ìgbà tó kù ńkọ́? (Ìṣe 16:22, 23) Òǹkọ̀wé kan fi hàn pé ní àkókò yìí, Sọ́ọ̀lù “ń jẹ́rìí nípa Kristi láàárín àwọn sínágọ́gù tó wà ní Ibùdó Àwọn Júù Tó Wà Lóde Ilẹ̀ Palẹ́sìnì lọ́nà kan tó lè fa inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn onísìn àtàwọn aláṣẹ ìjọba.”
Ìgbà mẹ́rin ni ọkọ̀ ri Sọ́ọ̀lù, àmọ́, ọ̀kan ṣoṣo ni Ìwé Mímọ́ fún wa ní àlàyé kíkún nípa rẹ̀, èyí tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó to àwọn ìyà tó jẹ lẹ́sẹẹsẹ nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì. (Ìṣe 27:27-44) Nítorí náà, àwọn mẹ́ta yòókù ní láti ṣẹlẹ̀ sí i lákòókò àwọn ìrìn àjò rẹ̀ lójú òkun tí a kò mọ ohunkóhun nípa wọn. Èyíkéyìí tàbí gbogbo ìwọ̀nyí lè ṣẹlẹ̀ sí i ní “àwọn ọdún tí a kò gbúròó” rẹ̀, abájọ tí ìròyìn nípa wọn fi kàn dé Jùdíà!
Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó dà bí ẹni pé àkókò yìí ló ṣẹlẹ̀ ni èyí tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú 2 Kọ́ríńtì 12:2-5. Sọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Mo mọ ọkùnrin kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ẹni tí a gbà lọ sí ọ̀run kẹta ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, lọ sínú párádísè, ó sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kò lè fẹnu sọ, èyí tí kò bófin mu fún ènìyàn láti sọ.’ Ó dájú pé ọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù ń sọ. Níwọ̀n bí ó ti kọ èyí láti nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa, ọdún mẹ́rìnlá ṣáájú ìyẹn yóò mú wa padà sẹ́yìn sí ọdún 41 Sànmánì Tiwa, ní àárín “àwọn ọdún tí a kò gbúròó” rẹ̀.
Láìsí àní-àní, ìran yẹn fún Sọ́ọ̀lù ní ìjìnlẹ̀ òye àrà ọ̀tọ̀ kan. Ṣé kí ó lè mú un gbára dì gẹ́gẹ́ bí “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” ni? (Róòmù 11:13) Ṣé ó wá nípa lórí ọ̀nà tó gbà ronú, ọ̀nà tó gbà kọ̀wé, àti bó ṣe sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbà náà ni? Ǹjẹ́ àwọn ọdún tó wà láàárín àkókò tí Sọ́ọ̀lù yí padà àti ìgbà tí a pè é lọ sí Áńtíókù ṣiṣẹ́ fún dídá a lẹ́kọ̀ọ́ àti sísọ ọ́ di ẹni tí ó dàgbà dénú fún àwọn ẹrù iṣẹ́ lọ́jọ́ iwájú? Ohun yòówù kí àwọn ìdáhùn sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ jẹ́, a lè ní ìdánilójú pé nígbà tí Bánábà ké sí i láti wá ṣèrànwọ́ ní mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ wíwàásù ní Áńtíókù, Sọ́ọ̀lù onítara ti tóótun pátápátá láti ṣe iṣẹ́ náà.—Ìṣe 11:19-26.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
SÍRÍÀ
Orontes
Áńtíókù
Séléúkíà
KÍPÍRỌ́SÌ
ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ
Jerúsálẹ́mù
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Òkè: Áńtíókù òde òní
Àárín: Wíwo Séléúkíà láti ìhà Gúúsù
Ìsàlẹ̀: Ògiri tó yí èbúté Séléúkíá ká