Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Rẹ Lè Túbọ̀ Nítumọ̀?

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Rẹ Lè Túbọ̀ Nítumọ̀?

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Rẹ Lè Túbọ̀ Nítumọ̀?

KÌ Í sábàá jẹ́ bí nǹkan ṣe rí lójú la fi ń mọ bó ṣe níye lórí tó gan-an. Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] dọ́là ni owó bébà tó níye lórí jù lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́, bébà tí wọ́n tẹ owó náà sí lára kò lè ju kọ́bọ̀ mélòó kan lọ lọ́jà.

Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa bóyá bébà lásán-làsàn, tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí, lè fún ìgbésí ayé rẹ ní ìtumọ̀ gidi? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ronú pé ó lè fún ìgbésí ayé àwọn nítumọ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru, tí wọ́n ń sáré owó bí ẹní máa kú. Nígbà míì, bí wọ́n ti ń sáré owó, wọn ò ní janpata nípa ìlera ara wọn, wọn ò sí ní kọ̀ láti pa àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wọn pàápàá tì. Ibo ló máa ń kángun sí? Ǹjẹ́ owó—tàbí ohun tówó lè rà—lè mú ojúlówó ayọ̀ pípẹ́ títí wá?

Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùwádìí ti wí, bí a bá ṣe ń ṣe kìtàkìtà tó, tí à ń wá ayọ̀ tí a gbé ka àwọn nǹkan ìní ti ara, bẹ́ẹ̀ náà ni ayọ̀ ọ̀hún yóò ṣe túbọ̀ máa jìnnà sí wa tó. Akọ̀ròyìn náà, Alfie Kohn, parí èrò sí pé “a ò lè rí ayọ̀ rà lórí àtẹ. . . . Àwọn tó fi ọ̀ràn dídi ọlọ́rọ̀ sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé sábà máa ń ní ìdààmú àti ìsoríkọ́ tó bùáyà, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ní àlàáfíà.”—International Herald Tribune.

Bí àwọn olùwádìí tilẹ̀ rí i dájú pé owó nìkan kò lè fún ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mà gbà o. Èyí ò kúkú yani lẹ́nu, nítorí pé ó máa ń tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ìpolówó ọjà táwọn tó ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń gbọ́ sétí lójoojúmọ́ ayé. Ì báà jẹ́ mọ́tò tàbí midinmíìdìn ni wọ́n ń polówó, ariwo tí wọ́n ń pa ni pé: ‘Ra kiní yìí, wàá sì túbọ̀ láyọ̀.’

Kí ni ìyọrísí gbígbé nǹkan tara lárugẹ ṣáá? Ṣebí èyí ló fà á táwọn èèyàn fi ń pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì! Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Newsweek ti wí, bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìlú Cologne, ní Jámánì, polongo lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé “láwùjọ wa, àwọn èèyàn ò jíròrò nípa Ọlọ́run mọ́.”

Bóyá eré àtijẹ àtimu lo ti ń fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ sá. Bóyá o rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ sáyè fún àwọn nǹkan míì mọ́. Àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè wá rí i pé ìgbésí ayé ò gbọ́dọ̀ mọ sórí kìkì fífi ojoojúmọ́ sá kòókòó jàn-án jàn-án, títí àìsàn á fi wá dá olúwarẹ̀ wó tàbí títí ara á fi wá di ara àgbà, kí gbogbo kìràkìtà ọ̀hún tó dópin.

Ǹjẹ́ títúbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí lè fi kún ayọ̀ rẹ? Kí ni yóò jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ túbọ̀ nítumọ̀?