Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pípolongo Ìhìn Rere Láwọn Oko Ìrẹsì ní Taiwan

Pípolongo Ìhìn Rere Láwọn Oko Ìrẹsì ní Taiwan

Àwa Jẹ́ Irú Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́

Pípolongo Ìhìn Rere Láwọn Oko Ìrẹsì ní Taiwan

TAIWAN jẹ́ ilẹ̀ olójò wẹliwẹli, ìyẹn ló fi jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dún ni ìrẹsì wọn máa ń so wọ̀ǹtìwọnti. Àmọ́ o, nígbà mìíràn òjò lè má rọ̀ sásìkò, àwọn ohun ọ̀gbìn á sì kú. Tí irú àkókò bẹ́ẹ̀ bá wáyé, ṣé àgbẹ̀ á wá jọ̀gọ̀ nù ni? Rárá o. Ó mọ̀ pé ìforítì ló gbà. Ṣe ló máa padà lọ gbin ohun ọ̀gbìn tuntun, tí á sì tún oko náà dá. Bó bá di pé ipò àwọn nǹkan wá dára sí i, àgbẹ̀ náà á kórè oko délé rẹpẹtẹ. Gbígbìn àti kíkórè nípa tẹ̀mí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí èyí.

Fíforítì Í Nínú Ìkórè Tẹ̀mí

Ó ti pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Taiwan ti ń ṣiṣẹ́ kára láti gbin àwọn irúgbìn òtítọ́ ti Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì kórè rẹ̀ ní àwọn àgbègbè kan tó dà bíi pé kò lè méso jáde. Àpẹẹrẹ ọ̀kan lára irú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀ ni Ìjọba Ìbílẹ̀ Miao-li. Àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí àwọn ìsapá àtìgbàdégbà láti jẹ́rìí lágbègbè yẹn. Nítorí náà, lọ́dún 1973, a yan tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà àkànṣe láti lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà lákòókò kíkún. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, àwọn kan fìfẹ́ hàn sí ìhìn rere náà. Àmọ́, kò pẹ́ tí ìfẹ́ wọ́n tutù. Bí a ṣe yan àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe náà sí ibòmíràn nìyẹn.

Ní 1991, a tún yan àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe méjì mìíràn lọ síbẹ̀. Ṣùgbọ́n, gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ tún fi hàn pé ilẹ̀ yẹn ò tíì lè méso wá nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, a ní káwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe náà kúrò níbẹ̀, kí wọ́n lọ máa ṣiṣẹ́ ní àwọn pápá tó jọ pé yóò méso jáde. Nípa báyìí, a fi ilẹ̀ yẹn sílẹ̀ láìro fún sáà kan.

Àwọn Ìsapá Àkọ̀tun Méso Jáde

Ní September 1998, a pinnu pé a ó sapá láti wá àwọn ilẹ̀ eléso kàn ní ìpínlẹ̀ Taiwan tó lọ salalu tí a kò yan ẹnikẹ́ni sí. Ọ̀nà wo la óò gbé e gbà? Nípa yíyan nǹkan bí ogójì aṣáájú ọ̀nà àkànṣe onígbà kúkúrú pé kí wọ́n lọ máa ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ elérò púpọ̀ tí a kò yan ẹnikẹ́ni sí.

Àwọn ìlú ńlá méjì tó tira wọn ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Miao-li wà lára àwọn ìpínlẹ̀ táa yàn fún ìgbòkègbodò yìí. Àwọn arábìnrin mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ àpọ́n ni yóò lọ ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà fún oṣù mẹ́ta, ká lè fi wo bó ṣe máa rí. Kò pẹ́ tí wọ́n débẹ̀ ni wọ́n kọ ìròyìn tó wúni lórí nípa ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n ń bá pàdé. Nígbà tí wọ́n fi máa parí oṣù mẹ́ta tí wọ́n fi ṣe aṣáájú ọ̀nà lágbègbè yẹn, wọ́n ti ń darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n tún dá àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan sílẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ alàgbà kan láti ìjọ itòsí.

Mẹ́ta lára àwọn arábìnrin yìí sọ ọ́ jáde ní kedere pé àwọn á fẹ́ máa bá a nìṣó láti máa bójú tó àwọn ọ̀jẹ̀lẹ́ “ohun ọ̀gbìn” tó ń rú gbẹ̀gẹ́gbẹ̀gẹ́ níbẹ̀. Fún ìdí yìí, a sọ méjì lára wọn di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe títí lọ, ẹnì kẹta sì ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Alàgbà kan láti ìjọ itòsí ṣí wá ságbègbè náà láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó lé ní ọgọ́ta èèyàn tó pésẹ̀ síbi àsọyé fún gbogbo ènìyàn táa kọ́kọ́ sọ lágbègbè yẹn. Ní báyìí o, ìjọ tó wà nítòsí ń ran àwùjọ jòjòló yìí lọ́wọ́ láti máa ṣe àwọn ìpàdé ọjọ́ Sunday déédéé láfikún sí àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mélòó kan. Ó ṣeé ṣe ká dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ lágbègbè yìí láìpẹ́.

Ìforítì Ń Mú Ìbùkún Wá Láwọn Apá Ibòmíràn ní Taiwan

Àwọn àgbègbè mìíràn pẹ̀lú méso jáde. Ní Ìjọba Ìbílẹ̀ I-lan tó wà níhà ìlà oòrùn àríwá erékùṣù náà, wọ́n dá Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tuntun sílẹ̀ lágbègbè tí àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe onígbà kúkúrú ti ṣiṣẹ́.

Bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe onígbà kúkúrú kan ti ń lọ láti ilé dé ilé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó pàdé ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ó sì fi ìwé ìléwọ́ kan tí a to àwọn ìpàdé ìjọ sí hàn án. Ojú ẹsẹ̀ ló béèrè pé: “Ṣé mo lè wá bá yín ṣèpàdé lálẹ́ ọ̀la? Bí mo bá ń bọ̀, irú aṣọ wo ni kí n wọ̀?” Aṣáájú ọ̀nà yìí bẹ̀rẹ̀ sí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́jọ pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Láìpẹ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà bí àwọn alára ṣe máa di akéde ìhìn rere náà, pẹ̀lú góńgó náà lọ́kàn pé àwọn á ṣe batisí.

Ẹlòmíràn ní ìlú kan náà yìí ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ kò rí ẹni tó lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí obìnrin yìí gbọ́ nípa ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, kíá ló tẹ́wọ́ gbà á. Wọ́n fún un níṣìírí pé kó máa múra ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Nígbà tí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe onígbà kúkúrú náà dé láti wá bá a kẹ́kọ̀ọ́, ó rí i pé obìnrin náà ti ṣe “iṣẹ́ àṣetiléwá” rẹ̀, ní ti pé ó ti ra ìwé kan tó kọ gbogbo ìbéèrè tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sí. Lẹ́yìn náà, ó kọ ìdáhùn rẹ̀ sí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan. Ó tún ṣe àdàkọ gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí nínú ẹ̀kọ́ náà sínú ìwé rẹ̀. Ìgbà tí arábìnrin yẹn fi máa dé láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́, obìnrin náà ti múra ẹ̀kọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ sílẹ̀!

A rí irú àwọn àṣeyọrí bẹ́ẹ̀ ní ìlú Dongshih ní àárín gbùngbùn Taiwan. Àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe onígbà kúkúrú náà fi ìwé pẹlẹbẹ tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì sóde láàárín oṣù mẹ́ta tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ìgbà tó fi máa di oṣù kẹta, wọ́n ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rìndínlógún. Ìsẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé láàárín gbùngbùn Taiwan ní September 21, 1999 ba ibi púpọ̀ jẹ́ ní ìlú náà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ olùfìfẹ́hàn ṣì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti rin ìrìn wákàtí kan kí wọ́n tó lè wá sáwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ wọn jù lọ. Lóòótọ́, ó ń béèrè ìforítì bí a óò bá kórè èso wọ̀ǹtìwọnti, ì báà jẹ́ ti ohun ọ̀gbìn tàbí èso tẹ̀mí.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

CHINA

Ọrùn Omi Taiwan

TAIWAN

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.