Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ṣeyebíye Lójú Rẹ̀
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ṣeyebíye Lójú Rẹ̀
LÁTI àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì la ti mọ Lẹ́bánónì mọ àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 72:16; Aísáyà 60:13) Èyí tó níye lórí jù lọ níbẹ̀ ni igi kédárì rẹ̀ gbígbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, tó jẹ́ ohun èlò ìkọ́lé tí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ nítorí ẹwà rẹ̀, òórùn ìtasánsán rẹ̀, àti níní tí ó ní àlòpẹ́. Ní ọ̀rúndún kìíní, ohun kan tó níye lórí ju ìyẹn lọ jáde láti Lẹ́bánónì. Ìwé Ìhìn Rere Máàkù ròyìn pé láti Tírè àti Sídónì, ní àwọn àgbègbè Lẹ́bánónì ìgbàanì, “ni ògìdìgbó ńlá ti wá sọ́dọ̀ [Jésù], nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa bí àwọn ohun tí ó ń ṣe ti pọ̀ tó.”—Máàkù 3:8.
Bákan náà ni lónìí, Lẹ́bánónì ṣì ń so àwọn èso tó ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí fi èyí hàn.
• Wọ́n sọ pé kí ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wissam bá kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ní ilé ẹ̀kọ́. Wissam wá pinnu pé yóò jẹ́ àǹfààní tó dáa láti jẹ́rìí fún wọn. Nítorí náà, ó lo ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? láti múra ọ̀rọ̀ lórí kókó náà, ìṣẹ̀dá. Àmọ́, bí olùkọ́ Wissam ṣe rí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ló sọ pé kókó kan tó ṣe pàtàkì ni, nítorí náà ó sọ pé Wissam lè fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn dé ìṣẹ́jú márùnlélógójì.
Bí Wissam ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni olùkọ́ rẹ̀ ní kó dánu dúró, ó sì ránṣẹ́ lọ pé ọ̀gá àgbà ilé ìwé náà. Láìpẹ́ ni ọ̀gá àgbà náà dé, tí Wissam sì tún mú ọ̀rọ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀. Bí ọ̀gá àgbà yìí ṣe gbọ́ àwọn ìbéèrè tí Wissam fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ dùn, ó sì sọ pé kí gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gba ẹ̀dà àsọyé náà.
Nígbà tó tún ṣe díẹ̀, olùkọ́ mìíràn tó ń kọjá lọ, kíyè sí bí inú àwọn tó wà nínú kíláàsì náà ṣe ń dùn ṣìnkìn, ó sì béèrè ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún un, ó béèrè bóyá ìṣẹ̀dá ni Wissam ń jẹ́rìí gbè ni àbí ẹfolúṣọ̀n. Wọ́n dá a lóhùn pé “ìṣẹ̀dá” ni. Nígbà tí olùkọ́ náà gbọ́ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Wissam, ó sọ fún kíláàsì náà pé: “Ẹ ó rí i nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìṣẹ̀dá ni sáyẹ́ǹsì ti lẹ́yìn kì í ṣe ẹfolúṣọ̀n.”
Àṣé olùkọ́ yìí ti ní ìwé Creation lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀, tó sì ti ń lò ó fún iṣẹ́ olùkọ́ tí ó ń ṣe ní yunifásítì! Kó tó fi ibẹ̀ sílẹ̀, ó béèrè bóyá òun lè kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òun wá ní ọjọ́ kejì, kí Wissam lè bá wọn sọ̀rọ̀. Ìyẹn tún yọrí sí ìjẹ́rìí àtàtà mìíràn nípa Jèhófà.
• Òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ Nina tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún. Ní ọjọ́ kan ọmọ ẹ̀gbọ́n baba rẹ̀ kan fún un ni Bíbélì kan, ó sì mú un lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Onígbàgbọ́ Wò-Ó-Sàn. Tayọ̀tayọ̀ ni Nina fi ka Bíbélì náà, tó sì rí i nínú ibi tó kà pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wàásù, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nìyẹn. Gbogbo àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ ló ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́ ni?” Ìbéèrè yẹn yà á lẹ́nu.
Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé Nina tí wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó kọ́kọ́ ń gbìyànjú láti wá àléébù tí òun lè tọ́ka sí nínú àwọn ẹ̀kọ́ wọn. Ṣùgbọ́n, ó wá rí i pé gbogbo ìdáhùn wọn ló bọ́gbọ́n mu, tí wọ́n sì fi Bíbélì tì lẹ́yìn.
Ohun tí Nina wá kọ́ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀—ìyẹn orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà; àwọn ìbùkún Ìjọba náà; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—ló wá fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun ti rí òtítọ́. Obìnrin náà ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ó sì ṣe ìrìbọmi. Nina ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún láti ọdún méje sẹ́yìn. Dájúdájú, Jèhófà ń bù kún àwọn tó ní ojúlówó ìfẹ́ fún un.—1 Kọ́ríńtì 2:9.