Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí Ìfojúsọ́nà Wa Mọ Níwọ̀n?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí Ìfojúsọ́nà Wa Mọ Níwọ̀n?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí Ìfojúsọ́nà Wa Mọ Níwọ̀n?

INÚ wa máa ń dùn tí a bá rí àwọn ohun tí à ń retí, tí ọwọ́ wa sì tẹ àwọn ohun tí à ń lé. Àmọ́ ṣá o, òótọ́ kúkú ni pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀nà kì í gba ibi táa fojú sí. Ìjákulẹ̀ ṣáá nínú ìgbésí ayé lè jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí ara wa àti sáwọn ẹlòmíì pàápàá. Ọkùnrin ọlọgbọ́n kan sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.”—Òwe 13:12.

Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè fa ìjákulẹ̀? Báwo la ṣe lè ṣiṣẹ́ lórí jíjẹ́ kí ìfojúsọ́nà wa mọ níwọ̀n? Síwájú sí i, èé ṣe tí yóò fi ṣàǹfààní fún wa táa bá ṣe bẹ́ẹ̀?

Ìfojúsọ́nà àti Ìjákulẹ̀

Pẹ̀lú kìràkìtà ayé òde òní, bó ti wù ká sáré tó, a lè máà rọ́wọ́ mú. Ọwọ́ wa máa ń dí ṣáá ni, sísá sókè sódò sì lè muni lómi gan-an, tó bá sì wá di pé ohun tí à ń sáré lé kò tẹ̀ wá lọ́wọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí dá ara wa lẹ́bi. A tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé a ń já àwọn ẹlòmíì kulẹ̀. Cynthia, tí í ṣe ìyàwó ilé àti ìyá ọlọ́mọ, tó mọ wàhálà tó wà nídìí ọmọ títọ́, sọ pé: “Ó máa ń dùn mí gan-an pé mi ò fọwọ́ gidi mú àwọn ọmọ mi tó bó ṣe yẹ, èyí sì ń jẹ́ kí n ronú pé bí mo ṣe ń tọ́ wọn kò dáa tó.” Stephanie, tí í ṣe ọ̀dọ́langba, sọ nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: “Mi ò ráyè ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́ ṣe, èyí sì máa ń jẹ́ kí n di aláìnísùúrù.”

Ìfojúsọ́nà tó ga jù a máa tètè sọni di aṣefínnífínní dóríi bíńtín, èyí ẹ̀wẹ̀, sì lè fa ìjákulẹ̀ tó kọjá sísọ. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ben, sọ pé: “Nígbà tí mo bá wo ìṣe mi, ìrònú mi, tàbí ojú ìwòye mi, gbogbo ìgbà ni mo ń rí i pé ó kù díẹ̀ káàtó. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń ṣe fínnífínní dóríi bíńtín, èyí sì máa ń fa àìnísùúrù, ìjákulẹ̀, àti ìmúlẹ̀mófo.” Kristẹni aya kan, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gail, sọ pé: “Níní èrò ìṣefínnífínní dóríi bíńtín kì í jẹ́ kéèyàn ronú pé òun mà lè kùnà. A máa ń fẹ́ láti jẹ́ ìyá àti aya tó jẹ́ alámọ̀tán. Iṣẹ́ àṣeyege nìkan ló ń fún wa láyọ̀, ìyẹn la fi máa ń kanra tí làálàá wa bá já sásán.”

Ohun mìíràn tó tún lè fa ìjákulẹ̀ ni àìlera àti ọjọ́ ogbó. Àìlègbéra páà àti àìní ìmí bíi ti tẹ́lẹ̀ lè wá jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí ro ara wa pin, ó sì ń dá kún ìjákulẹ̀. Elizabeth sọ pé: “Mo máa ń bínú sí ara mi nítorí pé mi ò lè ṣe àwọn nǹkan tó rọrùn tí mo máa ń ṣe wẹ́rẹ́ tẹ́lẹ̀, kí ó tó di pé àìsàn gbé mi dè.”

Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ohun tó lè fa ìjákulẹ̀. Bí a ò bá sì tètè wá nǹkan ṣe sí i, irú èrò bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé àwọn èèyàn ò mọyì wa. Nítorí náà, àwọn ìgbésẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ wo la lè gbé láti kojú ìjákulẹ̀, kí a sì jẹ́ kí ìfojúsọ́nà wa mọ níwọ̀n?

Bí A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìfojúsọ́nà Wa Mọ Níwọ̀n

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ já ká rántí pé Jèhófà jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti olóye. Sáàmù 103:14 rán wa létí pé: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” Nítorí pé Jèhófà mọ agbára àti ibi tí òye wa mọ, kì í béèrè pé ká ṣe kọjá agbára wa. Ohun tó sì ń béèrè lọ́wọ́ wa ni pé ká “jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run [wa] rìn.”—Míkà 6:8.

Jèhófà tún ń rọ̀ wá pé kí a máa tẹ́wọ́ àdúrà sí òun. (Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Àmọ́, báwo nìyẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́? Àdúrà ń jẹ́ kí a pọkàn pọ̀ kí a sì mọnúúrò. Àdúrà àtọkànwá ń fi hàn pé a ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́—ó jẹ́ àmì ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa nípa fífún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tí èso rẹ̀ jẹ́ àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, inú rere, ìwà rere, àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Lúùkù 11:13; Gálátíà 5:22, 23) Àdúrà tún máa ń dín àníyàn àti ìjákulẹ̀ kù. Elizabeth sọ pé nípasẹ̀ àdúrà, “èèyàn máa ń rí ìtùnú tí kò lè ti orísun mìíràn wá.” Kevin pẹ̀lú gbà, ó ní: “Mo máa ń gbàdúrà fún ìbàlẹ̀ ọkàn àti èrò inú yíyè kooro, kí n lè mọ bí mo ṣe máa yanjú ìṣòro. Jèhófà kò já mi kulẹ̀ rí.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ bí àdúrà ti ṣeyebíye tó. Ìdí nìyẹn tó fi dá a lábàá pé: “Kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Òdodo ọ̀rọ̀, bíbá Jèhófà sọ̀rọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ ní ti gidi láti mú kí àwọn ohun tí à ń retí látọ̀dọ̀ ara wa àti látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn mọ níwọ̀n.

Àmọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a máa ń nílò ìfinilọ́kànbalẹ̀ ojú ẹsẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó bọ́ sákòókò sì dáa gan-an. Fífinú han ọ̀rẹ́ kan tí a fọkàn tán, tí ó sì dàgbà dénú lè jẹ́ kí a ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí ohun tó ń fa ìjákulẹ̀ tàbí ìdààmú bá wa. (Òwe 15:23; 17:17; 27:9) Àwọn ọ̀dọ́ tó ní ìjákulẹ̀ máa ń rí i pé gbígba ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ àwọn òbí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kandi fi ẹ̀mí ìmọrírì sọ pé: “Ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn òbí mi ti jẹ́ kí n túbọ̀ máa fi òye ṣe nǹkan, kí ń sì wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó sì jẹ́ kí n túbọ̀ jẹ́ adùn-únbárìn.” Dájúdájú, ìránnilétí tó wà nínú ìwé Òwe orí kìíní, ẹsẹ kẹjọ àti ìkẹsàn-án ṣe wẹ́kú, ó kà pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì. Nítorí ọ̀ṣọ́ òdòdó fífanimọ́ra ni wọ́n jẹ́ fún orí rẹ àti àtàtà ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún ọrùn rẹ.”

Téèyàn bá ń ṣe fínnífínní dóríi bíńtín, ohun tó sábà máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni a rí nínú òwe tó sọ pé: “A kì í mọ̀ ọ́n gún mọ̀ ọ́n tẹ̀ kí iyán ewùrà máà ní kókó.” Ká lè yẹra fún èyí, a gbọ́dọ̀ yí ìrònú wa padà. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà—tí í ṣe mímọ̀wọ̀n ara wa—yóò jẹ́ kí a ní ìfojúsọ́nà tó mọ níwọ̀n, tó sì bọ́gbọ́n mu nípa ara wa. Abájọ tí ìwé Róòmù orí kejìlá, ẹsẹ kẹta fi kì wá nílọ̀ pé kí a “má ṣe ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” Láfikún sí i, ìwé Fílípì orí kejì, ẹsẹ kẹta rọ̀ wá pé kí a ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kí a sì máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.

Elizabeth táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú máa ń bínú sí ara rẹ̀ nítorí àìsàn tó ń ṣe é. Nínú ọ̀ràn tirẹ̀, ó gbọ́dọ̀ kọ́ láti máa wo àwọn nǹkan lọ́nà tí Jèhófà gbà ń wò wọ́n, kí ó sì máa fi òtítọ́ náà pé Jèhófà kì í gbàgbé iṣẹ́ ìsìn wa tu ara rẹ̀ nínú. Colin kò lè gbéra ńlẹ̀ nítorí àrùn kan tó dá a wó. Nígbà tí àìsàn yẹn kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ńṣe ló ń ronú pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun kò ní láárí ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí òun ń ṣe nígbà tí ara òun le. Àmọ́ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Kọ́ríńtì Kejì, orí kẹjọ, ẹsẹ kejìlá, ó pa ìrònú yẹn rẹ́. Ohun tí ẹsẹ náà sọ ni pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.” Colin sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí tí mo ń ṣe kò tó nǹkan, ṣùgbọ́n ó sàn ju àìṣe rárá, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà.” Ní Hébérù orí kẹfà, ẹsẹ kẹwàá, a rán wa létí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”

Báwo wá ni a ṣe lè mọ̀ bóyá ìfojúsọ́nà wa mọ níwọ̀n? Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ìfojúsọ́nà mi bá ìfojúsọ́nà Ọlọ́run mu?’ Gálátíà orí kẹfà, ẹsẹ kẹrin, sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.” Rántí pé Jésù sọ pé: “Àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àjàgà ń bẹ tí a óò gbé, ṣùgbọ́n ó “jẹ́ ti inú rere,” ó sì “fúyẹ́,” Jésù sì ṣèlérí pé yóò tù wá lára bí a bá gbé e dáadáa.—Mátíù 11:28-30.

Ìfojúsọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Mérè Wá

Èrè ojú ẹsẹ̀ àti èrè pípẹ́ títí máa ń wá látinú fífetí sí ìmọ̀ràn látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí á sì máa fi í sílò bí a ti ń mú kí ìfojúsọ́nà wa mọ níwọ̀n. Àǹfààní kan ni pé èyí ń mára tuni. Jennifer, tó ti jàǹfààní látinú àwọn ìránnilétí Jèhófà, sọ pé: “Ara mi le koko, ìgbésí ayé mi sì láyọ̀.” Abájọ tí ìwé Òwe orí kẹrin, ẹsẹ kọkànlélógún àti ìkejìlélógún fi rọ̀ wá pé kí a fi ojú àti ọkàn wa sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, “nítorí ìwàláàyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó wá wọn rí àti ìlera fún gbogbo ẹran ara wọn.”

Èrè mìíràn ni àlàáfíà ọpọlọ àti ti èrò orí. Theresa sọ pé: “Nígbà tí mo bá fi èrò inú àti ọkàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ńṣe ni ayọ̀ mi máa ń kún sí i.” Lóòótọ́, a ṣì máa ní ìjákulẹ̀ nínú ìgbésí ayé. Àmọ́, yóò túbọ̀ rọrùn fún wa láti kojú wọn. Jákọ́bù orí kẹrin, ẹsẹ kẹjọ rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Jèhófà tún ṣèlérí pé òun yóò fún wa lókun láti kojú àwọn ìpèníjà ìgbésí ayé, yóò sì fi àlàáfíà jíǹkí wa.—Sáàmù 29:11.

Níní ìfojúsọ́nà tó mọ níwọ̀n yóò jẹ́ kí a wà déédéé nípa tẹ̀mí. Èyí pàápàá, ìbùkún ni. A ó lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. (Fílípì 1:10) Á tún jẹ́ kí àwọn góńgó wa bọ́gbọ́n mu, kí wọ́n sì ṣeé lé bá, èyí á sì fi kún ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn wa. Á jẹ́ ká túbọ̀ fẹ́ láti gbára lé Jèhófà, nítorí a mọ̀ pé òun yóò jẹ́ kí àwọn nǹkan yọrí sí rere fún wa. Pétérù sọ pé: “Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.” (1 Pétérù 5:6) Ǹjẹ́ èrè míì tún wa tó pọ̀ ju pé kí Jèhófà gbé wa ga?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Níní ìfojúsọ́nà tó mọ níwọ̀n lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìjákulẹ̀ àti ìmúlẹ̀mófo