Èmi Olùṣe Ohun Ìjà Tẹ́lẹ̀ Wá Di Olùgba Ẹ̀mí Là
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Èmi Olùṣe Ohun Ìjà Tẹ́lẹ̀ Wá Di Olùgba Ẹ̀mí Là
GẸ́GẸ́ BÍ ISIDOROS ISMAILIDIS ṢE SỌ Ọ́
Orí ìkúnlẹ̀ ni mo wà, tí omijé ń dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú mi. Mo gbàdúrà pé: “Áà, ìwọ Ọlọ́run Ọba, ẹ̀rí ọkàn mi ò jẹ́ n gbádùn mọ́, ó ní kí n jáwọ́ nínú iṣẹ́ ṣíṣe ohun ìjà. Mo ti sá sókè sá sódò bóyá màá tiẹ̀ ríṣẹ́ míì, ṣùgbọ́n mi ò rí. Ọ̀la òde yìí ni màá kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀. Jèhófà, jọ̀ọ́ má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ wọ́n àwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin o.” Báwo ni mo ṣe bá ara mi nínú ipò yìí?
ỌKÀN àwọn èèyàn balẹ̀ dáadáa, wọn ò sì wa ilé ayé máyà ní Ẹkùn Ilẹ̀ Drama, ní àríwá Gíríìsì, tí wọ́n bí mi sí lọ́dún 1932. Bàbá mi máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa ohun tó fẹ́ kí n ṣe. Ó gbà mí níyànjú pé kí n lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ kàwé. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ ilẹ̀ Gíríìsì di ẹdun arinlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀rọ̀ táwọn Gíríìkì wá fi ń tu ara wọn nínú ni pé: “Ẹrù wa lẹ lè jí, ẹ ò le jí ohun tó wà nínú ọpọlọ wa.” Mo pinnu pé ohun tó bá gbà ni màá fún un, mo gbọ́dọ̀ kàwé kí n gboyè rẹpẹtẹ, kí ọwọ́ mi lè tẹ ohun tí ẹnikẹ́ni kò ní lè jí.
Láti kékeré pínníṣín ni mo ti wọ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì dá sílẹ̀. Wọ́n sọ fún wa níbẹ̀ pé ká yàgò fún àwọn ẹ̀ya ìsìn eléwu. Mo rántí ẹgbẹ́ kan pàtó tí wọ́n dárúkọ—èyíinì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—wọ́n ní aṣòdì-sí-Kristi ni wọ́n.
Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege ní iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ nílùú Áténì ní 1952, mo gbéra ó di ilẹ̀ Jámánì láti lọ wò ó bóyá màá lè ríṣẹ́, kí n sì tún máa lọ síléèwé. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìyẹn ò bọ́ sí i, mo rìnrìn àjò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, owó ọwọ́ mi tán porogodo ní ibùdókọ̀ kan ní Belgium. Mo rántí pé mo wọ ṣọ́ọ̀ṣì kan lọ, mo jókòó, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún, mo ké ké ké débi pé omijé ń kán tó tó tó sílẹ̀ níbi tí mo jókòó sí. Mo gbàdúrà pé bí Ọlọ́run bá lè bá mi ṣọ̀nà àtiwọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, mi ò ní lọ
máa du bí mo ṣe máa di ọlọ́là, bí kò ṣe kí n kàwé, kí n sì làkàkà láti jẹ́ Kristẹni rere àti ọmọlúwàbí ènìyàn. Níkẹyìn, mo débẹ̀ lọ́dún 1957.Ìgbésí Ayé Tuntun ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Ìgbésí ayé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nira fún àtọ̀húnrìnwá tí kò gbédè, tí kò sì lówó lọ́wọ́. Iṣẹ́ méjì ni mo ń ṣe lóru, mo sì tún ń làkàkà láti lọ síléèwé lọ́sàn-án. Mo lọ sí àwọn iléèwé gíga mélòó kan, mo sì gboyè tó fi díẹ̀ rẹlẹ̀ sí oyè tí wọ́n ń gbà jáde ní yunifásítì. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni mo wá lọ sí Yunifásítì California ní Los Angeles, mo sì gboyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ẹ̀ka ti físíìsì tó ṣeé mú lò. Ọ̀rọ̀ bàbá mi nípa ìwé kíkà ló fún mi níṣìírí ní àwọn ọdún líle koko wọ̀nyẹn.
Sáà yìí ni mo pàdé òrékelẹ́wà, ọmọbìnrin Gíríìkì kan, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ekaterini, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1964. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà la bí àkọ́bí wa tó jẹ́ ọkùnrin, a sì bí ọmọkùnrin méjì míì àti ọmọbìnrin kan kí ọdún mẹ́rin mìíràn tó pé. Ó mu mí lómi gan-an láti máa gbọ́ bùkátà ìdílé, bí mo ti ń kàwé lọ́wọ́ ní yunifásítì.
Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Òfuurufú Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni mo ń bá ṣiṣẹ́, ní iléeṣẹ́ kan tó wà ní Sunnyvale, California, tó ń ṣe ohun ìjà àtàwọn ọkọ̀ tí ń lọ sí gbalasa òfuurufú. Mo lọ́wọ́ nínú oríṣiríṣi iṣẹ́ àkànṣe tó jẹ mọ́ fífi ọkọ̀ ránṣẹ́ sí ojú sánmà àti sí gbalasa òfuurufú, bí àpẹẹrẹ, a jọ ṣe gbogbo ètò iṣẹ́ Agena àti Apollo ni. Mo tilẹ̀ gba àwọn àmì ẹ̀yẹ nítorí ipa tí mo kó nínú iṣẹ́ ọkọ̀ gbalasa òfuurufú Apollo 8 àti Apollo 11. Lẹ́yìn ìyẹn, mo tún ń kàwé nìṣó, mo sì ri ara mi bọnú onírúurú iṣẹ́ ológun tó jẹ mọ́ gbalasa òfuurufú. Níbi tí mo bá a dé yìí, lójú tèmi, mo ti ní gbogbo ohun téèyàn ń ní—mo ní aya rere lọ́ọ̀dẹ̀, mo ní àwọn ọmọ mẹ́rin tó jẹ ọmọ gidi, mo ní iṣẹ́ tó ti gbé mi dépò iyì, ilé tí mo sì fà kalẹ̀ rèé, ajé-kú-ìjókòó ni.
Ọ̀gbẹ́ni Kan Tí Kò Jáwọ́
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1967, mo bá Jim pàdé níbi iṣẹ́, ó jẹ́ ọkùnrin tó níwà ìrẹ̀lẹ̀ gan-an, tó sì jẹ́ onínúure. Ẹ̀rín ni lọ́jọ́ gbogbo, kò sì sígbà tí mo bá ní kí Jim wá, kí ó jẹ́ ká jọ lo àkókò ìsinmi ráńpẹ́, ká sì wá nǹkan fi panu lẹ́nu iṣẹ́ tí kò ní wá. Ó máa ń lo àkókò yìí láti fi bá mi jíròrò àwọn ìsọfúnni látinú Bíbélì. Jim sọ fún mi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.
Àyà mi já láti gbọ́ pé Jim ti ń dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn yìí. Báwo ni ẹ̀ya ìsìn aṣòdì-sí-Kristi yẹn ṣe rí irú ọmọlúwàbí èèyàn báyìí mú? Ṣùgbọ́n mi ò lè fi Jim sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ tó ní sí mi àti inú rere rẹ̀. Ó jọ pé ojoojúmọ́ ni ó ṣáà máa ń rí ìwé kan tó máa fún mi kà. Fún àpẹẹrẹ, ọjọ́ kan ló wọ ọ́fíìsì mi, tó ní: “Isidoros, àpilẹ̀kọ yìí nínú Ilé Ìṣọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa fífún ìgbésí ayé ìdílé lókun. Mú un lọ sílé, kí ìwọ àti ìyàwó rẹ jọ kà á.” Mo sọ fún un pé màá ka ìtẹ̀jáde náà, ṣùgbọ́n bó ṣe lọ tán ni mo gbọ̀nà ilé ìtura lọ, tí mo ya ìwé ìròyìn náà sí wẹ́wẹ́, tí mo sì kó o dà sínú ìkólẹ̀.
Ọdún mẹ́ta gbáko ni mo fi ń ya gbogbo ìwé àti ìwé ìròyìn tí Jim ń fún mi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ní ẹ̀tanú sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ mo fẹ́ máa bá Jim ṣọ̀rẹ́, fún ìdí yìí, mo ronú pé ohun tó máa dáa jù ni pé kí n máa gbọ́ tẹnu ẹ̀, kí n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa gba etí ọ̀tún wọlé kí ó sì máa gba tòsì jáde.
Àmọ́ ṣá o, látinú àwọn ìjíròrò Oníwàásù 9:10; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Jòhánù 20:17) Gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ ẹgbẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì, mi ò kàn fẹ́ gbà báyẹn pé òótọ́ lohun tí Jim ń sọ. Ṣùgbọ́n nígbà tó jẹ́ pé Bíbélì ló máa ń lò nígbà gbogbo, tí kò sì gbé èrò ti ara rẹ̀ kalẹ̀ rí, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín mo gbà pé ọkùnrin yìí ní ìsọfúnni pàtàkì kan fún mi látinú Bíbélì.
wọ̀nyẹn, mo rí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára ohun tí mo gbà gbọ́, tí mo sì ń ṣe, ni kò sí nínú Bíbélì. Mo wá rí i pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run àpáàdì, àti àìleèkú ọkàn kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Ìyàwó mi fura pé nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀, ó sì bi mí pé ṣé kì í ṣe pé mo ti ń bá ọ̀rẹ́ mi tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ pé: “A lè lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí, yàtọ̀ sí tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ṣùgbọ́n kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni èmi àti ìyàwó mi, àtàwọn ọmọ wa, bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí déédéé.
Ìpinnu Tó Le Koko Bí Ojú Ẹja
Bí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà, tó sọ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:4) Mo bi ara mi léèrè pé, ‘Báwo ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà ṣe lè máa ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wéwèé àwọn ohun ìjà ìpanirun, tí wọ́n sì ń ṣe wọ́n jáde?’ (Sáàmù 46:9) Kò pẹ́ tí mo fi dé ìparí èrò náà pé mo gbọ́dọ̀ wáṣẹ́ míì ṣe.
Ó jọ pé ọ̀rọ̀ ti ń lọ síbi tó ju agbára mi lọ báyìí o. Mo níṣẹ́ tó ti gbé mi dépò iyì. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ṣiṣẹ́ àṣekára, tí mo kàwé àkàkúdórógbó, tí mo fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara mi, kí n lè dé ipò tí mo wà yìí. Mo ti wá gòkè àgbà níbi iṣẹ́ báyìí, ó sì wá di dandan fún mi láti fi iṣẹ́ ọ̀hún sílẹ̀. Bó ti wù kó rí, ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí mo ní fún Jèhófà àti ìfẹ́ àtọkànwá láti ṣe ohun tó wù ú ló borí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.—Mátíù 7:21.
Mo pinnu pé màá wáṣẹ́ lọ sí iléeṣẹ́ kan ní Seattle, Washington. Àmọ́ ìjákulẹ̀ gbáà ló jẹ́, nítorí pé kò pẹ́ tí mo wá rí i pé ńṣe ni mo tún túbọ̀ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó tako ohun tó wà nínú Aísáyà orí kejì, ẹsẹ ìkẹrin. Gbogbo akitiyan mi láti rí i dájú pé mi ò bá wọn ṣe iṣẹ́ kankan tó jẹ mọ́ ohun ìjà, pàbó ló já sí, ni ẹ̀rí ọkàn mi bá tún bẹ̀rẹ̀ sí nà mí ní pàṣán. Mo wá rí i kedere pé mi ò ní lè máa ṣe iṣẹ́ yìí lọ, bí mo bá fẹ́ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́.—1 Pétérù 3:21.
Ó wá hàn gbangba báyìí pé a gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì. Kí oṣù mẹ́fà tó pé, a ti yí ọ̀nà ìgbésí ayé wa padà, a sì dín ìnáwó ìdílé wa kù sí ìdajì. Lẹ́yìn náà, a ta ilé ńlá wa, a sì ra ilé kékeré kan ní Denver, Colorado. Mo ti múra tán báyìí láti gbé ìgbésẹ̀ ìkẹyìn—ìyẹn ni láti fi iṣẹ́ mi sílẹ̀. Mo tẹ lẹ́tà tí mo fi sọ fún wọn pé mo fẹ́ fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, mo sì ṣàlàyé ìdúró tó bá ẹ̀rí ọkàn mi mu. Òru ọjọ́ yẹn, lẹ́yìn táwọn ọmọ ti lọ sùn, èmi àti ìyàwó mi kúnlẹ̀, a sì gbàdúrà sí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣàlàyé níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.
Kí oṣù kan tó pé, a ti ṣí lọ sí Denver, ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, ní July 1975, ni èmi àti ìyàwó mi ṣe batisí. Oṣù mẹ́fà gbáko ni mo fi ń wáṣẹ́ tí mi ò ríṣẹ́, owó wa sì ń tán lọ. Nígbà tó fi máa di oṣù keje, iye tó kù sínú àkáǹtì wa ní báńkì kò tiẹ̀ tó san iye tí a Mátíù 6:33.
ń san lórí ilé wa lóṣooṣù mọ́. Mi ò tiẹ̀ wá kọ iṣẹ́kíṣẹ́ tí mo bá rí báyìí, àmọ́ kété lẹ́yìn ìyẹn ni mo rí iṣẹ́ kan tó jẹ́ ti ìmọ̀ ẹ̀rọ. Owó oṣù mi kò ju ìdajì owó tí ń wọlé fún mi tẹ́lẹ̀; bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó pọ̀ gan-an ju ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà. Inú mi mà dùn pé mo fi ire tẹ̀mí sí ipò kìíní o!—Títọ́ Àwọn Ọmọ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Ohun tó wá kàn tí èmi àti Ekaterini ń bá yí ni iṣẹ́ ńlá títọ́ àwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run. A láyọ̀ pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, gbogbo wọn ti di Kristẹni tó dàgbà dénú ní ìṣojú wa, àní wọ́n ti ya ìgbésí ayé wọn sọ́tọ̀ pátápátá fún iṣẹ́ pàtàkì ti wíwàásù Ìjọba náà. Àwọn ọmọkùnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn, Christos, Lakes, àti Gregory, ló ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, wọ́n sì ń sìn lẹ́nu iṣẹ́ táa yàn fún wọn, tí wọ́n ń bẹ àwọn ìjọ wò, tí wọ́n sì ń fún wọn lókun. Toula, ọmọbìnrin wa, ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York. Ó wú wa lórí gan-an ni, bí a ti rí i tí gbogbo wọ́n pa àwọn iṣẹ́ tó lè sọni di èèyàn pàtàkì nínú ayé àti àwọn iṣẹ́ olówó ńlá tì, láti lè sin Jèhófà.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bi wá léèrè ọgbọ́n tí a dá, tí a fi tọ́ àwọn ọmọ wa ní àtọ́yanjú bẹ́ẹ̀. Ní tìyẹn o, kò sí oògùn ajẹ́bíidán kankan fún títọ́ ọmọ, ohun tí a kàn ṣe ni pé a sapá kárakára láti gbin ìfẹ́ fún Jèhófà àti fún àwọn aládùúgbò sí wọn lọ́kàn. (Diutarónómì 6:6, 7; Mátíù 22:37-39) Àwọn ọmọ kẹ́kọ̀ọ́ pé a ò lè máa fẹnu lásán sọ fún Jèhófà pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àfi tí iṣẹ́ ọwọ́ wa bá ń fi hàn bẹ́ẹ̀.
A máa ń jáde òde ẹ̀rí pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé lọ́jọ́ kan lọ́sẹ̀, èyí sì sábà máa ń jẹ́ lọ́jọ́ Sátidé. Ní alaalẹ́ Monday, lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a sì tún ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọmọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àwọn ọmọ wà ní kékeré, a máa ń bá kálukú wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ráńpẹ́ ní ẹ̀ẹ̀melòó kan lọ́sẹ̀, bí wọ́n sì ti ń dàgbà sí i, a wá jẹ́ kí sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà túbọ̀ gùn sí i, àmọ́ a sọ ọ́ di ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí bá ń lọ lọ́wọ́, àwọn ọmọ wa máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, wọ́n sì máa ń jíròrò gbogbo ìṣòro tí wọ́n ní pẹ̀lú wa ní fàlàlà.
A tún máa ń jùmọ̀ gbádùn eré ìtura tó mọ́yán lórí pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. A fẹ́ràn jíjùmọ̀ fi àwọn ohun èlò orin kọrin, ọmọ kọ̀ọ̀kan sì fẹ́ràn láti máa fi ohun èlò wọ̀nyí kọ orin tó fẹ́ràn jù lọ. Ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀ mìíràn, a máa ń ké sí àwọn ìdílé míì fún ìbákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró. A tún máa ń rin ìrìn àjò pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan nígbà ìsinmi. Nígbà ọ̀kan lára irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀, ọ̀sẹ̀ méjì la fi ń gun àwọn òkè Colorado kiri, tí a sì ń bá àwọn ìjọ àdúgbò náà ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Tayọ̀tayọ̀ làwọn ọmọ wa fi ń rántí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nígbà àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ní onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́, àti bí wọ́n ṣe ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní oríṣiríṣi àdúgbò. Nígbà tí a
kó àwọn ọmọ lọ sí ilẹ̀ Gíríìsì láti lọ rí àwọn ìbátan wọn, wọ́n tún ní àǹfààní láti rí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ tó ti ṣẹ̀wọ̀n rí nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Èyí wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an, ó sì jẹ́ kí wọ́n pinnu láti dúró gbọn-in, kí wọ́n sì jẹ́ onígboyà fún òtítọ́.Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà míì wà tí àwọn kan lára àwọn ọmọ hùwà tí kò dára tàbí tí wọ́n yan àwọn ẹni tí kò dáa lọ́rẹ̀ẹ́. Nígbà míì, àwa òbí la dá ìṣòro sílẹ̀ fún wọn, bóyá nípa ṣíṣòfin má-ṣu-má-tọ̀ nípa àwọn nǹkan kan. Ṣùgbọ́n yíyíjú sí “ìlànà èrò orí Jèhófà,” gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Bíbélì, máa ń jẹ́ kí gbogbo wa ṣàtúnṣe.—Éfésù 6:4; 2 Tímótì 3:16, 17.
Àkókò Tí Mo Láyọ̀ Jù Lọ Láyé Mi
Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ wa tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, èmi àti Ekaterini bẹ̀rẹ̀ sí ronú gidigidi nípa ohun tí a lè ṣe láti fi kún ipa tí à ń kó nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, ní 1994, lẹ́yìn tí mo fẹ̀yìn tì láìtọ́jọ́, àwa méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa wé mọ́ ṣíṣèbẹ̀wò sí àwọn iléèwé gígagíga àtàwọn yunifásítì tí ń bẹ lágbègbè wa, níbi tí a ti máa ń wàásù fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, tí a sì ń bá àwọn kan nínú wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí pé mi ò ṣàìmọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú—níwọ̀n bí èmi náà ti wà nínú ipò tí wọ́n wà báyìí ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn—mo máa ń kẹ́sẹ járí gan-an nínú ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó láti bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wá láti orílẹ̀-èdè Bolivia, Brazil, Chile, China, Etiópíà, Íjíbítì, Mẹ́síkò, Thailand, àti Turkey ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́! Mo tún máa ń gbádùn ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù, àgàgà tí mo bá fi ń wàásù fún àwọn èèyàn tí ń sọ èdè ìbílẹ̀ mi.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ní ìwọ̀n tí mo lè ṣe, nítorí pé ahọ́n Gíríìkì máa ń hàn nínú ìsọ̀rọ̀ mi, àti nítorí pé ara ti ń di ara àgbà báyìí, ìgbà gbogbo ni mo máa ń gbìyànjú láti yọ̀ǹda ara mi, mo sì ní ẹ̀mí Aísáyà, tó polongo pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 6:8) A ti ní ayọ̀ ríran àwọn èèyàn tó ju mẹ́fà lọ lọ́wọ́ láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó dájú pé èyí ni àkókò tí a láyọ̀ jù lọ láyé wa.
Nígbà kan rí, ohun tí mo ń fi gbogbo ìgbésí ayé mi ṣe ni àwọn ohun ìjà olóró fún pípa àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ mi. Àmọ́, Jèhófà, nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ṣí ọ̀nà sílẹ̀ kí èmi àti ìdílé mi lè di ìránṣẹ́ tó ń fọkàn sìn ín, kí a sì ya ìgbésí ayé wa sọ́tọ̀ pátápátá fún mímú ìhìn rere nípa ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ Párádísè tọ àwọn èèyàn lọ. Bí mo ti ń rántí ìpinnu gbankọgbì tí mo dojú kọ nígbà yẹn, ọ̀rọ̀ Málákì orí kẹta, ẹsẹ ìkẹwàá, ló wá sí mi lọ́kàn, ó kà pé: “‘Kí ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò nínú ọ̀ràn yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’” Ká sòótọ́, ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún wa—tẹ́rùntẹ́rùn!
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Lakes: Bàbá mi kórìíra àgàbàgebè. Ó máa ń gbìyànjú gidigidi láti má ṣe hùwà àgàbàgebè, àgàgà tó bá dọ̀ràn fífi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún ìdílé rẹ̀. Ó máa ń sọ fún wa pé: “Bí ẹ bá ya ìgbésí ayé yín sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun tó dáa gan-an lẹ ṣe yẹn. Ẹ gbọ́dọ̀ múra tán láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan nítorí Jèhófà. Ohun tí jíjẹ́ Kristẹni túmọ̀ sí gan-an nìyẹn.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò jẹ́ kúrò lọ́kàn mi, wọ́n sì ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú yíyááfì ọ̀pọ̀ nǹkan nítorí Jèhófà.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Christos: Mo mọrírì ẹ̀mí ìdúróṣinṣin àtọkànwá tí àwọn òbí mi ní sí Jèhófà lọ́pọ̀lọpọ̀, mo sì tún mọrírì ọwọ́ pàtàkì tí wọ́n fi mú ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí òbí. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ńṣe ni a máa ń ṣe gbogbo nǹkan pa pọ̀—látorí iṣẹ́ ìsìn wa dórí àkókò ìsinmi wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n láǹfààní láti di ogún, kí wọ́n di ọgbọ̀n, síbẹ̀ wọn ò wa ilé ayé máyà, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Lónìí, mo mọ̀ pé ohun tí yóò mú mi láyọ̀ jù lọ ni ríri ara mi bọnú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà pátápátá.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Gregory: Ohun tó mú kí n fara balẹ̀ gbé ọ̀ràn ara mi yẹ̀ wò, kí n sì pa gbogbo àníyàn àti ìbẹ̀rù nípa bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tì, kí n sì túbọ̀ tẹpá mọ́ iṣẹ́ Jèhófà, ni àpẹẹrẹ àwọn òbí mi àti ẹ̀rí náà pé wọ́n láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kì í kàn-án ṣe ọ̀rọ̀ ìṣírí tí wọ́n ń sọ, pé kí n mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi gbòòrò sí i. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi nítorí bí wọ́n ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ tí ń wá látinú sísa gbogbo ipá mi.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Toula: Ìgbà gbogbo làwọn òbí mi máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa létí pé àjọṣe láàárín àwa àti Jèhófà ni ohun ìní ṣíṣeyebíye jù lọ tí a lè ní láyé yìí, àti pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè gbà ní ayọ̀ tòótọ́ ni ṣíṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe fún Jèhófà. Wọ́n jẹ́ kí Jèhófà jẹ́ ẹni gidi sí wa. Bàbá mi máa ń sọ pé èèyàn máa ń ní ayọ̀ kan tí kò ṣeé ṣàpèjúwe, tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá mọ́ bí ó ti fẹ́ lọ sùn lálẹ́, nítorí tí ó mọ̀ pé òun ti ṣe gbogbo ohun tí òun lè ṣe láti mú inú Jèhófà dùn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Nígbà tí mo jẹ́ sójà ní ilẹ̀ Gíríìsì, ní 1951
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti Ekaterini ní 1966
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìdílé mi ní 1996: (láti apá òsì sí apá ọ̀tún, lọ sẹ́yìn) Gregory, Christos, Toula; (níwájú) Lakes, Ekaterini, àti èmi