Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìkùgbù Máa Ń fa Àbùkù

Ìkùgbù Máa Ń fa Àbùkù

Ìkùgbù Máa Ń fa Àbùkù

“Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”—ÒWE 11:2.

1, 2. Kí ni ìkùgbù, báwo ló sì ṣe mú kí àwọn kan kàgbákò?

 ONÍLARA ọmọ Léfì kan kó àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyànkéèyàn kan sòdí láti bá àwọn aláṣẹ tí Jèhófà yàn sípò jà. Ọmọ ọba kan tó ń kánjú àtidi ọba gbé ọ̀nà àrékérekè kan kalẹ̀ láti gbapò ọba lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ọba kan tí kò ní sùúrù kọ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́ni ṣíṣe kedere tí wòlíì Ọlọ́run fún un. Ohun tó mú kí ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí bára mu ni: ìkùgbù.

2 Ìkùgbù jẹ́ ohun kan tó máa ń dìde látinú ọkàn-àyà, tó sì jẹ́ ewu ńlá tó dojú kọ gbogbo wa. (Sáàmù 19:13) Oníkùgbù ènìyàn máa ń kù gìrì ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe láìsí pé a fún un láṣẹ àtiṣe é. Àgbákò sì ni èyí máa ń já sí lọ́pọ̀ ìgbà. Àní sẹ́, ìkùgbù ti bayé ọba jẹ́, ó sì ti bi ilẹ̀ ọba ṣubú. (Jeremáyà 50:29, 31, 32; Dáníẹ́lì 5:20) Ó tilẹ̀ ti dẹkùn mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan, ó sì ba tiwọn jẹ́ pátápátá.

3. Báwo la ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ewu tó wà nínú ìkùgbù?

3 Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Bíbélì fún wa láwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé òótọ́ ni òwe yìí. Ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn kan lára ìwọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ewu tó wà nínú kíkọjá àyè ẹni. Nítorí ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò bí ìlara, lílépa ipò ọlá, àti àìnísùúrù ṣe mú kí àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a mẹ́nu kàn níṣàájú fi ìkùgbù hùwà, tó wá yọrí sí àbùkù fún wọn.

Kórà—Onílara Tó Ṣọ̀tẹ̀

4. (a) Ta ni Kórà, kí sì ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbígbàfiyèsí tó dájú pé ó wà lára àwọn tó kópa nínú wọn? (b) Ọ̀tẹ̀ ńlá wo ni Kórà dá sílẹ̀ ní òpin ìgbésí ayé rẹ̀?

4 Ọmọkùnrin Kóhátì, ọmọ Léfì ni Kórà, ó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò baba Mósè òun Áárónì. Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ló fi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Kórà ní àǹfààní wíwà lára àwọn táa fi iṣẹ́ ìyanu gbà là ní Òkun Pupa, ó sì ṣeé ṣe kó wà lára àwọn tó mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jọ́sìn ère ọmọ màlúù ní Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 32:26) Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Kórà wá di baba ìsàlẹ̀ fún Dátánì, Ábírámù, àti Ónì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Rúbẹ́nì pẹ̀lú àwọn àádọ́ta-lérúgba [250] ọkùnrin nínú àwọn ìjòyè ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dìde ọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì. a Wọ́n sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín, nítorí pé gbogbo àpéjọ ni ó jẹ́ mímọ́ ní àtòkèdélẹ̀ wọn, Jèhófà sì wà ní àárín wọn. Kí wá ni ìdí tí ẹ fi gbé ara yín sókè lórí ìjọ Jèhófà?”—Númérì 16:1-3.

5, 6. (a) Kí ló fà á tí Kórà fi ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì? (b) Èé ṣe táa fi lè sọ pé ó ṣeé ṣe kí Kórà fojú tẹ́ńbẹ́lú ipò tirẹ̀ nínú ìṣètò Ọlọ́run?

5 Èé ṣe tí Kórà fi ṣọ̀tẹ̀, lẹ́yìn tó ti jẹ́ olóòótọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún? Ó dájú pé Mósè kò fi ipò aṣíwájú ni Ísírẹ́lì lára, nítorí pé ó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Númérì 12:3) Àmọ́, ó dà bí ẹni pé Kórà ṣe ìlara Mósè àti Áárónì, ó sì kórìíra bí wọ́n ṣe yọrí ọlá, èyí ló mú kí ó sọ̀rọ̀ lọ́nà òdì pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń fi ìmọtara-ẹni-nìkan fẹlá lé ìjọ lórí.—Sáàmù 106:16.

6 Apá kan lára ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro Kórà ni pé kò mọyì àǹfààní tí òun ní nínú ètò Ọlọ́run. Lóòótọ́, àwọn ọmọkùnrin Kóhátì, ọmọ Léfì kì í ṣe àlùfáà, ṣùgbọ́n olùkọ́ni ní Òfin Ọlọ́run ni wọ́n. Àwọn ni wọ́n sì máa ń gbé àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ àti àwọn ohun èlò tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kó wọn láti ibì kan lọ sí ibòmíràn. Ìyẹn kì í sì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá, nítorí pé kìkì àwọn tí wọ́n mọ́ ní ti ìsìn àti ní ti ìwà rere nìkan ló lè gbé àwọn ohun èlò mímọ́ wọ̀nyí. (Aísáyà 52:11) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Mósè ko Kórà lójú, ohun tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ni pé, Ṣé o rò pé iṣẹ́ tìrẹ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ni, tí o tún fi ní láti gba iṣẹ́ àlùfáà síkàáwọ́? (Númérì 16:9, 10) Kórà kùnà láti rí i pé fífi òtítọ́ sin Jèhófà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò rẹ̀ ni ọlá tó ga jù lọ—kì í ṣe wíwà ní ipò pàtàkì kan.—Sáàmù 84:10.

7. (a) Báwo ni Mósè ṣe pe Kórà àti àwọn ọkùnrin tó kó jọ níjà? (b) Báwo la ṣe mú ìṣọ̀tẹ̀ Kórà wá sí òpin oníjàǹbá?

7 Mósè ké sí Kórà àti gbogbo àwọn tó jẹ́ tirẹ̀ láti pésẹ̀ sí àgọ́ ìpàdé ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí wọ́n sì mú ìkóná àti tùràrí wá. Kórà àtàwọn èèyàn rẹ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sun tùràrí, nítorí pé wọn kì í ṣe àlùfáà. Bí wọ́n bá wá lọ mú ìkóná àti tùràrí wá, èyí yóò fi hàn ní kedere pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣì ń rò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti ṣe iṣẹ́ àlùfáà—kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti fi gbogbo òru gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Nígbà tí wọ́n kó ara wọn dé ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jèhófà fi ìbínú rẹ̀ hàn sí wọn lọ́nà tó tọ́. Ní ti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, “ilẹ̀ la ẹnu ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn mì.” Àwọn tó kù, títí kan Kórà, ni iná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run jó run. (Diutarónómì 11:6; Númérì 16:16-35; 26:10) Ìkùgbù Kórà ló fa àbùkù tó ju àbùkù lọ yìí—ìyẹn ìbínú Ọlọ́run!

Dènà “Ìtẹ̀sí Láti Ṣe Ìlara”

8. Báwo ni “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara” ṣe lè fara hàn láàárín àwọn Kristẹni?

8 Ìkìlọ̀ ni ìtàn Kórà jẹ́ fún wa. Níwọ̀n bí “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara” ti wà nínú ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, ó lè fi ara rẹ̀ hàn nínú ìjọ Kristẹni pàápàá. (Jákọ́bù 4:5) Fún àpẹẹrẹ, a lè jẹ́ ẹni tí ọ̀rọ̀ ipò ká lára. Bíi ti Kórà, a lè máa ṣe ìlara àwọn tó láwọn àǹfààní tó ń wù wá. A sì tún lè dà bíi Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nì, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dìótíréfè. Ẹni tó ń bẹnu àtẹ́ lu ọlá àṣẹ táwọn àpọ́sítélì ní, bóyá nítorí pé ó fẹ́ kí ó wà níkàáwọ́ òun. Àní, Jòhánù kọ̀wé pé Dìótíréfè “ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́.”—3 Jòhánù 9.

9. (a) Irú ẹ̀mí wo la ò gbọ́dọ̀ ní sí àwọn ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ? (b) Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ipò wa nínú ètò Ọlọ́run?

9 Láìsí àní-àní, kò sí ohun tó burú nínú kí Kristẹni ọkùnrin kan máa nàgà fún àwọn àǹfààní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Pọ́ọ̀lù pàápàá sọ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Tímótì 3:1) Àmọ́ ṣá o, a ò gbọ́dọ̀ fojú wo àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ bí àmì àṣeyọrí kan, bí ẹni pé bí ọwọ́ wa bá ti lè tẹ̀ ẹ́ báyìí, a ti gun ọ̀kan já nínú àwọn àtẹ̀gùn tó wà fún ìlọsíwájú nìyẹn. Rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.” (Mátíù 20:26, 27) Ní kedere, yóò jẹ́ ohun tó lòdì láti ṣe ìlara àwọn tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀, bí ẹni pé “ipò” táa wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run ló ń díwọ̀n bí a ṣe níye lórí tó lójú rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ará ni gbogbo yín.” (Mátíù 23:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, yálà akéde ni wá tàbí aṣáájú ọ̀nà, yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi ni tàbí a ti pẹ́ lẹ́nu pípa ìwà títọ́ mọ́—gbogbo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà ló ní ipò tó jọjú nínú ètò rẹ̀. (Lúùkù 10:27; 12:6, 7; Gálátíà 3:28; Hébérù 6:10) Ká sòótọ́, ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti máa ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí wọ́n ń tiraka láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—1 Pétérù 5:5.

Ábúsálómù—Ajìfà Tó Ń Lépa Ipò Ọlá

10. Ta ni Ábúsálómù, báwo ló sì ṣe gbìyànjú àtifa ojú àwọn tó ń wá sọ́dọ̀ ọba fún ìdájọ́ mọ́ra?

10 Ìtàn ìgbésí ayé Ábúsálómù, ọmọkùnrin tí Dáfídì Ọba bí ṣèkẹta, jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn tó ń lépa ipò ọlá. Ajìfà yìí ta gbogbo ọgbọ́n láti fa ojú àwọn tó ń wá sọ́dọ̀ ọba fún ìdájọ́ mọ́ra. Ó kọ́kọ́ dọ́gbọ́n sọ pé Dáfídì kò bìkítà nípa àwọn ìṣòro wọn. Ìgbà tó yá kò tiẹ̀ wá dọ́gbọ́n mọ́, ṣe ló kúkú sọ ohun tó fẹ́ ṣe jáde ní pàtó. Ábúsálómù wá sọ bí ẹni ń kọrin pé: “Ì bá ṣe pé a yàn mí ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí, pé kí olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá ní ẹjọ́ tàbí ìdájọ́ lè tọ̀ mí wá! Nígbà náà, èmi ì bá ṣe ìdájọ́ òdodo fún un dájúdájú.” Ábúsálómù ò tiẹ̀ fi àwọn ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀ wọ̀nyí mọ síbì kan. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá sún mọ́ tòsí láti tẹrí ba fún un, òun a na ọwọ́ rẹ̀, a sì rá a mú, a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Ábúsálómù sì ń ṣe irú nǹkan báyìí sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó bá wọlé tọ ọba wá fún ìdájọ́.” Kí wá ni àbájáde rẹ̀? “Ábúsálómù sì ń jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ.”—2 Sámúẹ́lì 15:1-6.

11. Báwo ni Ábúsálómù ṣe gbìyànjú àtigba ìtẹ́ Dáfídì lọ́wọ́ rẹ̀?

11 Ábúsálómù pinnu láti fi tipátipá gba ipò ọba lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ọdún márùn-ún ṣáájú àkókò yẹn ló sọ pé kí wọ́n pa Ámínónì, àrẹ̀mọkùnrin Dáfídì, tó sì dà bí ẹni pé ó ṣe bẹ́ẹ̀ láti gbẹ̀san ipá tíyẹn fi bá Támárì, àbúrò Ábúsálómù, lò pọ̀. (2 Sámúẹ́lì 13:28, 29) Àmọ́ o, ó lè jẹ́ ọ̀nà bí Ábúsálómù ṣe máa dórí ìtẹ́ ló ń wá nígbà yẹn, kó sì ti rò pé pípa Ámínónì ló máa jẹ́ kí nǹkan rọrùn, tí kò fi ní sẹ́ni tó máa bá òun dupò. b Ká má fọ̀rọ̀ gùn, nígbà tí ọjọ́ pé, Ábúsálómù gbé ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé. Ó polongo ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà.—2 Sámúẹ́lì 15:10.

12. Ṣàlàyé bí ìkùgbù ṣe fa àbùkù fún Ábúsálómù.

12 Ábúsálómù kẹ́sẹ járí fúngbà díẹ̀, nítorí pé “tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun náà sì túbọ̀ ń le sí i, àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú Ábúsálómù sì ń pọ̀ sí i níye.” Nígbà tó yá, ó di dandan kí Dáfídì Ọba sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 15:12-17) Àmọ́, kò pẹ́ tí gbogbo làlàkokofẹ̀fẹ̀ Ábúsálómù fi dópin, nígbà tí Jóábù pa á, tó gbé e sọ sínú kòtò ńlá kan, tó sì kó òkúta bò ó mọ́lẹ̀. Fojú inú wò ó ná—àní wọn ò tilẹ̀ sin òkú ọkùnrin tó ń lépa àtidi ọba yìí lọ́nà ẹ̀yẹ! c Lóòótọ́, ìkùgbù fa àbùkù fún Ábúsálómù.—2 Sámúẹ́lì 18:9-17.

Yàgò fún Lílépa Ipò Ọlá Onímọtara-Ẹni-Nìkan

13. Báwo ni ẹ̀mí ìlépa ipò ọlá ṣe lè ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà Kristẹni kan?

13 Bí Ábúsálómù ṣe yára gòkè dé ipò agbára àti bó ṣe ṣubú láìpẹ́ ọjọ́ jẹ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì fún wa. Nínú ayé oníwàkiwà yìí, kì í ṣe nǹkan àjèjì mọ́ kí àwọn èèyàn máa pá kúbẹ́kúbẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá, nítorí pé wọ́n ń wá ojú rere ọ̀gá, kíyẹn sáà lè kà wọ́n sí tàbí bóyá kó lè fún wọn ní àwọn àǹfààní kan tàbí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́. Nígbà kan náà, wọ́n tún lè máa fọ́nnu lójú àwọn tó kéré sí wọn, ní ìrètí pé wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ fajú àwọn yẹn mọ́ra, àti kí àwọn yẹn lè máa tì wọ́n lẹ́yìn. Bí a kò bá ṣọ́ra, irú ẹ̀mí ìlépa ipò ọlá bẹ́ẹ̀ lè ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà wa. Ó hàn gbangba pé èyí ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní, tó mú kó pọndandan fún àwọn àpọ́sítélì láti fúnni ní ìkìlọ̀ lílágbára nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.—Gálátíà 4:17; 3 Jòhánù 9, 10.

14. Èé ṣe tí a fi ní láti yẹra fún ẹ̀mí ìgbéra-ẹni-ga àti ti ìlépa ipò ọlá?

14 Jèhófà kò ní àyè kankan fún àwọn tó ń hùmọ̀ àtigbé ara wọn ga ju àwọn ẹlòmíì lọ nínú ètò àjọ rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń gbìyànjú láti “máa wá ògo ara wọn.” (Òwe 25:27) Àní, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Jèhófà yóò ké gbogbo ètè dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in kúrò, ahọ́n tí ń sọ àwọn ohun ńláńlá.” (Sáàmù 12:3) Ábúsálómù ní ètè dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in. Ó ń sọ àwọn ohun kàǹkà-kàǹkà fún àwọn tó ń wá ojú rere wọn—gbogbo ẹ̀ gbògbò ẹ̀ kó sáà lè rí ipò ọlá tí kò tọ́ sí i gbà ni. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, ẹ wo ìbùkún ńlá tó jẹ́ fún wa láti wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “[Ẹ má ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ . . . kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.”—Fílípì 2:3.

Sọ́ọ̀lù—Ọba Tí Kò Ní Sùúrù

15. Báwo ni Sọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun mẹ̀tọ́mọ̀wà nígbà kan?

15 Ìgbà kan wà tí Sọ́ọ̀lù, tó wá di ọba Ísírẹ́lì, jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Fún àpẹẹrẹ, gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ yẹ̀ wò. Nígbà tí Sámúẹ́lì wòlíì Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa rẹ̀, Sọ́ọ̀lù dáhùn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Èmi kì í ha ṣe ọmọ Bẹ́ńjámínì tí ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí ìdílé mi sì jẹ́ èyí tí ìjámọ́ pàtàkì rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi sọ irú ohun yìí fún mi?”—1 Sámúẹ́lì 9:21.

16. Ọ̀nà wo ni Sọ́ọ̀lù gbà fi ẹ̀mí àìnísùúrù hàn?

16 Àmọ́, lẹ́yìn náà, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Sọ́ọ̀lù pòórá. Nígbà tó lọ bá àwọn Filísínì jagun, ó lọ sí Gílígálì, níbi tó yẹ kó dúró sí de Sámúẹ́lì láti wá fi ẹbọ tu Ọlọ́run lójú. Nígbà tí Sámúẹ́lì ò dé ní àkókò tí wọ́n dá, Sọ́ọ̀lù fi ìkùgbù rú ẹbọ sísun náà fúnra rẹ̀. Bó ṣe ń parí rẹ̀ gẹ́ẹ́ ni Sámúẹ́lì dé. Sámúẹ́lì wá béèrè pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ṣe?” Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo rí i pé àwọn ènìyàn ti fọ́n ká kúrò lọ́dọ̀ mi, àti ìwọ—ìwọ kò wá láàárín àwọn ọjọ́ tí a dá . . . Nítorí náà, mo ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ara mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ sísun náà.”—1 Sámúẹ́lì 13:8-12.

17. (a) Táa bá kọ́kọ́ wo ọ̀ràn náà, èé ṣe tó fi lè dà bí ẹni pé kò sí ohun tó burú nínú ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe? (b) Èé ṣe tí Jèhófà fi dẹ́bi fún Sọ́ọ̀lù nítorí àìnísùúrù rẹ̀?

17 Táa bá kọ́kọ́ wo ọ̀ràn náà, ó lè dà bí ẹni pé ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe kò burú. Ó ṣe tán, àwọn èèyàn Ọlọ́run wà “nínú hílàhílo,” a ni wọ́n “lára dé góńgó,” wọ́n sì ń wárìrì nítorí ipò àìnírètí tí wọ́n wà. (1 Sámúẹ́lì 13:6, 7) Ká sọ tòótọ́, kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn lo ìdánúṣe nígbà tí ipò nǹkan bá béèrè pé ká ṣe bẹ́ẹ̀. d Àmọ́ ṣá o, rántí pé Jèhófà rí ọkàn-àyà wa, ó sì mọ èrò inú wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nítorí ìdí èyí, ó ti ní láti rí àwọn nǹkan kan lára Sọ́ọ̀lù tí Bíbélì ò ròyìn ní tààràtà. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà ti lè rí i pé ìgbéraga ló fà á tí Sọ́ọ̀lù kò fi ní sùúrù. Ó ṣeé ṣe kí Sọ́ọ̀lù ti bínú gan-an pé òun—ọba gbogbo Ísírẹ́lì—ní láti dúró de ẹnì kan tó wò gẹ́gẹ́ bí wòlíì kan tó ti darúgbó, tó ń fònídónìí-fọ̀ladọ́la. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, Sọ́ọ̀lù rò pé pípẹ́ tí Sámúẹ́lì pẹ́ ti fún òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìfẹ́ inú òun, kí òun sí fojú di ìtọ́ni ṣíṣe kedere tí wọ́n fún òun. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Inú Sámúẹ́lì kò dùn sí ìdánúṣe tí Sọ́ọ̀lù lò rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bá Sọ́ọ̀lù wí gidigidi, ó sọ pé: “Ìjọba rẹ kì yóò pẹ́ . . . nítorí pé ìwọ kò pa ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún ọ mọ́.” (1 Sámúẹ́lì 13:13, 14) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìkùgbù tún fa àbùkù.

Yẹra fún Àìnísùúrù

18, 19. (a) Ṣàpèjúwe bí àìnísùúrù ṣe lè mú kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan hu ìwà ìkùgbù lóde òní. (b) Kí ló yẹ kí a rántí nípa ọ̀nà tí ìjọ Kristẹni ń gbà ṣiṣẹ́?

18 Àkọsílẹ̀ ìwà ìkùgbù Sọ́ọ̀lù yìí wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àǹfààní wa. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Ó rọrùn fún wa gan-an láti bínú nítorí àìpé àwọn arákùnrin wa. Bíi ti Sọ́ọ̀lù, a lè ṣe aláìnísùúrù, kí a máa rò pé bí a bá fẹ́ kí nǹkan yọrí sí rere, a gbọ́dọ̀ ṣe wọ́n fúnra wa. Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé arákùnrin kan tayọ nínú bíbójútó àwọn ètò kan. Ó máa ń tẹ̀ lé àkókò, ó mọ gbogbo ìtọ́ni tó dé gbẹ̀yìn, ó sì lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó wá rí pé àwọn tó kù ò tiẹ̀ sún mọ́ òun rárá nínú ṣíṣe gbogbo nǹkan fínnífínní, wọn ò sì já fáfá tó bí òun ṣe fẹ́. Ṣé èyí wá sọ pé kó máà ní sùúrù? Ṣé ó wá yẹ kó máa ṣe lámèyítọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀, bóyá kó máa ṣe bí ẹni pé tí kì í bá ṣe nítorí ìsapá òun ni, kò sí ohun kan tí wọn ì bá ṣe yanjú, ìjọ ì bá sì ti fọ́? Èyí yóò jẹ́ ìkùgbù!

19 Ní ti gidi, kí ló so ìjọ àwọn Kristẹni pọ̀ ṣọ̀kan? Ṣé mímọ bí a ṣe ń ṣe àbójútó ni? tàbí jíjẹ́ ọ̀jáfáfá? àbí bí ìmọ̀ ẹnì kan ṣe jinlẹ̀ tó? Lóòótọ́, àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe pàtàkì kí nǹkan lè máa lọ déédéé nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 14:40; Fílípì 3:16; 2 Pétérù 3:18) Àmọ́, Jésù sọ pé ìfẹ́ ni ohun àkọ́kọ́ tí a fi máa dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀. (Jòhánù 13:35) Ìdí nìyẹn tí àwọn alàgbà tó bìkítà, tí wọ́n sì wà létòlétò, fi mọ̀ pé ìjọ kì í ṣe ibi ìṣòwò kan tó nílò ọwọ́ líle; dípò ìyẹn, àwọn àgùntàn tí wọ́n ń fẹ́ àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ló wà níbẹ̀. (Aísáyà 32:1, 2; 40:11) Fífi ìkùgbù kọ̀ láti tẹ̀ lé irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ sábà máa ń yọrí sí asọ̀. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, àlàáfíà ni wíwà létòlétò lọ́nà ti Ọlọ́run máa ń mú wá.—1 Kọ́ríńtì 14:33; Gálátíà 6:16.

20. Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

20 Ìtàn Bíbélì nípa Kórà, Ábúsálómù, àti Sọ́ọ̀lù fi hàn kedere pé ìkùgbù ń fa àbùkù, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé Òwe orí kọkànlá ẹsẹ ìkejì. Àmọ́, ẹsẹ Bíbélì kan náà yẹn tún fi kún un pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” Kí ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà? Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ànímọ̀ yìí dáadáa, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a mẹ̀tọ́mọ̀wà lónìí? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Níwọ̀n bí Rúbẹ́nì ti jẹ́ àkọ́bí Jékọ́bù, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tí Kórà mú ṣọ̀tẹ̀ ti ní láti kórìíra bí Mósè—tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Léfì—ṣe ní àṣẹ lé wọn lórí.

b A ò dárúkọ Ṣílíábù, tó jẹ́ ọmọkùnrin tí Dáfídì bí ṣèkejì mọ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti bí i. Ó ṣeé ṣe kó ti kú ṣáájú àkókò tí Ábúsálómù bẹ̀rẹ̀ wàhálà rẹ̀.

c Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, sísin òkú ẹnì kan jẹ́ ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì gan-an ni. Nítorí náà, fífi irú ìsìnkú bẹ́ẹ̀ du ẹnì kan sábà máa ń jẹ́ àbùkù gbáà, ó sì fi hàn pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kùnà ojú rere Ọlọ́run.—Jeremáyà 25:32, 33.

d Fún àpẹẹrẹ, Fíníhásì yára kánkán láti dá àrùn lùkúlùkú tó pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dúró, Dáfídì sì gba àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lù pa níyànjú láti dara pọ̀ mọ́ òun nínú jíjẹ búrẹ́dì àfihàn tó wà nínú “ilé Ọlọ́run.” Kò sí èyí tí Ọlọ́run dẹ́bi fún pé ó jẹ́ ìkùgbù nínú ọ̀ràn méjèèjì yìí.—Mátíù 12:2-4; Númérì 25:7-9; 1 Sámúẹ́lì 21:1-6.

Ṣé O Rántí?

• Kí ni ìkùgbù?

• Báwo ni ìlara ṣe mú kí Kórà fi ìkùgbù hùwà?

• Kí la rí kọ́ nínú ìtàn Ábúsálómù tó ń lépa ipò ọlá?

• Báwo la ṣe lè yẹra fún ẹ̀mí àìnísùúrù tí Sọ́ọ̀lù fi hàn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Sọ́ọ̀lù kò ní sùúrù, ó sì fi ìkùgbù hùwà