Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ—Èé Ṣe Tí Kò Fi Sí mọ́?

Ọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ—Èé Ṣe Tí Kò Fi Sí mọ́?

Ọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ—Èé Ṣe Tí Kò Fi Sí mọ́?

“Fífi àwọn aláṣẹ tayín, ì báà jẹ́ àwọn aláṣẹ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn àti nínú iṣẹ́ ti ayé, ì báà jẹ́ àwọn aláṣẹ nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti nínú òṣèlú, ti ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé báyìí o, ó sì lè wá di ohun táa lè pè ní mérìíyìírí nínú ẹ̀wádún tó kọjá yìí.”

Ọ̀PỌ̀ ọdún ti kọjá láti àwọn ọdún 1960, tí í ṣe ẹ̀wádún tí òpìtàn àti onímọ̀ ọgbọ́n orí nì, Hannah Arendt, ń tọ́ka sí lókè yìí. Lónìí, ńṣe ni ìwà àìbọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ túbọ̀ ń gogò sí i.

Fún àpẹẹrẹ, ìròyìn àìpẹ́ yìí kan nínú ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé: “Àwọn òbí kan kò gbà pé olùkọ́ ní ọlá àṣẹ lórí ọmọ àwọn, nígbà tí olùkọ́ bá sì gbìyànjú láti bá ọmọ wọn wí, ṣe ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí ṣàròyé.” Àìmọye ìgbà ló jẹ́ pé tí wọ́n bá bá ọmọ wọn wí pẹ́nrẹ́n níléèwé, ṣe ni wọ́n á gbéra, ó di iléèwé, kì í kàn-án ṣe láti lọ halẹ̀ mọ́ àwọn olùkọ́, bí kò ṣe láti lọ gbéjà kò wọ́n.

Agbẹnusọ fún Àjọ Àwọn Ọ̀gá Iléèwé Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni a gbọ́ tó sọ pé: “Ohun táwọn aráàlú ń sọ ni pé ‘Ẹ̀tọ́ mi ni,’ dípò ‘Ojúṣe mi ni.’” Yàtọ̀ sí pé àwọn òbí kan ò tiẹ̀ gbin ọ̀wọ̀ tó yẹ fáwọn aláṣẹ sọ́kàn àwọn ọmọ wọn, wọn kì í tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà—wọn kì í sì í jẹ́ kí ẹlòmíràn tọ́ wọn sọ́nà. Wọ́n ń jẹ́ kí àwọn ọmọ tó ń sọ pé àwọn ń jà fún “ẹ̀tọ́” àwọn máa tẹ àṣẹ òbí àti ti olùkọ́ lójú, àwa náà sì mọ ohun tó ń yọrí sí—èyí ló ń fà á tí “àwọn ọmọ ìgbàlódé kò bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ, tí wọn kò sì mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́,” gẹ́gẹ́ bí Margarette Driscoll tó jẹ́ òǹkọ̀wé nínú ìwé ìròyìn kan ti kọ̀wé nípa wọn.

Nínú àpilẹ̀kọ kan tí ìwé ìròyìn Time pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìran Àwọn Ọmọ Táyé Wọ́n Ti Ta,” ó tọ́ka ní pàtó sí àìnírètí tí ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà láàmú, ó fa ọ̀rọ̀ gbajúmọ̀ olórin wótòwótò kan yọ, ẹni tó sọ pé: “Báwo lẹnikẹ́ni tí a bí sínú ayé yìí, níbi tí kò ti sí nǹkan kan tó láyọ̀lé, tó sì jẹ́ pé ìwà ìrẹ́jẹ nìkan ló gbòde kan, ṣe lè fọkàn tán ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà?” Onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Mikhail Topalov, gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí, ó ní: “Àwọn ọmọ ìwòyí kì í ṣe ọ̀dẹ̀. Wọ́n ti rí i tí ìjọba purọ́ tan àwọn òbí wọn jẹ, wọ́n ti rí i tí owó àwọn òbí wọn wọmi, tí iṣẹ́ sì bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ǹjẹ́ a lè retí pé kí wọ́n bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?”

Àmọ́ ṣá o, yóò lòdì láti parí èrò sí pé ìran àwọn ọ̀dọ́ nìkan ni kò fọkàn tán àwọn aláṣẹ. Láyé ìsinsìnyí, tọmọdé tàgbà ni kò fọkàn tán àwọn aláṣẹ, kódà wọ́n máa ń tẹ́ńbẹ́lú wọn ni. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí aláṣẹ kankan táa lè fọkàn tán? Bí a bá lò ó lọ́nà yíyẹ, ọlá àṣẹ, tó túmọ̀ sí “agbára tàbí ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso, láti ṣèdájọ́, tàbí láti ká ìgbésẹ̀ àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kò,” lè ní ipa rere. Ó lè ṣàǹfààní fún àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti fún àwùjọ. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò gbé bí èyí ṣe lè ṣàǹfààní yẹ̀ wò.