Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọgbọ́n Tó Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá Báwo La Ṣe Lè Mọ̀ Ọ́n?

Ọgbọ́n Tó Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá Báwo La Ṣe Lè Mọ̀ Ọ́n?

Ọgbọ́n Tó Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá Báwo La Ṣe Lè Mọ̀ Ọ́n?

“AMÁA ń tẹ́ńbẹ́lú ọgbọ́n aláìní, a kì í sì í fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì fi kádìí ìtàn ọkùnrin kan tó jẹ́ mẹ̀kúnnù ṣùgbọ́n tó gbọ́n, tó sì gba odindi ìlú ńlá kan lọ́wọ́ ìparun. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, “kò sí ẹnì kankan tí ó rántí ọkùnrin aláìní yẹn.”—Oníwàásù 9:14-16.

Ńṣe làwọn èèyàn máa ń fojú pa àwọn tálákà rẹ́, kódà bí àwọn òtòṣì wọ̀nyí tiẹ̀ ń ṣe bẹbẹ. Bọ́ràn Jésù ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “A tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwọn ènìyàn sì yẹra fún un, ọkùnrin tí a pète fún ìrora àti fún dídi ojúlùmọ̀ àìsàn.” (Aísáyà 53:3) Àwọn kan tẹ́ńbẹ́lú Jésù kìkì nítorí pé kò ní ipò ọlá tàbí pé kò gbajúmọ̀ tó àwọn aṣáájú tí ń bẹ nígbà ayé rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ní ọgbọ́n tó ga fíìfíì ju ti ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ èyíkéyìí. Àwọn ará ìlú Jésù kọ̀ láti gbà pé “ọmọkùnrin káfíńtà” lásán-làsàn yìí lè ní ọgbọ́n tó pọ̀ tó ìyẹn, tí ó sì lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́, wọ́n mà kúkú ṣàṣìṣe o, nítorí ìròyìn náà sọ síwájú sí i pé Jésù “kò . . . ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára níbẹ̀ ní tìtorí àìnígbàgbọ́ wọn.” Wọ́n mà pàdánù o!—Mátíù 13:54-58.

Ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ o. Jésù sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” Kì í ṣe nípa jíjẹ́ èèyàn jàǹkànjàǹkàn láwùjọ la fi ń mọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi ọgbọ́n àtọ̀runwá kọ́ni, bí kò ṣe nípa “èso àtàtà” tí wọ́n ń so—èyíinì ni ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ wọn tí a gbé ka Bíbélì.—Mátíù 7:18-20; 11:19.