“Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”
“Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”
“Kí . . . ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé . . . kí o jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—MÍKÀ 6:8.
1, 2. Kí ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí ìkùgbù?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ kan tó lókìkí kọ̀ láti pe àfiyèsí sí ara rẹ̀. Onídàájọ́ kan tó jẹ́ onígboyà ní Ísírẹ́lì pe ara rẹ̀ ní ẹni tí ó kéré jù lọ nínú agbo ilé baba rẹ̀. Ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí gbà pé ó ní ibi tí ọlá àṣẹ òun mọ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ló fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn.
2 Òdìkejì ìkùgbù ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà. Ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ni ẹni tí kì í ka agbára àti àwọn ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe sí bàbàrà, kì í sì í jọra rẹ̀ lójú tàbí kí ó máa ruga. Dípò tí ì bá fi máa gbéra ga, kí ó máa fẹgẹ̀, tàbí kí ó máa lépa ipò ọlá, ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà kì í kọjá àyè rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, ó sì máa ń gba ti ìmọ̀lára àti ojú ìwòye wọn rò.
3. Ní ọ̀nà wo ni ọgbọ́n fi “wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà”?
3 Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà jẹ́ ọlọgbọ́n nítorí pé ó ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, ó sì ń yẹra fún ẹ̀mí ìkùgbù tó ń yọrí sí àbùkù. (Òwe 8:13; 1 Pétérù 5:5) Ọgbọ́n tó wà nínú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ni a rí nínú ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta táa mẹ́nu kàn nínú ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ yẹ̀ wò.
Pọ́ọ̀lù—“Òṣìṣẹ́ Ọmọ Abẹ́” àti “Ìríjú”
4. Kí ni àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní?
4 Ẹnì kan tó gbajúmọ̀ gan-an ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí, a sì mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó rin ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lójú òkun àti lórí ilẹ̀, ó sì dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀. Láfikún sí i, Jèhófà fi rírí àwọn ìran àti ẹ̀bùn fífi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀ jíǹkí Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́ríńtì 14:18; 2 Kọ́ríńtì 12:1-5) Ó tún mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ mẹ́rìnlá lára àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì báyìí. Ní kedere, a lè sọ pé òpò tí Pọ́ọ̀lù ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ.—1 Kọ́ríńtì 15:10.
5. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà?
5 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ló ń mú ipò iwájú nínú ìgbòkègbodò Kristẹni, àwọn kan lè máa retí àtirí i kó máa yan fanda kiri, kódà kó tiẹ̀ máa fi ọlá àṣẹ tó ní ṣe fọ́rífọ́rí pàápàá. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Ó pe ara rẹ̀ ní ẹni tí ó “kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì,” ó fi kún un pé: “Èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì, nítorí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 15:9) Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀, Pọ́ọ̀lù ò lè gbàgbé láé pé tí kì í bá ṣe inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni, òun ì bá máà ní ìbátan kankan pẹ̀lú Ọlọ́run, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti bó ṣe gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Jòhánù 6:44; Éfésù 2:8) Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn, Pọ́ọ̀lù ò ronú pé àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ tí òun gbé ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ti mú kí òun sàn ju àwọn yòókù lọ.—1 Kọ́ríńtì 9:16.
6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nínú bó ṣe bá àwọn ará Kọ́ríńtì lò?
6 Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù fara hàn kedere nínú bó ṣe bá àwọn ará Kọ́ríńtì lò. Ó hàn gbangba pé àwọn kan lára wọn ń kan sáárá sí àwọn alábòójútó tí wọ́n kà sí gbajúmọ̀ láàárín wọn, títí kan Àpólò, Kéfà, àti Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 1:11-15) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò bẹ àwọn ará Kọ́ríńtì rí pé kí wọ́n gbóríyìn fún òun bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tó fẹ́ fi ìkansáárá wọn ṣe. Nígbà tó bá ń bẹ̀ wọ́n wò, kì í wá “pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọrégèé tàbí ọgbọ́n.” Dípò ìyẹn, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni pé: “Kí ènìyàn díwọ̀n wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ́ Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.” a—1 Kọ́ríńtì 2:1-5; 4:1.
7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn, kódà nígbà tí ó ń fúnni ní ìmọ̀ràn?
7 Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nígbà tó yẹ kó fúnni ní ìbáwí líle koko àti ìtọ́ni. Ó “fi ìyọ́nú Ọlọ́run” pàrọwà sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ “nítorí ìfẹ́” kì í ṣe lọ́lá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì. (Róòmù 12:1, 2; Fílémónì 8, 9) Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi ṣe èyí? Nítorí pé ó ka ara rẹ̀ sí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” àwọn arákùnrin rẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ‘ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wọn.’ (2 Kọ́ríńtì 1:24) Láìsí àní-àní, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù ló fà á tó fi jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún àwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 20:36-38.
Fífi Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Lo Àwọn Àǹfààní Táa Ní
8, 9. (a) Èé ṣe tó fi yẹ ká jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà? (b) Báwo ni àwọn tó ní ẹrù iṣẹ́ ṣe lè fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn?
8 Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni lónìí. Bó ti wù kí ẹrù iṣẹ́ tí a gbé lé wa lọ́wọ́ ti tó, kò sí èyíkéyìí nínú wa tó gbọ́dọ̀ ronú pé òun sàn ju àwọn yòókù lọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.” (Gálátíà 6:3) Èé ṣe? Nítorí pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23; 5:12) Bẹ́ẹ̀ ni, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé gbogbo wa ló jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ Ádámù. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ táa ní kò lè mú wa kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Oníwàásù 9:2) Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù, tí kì í bá ṣe inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni, ẹ̀dá ènìyàn ì bá máà lájọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti sísìn ín ní àwọn ipò pàtàkì kan.—Róòmù 3:12, 24.
9 Mímọ èyí kò ní jẹ́ kí ẹnì kan tó mẹ̀tọ́mọ̀wà máa fi àwọn àǹfààní tó ní yangàn tàbí kó máa ganpá nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 4:7) Nígbà tó bá ń fúnni nímọ̀ràn tàbí ìtọ́sọ́nà, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ni—kì í ṣe bí ọ̀gá. Dájúdájú, yóò jẹ́ ohun tí kò dára rárá kí ẹnì kan tí òye rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ kan tayọ máa wá ìyìn látọ̀dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tàbí kí ó fẹ́ kí wọ́n máa kan sáárá sí òun. (Òwe 25:27; Mátíù 6:2-4) Kìkì ìyìn tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn wá ni ojúlówó ìyìn—ó sì gbọ́dọ̀ ti ọkàn wọn wá láìjẹ́ pé a bẹ̀bẹ̀ fún un. Bí irú ìyìn bẹ́ẹ̀ bá wá, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó mú wa ro ara wa ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.—Òwe 27:2; Róòmù 12:3.
10. Ṣàlàyé bí àwọn kan tó dà bíi pé wọ́n wà ní ipò rírẹlẹ̀ ṣe lè jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́” ní ti gidi.
10 Nígbà tí a bá gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún pípe àfiyèsí sí ara wa jù, kí a máa fún àwọn ará ní ìmọ̀lára pé tí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ ìsapá àti agbára tiwa ni, ìjọ ì bá má lè dúró. Fún àpẹẹrẹ, a lè ní ẹ̀bùn ìkọ́ni tó tayọ. (Éfésù 4:11, 12) Àmọ́, bí a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, a ó mọ̀ pé kì í ṣe orí pèpéle nìkan ni gbogbo ẹ̀kọ́ pàtàkì-pàtàkì tí à ń kọ́ nínú ìpàdé ìjọ ti ń wá. Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ kì í wú ọ lórí nígbà tóo bá rí obí anìkantọ́mọ tó ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba déédéé? Tàbí ọkàn kan tó sorí kọ́ tí kì í pa ìpàdé jẹ láìka ìmí ẹ̀dùn pé òun kò já mọ́ nǹkankan tó máa ń ní sí? Tàbí ọ̀dọ́ kan tó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí lójú gbogbo ipa búburú tí ilé ìwé àti àwọn ibòmíràn máa ń ní lórí ẹni? (Sáàmù 84:10) Àwọn wọ̀nyí lè má gbajúmọ̀. Àwọn ẹlòmíràn lè má tiẹ̀ mọ gbogbo àdánwò ìwà títọ́ tí wọ́n dójú kọ. Síbẹ̀, wọ́n lè jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́” bíi ti àwọn tó gbajúmọ̀. (Jákọ́bù 2:5) Ó ṣe tán, ní àbárèbábọ̀, ìṣòtítọ́ ni yóò mú wa jèrè ojú rere Jèhófà.—Mátíù 10:22; 1 Kọ́ríńtì 4:2.
Gídíónì—Ẹni Tí “Ó Kéré Jù Lọ” ní Ilé Baba Rẹ̀
11. Ọ̀nà wo ni Gídíónì gbà fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nígbà tó ń bá áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ̀rọ̀?
11 Gídíónì, ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ akíkanjú látinú ẹ̀yà Mánásè gbé ayé ní àkókò kan tí rúkèrúdò wà nínú ìtàn Ísírẹ́lì. Fún ọdún méje gbáko ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi jìyà lábẹ́ ìnilára àwọn Mídíánì. Àmọ́, àkókò wá tó wàyí tí Jèhófà yóò dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè. Nítorí náà, áńgẹ́lì kan fara han Gídíónì, ó sì wí fún un pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ akíkanjú, alágbára ńlá.” Gídíónì mẹ̀tọ́mọ̀wà, nítorí náà kò wá bẹ̀rẹ̀ sí yan kọ́ńdú-kọ́ńdú kiri nítorí àpọ́nlé tí kò retí yìí. Dípò ìyẹn, ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Dákun, olúwa mi, ṣùgbọ́n bí Jèhófà bá wà pẹ̀lú wa, èé ṣe nígbà náà, tí gbogbo èyí fi wá sórí wa?” Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé bí ọ̀ràn ṣe rí, ó sì wí fún Gídíónì pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò sì gba Ísírẹ́lì là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ Mídíánì.” Báwo ni Gídíónì ṣe fèsì? Kàkà tí Gídíónì ì bá fi bẹ́ mọ́ iṣẹ́ yìí, kí ó gbà á gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan fún òun láti di akọni ní gbogbo ilẹ̀ náà, ńṣe ló fèsì pé: “Dákun, Jèhófà. Kí ni kí n fi gba Ísírẹ́lì là? Wò ó! Ẹgbẹ̀rún tèmi ni èyí tí ó kéré jù lọ ní Mánásè, èmi sì ni ó kéré jù lọ ní ilé baba mi.” Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà gidi lèyí!—Àwọn Onídàájọ́ 6:11-15.
12. Báwo ni Gídíónì ṣe fi ọgbọ́n inú hàn nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un?
12 Jèhófà dán Gídíónì wò kó tó di pé ó rán an lọ sójú ogun. Lọ́nà wo? A sọ fún Gídíónì pé kí ó wó pẹpẹ tí bàbá rẹ̀ kọ́ fún Báálì, kí ó sì gé òpó ọlọ́wọ̀ tí ó wà ní ẹgbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀. Iṣẹ́ yìí gba ìgboyà, àmọ́ Gídíónì tún fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ọgbọ́n inú hàn nínú ọ̀nà tó gbà ṣe iṣẹ́ náà. Dípò tí Gídíónì ì bá fi fi ara rẹ̀ ṣe ìran àpéwò, òru ọ̀gànjọ́ ló fi ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lè rí i. Síwájú sí i, tìṣọ́ratìṣọ́ra ni Gídíónì ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un yìí. Ó mú àwọn ìránṣẹ́ mẹ́wàá—bóyá ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí àwọn kan lè máa ṣọ́nà nígbà tí àwọn tó kù bá ń ràn án lọ́wọ́ láti wó pẹpẹ àti òpó ọlọ́wọ̀ náà. b Bó ti wù kó rí, pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, Gídíónì ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un, nígbà tí àkókò sì tó, Ọlọ́run lò ó láti gba Ísírẹ́lì là lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì.—Àwọn Onídàájọ́ 6:25-27.
Fífi Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti Ọgbọ́n Inú Hàn
13, 14. (a) Báwo la ṣe lè fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nígbà tí a bá nawọ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn sí wa? (b) Báwo ni Arákùnrin A. H. Macmillan ṣe fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nínú fífi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn?
13 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ látinú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Gídíónì. Fún àpẹẹrẹ, báwo la ṣe máa hùwà nígbà táa bá nawọ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn sí wa? Ṣé ohun tó kọ́kọ́ máa wá sọ́kàn wa ni ọlá àti iyì táa máa rí níbẹ̀? Àbí ṣé a máa fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wo tàdúràtàdúrà, kí a sì wò ó bóyá a kún ojú ìwọ̀n ohun tí iṣẹ́ náà ń béèrè? Arákùnrin A. H. Macmillan, tí ó parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní ọdún 1966, fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀ràn yìí. C. T. Russell, tí ó jẹ́ ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Society, nígbà kan béèrè èrò Arákùnrin Macmillan nípa ẹni tó lè bójú tó iṣẹ́ yìí nígbà tí òun bá ṣe aláìsí. Nínú ìjíròrò tí ó tẹ̀ lé e, Arákùnrin Macmillan kò kàn ṣe báyẹn yan ara rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, Arákùnrin Russell ké sí Arákùnrin Macmillan pé kó gbé títẹ́wọ́gba iṣẹ́ náà yẹ̀ wò. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Arákùnrin Macmillan kọ̀wé pé: “Ńṣe ni iyè mi kàn fò lọ lórí ìdúró. Mo ronú nípa rẹ̀ dáadáa, mo rò ó, mo tún un rò, mo sì gbàdúrà nípa rẹ̀ fúngbà díẹ̀ kí n tó wá sọ fún un níkẹyìn pé inú mi yóò dùn láti ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.”
14 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí Arákùnrin Russell kú, tí àyè ààrẹ Watch Tower Society sì ṣófo. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Arákùnrin Macmillan ló di ipò yìí mú ní àwọn àkókò tí Arákùnrin Russell lò kẹ́yìn nínú ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀, arákùnrin kan wá sọ fún un pé: “Mac, ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún ọ láti gorí àlééfà báyìí. Ìwọ ni àkànṣe aṣojú Arákùnrin Russell láti ìgbà tó ti lọ, ó sì sọ fún gbogbo wa pé ohun tóo bá ti sọ ni ká máa ṣe. Tóò, ó ti lọ báyìí, kò sì lè padà wá mọ́. Ó dà bí ẹni pé ìwọ ni ọpọ́n sún kàn.” Arákùnrin Macmillan fèsì pé: “Arákùnrin, bí o ṣe ń ronú yẹn kọ́ lọ̀rọ̀ rí. Iṣẹ́ Olúwa lèyí, kìkì ipò tí o sì lè dé nínú ètò Olúwa ni èyí tí Olúwa bá rí i pé ó yẹ láti fún ọ; ó sì dá mi lójú pé èmi kọ́ ni iṣẹ́ yẹn tọ́ sí.” Arákùnrin Macmillan wá dámọ̀ràn ẹlòmíràn fún ipò náà. Bíi tí Gídíónì, òun náà mọ̀wọ̀n ara rẹ̀—ì bá dára tí àwa náà bá lè ṣe bẹ́ẹ̀.
15. Àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ wo la lè gbà lo ìfòyemọ̀ nígbà táa bá ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn?
15 Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà nínú ọ̀nà tí a gbà ń ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wa. Gídíónì jẹ́ olóye, ó sì gbìyànjú láti má ṣe mú àwọn alátakò rẹ̀ bínú láìnídìí. Bákan náà, nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà, kí a sì jẹ́ olóye nípa bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, ogun tẹ̀mí là ń jà láti dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” àti “àwọn ìrònú” dé. (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ tó máa tàbùkù àwọn ẹlòmíràn tàbí kí a ṣe ohunkóhun tó lè mú wọn bínú sí iṣẹ́ wa. Dípò ìyẹn, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye wọn, kí a tẹnu mọ́ ohun ti àwa àtàwọn jọ gbà pé òótọ́ ni, kí a sì máa darí àfiyèsí wọn sí àwọn apá tó lè ṣe wọ́n láǹfààní nínú iṣẹ́ wa.—Ìṣe 22:1-3; 1 Kọ́ríńtì 9:22; Ìṣípayá 21:4.
Jésù—Àpẹẹrẹ Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Tó Ga Jù Lọ
16. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun?
16 Àpẹẹrẹ ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tó ga jù lọ ni ti Jésù Kristi. c Pẹ̀lú bí Jésù ṣe ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba rẹ̀ tó, kò lọ́ tìkọ̀ láti gbà pé àwọn ọ̀ràn kan wà tó kọjá ibi tí ọlá àṣẹ òun mọ. (Jòhánù 1:14) Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí màmá Jákọ́bù àti Jòhánù wá bá a pé kí àwọn ọmọ òun jókòó sí ẹ̀gbẹ́ Jésù nínú ìjọba rẹ̀, Jésù sọ pé: “Jíjókòó yìí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni.” (Mátíù 20:20-23) Ní àkókò mìíràn, Jésù gbà láìjanpata pé: “Èmi kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara mi . . . kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mo ń wá, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 5:30; 14:28; Fílípì 2:5, 6.
17. Báwo ni Jésù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nínú bó ṣe hùwà sí àwọn ẹlòmíràn?
17 Gbogbo ọ̀nà ni Jésù fi ga ju ẹ̀dá ènìyàn aláìpé lọ, ó sì ní ọlá àṣẹ tí kò láfiwé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, Baba rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù mẹ̀tọ́mọ̀wà nínú bó ṣe hùwà sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Kì í ṣe pé ó kan ń rọ́ ìmọ̀ sórí wọn, kí wọ́n lè máa kan sáárá sí i. Ọ̀rọ̀ wọn ká a lára, ó fi ìyọ́nú hàn sí wọn, ó sì gba ti àìní wọn rò. (Mátíù 15:32; 26:40, 41; Máàkù 6:31) Nípa bẹ́ẹ̀, bí Jésù tilẹ̀ jẹ́ ẹni pípé, kì í ṣe aṣefínnífínní dóríi bíńtín. Kò béèrè ohun tó ju agbára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ wọn rí, kò sì gbé ẹrù tí wọn ò lè rù kà wọ́n lórí. (Jòhánù 16:12) Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi rí ìtura lọ́dọ̀ rẹ̀!—Mátíù 11:29.
Fara Wé Àpẹẹrẹ Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Jésù
18, 19. Báwo la ṣe lè fara wé ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Jésù nínú (a) ojú tí a fi ń wo àwọn ẹlòmíràn, àti (b) bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò?
18 Bí ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí bá mẹ̀tọ́mọ̀wà, a jẹ́ pé àwa náà gbọ́dọ̀ mẹ̀tọ́mọ̀wà gan-an nìyẹn. Kì í sábà rọrùn fún ẹ̀dá ènìyàn aláìpé láti gbà pé àwọn ò ní ọlá àṣẹ tí kò láàlà. Àmọ́ ṣá o, kí àwọn Kristẹni lè fara wé Jésù, wọ́n ń tiraka láti mẹ̀tọ́mọ̀wà. Wọn kì í jọ ara wọn lójú débi tí wọn kò fi ní lè fi ẹrù iṣẹ́ lé àwọn tó bá tóótun lọ́wọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni wọn kì í ṣe agbéraga tàbí ẹni tí kì í fẹ́ gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ àwọn tó láṣẹ láti tọ́ni sọ́nà. Nípa fífi ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ hàn, wọ́n ń jẹ́ kí ohun gbogbo nínú ìjọ ṣẹlẹ̀ “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́ríńtì 14:40.
19 Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yóò tún sọ wá di ẹni tí ń fòye báni lò nínú ohun tí a ń retí látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, yóò sì jẹ́ kí a máa gba ti àìní wọn rò. (Fílípì 4:5) A lè ní agbára àti okun táwọn ẹlòmíì ò ní. Síbẹ̀, tí a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, a ò ní máa retí pé ohun tí a fẹ́ ni àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe ní gbogbo ìgbà. Ní mímọ̀ pé olúkúlùkù ló ní ibi tí agbára rẹ̀ mọ, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yóò jẹ́ kí a fara da ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn ẹlòmíràn. Pétérù kọ̀wé pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pétérù 4:8.
20. Kí la lè ṣe láti borí ìtẹ̀sí èyíkéyìí láti di aláìmẹ̀tọ́mọ̀wà?
20 Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀, ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní tòótọ́. Àmọ́, tí o bá wá rí i pé o ní ìtẹ̀sí láti di aláìmẹ̀tọ́mọ̀wà tàbí oníkùgbù ńkọ́? Má ṣe banú jẹ́. Dípò ìyẹn, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì, tó gbàdúrà pé: “Fa ìránṣẹ́ rẹ sẹ́yìn kúrò nínú àwọn ìṣe ìkùgbù; má ṣe jẹ́ kí wọ́n jọba lé mi lórí.” (Sáàmù 19:13) Nípa fífarawé ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn bíi Pọ́ọ̀lù, Gídíónì, àti—lékè gbogbo ẹ̀dá ènìyàn mìíràn—Jésù Kristi, àwa fúnra wa yóò rí òtítọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ náà pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”—Òwe 11:2.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ” lè túmọ̀ sí ẹrú kan tí ó ń fi àjẹ̀ tukọ̀ lórí ìjókòó ìsàlẹ̀ nínú ọkọ̀ òkun ńlá kan. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, “ìríjú” lè jẹ́ ẹni tí a fi ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, bíi pé kó máa bójú tó dúkìá kan. Síbẹ̀síbẹ̀, lójú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀gá, ìríjú ò yàtọ̀ sí ẹrú nínú ọkọ̀ òkun alájẹ̀.
b A ò gbọ́dọ̀ ka ọgbọ́n inú àti ìṣọ́ra tí Gídíónì lò sí ìwà ojo. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí jíjẹ́ ojo, ìwé Hébérù 11:32-38 jẹ́rìí sí ìwà akin rẹ̀, níbi tí a ti ka Gídíónì mọ́ àwọn tí “a sọ . . . di alágbára” àti àwọn tí “wọ́n di akíkanjú nínú ogun.”
c Nítorí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ní ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni nínú, a kò lè sọ pé Jèhófà jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Àmọ́ o, ó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.—Sáàmù 18:35.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà?
• Báwo la ṣe lè fara wé ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù?
• Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ nípa ìmẹ̀tọ́mọ̀wà látinú àpẹẹrẹ Gídíónì?
• Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tó ga jù lọ lélẹ̀?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ di àyànfẹ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Gídíónì lo òye bó ti ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nínú gbogbo ohun tí ó ṣe