Kí Ló Dé Tí Wọn Kò Bímọ?
Kí Ló Dé Tí Wọn Kò Bímọ?
Ẹ̀KA iléeṣẹ́ Watch Tower Society ní Nàìjíríà ni Délé àti Fọlá, a tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya, ń gbé, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti ń ṣiṣẹ́. Kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sìn níbẹ̀ nígbà tí ìyá Fọlá wá bẹ̀ wọ́n wò. Ìyá yìí dìídì wá láti ọ̀nà jíjìn kí ó lè wá bá wọn jíròrò ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, èyí tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í jẹ́ kó sùn lóru.
Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ń tọ́jú mi gan-an ni. Ẹ ń fi àwọn nǹkan ránṣẹ́ sí mi, ẹ sì wá ń bẹ̀ mí wò. Mo mọrírì ìfẹ́ tí ẹ ń fi hàn sí mi gan-an. Àmọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ẹ ń ṣe tún ń bà mí nínú jẹ́, nítorí pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń rò ó pé ta ló máa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún yín nígbà tẹ́ẹ bá darúgbó bíi tèmi? Ọdún kejì rèé tí ẹ ti ṣègbéyàwó, ẹ ò sì bímọ. Ṣé ẹ ò ronú pé ó ti tó àkókò fún yín láti fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ kí ẹ wá bímọ tiyín ni?”
Ohun tí ìyá yìí ń rò ni pé: Àkókò tí Délé àti Fọlá ti lò ní Bẹ́tẹ́lì ti tó. Àkókò ti tó fún wọn báyìí láti ronú nípa ọjọ́ ọ̀la wọn. Ó sì dájú pé àwọn ẹlòmíràn lè ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Kì í sáà ṣe pé Délé àti Fọlá máa fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, àmọ́ wọ́n lè gba iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mìíràn, èyí tí yóò fún wọn láyè láti bímọ kí wọ́n sì gbádùn ayọ̀ tó wà nínú jíjẹ́ òbí.
Àníyàn Ìyá
Àníyàn tí ìyá yìí ní yéni. Ìfẹ́ láti bímọ jẹ́ ohun tí a dá mọ́ wa, kò sì sí àṣà ìbílẹ̀ kan tàbí ìgbà kan táwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí ọmọ bíbí. Ọmọ bíbí máa ń fúnni láyọ̀ àti ìrètí kíkọyọyọ. Bíbélì sọ pé: “Èso ikùn jẹ́ èrè.” Ó dájú pé níní agbára láti bímọ jẹ́ ẹ̀bùn tó níye lórí láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́.—Sáàmù 127:3.
Ní ọ̀pọ̀ àwùjọ, ìyọlẹ́nu tí tọkọtaya máa ń dojú kọ kì í ṣe kékeré nítorí àtibímọ. Fún àpẹẹrẹ, ní Nàìjíríà, níbi tó jẹ́ pé mẹ́fà ni ìpíndọ́gba ọmọ tí obìnrin kọ̀ọ̀kan ń bí, àdúrà tí àwọn èèyàn sábà máa ń ṣe fún àwọn tọkọtaya lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn ni pé: “Ẹ̀yìn ìyàwó ò ní mọ́ ẹní o.” Àwọn ọkọ àti ìyàwó tiẹ̀ máa ń gba ọ̀já ọmọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ní ọjọ́ ìgbéyàwó wọn. Ojoojúmọ́ ni ìyá ọkọ àti ìyá ìyàwó á máa ka ọjọ́. Bí ìyàwó ò bá wá lóyún láàárín nǹkan bí ọdún kan, wọ́n a bẹ̀rẹ̀ sí wádìí bóyá ìṣòro èyíkéyìí wà tí àwọn lè ṣèrànwọ́ láti yanjú.
Lójú ọ̀pọ̀ ìyá, ìdí tí àwọn èèyàn fi ń ṣe ìgbéyàwó ò ju pé kí wọ́n bí àwọn ọmọ kí ìlà ìdílé yẹn má bàa dópin. Ìyá Fọlá sọ fún un pé: “Ìgbà tóo mọ̀ pé o ò ní bímọ kí ló mú ẹ ṣègbéyàwó? Wọ́n bí ọ ni, ó sì yẹ kí ìwọ náà bí àwọn ọmọ tìrẹ.”
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀ràn mìíràn tó ṣe kókó wà táa ní láti gbé yẹ̀ wò. Ìwọ̀nba díẹ̀ ni ètò tí ìjọba ṣe láti bójú tó àwọn arúgbó ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, àwọn ọmọ ló sábà máa ń tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí wọn ṣe tọ́jú wọn nígbà tí wọ́n wà ní kékeré. Ìdí nìyẹn tí ìyá Fọlá fi ronú pé àyàfi tí àwọn ọmọ òun bá bí àwọn ọmọ tiwọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọjọ́ alẹ́ wọn ni wọ́n fi ń ṣeré yẹn, torí pé bí wọn ò bá bímọ, wọ́n lè wá nìkan wà, tí kò ní sí ẹni tó ń wá wọn, tí wọ́n lè wá bára wọn nípò òṣì, láìsí ẹni tó máa sin wọ́n nígbà tí wọ́n bá kú.
Jákèjádò ọ̀pọ̀ jù lọ ilẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti gbà pé èpè ló mọ́ ẹni tí kò bá bímọ. Ní àwọn àgbègbè
kan, wọ́n tiẹ̀ máa ń retí pé kí àwọn obìnrin fẹ̀rí hàn pé àwọn lè bímọ kó tó di pé a gbé wọn níyàwó. Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí kò lè bímọ ló máa ń wá egbòogi kiri lójú méjèèjì kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro àìrọ́mọbí wọn.Nítorí àwọn nǹkan báwọ̀nyí ni wọ́n ṣe máa ń wo àwọn tọkọtaya tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti bímọ bí ẹni tó ń fi ohun tó dáa du ara wọn. Wọ́n máa ń wò wọ́n bí ẹni tí kò bẹ́gbẹ́ mu, tí kò ro ọjọ́ ọ̀la, tó sì wà nípò tó ń ṣeni láàánú.
Ayọ̀ àti Ẹrù Iṣẹ́
Àwọn ènìyàn Jèhófà mọ̀ pé bí ayọ̀ ṣe wà nínú ọmọ títọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹrù iṣẹ́ tún wà níbẹ̀. Bíbélì sọ nínú 1 Tímótì 5:8, pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”
Àwọn òbí gbọ́dọ̀ pèsè fún àwọn ìdílé wọn nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí, èyí sì máa ń gba àkókò àti ìsapá tí kò kéré. Wọn kì í ní ẹ̀mí pé níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run ló ń fúnni lọ́mọ, Ọlọ́run náà ló máa tọ́jú wọn. Wọ́n mọ̀ pé títọ́mọ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì jẹ́ ẹrù iṣẹ́ alákòókò kíkún tí Ọlọ́run yàn fún àwọn òbí; kì í ṣe èyí tí a gbọ́dọ̀ gbé lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.—Diutarónómì 6:6, 7.
Iṣẹ́ ọmọ títọ́ tiẹ̀ wá ṣòro báyìí, àgàgà ní àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” tí ó jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1-5) Yàtọ̀ sí ètò ọrọ̀ ajé tó túbọ̀ ń burú sí i, pípọ̀ tí àìṣèfẹ́ Ọlọ́run ń pọ̀ sí i láwùjọ tún ń fi kún ìṣòro tó wà nídìí ọmọ títọ́ lóde òní. Pẹ̀lú ìyẹn náà, káàkiri àgbáyé la ti rí àwọn tọkọtaya Kristẹni tí wọn ti tẹ́rí gba iṣẹ́ yìí, wọ́n sì ti ṣàṣeyọrí ní títọ́ àwọn ọmọ olùbẹ̀rù Ọlọ́run dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọ̀nyí, ó sì ń bù kún wọn nítorí iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe.
Ìdí Tí Àwọn Kan Kò Fi Bímọ
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ tọkọtaya Kristẹni ni kò bímọ. Àwọn kan yàgàn, síbẹ̀ wọn ò gba ọmọ ọlọ́mọ ṣọmọ. Àwọn tọkọtaya mìíràn tí wọ́n lè bímọ pinnu pé àwọn ò ní bímọ. Kì í ṣe tìtorí àtisá fún ẹrù iṣẹ́ ni irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ ò ṣe bímọ, kì í sì í ṣe pé ẹ̀rù ń bà wọ́n láti kojú ìṣòro tó wà nídìí jíjẹ́ òbí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti pinnu láti gbájú mọ́ apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pín sí, wọ́n sì mọ̀ pé ọmọ títọ́ máa dí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn lọ́wọ́. Àwọn kan ń sìn bíi míṣọ́nnárì. Àwọn míì ń sin Jèhófà nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò tàbí ní Bẹ́tẹ́lì.
Bíi ti gbogbo Kristẹni, wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ kánjúkánjú kan wà láti ṣe. Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Iṣẹ́ yìí ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì sì ni, nítorí pé “òpin” yóò túmọ̀ sí ìparun àwọn tí kò kọbi ara sí ìhìn rere náà.—Mátíù 24:14; 2 Tẹsalóníkà 1:7, 8.
Àkókò tiwa yìí ló dà bí àkókò tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ń kan ọkọ̀ áàkì gìrìwò náà, èyí tó dáàbò bò wọ́n ní gbogbo àkókò Ìkún Omi ńlá náà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13-16; Mátíù 24:37) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Nóà bí ló gbéyàwó nígbà yẹn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tó bímọ kí Àkúnya náà tó parí. Ó lè jẹ́ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn tọkọtaya wọ̀nyí fẹ́ pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ wọn ní àkókò yẹn, wọ́n sì fẹ́ fi gbogbo agbára wọn ṣe é. Ìdí mìíràn lè jẹ́ nítorí pé wọn ò fẹ́ bímọ sínú ayé ẹlẹ́gbin tó kún fún ìwà ipá níbi tí ‘ìwà búburú ènìyàn ti pọ̀ yanturu . . . tí gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.’—Jẹ́nẹ́sísì 6:5.
Bí èyí kò tilẹ̀ túmọ̀ sí pé ó lòdì láti bímọ lóde òní, ọ̀pọ̀ tọkọtaya Kristẹni ni kò bímọ kí wọ́n lè nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ kánjúkánjú tí Jèhófà yàn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti ṣe. Àwọn tọkọtaya kan ti dúró fún sáà kan kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí bímọ; àwọn mìíràn ti pinnu àtidúró láìbímọ rárá, wọ́n sì ti gbà pé inú ayé tuntun òdodo ti Jèhófà làwọn ti máa bímọ. Ṣé àìro ọjọ́ ọ̀la lèyí ni? Ṣé wọ́n ti pàdánù adùn ìgbésí ayé ni? Ṣé ó yẹ ká máa káàánú wọn?
Ìgbésí Ayé Aláàbò Tó sì Jẹ́ Aláyọ̀
Ó ti lé ni ọdún mẹ́wàá báyìí tí Délé àti Fọlá táa mẹ́nu kàn níṣàájú ti ṣègbéyàwó, wọ́n sì ti pinnu láti máa bá a lọ láìbímọ. Délé sọ pé:
“Àwọn mọ̀lẹ́bí wa ṣì ń fúngun mọ́ wa pé ká sáà bímọ. Ọ̀rọ̀ nípa bọ́jọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí ló ń ká wọn lára. Gbogbo ìgbà la máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọrírì ìgbatẹnirò wọn, àmọ́ a máa ń fọgbọ́n ṣàlàyé fún wọn pé iṣẹ́ tí a ń ṣe ń mú inú wa dùn gan-an ni. Ní ti bọ́jọ́ ọ̀la ṣe máa rí, a sọ fún wọn pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé, òun lẹni tó ń bojú tó àìní gbogbo àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì í. A tún ṣàlàyé fún wọn pé béèyàn tilẹ̀ bímọ, ìyẹn ò fi dandan túmọ̀ sí pé wọ́n máa tọ́jú ẹ̀ nígbà tó bá dàgbà. Àwọn kan kì í bìkítà fáwọn òbí wọn, àwọn míì sì wà tí wọn ò lágbára láti ṣèrànwọ́, àwọn mìíràn tiẹ̀ ń kú ṣáájú àwọn òbí wọn pàápàá. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ọjọ́ ọ̀la wa dájú lọ́dọ̀ Jèhófà.”Délé àtàwọn mìíràn bíi tirẹ̀ gbé gbogbo ọkàn wọn lé ìlérí tí Jèhófà ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5) Wọ́n tún gbà gbọ́ pé, “ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù tí kò fi lè gbani là, bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò wúwo jù tí kò fi lè gbọ́.”—Aísáyà 59:1.
Ohun mìíràn tó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ ni bí wọ́n ṣe rí i pé Jèhófà máa ń pèsè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” Ronú nípa ìyẹn ná. Ǹjẹ́ o tíì rí olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan tí a fi “sílẹ̀ pátápátá”?—Sáàmù 37:25.
Dípò kí àwọn tó ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn sin Jèhófà àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn bojú wẹ̀yìn kí wọn sì ki ìka àbámọ̀ bọnu, ńṣe ni wọ́n máa ń kún fún ayọ̀ nígbà tí wọ́n bá ronú nípa iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Arákùnrin Iro Umah ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ọdún márùnlélógójì, ó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní Nàìjíríà báyìí. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àti ìyàwó mi kò bímọ, a mọ̀ dájú pé Jèhófà ń tọ́jú wa nípa tẹ̀mí àti nípa ti ara. A ò ṣe aláìní ohunkóhun. Kò sì ní fi wá sílẹ̀ báa ṣe ń dàgbà sí i. Àwọn ọdún tí a lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni a ti láyọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Inú wa dùn pé a lè sin àwọn arákùnrin wa, àwọn arákùnrin wa mọrírì iṣẹ́ ìsìn wa, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni kò bímọ tiwọn, síbẹ̀ wọ́n ti ní irú àwọn ọmọ mìíràn: ìyẹn àwọn Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn tí ń jọ́sìn Jèhófà. Àpọ́sítélì Jòhánù ti ń lọ sí nǹkan bí ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Ìṣòtítọ́ “àwọn ọmọ” Jòhánù—ìyẹn àwọn tó tipasẹ̀ rẹ̀ rí “òtítọ́”—ń fún un ní ayọ̀ ńláǹlà.
Irú ayọ̀ kan náà wà lóde òní. Ọdún kọkàndínlógún tí Bernice, tí í ṣe ọmọ Nàìjíríà, ti ṣègbéyàwó rèé, ó sì fúnra rẹ̀ yàn láti dúró láìbímọ. Àtọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn ló ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Bó ṣe ń sún mọ́ àkókò kan nínú ìgbésí ayé, nígbà tí kò ní ṣeé ṣe fún un láti bí àwọn ọmọ tirẹ̀ mọ́, kò kábàámọ̀ nípa bó ṣe lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ fún iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ó sọ pé: “Inú mi ń dùn bí mo ṣe ń rí i tí àwọn ọmọ mi nípa tẹ̀mí ń dàgbà. Ká tiẹ̀ sọ pé mo bí àwọn ọmọ tèmi, mi ò rò pé wọ́n lè sún mọ́ mi ju àwọn tí mo ti ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Wọ́n máa ń ṣe mí bí ẹni pé èmi gan-an ni ìyá wọn, wọ́n máa ń bá mi jíròrò ayọ̀ wọn àti ìṣòro wọn, wọ́n sì máa ń wá gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi. Wọ́n máa ń kọ̀wé sí mi, a sì máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ara wa.
“Ojú táwọn kan fi ń wò ó ni pé èpè ló mọ́ ẹni tí kò bá bímọ. Wọ́n ní ìyà á jẹ ọ́ tóo bá darúgbó. Ṣùgbọ́n èmi ò gbà pé bó ṣe rí nìyẹn. Mo mọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, yóò san èrè fún mi, yóò sì bójú tó mi. Kò ní gbé mi sọ nù láé nígbà tí mo bá di arúgbó.”
Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wọn, Ó sì Kà Wọ́n sí Pàtàkì
Àwọn tó bímọ, tí wọ́n sì ti tọ́ àwọn ọmọ tí “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́” dàgbà ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti máa dúpẹ́ fún. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Baba olódodo yóò kún fún ìdùnnú láìsí àní-àní; ẹni tí ó bí ọlọgbọ́n yóò yọ̀ pẹ̀lú nínú rẹ̀. Baba rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, obìnrin tí ó bí ọ yóò sì kún fún ìdùnnú”!—Òwe 23:24, 25.
Àwọn Kristẹni tí kò ní ayọ̀ mímú ọmọ wá sáyé ni a ti bù kún láwọn ọ̀nà mìíràn. Ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya wọ̀nyí ló ti kó ipa pàtàkì nínú mímú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú lọ́nà gbígbòòrò. Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, wọ́n ti ní ìrírí, ọgbọ́n, àti òye tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti kó ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ Ìjọba náà. Ọ̀pọ̀ ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ náà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti dúró láìbímọ nítorí ire Ìjọba náà, Jèhófà ti fi ìdílé tẹ̀mí tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tó sì mọrírì ìrúbọ tí wọ́n ṣe, jíǹkí wọn. Bí Jésù ṣe sọ ọ́ gẹ́ẹ́ ló rí, pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó fi [kí a sọ ọ́ láìlábùlà, “yááfì”] ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí baba tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ àti àwọn pápá . . . àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 10:29, 30.
Ẹ ò rí i bí àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ti ṣeyebíye tó lójú Jèhófà! Gbogbo irú àwọn adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀, ìyẹn àwọn tó bímọ àtàwọn tí kò bímọ lápapọ̀, ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ wọ̀nyí padà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
A ti fi ìdílé tẹ̀mí tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ jíǹkí àwọn tọkọtaya tí kò bímọ