Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ǹjẹ́ o mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá o lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

Èé ṣe tó fi dá wa lójú pé ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” nínú Aísáyà 65:17-19 kò mọ sórí ìpadàbọ̀ àwọn Júù láti oko òǹdè?

Nítorí pé àwọn àpọ́sítélì náà, Pétérù àti Jòhánù, tó kọ̀wé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, tọ́ka sí ìmúṣẹ kan lọ́jọ́ iwájú, èyí tó wé mọ́ àwọn ìbùkún tó ṣì wà níwájú. (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:1-4)—4/15, ojú ìwé 10 sí 12.

Kí lohun tó jọ pé ó bí àwọn ìtàn àròsọ tí àwọn Gíríìkì ìgbàanì ń sọ nípa àwọn ẹbọra oníwà ipá?

Bóyá ṣe ni wọ́n ṣe àbùmọ́, tàbí kó jẹ́ pé wọ́n já àlùbọ́sà sí ìtàn náà pé ṣáájú Ìkún Omi, àwọn áńgẹ́lì gbé ara ènìyàn wọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé ìwà ipá àti ti ìṣekúṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2)—4/15, ojú ìwé 27.

Kí ni díẹ̀ lára ewu tí àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú gbọ́dọ̀ yẹra fún nígbà ìgbéyàwó?

Ó ṣe pàtàkì láti yẹra fún àríyá aláriwo, tó lè wáyé bí ọtí bá ń ṣàn bí omi òjò, táwọn èèyàn sì ń jó ijó àjótàkìtì bí orin ti ń dún lákọlákọ. Àfi táwọn onínàáwó bá sọ pé gbogbo ayé làwọn pè wá síbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn tí a ò pè kò gbọ́dọ̀ yọjú síbẹ̀. Ọkọ ìyàwó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn Kristẹni tó tóótun yóò wà níbẹ̀ títí ayẹyẹ náà yóò fi parí lásìkò tó bójú mu.—5/1, ojú ìwé 19 sí 22.

Kí ni ó túmọ̀ sí nígbà tí Sáàmù 128:3 sọ pé àwọn ọmọ yóò “dà bí àwọn àgélọ́ igi ólífì” yí tábìlì ẹnì kan ká?

Ìdí igi ólífì ni ọ̀mùnú ti sábà máa ń yọ. Nígbà tí igi yìí tó ti lọ́jọ́ lórí gan-an kò bá lè so èso mọ́, àwọn ẹ̀ka tuntun lè yọ gbọ̀ngbọ̀nrọ̀n yí ògbólógbòó igi náà ká. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, inú àwọn òbí máa ń dùn láti rí àwọn ọmọ wọn tí ń sèso bí wọ́n ti ń sin Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.—5/15, ojú ìwé 27.

Kí ni díẹ̀ lára àǹfààní táwọn ọmọdé ń jẹ látinú ìdílé tó tòrò?

Ó máa ń fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún wọn, kí wọ́n lè máa fi ojú tó dáa wo àwọn aláṣẹ, kí wọ́n mọyì ìwà ọmọlúwàbí, kí àjọṣe àárín àwọn àtàwọn mìíràn sì dán mọ́rán. Irú àyíká bẹ́ẹ̀ sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—6/1, ojú ìwé 18.

Ní ilẹ̀ kan ní Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé, kí ni a ṣe láti jẹ́ kí àwọn ará mọ̀ pé arákùnrin ni gbogbo àwọn Kristẹni jẹ́?

A rọ gbogbo àwọn ìjọ pé kí wọ́n má ṣe máa fi ọ̀rọ̀ tó máa fini hàn bí ọ̀gá pe àwọn kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, arákùnrin ni kí wọ́n máa pe gbogbo àwọn ará.—6/15, ojú ìwé 21.

Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo àwọn oògùn tí wọ́n mú jáde látinú ẹ̀jẹ̀?

A gbà gbọ́ pé àṣẹ Bíbélì pé ká ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀’ fagi lé fífa odindi ẹ̀jẹ̀ síni lára tàbí fífa àwọn èròjà tó pilẹ̀ rẹ̀ (ìyẹn, omi inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀, àti sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀) síni lára. (Ìṣe 15:28, 29) Ní ti àwọn ìpín tín-tìn-tín tó wá látinú àwọn èròjà ìpìlẹ̀ wọ̀nyí, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ni yóò dá ṣe ìpinnu, láìgbàgbé ohun tí Bíbélì sọ àti ìbátan tí ó ní pẹ̀lú Ọlọ́run.—6/15, ojú ìwé 29 sí 31.

Ṣé lóòótọ́ ló ṣeé ṣe láti rí ìbàlẹ̀ ọkàn lónìí?

Bẹ́ẹ̀ ni. Nípasẹ̀ Bíbélì, Jésù Kristi ń tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà ìjọsìn mímọ́ gaara àti ọ̀nà àlàáfíà táa ṣàpèjúwe nínú Aísáyà orí kejìlélọ́gbọ̀n, ẹsẹ kejìdínlógún. Síwájú sí i, àwọn tó bá ní irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ ní ìrètí gbígbádùn àlàáfíà títí láé lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ìwé Sáàmù kẹtàdínlógójì, ẹsẹ kọkànlá àti ìkọkàdínlọ́gbọ̀n bá ní ìmúṣẹ.—7/1, ojú ìwé 7.

Ipa wo ni George Young kó nínú ìtàn iṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní?

Láti ọdún 1917 ló ti ń tànmọ́lẹ̀ sí ìhìn rere Ìjọba náà ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gbé e dé gbogbo ilẹ̀ Kánádà, dé àwọn erékùṣù Caribbean, dé Brazil àti àwọn ilẹ̀ mìíràn tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà, dé Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, dé Sípéènì, dé Ilẹ̀ Potogí, títí dé ibi táa mọ̀ sí Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí, àti dé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.—7/1, ojú ìwé 22 sí 27.

Kí ni ìtumọ̀ ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:29 pé àwọn kan wà “tí a ń batisí fún ète jíjẹ́ òkú”?

Ohun tó túmọ̀ sí ni pé nígbà táa bá fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn Kristẹni, a ti rì wọ́n bọ inú ìgbésí ayé kan tí yóò ṣamọ̀nà sí ikú wọn, àti àjíǹde lẹ́yìn náà sí ìyè ti ọ̀run.—7/15, ojú ìwé 17.

Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣe láwọn ọdún táwọn kan ń sọ pé a ò gbúròó rẹ̀?

Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ń ṣèrànwọ́ láti dá àwọn ìjọ sílẹ̀ tàbí láti fún wọn lókun ní Síríà àti Sìlíṣíà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìpọ́njú tó mẹ́nu kàn nínú 2 Kọ́ríńtì 11:23-27 ti ní láti ṣẹlẹ̀ ní sáà yìí, tó fi hàn pé ọwọ́ rẹ̀ kò dilẹ̀ rárá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.—7/15, ojú ìwé 26 àti 27.

Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìfojúsọ́nà wa mọ níwọ̀n?

Rántí pé Jèhófà lóye wa. Àdúrà gbígbà sí i lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìrònú wa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó sì ń fi hàn pé a mọ ibi tí agbára wa mọ. Ìrànlọ́wọ́ mìíràn ni níní àkọ̀tun èrò nígbà tí o bá bá ọ̀rẹ́ kan tó dàgbà dénú sọ̀rọ̀.—8/1, ojú ìwé 29 àti 30.