Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tí A Lè Gbà Mú Ìkórìíra Kúrò Pátápátá

Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tí A Lè Gbà Mú Ìkórìíra Kúrò Pátápátá

Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tí A Lè Gbà Mú Ìkórìíra Kúrò Pátápátá

“Kò lè sí ìkórìíra láìsí ẹ̀rù. . . . Ohun táa ń bẹ̀rù la máa ń kórìíra, nítorí náà ibi tí ìkórìíra bá wà, ẹ̀rù gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀.”—CYRIL CONNOLLY, OLÙṢE LÁMÈYÍTỌ́ LÍTÍRÉṢỌ̀ ÀTI OLÓÒTÚ.

Ọ̀PỌ̀ àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ló gbà gbọ́ pé ìkórìíra ti ta gbòǹgbò sọ́kàn ènìyàn láìmọ̀. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan nípa òṣèlú sọ pé: “Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ṣe ni a bí apá tó pọ̀ jù lọ níbẹ̀ mọ́ wa,” ìyẹn ni pé kí ó jẹ́ ara àbùdá ènìyàn.

A lóye ìdí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣarasíhùwà ẹ̀dá ènìyàn fi dé ìparí èrò yẹn. Ìdí náà ni pé àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin tí ẹ̀kọ́ wọn dá lé lórí ni a bí “pẹ̀lú ìṣìnà” àti “nínú ẹ̀ṣẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bíbélì tí a mí sí ti fi hàn. (Sáàmù 51:5) Kódà, Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ ṣàyẹ̀wò bí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ṣe rí ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún sẹ́yìn, ó sì “rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5.

Ẹ̀tanú, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àti ìkórìíra tí ó wá látinú wọn jẹ́ àbájáde àìpé àti ìmọtara-ẹni-nìkan tí a jogún. (Diutarónómì 32:5) Ó ṣeni láàánú pé kò sí àjọ kan téèyàn gbé kalẹ̀ tàbí ìjọba èyíkéyìí, bó ti wù kí ìlànà rẹ̀ rí, tí ó tíì ṣeé ṣe fún láti fòfin yí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn padà lórí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Akọ̀ròyìn ilẹ̀ òkèèrè nì, Johanna McGeary, sọ pé: “Kò sí agbófinró kankan láyé, bó ti wù kó lágbára tó, tó lè sọ pé òun máa fòpin sí ìkórìíra tó ti sọ Bosnia, Sòmálíà, Liberia, Kashmir, àti Caucasus di ibi tí ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn.”

Àmọ́ ṣá o, kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí wá ojútùú, ó yẹ ká kọ́kọ́ lóye ohun tó ń fa ìkórìíra.

Ìkórìíra Tí Ìbẹ̀rù Ń Fà

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìkórìíra ń gbà wá, oríṣiríṣi rẹ̀ ló sì wà. Òǹkọ̀wé Andrew Sullivan ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó dáa, ó ní: “Ìkórìíra tí ń bẹ̀rù wà, ìkórìíra tó kàn ń tẹ́ńbẹ́lú sì wà; ìkórìíra tó ń fi agbára hàn wà, bẹ́ẹ̀ ni àìlágbára tún ń fa ìkórìíra; ti ẹ̀mí ìgbẹ̀san wà, a sì tún rí ìkórìíra tí ìlara ń fà. . . . Ìkórìíra apọ́nni-lójú wà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìkórìíra tún ń wá látọ̀dọ̀ ẹni tí a ń pọ́n lójú. Ìkórìíra tí a rọra ń súnná sí wà, èyí tó sì ń ṣá wà pẹ̀lú. Ìkórìíra tó máa ń bú gbàù wà, a sì rí ìkórìíra tí kì í gbaná jẹ láé.”

Láìsí àní-àní, díẹ̀ lára ohun tó ń fa ìkórìíra tí ń múni forí gbárí ní àkókò tiwa yìí ni àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ètò ọrọ̀ ajé. Ẹ̀tanú líle koko àti ìkórìíra tó ń hàn sójútáyé ni a sábà máa ń rí láwọn àgbègbè tí àwọn díẹ̀ tó rí jájẹ ti ń jayé ọba láàárín àwọn tálákà tó pọ̀ lọ súà. Bákan náà, ìkórìíra tún máa ń wà láwọn ibi tí àwọn àjèjì tó ń rọ́ wọ̀lú ti mú kó dà bí ẹni pé àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé apá ibì kan láwùjọ kò ní tó.

Àwọn kan lè máa ronú pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀-dé wọ̀nyí kò ní jẹ́ kí àwọn ríṣẹ́ ṣe, wọ́n á jẹ́ kí owó iṣẹ́ àwọn kéré, tàbí pé wọ́n á jẹ́ kí ohun ìní àwọn di ọ̀pọ̀kúyọ̀kú. Kókó mìíràn ni bóyá irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ tọ́ tàbí kò tọ́. Bíbẹ̀rù pé ọrọ̀ ajé àwọn lè dẹnu kọlẹ̀ àti bíbẹ̀rù pé ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere àwùjọ àwọn tàbí ọ̀nà tí àwọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé lè jó rẹ̀yìn jẹ́ àwọn kókó tó lágbára tí ń fa ẹ̀tanú àti ìkórìíra.

Kí ni ohun àkọ́kọ́ tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti mú ìkórìíra kúrò pátápátá? Ó ń béèrè yíyí ìṣarasíhùwà padà.

Yíyí Ìṣarasíhùwà Padà

McGeary sọ pé: “Ọ̀nà kan ṣoṣo tí ìyípadà tòótọ́ fi lè wáyé ni kí ó wá láti inú ọkàn àwọn èèyàn tọ́ràn kàn.” Báwo sì ni a ṣe lè yí ọkàn àwọn èèyàn padà? Ìrírí ti fi hàn pé ipa tó lágbára jù lọ, tó ń súnni ṣe nǹkan jù lọ, tó sì lè wà pẹ́ títí jù lọ láti ṣẹ́gun ìkórìíra ni èyí tó wá látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.”—Hébérù 4:12.

Òótọ́ kúkú ni pé ẹ̀tanú àti ìkórìíra kì í ṣe ohun táa kàn lè fà tu lójú ẹsẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun táa lè mú kúrò ní ọ̀sán-kan-òru-kan. Àmọ́, ó ṣeé mú kúrò. Jésù Kristi, ẹni tí ń sún ọkàn-àyà ṣiṣẹ́ jù lọ, tó sì ń ta ẹ̀rí ọkàn jí, mú kí àwọn ènìyàn yí padà. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti kẹ́sẹ járí nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jésù Kristi fúnni pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.”—Mátíù 5:44.

Ká lè mọ̀ pé òótọ́ ni ohun tó fi ń kọ́ni, Mátíù, tó jẹ́ agbowó òde tẹ́lẹ̀, tó sì jẹ́ ẹnì kan tí wọ́n kórìíra gidigidi láwùjọ àwọn Júù wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tí Jésù fọkàn tán jù lọ. (Mátíù 9:9; 11:19) Síwájú sí i, Jésù fi ọ̀nà ìjọsìn mímọ́ gaara kan lélẹ̀, èyí tó jẹ́ pé ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ yóò ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kèfèrí nínú, àwọn tí a ti fìgbà kan rí pa tì, tí a sì kórìíra. (Gálátíà 3:28) Káàkiri ayé ìgbà yẹn làwọn èèyàn ti di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. (Ìṣe 10:34, 35) A sì fi ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní mọ̀ wọ́n. (Jòhánù 13:35) Nígbà tí àwọn tí ìkórìíra ń pa bí ọtí sọ Sítéfánù, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù lókùúta pa, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kẹ́yìn ni pé: “Jèhófà, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Ohun tó dára jù lọ ni Sítéfánù fẹ́ fún àwọn tó kórìíra rẹ̀.—Ìṣe 6:8-14; 7:54-60.

Bákan náà ni àwọn Kristẹni tòde òní ṣe ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé kí wọ́n máa ṣe ohun rere, kì í ṣe fún àwọn Kristẹni arákùnrin wọn nìkan, àmọ́ fún àwọn tó kórìíra wọn pàápàá. (Gálátíà 6:10) Wọ́n ń tiraka gan-an láti mú ìkórìíra onínú burúkú kúrò nínú ìgbésí ayé wọn. Bí wọn bá rí ohun tó lè fa ìkórìíra lọ́kàn wọn, kíá ni wọ́n máa ń gbé ìgbésẹ̀ tó dára, tí wọn ó sì fi ìfẹ́ dípò ìkórìíra. Dájúdájú, ọ̀rọ̀ náà rí bí ọlọgbọ́n ọkùnrin ayé ọjọ́un kan ṣe sọ ọ́ pé, “ìkórìíra ní ń ru asọ̀ sókè, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo ìrélànàkọjá pàápàá mọ́lẹ̀.”—Òwe 10:12.

Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.” (1 Jòhánù 3:15) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba ìyẹn gbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n kóra jọ pọ̀ nísinsìnyí—láti inú gbogbo ẹ̀yà, àwùjọ, ìsìn àti ìṣèlú—di ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìṣọ̀kan, tí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìkórìíra, wọ́n jẹ́ ojúlówó ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé.—Wo àwọn àpótí tí ó wà pẹ̀lú àpilẹ̀kọ yìí.

A Óò Mú Ìkórìíra Kúrò Pátápátá!

O lè sọ pé: ‘Ṣùgbọ́n, àárín àwọn tí ẹ̀ ń sọ yìí nìkan ni ìkórìíra ò sí. Síbẹ̀, èyí kò lè mú ìkórìíra kúrò nínú ayé táa wà yìí pátápátá.’ Òótọ́ lo sọ, àní bí ìkórìíra ò tiẹ̀ sí lọ́kàn tìrẹ, ẹlòmíràn ṣì lè kórìíra rẹ. Nítorí náà, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ yíjú sí fún ojútùú tí ó ṣe gúnmọ́ sí ìṣòro tó kárí ayé yìí.

Ọlọ́run pète pé gbogbo ohun tó ń jẹ́ ìkórìíra ni a óò mú kúrò lórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Èyí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba ọ̀run tí Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà fún pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.

Nígbà tí àdúrà yẹn bá di èyí tí a dáhùn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, àwọn ipò tó ń fa ìkórìíra kò ní sí mọ́. A ó ti mú àwọn ohun tó máa ń bá a rìn kúrò pátápátá. A ó ti fi ìlàlóye, òtítọ́, àti òdodo rọ́pò ìgbékèéyíde, àìmọ̀kan, àti ẹ̀tanú. Ní tòótọ́, nígbà yẹn, Ọlọ́run ‘yóò ti nu omijé gbogbo nù kúrò, ikú kì yóò sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.’—Ìṣípayá 21:1-4.

Kódà, ìròyìn ayọ̀ wà báyìí! Àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro ti wà báyìí pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Nítorí ìdí èyí, ọkàn wá lè balẹ̀ pé láìpẹ́, a ó rí i pé ìkórìíra tí inú Ọlọ́run kò dùn sí yóò kásẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ ayé yìí. (2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:3-14) Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, ojúlówó ẹ̀mí ẹgbẹ́ àwọn ará yóò gbilẹ̀ nítorí pé a ó ti mú ìran ènìyàn padà bọ̀ sí ìjẹ́pípé.—Lúùkù 23:43; 2 Pétérù 3:13.

Ṣùgbọ́n o kò ní láti dúró di àkókò yẹn kí o tó gbádùn ojúlówó ẹgbẹ́ àwọn ará. Àní, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ìròyìn tó wà pẹ̀lú àpilẹ̀kọ yìí, ìfẹ́ Kristẹni ti gba ọkàn-àyà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn dípò ìkórìíra tí ì bá wà níbẹ̀. A ké sí ìwọ náà láti wá di ara ẹgbẹ́ àwọn ará onífẹ̀ẹ́ yìí!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Kí Ni Jésù Ì Bá Ṣe?”

Ní June 1998, àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ funfun gbéjà ko James Byrd Kékeré, tó jẹ́ adúláwọ̀ ní abúlé Texas tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n mú un lọ sí àgbègbè jíjìnnà kan tó dá páropáro, wọ́n lù ú, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n so ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì pa pọ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá so ó mọ́ ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan tí wọ́n sì wọ́ ọ tuuru káàkiri ibi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kìlómítà márùn-ún lójú títì, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ títí ara rẹ̀ fi já sínú gọ́tà kan tí wọ́n fi kankéré ṣe. Èyí ni wọ́n pè ní ìkórìíra oníwà ipá tó burú jù lọ nínú ẹ̀wádún yẹn (ìyẹn láwọn ọdún 1990 sí 1999).

Obìnrin mẹ́ta lára àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò James Byrd ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ni èrò wọn nípa àwọn tó hu ìwà ọ̀daràn tó burú jáì yìí? Nínú ọ̀rọ̀ kan tí gbogbo wọn jọ fohùn ṣọ̀kan lé lórí, wọ́n ní: “Rírí i kí a dá olólùfẹ́ ẹni lóró kí a sì pa á jẹ́ àdánù ńlá àti ẹ̀dùn ọkàn tí kò ṣeé fẹnu sọ. Báwo lèèyàn ṣe máa hùwà padà sí irú ìwà òkú òǹrorò bẹ́ẹ̀? Kò tiẹ̀ wá sọ́kàn wa rárá pé ká gbẹ̀san, tàbí ká sọ̀rọ̀ ìkórìíra, tàbí ká bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti gbin ìkórìíra sáwọn èèyàn lọ́kàn. A ronú pé: ‘Kí ni Jésù ì bá ṣe? Báwo ni ì bá ṣe hùwà padà?’ Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yẹn ò fara sin rárá. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ì bá ti jẹ́ ti àlàáfíà àti ìrètí.”

Lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ràn wọ́n lọ́wọ́, tí wọn ò fi jẹ́ kí ìkórìíra wà nínú ọkàn-àyà wọn ni Róòmù 12:17-19. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”

Wọ́n ń bá ọ̀rọ̀ wọn lọ pé: “A rántí ojúlówó ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa pé àwọn àìfẹ̀tọ́bánilò tàbí àwọn ìwà ọ̀daràn kan wà tó burú jáì débi pé yóò ṣòro fún ọ láti sọ pé, ‘Mo dárí jì ọ́, kí o sì gbàgbé ẹ̀. Ìdáríjì ní irú ipò yẹn wulẹ̀ lè jẹ́ kí ẹnì kan sáà jáwọ́ nínú ìkorò ọkàn, kó lè máa gbé ìgbésí ayé tirẹ̀ lọ, kó má sọ ara rẹ̀ di aláìsàn tàbí kó da ara rẹ̀ lórí rú nítorí dídi kùnrùngbùn.” Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí tó fakíki lèyí jẹ́ sí agbára Bíbélì tí kò jẹ́ kí ìkórìíra ta gbòǹgbò lọ́kàn ẹni!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Kèéta Tó Yí Padà Di Ìbádọ́rẹ̀ẹ́

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aṣíwọ̀lú ló ń ya wọ ilẹ̀ Gíríìsì láti wáṣẹ́ ṣe. Àmọ́, ipò ọrọ̀ ajé tó túbọ̀ ń burú sí i ti jẹ́ kí àǹfààní iṣẹ́ rírí dín kù gan-an ni, èyí sì wá jẹ́ kí àwọn èèyàn tẹra mọ́ iṣẹ́ wíwá lójú méjèèjì. Nítorí ìdí èyí, kèéta tó kọjáa sísọ ti wá wà láàárín onírúurú ẹ̀yà. Àpẹẹrẹ kan tó gba àfiyèsí ni ti ìbáradíje tó wà láàárín àwọn tó ṣí wá láti Albania àti àwọn tó wá láti Bulgaria. Ní ọ̀pọ̀ àgbègbè ilẹ̀ Gíríìsì, ìbáradíje tó wà láàárín àwọn ẹ̀yà méjì wọ̀nyí le gan-an ni.

Ní ìlú Kiato, ní ìhà àríwá ìlà oòrùn Peloponnisos, ìdílé kan tó wá láti Bulgaria àti ọkùnrin kan tó jẹ́ ará Albania bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì wá di ojúlùmọ̀ ara wọn. Àwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n fi sílò ló mú kèéta tó wà láàárín ọ̀pọ̀ àwọn tó wá láti ẹ̀yà méjì wọ̀nyí kúrò. Ó tún ṣàlékún sí níní ojúlówó ìbádọ́rẹ̀ẹ́ láàárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ivan, tó jẹ́ ará Bulgaria, tilẹ̀ bá Loulis, tó jẹ́ ará Albania rílé sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé tí òun fúnra rẹ̀ ń gbé gangan. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ìdílé méjèèjì náà jọ ń jẹun pọ̀ tí wọ́n sì máa ń lo àwọn nǹkan ìní ara wọn. Àwọn ọkùnrin méjèèjì náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣe batisí báyìí, wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, gbogbo àwọn aládùúgbò ló kíyè sí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Kristẹni yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo ohun tó ń jẹ́ ìkórìíra ni a óò mú kúrò lórí ilẹ̀ ayé