Ṣé O Ti Di “Géńdé” Kristẹni?
Ṣé O Ti Di “Géńdé” Kristẹni?
“NÍGBÀ tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó.” Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ nìyẹn. Lóòótọ́, gbogbo wa la fìgbà kan jẹ́ ìkókó tí kò lè dá ohunkóhun ṣe. Àmọ́, a ò wà bẹ́ẹ̀ títí ayé. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.”—1 Kọ́ríńtì 13:11.
Ní ọ̀nà kan náà, gbogbo Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀ bí ìkókó nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n bí àkókò ti ń lọ, gbogbo wa lè “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé ọkùnrin, tí a ó fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.” (Éfésù 4:13) Nínú Kọ́ríńtì Kìíní orí kẹrìnlá, ẹsẹ ogún, a gbà wá níyànjú pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe di ọmọ kéékèèké nínú agbára òye . . . Ẹ dàgbà di géńdé nínú agbára òye.”
Bí àwọn géńdé Kristẹni tó dàgbà dénú ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó jẹ́ ìbùkún fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run lóde òní, pàápàá nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun táa ní. Àwọn géńdé Kristẹni ń jẹ́ kí ìjọ túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Wọ́n ń ní ipa tó dára lórí ẹ̀mí ìjọ èyíkéyìí tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́.
Nígbà tó jẹ́ pé ṣe ni dídàgbà nípa tara máa ń wá fúnra rẹ̀, dídàgbà nípa tẹ̀mí máa ń gba àkókò àti ìsapá. Abájọ, tó fi jẹ́ pé nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn Kristẹni kan kùnà láti “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Hébérù 5:12; 6:1) Ìwọ náà ńkọ́? Yálà ó ti ń sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún ni o, tàbí kìkì àkókò kúkúrú lo tíì fi sìn ín, yóò dára tí o bá lè yẹ ara rẹ wò láìṣàbòsí. (2 Kọ́ríńtì 13:5) Ǹjẹ́ o wà lára àwọn táa lè pè ní géńdé Kristẹni tó dàgbà dénú ní tòótọ́? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, báwo lo ṣe lè dà bẹ́ẹ̀?
“Géńdé Nínú Agbára Òye”
Ẹni tí ó jẹ́ ìkókó nípa tẹ̀mí rọrùn láti di ẹni “tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.” Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi.” (Éfésù 4:14, 15) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Hébérù orí karùn-ún, ẹsẹ ìkẹrìnlá sọ pé: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”
Ṣàkíyèsí pé àwọn tí ó dàgbà dénú ti kọ́ agbára ìwòye wọn nípasẹ̀ lílò, tàbí nípasẹ̀ ìrírí tí wọ́n ti ní nínú fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Ó hàn gbangba nígbà náà pé èèyàn ò lè dàgbà dénú lọ́sàn-án kan òru kan; ó ń gba àkókò láti dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. Bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti tipasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ mú kí ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí rẹ rọrùn—àgàgà kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní ẹnu àìpẹ́ yìí, Ilé Ìṣọ́ ti jíròrò ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀. Àwọn tó dàgbà dénú kì í sá fún irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó ní “àwọn ohun kan tí ó nira láti lóye” nínú. (2 Pétérù 3:16) Dípò ìyẹn, tìtaratìtara ni wọ́n fi ń jẹ irú oúnjẹ líle bẹ́ẹ̀ ní àjẹtán!
Àwọn Oníwàásù àti Olùkọ́ Tó Nítara
Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Fífi tìtaratìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà lè mú kí o tètè dàgbà nípa tẹ̀mí. Kí ló dé tí o kò fi tiraka láti kópa nínú rẹ̀ dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ibi tí agbára rẹ lè ṣe é dé?—Mátíù 13:23.
Nígbà míì, àwọn pákáǹleke inú ìgbésí ayé lè mú kó ṣòro fún wa láti rí àkókò tí a ó fi wàásù. Síbẹ̀, nípa ‘títiraka tokuntokun’ gẹ́gẹ́ bí oníwàásù, o ń fi bí o ṣe ka “ìhìn rere” náà sí pàtàkì tó hàn. (Lúùkù 13:24; Róòmù 1:16) O lè wá tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí a ń wò gẹ́gẹ́ bí “àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́.”—1 Tímótì 4:12.
Àwọn Olùpa Ìwà Títọ́ Mọ́
Dídàgbà dénú tún ní sísapá láti pa ìwà títọ́ mọ́ nínú. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Sáàmù kẹrìndínlọ́gbọ̀n, ẹsẹ kìíní, Dáfídì polongo pé: “Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, nítorí pé mo ti rìn nínú ìwà títọ́ mi.” Ìwà títọ́ jẹ́ ìwà rere, tó dára délẹ̀délẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kò túmọ̀ sí ìjẹ́pípé. Dáfídì alára dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo bíi mélòó kan. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó gba ìbáwí, tí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe, ó fi hàn kedere pé ọkàn-àyà òun ṣì ní ojúlówó ìfẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 26:2, 3, 6, 8, 11) Ìwà títọ́ ní ìfọkànsìn tí kò lábùlà, tàbí tó pé pérépéré nínú. Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré . . . sìn ín.”—1 Kíróníkà 28:9.
Pípa ìwà títọ́ mọ́ ní í ṣe pẹ̀lú jíjẹ́ ẹni tí “kì í ṣe apá kan ayé,” nípa títa kété sí ètò ìṣèlú àwọn orílẹ̀-èdè àti ogun wọn. (Jòhánù 17:16) O sì tún gbọ́dọ̀ yàgò fún ìwà ìbàjẹ́, bí àgbèrè, panṣágà, àti ìjoògùnyó. (Gálátíà 5:19-21) Àmọ́ ṣá o, ohun tí ìwà títọ́ túmọ̀ sí ré kọjá yíyẹra fún àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Sólómọ́nì kìlọ̀ pé: “Àwọn òkú eṣinṣin ní ń mú kí òróró olùṣe òróró ìkunra ṣíyàn-án, kí ó máa hó kùṣọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ń ṣe sí ẹni tí ó ṣe iyebíye nítorí ọgbọ́n àti ògo.” (Oníwàásù 10:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, kódà “ìwà òmùgọ̀ díẹ̀,” bíi àwàdà tí kò ṣeé gbọ́ sétí, tàbí bíbá ẹ̀yà kejì tage, lè ba orúkọ rere ẹni tí ó “ṣe iyebíye nítorí ọgbọ́n” jẹ́. (Jóòbù 31:1) Nítorí náà, fi ìdàgbàdénú rẹ hàn nípa gbígbìyànjú láti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú gbogbo ìṣesí rẹ, tiẹ̀ yàgò fún “ohun gbogbo tí ó jọ ibi” pàápàá.—1 Tẹsalóníkà 5:22, Bibeli Mimọ.
Àwọn Adúróṣinṣin
Géńdé Kristẹni kan tún jẹ́ adúróṣinṣin. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kà á nínú Éfésù orí kẹrin, ẹsẹ ìkẹrìnlélógún, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ . . . gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí a lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún “ìdúróṣinṣin” gbé èrò nípa ìjẹ́mímọ́, òdodo, àti ọ̀wọ̀ yọ. Ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin jẹ́ olùfọkànsìn, ó jẹ́ onítara; ó máa ń fara balẹ̀ ṣe gbogbo ojúṣe rẹ̀ sí Ọlọ́run.
Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà mú irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ dàgbà? Ọ̀nà kan ni pé kí o máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ àdúgbò rẹ. (Hébérù 13:17) Ní mímọ̀ pé Kristi ni a yàn gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristẹni, àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú máa ń dúró ṣinṣin ti àwọn tí a yàn “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:28) Ẹ wo bí yóò ti burú tó láti fojú di ọlá àṣẹ àwọn alàgbà tí a yàn tàbí kí a jìn ín lẹ́sẹ̀! O sì tún gbọ́dọ̀ fi ìdúróṣinṣin rẹ hàn sí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àti àwọn aṣojú tí a ń lò láti pín “oúnjẹ” tẹ̀mí káàkiri “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:45) Yára láti ka àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tó ń jáde pẹ̀lú rẹ̀, kí o sì fi ìsọfúnni wọ̀nyẹn sílò.
Máa Fi Ìfẹ́ Hàn Nínú Ìṣe Rẹ
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Ìfẹ́ yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ sì ń pọ̀ sí i lẹ́nì kìíní sí ẹnì kejì.” (2 Tẹsalóníkà 1:3) Dídàgbà nínú ìfẹ́ jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìdàgbàsókè tẹ̀mí. Jésù sọ bó ṣe wà nínú Jòhánù orí kẹtàlá, ẹsẹ karùndínlógójì pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” Irú ìfẹ́ ará bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìfẹ́ tí ò dénú tàbí ìgbónára lásánlàsàn. Ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words ṣàlàyé pé: “Kìkì ohun tí ìfẹ́ bá súnni ṣe la lè fi mọ̀ ọ́n.” Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, tẹ̀ síwájú dé ìdàgbàdénú lọ́nà yìí nípa jíjẹ́ kí ìfẹ́ sún ọ ṣiṣẹ́!
Fún àpẹẹrẹ, a kà á nínú Róòmù orí kẹẹ̀ẹ́dógún, ẹsẹ ìkeje pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Ọ̀nà kan láti fi ìfẹ́ hàn ni pé kí o máa kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ àti àwọn ẹni tuntun láwọn ìpàdé ìjọ—máa kí wọn pẹ̀lú ìtara, tọ̀yàyàtọ̀yàyà! Gbìyànjú láti mọ̀ wọ́n lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Jẹ́ kí “ire ara ẹni” ti àwọn ẹlòmíràn jẹ ọ́ lógún. (Fílípì 2:4) O tiẹ̀ lè fi aájò àlejò hàn pàápàá, kí o sì ké sí àwọn kan wá sílé rẹ. (Ìṣe 16:14, 15) Àìpé àwọn ẹlòmíì lè dán bí ìfẹ́ ìwọ alára ṣe jinlẹ̀ tó wò nígbà mìíràn, àmọ́ bí o ti ń kọ́ láti ‘fara dà á fún wọn nínú ìfẹ́,’ o ń fi hàn pé o ti ń dàgbà di géńdé.—Éfésù 4:2.
Lílo Ohun Ìní Wa Láti Gbé Ìsìn Mímọ́ Lárugẹ
Ní ayé ìgbàanì, kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run ló ṣe ojúṣe wọn láti ṣe ìtìlẹ́yìn fún tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ọlọ́run wá tìtorí bẹ́ẹ̀ rán àwọn wòlíì rẹ̀, bíi Hágáì àti Málákì láti ru àwọn ènìyàn Rẹ̀ sókè sí ojúṣe yìí. (Hágáì 1:2-6; Málákì 3:10) Lóde òní, àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú ń fi tayọ̀tayọ̀ lo ohun ìní wọn láti ṣe ìtìlẹ́yìn fún ìjọsìn Jèhófà. Fara wé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nípa títẹ̀lé ìlànà tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 16:1, 2 pé, ‘kí o ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe’ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ìjọ àti fún iṣẹ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe jákèjádò ayé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Ẹni tí ó bá . . . ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú.”—2 Kọ́ríńtì 9:6.
Má ṣe gbójú fo ohun iyebíye mìíràn tí o ní dá, ìyẹn àwọn nǹkan bí àkókò tàbí agbára rẹ. Gbìyànjú láti ‘ra àkókò padà’ látinú àwọn ìgbòkègbodò tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. (Éfésù 5:15, 16; Fílípì 1:10) Kọ́ láti túbọ̀ lo àkókò rẹ lọ́nà tó dáa. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti kópa nínú iṣẹ́ bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ìgbòkègbodò mìíràn bẹ́ẹ̀ tó ń gbé ìjọsìn Jèhófà lárugẹ. Lílo ohun ìní rẹ lọ́nà yìí yóò túbọ̀ fi ẹ̀rí hàn pé o ti ń di géńdé Kristẹni.
Tẹ̀ Síwájú Dé Ìdàgbàdénú!
Ní ti tòótọ́, ìbùkún ńlá ni àwọn ọkùnrin àtobìnrin wọ̀nyí jẹ́, ìyẹn àwọn tí wọ́n láápọn ìkẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí wọ́n ń fi ìtara wàásù, tí ìwà títọ́ wọn dúró sán-ún, tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin àti onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ṣe tán láti lo ara wọn àti ohun ìní wọn láti ṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà. Abájọ nígbà náà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gbani níyànjú pé: “Nísinsìnyí tí a ti fi àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú”!—Hébérù 6:1.
Ṣé géńdé Kristẹni tó dàgbà dénú ni ọ́? Àbí o ṣì jẹ́ ìkókó nípa tẹ̀mí láwọn ọ̀nà kan? (Hébérù 5:13) Èyí ó wù kó jẹ́, pinnu láti jára mọ́ ìdákẹ́kọ̀ọ́, wíwàásù, àti fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn arákùnrin rẹ. Tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tàbí ìbáwí èyíkéyìí tí àwọn tó dàgbà dénú bá fún ọ. (Òwe 8:33) Ṣe gbogbo ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Bí àkókò ti ń lọ, pẹ̀lú ìsapá, ìwọ náà lè “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé ọkùnrin, tí a ó fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.”—Éfésù 4:13.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
Àwọn géńdé Kristẹni ń jẹ́ kí ìjọ túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Wọ́n ń ní ipa tó dára lórí ẹ̀mí ìjọ.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú máa ń ṣàlékún ẹ̀mí ìjọ nípa ṣíṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn