Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Forí Lé Àwọn Erékùṣù Pàsífíìkì Láti Lọ Ṣiṣẹ́!

A Forí Lé Àwọn Erékùṣù Pàsífíìkì Láti Lọ Ṣiṣẹ́!

A Forí Lé Àwọn Erékùṣù Pàsífíìkì Láti Lọ Ṣiṣẹ́!

APÁ ibi tí ìjókòó àwọn èrò tó ń dúró de ọkọ̀ wà ní pápákọ̀ òfuurufú ńlá ti Brisbane àti Sydney, ní Ọsirélíà, kún fún ayọ̀ tó ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àwùjọ ẹlẹ́ni mẹ́rìndínláàádọ́ta kan fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí Samoa tí oòrùn ti máa ń mú gan-an láti lọ pàdé àwọn mọ́kàndínlógójì míì láti New Zealand, Hawaii, àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni ẹrù wọn—àwọn ohun èlò ni lájorí ohun tó wà níbẹ̀, àwọn nǹkan bí òòlù, ayùn, àti èlò táa fi ń dáhò sí nǹkan—ìwọ̀nyí yàtọ̀ pátápátá sí irú àwọn ẹrù téèyàn máa ń kó tó bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí erékùṣù Pàsífíìkì fífanimọ́ra. Àmọ́ ṣá o, ète tí wọ́n fẹ́ fi rìnrìn àjò tiwọn yìí, àrà ọ̀tọ̀ ni.

Àwọn ni wọ́n sanwó ọkọ̀ ara wọn, wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn láti fọ̀sẹ̀ méjì ṣiṣẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ níbi ètò ìkọ́lé kan tó wà lábẹ́ àbójútó Ilé Iṣẹ́ Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọsirélíà. Owó táwọn èèyàn fínnúfíndọ̀ dá ni wọ́n ń ná sórí iṣẹ́ yìí, tó ní í ṣe pẹ̀lú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ilé àwọn míṣọ́nnárì, àti ẹ̀ka tàbí àwọn ọ́fíìsì ìtúmọ̀ èdè, nítorí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbèrú sí i ní àwọn erékùṣù Pàsífíìkì. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ tẹnu àwọn kan lára àwọn òṣìṣẹ́, tí wọ́n wà lára àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lórílẹ̀-èdè tiwọn.

Max, tó ń kan páànù ilé, wá láti ìlú Cowra ní New South Wales, Ọsirélíà. Ó ti gbéyàwó, ó sì lọ́mọ márùn-ún. Hawaii ni Arnold ti wá. Òun àti aya rẹ̀ ní ọmọkùnrin méjì, ó sì tún jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bíi ti Max, Arnold náà ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ rẹ̀. Ó dájú pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí—tí ipò wọn ò yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ náà—kò yọ̀ǹda ara wọn nítorí pé wọn ò ríkan ṣèkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àti ìdílé wọn rí i pé àwọn kan ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́, wọ́n sì fẹ́ sa gbogbo ipá wọn láti ṣèrànwọ́.

Àwọn Òṣìṣẹ́ Káyé Ń Kó Ipa Pàtàkì

Ibì kan tí wọ́n ti nílò iṣẹ́ wọn ni Tuvalu, orílẹ̀-èdè kan ní Pàsífíìkì tó ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [10,500] olùgbé, ó wà níbi àgbájọ erékùṣù mẹ́sàn-án jíjìnnà réré tí omi wọ́n ní ìlẹ̀kẹ̀ iyùn, nítòsí agbedeméjì ayé àti àríwá ìlà oòrùn Samoa. Ìpíndọ́gba ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn erékùṣù tàbí erékùṣù olómi láàárín wọ̀nyí tó nǹkan bíi kìlómítà méjì àtààbọ̀ níbùú lóròó. Ní 1994, àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́kànlélọ́gọ́ta tó wà níbẹ̀ nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àti ọ́fíìsì ńlá fún títúmọ̀ èdè, wọ́n sì nílò ilé wọ̀nyí ní kánjúkánjú.

Ní Pàsífíìkì ilẹ̀ olóoru níbí, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ilé wọn lọ́nà tí yóò fi lè dúró gbọn-in nítorí ìjì àti ẹ̀fúùfù líle tó máa ń jà níbẹ̀ nígbà gbogbo. Àmọ́, díẹ̀ ni ojúlówó nǹkan ìkọ́lé tí a lè rí ní àwọn erékùṣù náà. Kí wá ni ṣíṣe? Gbogbo ohun èlò—láti orí páànù àti igi ìrólé títí dórí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti aṣọ ojú fèrèsé, àwọn àwo ilé ìyàgbẹ́ àti ojú ibi tómi ti ń tú síni lára ní balùwẹ̀, títí kan àwọn ìdè àti ìṣó—la kó sínú àwọn ohun ìkẹ́rùsí tí a sì fi ọkọ̀ òkun kó wọn wá láti Ọsirélíà.

Kó tó di pé àwọn ẹrù wọ̀nyí dé, àwọn díẹ̀ ti kọ́kọ́ lọ ṣáájú tí wọ́n lọ ṣètò ilẹ̀ náà tí wọ́n sì fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn òṣìṣẹ́ káyé dé, wọ́n kọ́lé náà, wọ́n kùn ún, wọ́n sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.

Lọ́nà kan ṣáá, àṣé gbogbo ìgbòkègbodò tó ń lọ ní Tuvalu yìí ń bí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ládùúgbò nínú bí nǹkan míì, ó wá lọ kéde lórí rédíò pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ “Ilé Gogoro Bábélì”! Àmọ́ kí lohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an? Graeme, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn sọ pé: “Nígbà tí àwọn tó ń kọ́ Ilé Gogoro Bábélì ti inú Bíbélì ò gbọ́ra wọn yé mọ́ nítorí pé Ọlọ́run ti dà wọ́n lédè rú, ni wọ́n paṣẹ́ náà tì, tí wọ́n sì fi ilé gogoro náà sílẹ̀ láìparí.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9) Ó ń bá a lọ pé: “Tàwọn tó ń ṣiṣẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run ò rí bẹ́ẹ̀. Láìka èdè àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tó yàtọ̀ sí, iṣẹ́ náà máa ń parí ṣáá ni.” Bẹ́ẹ̀ náà ni eléyìí—ọ̀sẹ̀ méjì péré ni wọ́n fi parí ẹ̀. Àní, àwọn èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́jọ [163] títí kan ìyàwó olórí ìjọba ló wà níbi ayẹyẹ ìyàsímímọ́ náà.

Doug, tó bójú tó iṣẹ́ náà, rántí ìrírí náà, ó sì sọ pé: “Ayọ̀ ńlá ló jẹ́ láti bá àwọn òṣìṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn láti orílẹ̀-èdè míì ṣiṣẹ́. Ọ̀nà táa gbà ń ṣe nǹkan yàtọ̀ síra, ìlò èdè wá yàtọ̀ síra, kódà ìyàtọ̀ wà nínú bí a ṣe ń wọn nǹkan, síbẹ̀ kò sí èyí tó fa ìṣòro nínú gbogbo ìwọ̀nyí.” Nísinsìnyí tó ti kópa nínú irú iṣẹ́ yẹn bíi mélòó kan, ó fi kún un pé: “Èyí túbọ̀ fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé, pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, àwọn ènìyàn rẹ̀ lè kọ́lé síbikíbi lórí ilẹ́ ayé yìí, bó ti wù kí ibẹ̀ jẹ́ àdádó tó, tàbí bó ti wù kó jẹ́ ibi tó ṣòro tó. Lóòótọ́, a ní ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ní ẹ̀bùn àbínibí, àmọ́ ẹ̀mí Jèhófà ló ń mú kó ṣeé ṣe.”

Ẹ̀mí Ọlọ́run tún mú kí àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí tó wà ní àwọn erékùṣù náà pèsè oúnjẹ àti ilé, tó jẹ́ pé fún àwọn kan, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n fi du ara wọn. Àwọn tí wọ́n ṣe irú aájò àlejò bẹ́ẹ̀ fún sì mọrírì rẹ̀ gan-an ni. Ken, tó wá láti Melbourne, Ọsirélíà, ti ṣe irú iṣẹ́ kan náà ní ilẹ̀ French Polynesia. Ó sọ pé: “A wá síbí bí ìránṣẹ́, àmọ́ wọ́n ṣe wá bí ọba.” Láwọn ibi tó bá ti ṣeé ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò tún máa ń ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Ní Solomon Islands, àwọn obìnrin ń po kankéré—láìsí ẹ̀rọ. Ọgọ́rùn-ún ọkùnrin àtobìnrin ló gun orí òkè ńlá tí wábi-wọ́sí òjò ti rọ̀, tí wọ́n sì gbé ogójì tọ́ọ̀nù igi gẹdú sọ̀ kálẹ̀. Àwọn èwe náà ṣèrànwọ́. Òṣìṣẹ́ kan láti New Zealand sọ pé: “Mo rántí arákùnrin ọ̀dọ́ kan ní erékùṣù yẹn tó máa ń gbé àpò sìmẹ́ǹtì méjì tàbí mẹ́ta lẹ́ẹ̀kan. Ó sì máa ń fi ṣọ́bìrì kó yanrìn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, nínú oòrùn àti nínú òjò sì ni.”

Àǹfààní mìíràn ló tún jẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò láti kópa nínú iṣẹ́ náà. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society tó wà ní Samoa ròyìn pé: “Àwọn arákùnrin tó wà ní erékùṣù náà ti kọ́ àwọn iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n lè lò láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, láti ṣàtúnṣe àwọn ibi tí ìjì bà jẹ́, kí wọ́n sì tún ilé kọ́. Ó sì tún lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní iṣẹ́ tí wọ́n óò máa ṣe jẹun ní àwùjọ kan tí iṣẹ́ ò ti rọrùn láti rí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

Iṣẹ́ Ilé Kíkọ́ Náà Ń Jẹ́rìí Àtàtà

Honiara ni Colin wà nígbà tó rí i pé wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ sí Solomon Islands. Ó wú u lórí gan-an, ó sì kọ ìsọfúnni yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society tó wà ládùúgbò náà, èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a mú rọrùn tí wọ́n ń sọ ládùúgbò náà ló fi kọ ọ́ pé: “Gbogbo wọn ló wà ní ìṣọ̀kan, kò sì sẹ́ni tó fàbínú yọ, wọ́n jẹ́ ìdílé kan.” Kété lẹ́yìn náà, nígbà tó padà sábúlé rẹ̀ ní Aruligo, tó jẹ́ ogójì kìlómítà síbẹ̀, òun àti ìdílé rẹ̀ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn. Wọ́n tún wá fi ìsọfúnni míì ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì pé: “A ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tán, tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ sì ti wà níbẹ̀, nítorí náà ṣé a lè máa ṣe ìpàdé níhìn-ín?” Wọ́n ṣètò fún èyí ní kíá mọ́sá, àwọn èèyàn bí ọgọ́ta sì ń wá déédéé.

Olùdámọ̀ràn fún Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù rí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe ní Tuvalu. Ó sì sọ fún òṣìṣẹ́ kan pé: “Mo rò pé gbogbo ènìyàn ló ń sọ bẹ́ẹ̀ fún yín, àmọ́ lójú tèmi iṣẹ́ ìyanu lèyí jẹ́!” Obìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ nídìí tẹlifóònù béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn pé: “Kí ló fà á tí gbogbo yín fi láyọ̀ tó báyìí? Ibí yìí gbóná gan-an ni!” Wọn ò tíì fìgbà kan rí i kí ìsìn Kristẹni súnni ṣiṣẹ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́ tó sì jẹ́ ti ìfara-ẹni-rúbọ báyìí.

Ìrúbọ Láìsí Àbámọ̀

Bíbélì sọ nínú 2 Kọ́ríńtì 9:6 pé: “Ẹni tí ó bá . . . ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú. Àwọn òṣìṣẹ́ náà, ìdílé wọn, àti ìjọ wọn ń bá a lọ láti máa fìwà ọ̀làwọ́ fúnrúgbìn nípa ríran àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn ní Pàsífíìkì lọ́wọ́. Ross, tó jẹ́ alàgbà láti Kincumber, nítòsí Sydney sọ pé: “Ìjọ mi ló dá ìdámẹ́ta owó tí mo fi wọkọ̀, àna mi, táa jọ lọ, sì bá mi fi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] dọ́là kún un.” Òṣìṣẹ́ mìíràn ta ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ kó lè rówó ọkọ̀ san. Bẹ́ẹ̀ náà ni òṣìṣẹ́ mìíràn ta ilẹ̀ kan fún ìdí kan náà. Ó ku ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] dọ́là kí owó ọkọ̀ Kevin pé, nítorí náà ó ta àwọn ẹyẹlé rẹ̀ mẹ́rìndínlógún tí wọ́n jẹ́ ọlọ́dún méjì. Nípasẹ̀ ojúlùmọ̀ rẹ̀ kan, ó rí oníbàárà kan tó rà wọ́n ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] dọ́là gééré!

Wọ́n béèrè lọ́wọ́ Danny àti Cheryl pé: “Ṣé ó tó nǹkan tẹ́ẹ máa tìtorí ẹ̀ san owó ọkọ̀ òfuurufú tí ẹ ó sì tún pàdánù owó ọ̀yà tí gbogbo rẹ̀ ń lọ sí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] dọ́là ni?” Wọ́n fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni! Kódà bó ju ìlọ́po méjì ìyẹn ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Alan, tó wá láti Nelson, New Zealand, fi kún un pé: “Ohun tó ná mi láti lọ sí Tuvalu tó èyí tí mo máa fi wọ ọkọ̀ lọ sí Yúróòpù tí màá sì tún gba ṣéńjì. Àmọ́, ṣé ǹ bá rí àwọn ìbùkún wọ̀nyí gbà, tàbí ṣé ǹ bá ti ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ tí wọ́n wá láti ibòmíràn gbogbo wọ̀nyí, tàbí ṣé ì bá ti ṣeé ṣe fún mi láti ṣe ohun kan fún ẹlòmíràn yàtọ̀ sí ará mi? Rárá o! Yàtọ̀ sí ìyẹn, ohunkóhun tó wù kí n fún àwọn arákùnrin wa tó wà ní erékùṣù, ohun tí wọ́n fi san án fún mi jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ohun mìíràn tó tún jẹ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kẹ́sẹ járí ni ìtìlẹ́yìn ìdílé. Nígbà tó jẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún àwọn aya kan láti tẹ̀ lé ọkọ wọn wá, tí wọ́n tiẹ̀ tún ṣiṣẹ́ níbi ìkọ́lé náà pàápàá, àwọn mìíràn ní àwọn ọmọ tó ń lọ sílé ìwé tàbí tí wọ́n ní iṣẹ́ okòwò ìdílé láti bójú tó. Clay sọ pé: “Bí ìyàwó mi ṣe múra tán láti bójú tó àwọn ọmọ àti gbogbo ilé nígbà tí mo bá lọ jẹ́ ìrúbọ kan tó ju èyí tí mo ṣe lọ fíìfíì.” Lóòótọ́, gbogbo àwọn ọkọ tí kò lè mú ìyàwó wọn wá ló máa sọ pé “Òdodo ọ̀rọ̀” nìyẹn!

Láti ìgbà tí iṣẹ́ Tuvalu ti parí, àwọn òṣìṣẹ́ tó ń yọ̀ǹda ara wọn ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ilé àwọn míṣọ́nnárì, wọ́n sì ti kọ́ àwọn ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń túmọ̀ èdè sí àwọn ìlú Fiji, Tonga, Papua New Guinea, New Caledonia, àti ibòmíràn gbogbo. Ìwéwèé ṣì ń lọ lórí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé, títí kan àwọn kan tí wọ́n fẹ́ kọ́ sí Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà. Ṣé a óò rí àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ tó?

Dájúdájú, ìyẹn ò lè jẹ́ ìṣòro. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Hawaii kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn tó wà níbí, tí wọ́n ti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé káàkiri ló sọ pé ká rántí àwọn nígbàkigbà tí a bá ti fẹ́ kọ́ òmíràn. Bí wọ́n ṣe ń padà sílé ni wọ́n ń tu owó jọ fún un.” Báwo ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ò ṣe ní kẹ́sẹ járí nígbà táa bá fi ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún Jèhófà kún irú ìyọ̀ǹda ara ẹni tọkàntọkàn bẹ́ẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn ohun èlò fún iṣẹ́ náà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Agbo òṣìṣẹ́ níbi ìkọ́lé náà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nígbà tí iṣẹ́ náà parí, inú wa dùn sí ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run mú kó kẹ́sẹ járí