Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀?

Báwo Lo Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀?

Báwo Lo Ṣe Ń Yanjú Aáwọ̀?

ONÍRÚURÚ ẹ̀dá là ń bá pàdé lójoojúmọ́. Èyí sábà máa ń fún wa láyọ̀, ó sì ń mú kí á ní èrò tuntun. Nígbà míì, ó tún máa ń fa aáwọ̀ ńlá tàbí kékeré nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Irú yòówù kó jẹ́, báa ṣe ń hùwà nígbà tí aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀, máa ń nípa lórí èrò orí, ìmọ̀lára, àti ipò tẹ̀mí wa.

Òótọ́ kúkú ni pé ṣíṣe gbogbo ohun tágbára wa bá ká láti yanjú aáwọ̀ ní ìtùnbí-ìnùbí yóò fi kún ìlera ara wa, àárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn á sì túbọ̀ dán mọ́rán. Òwe ayé àtijọ́ kan sáà sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.”—Òwe 14:30.

Òdìkejì pátápátá ni òdodo ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Bí ìlú ńlá tí a ya wọ̀, láìní ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí kò kó ẹ̀mí rẹ̀ níjàánu.” (Òwe 25:28) Lára wa, ta ni yóò fẹ́ láti ṣí ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu kí èròkérò máa ya wọlé, àní àwọn èrò tó lè jẹ́ ká hùwà lọ́nà àìtọ́—lọ́nà tó lè pa àwa àtàwọn ẹlòmíì lára? Irú ìpalára yẹn gẹ́lẹ́ ni ìbínú fùfù máa ń fa. Nínú Ìwàásù tí Jésù ṣe Lórí Òkè, ó dámọ̀ràn pé ká yẹ ìṣarasíhùwà wa wò, nítorí pé ó lè nípa lórí bí a ṣe ń yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíì. (Mátíù 7:3-5) Dípò tí a ó fi jẹ́ arítẹnimọ̀ọ́wí, ó yẹ ká ronú nípa báa ṣe lè sún mọ́ àwọn tí èrò wọn àti ipò wọn yàtọ̀ sí tiwa, kí a sì di ọ̀rẹ́ wọn.

Ìṣarasíhùwà Wa

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí a óò gbé táa bá fẹ́ yanjú ohun táa ronú pé ó jẹ́ aáwọ̀ tàbí ohun tó dìídì jẹ́ aáwọ̀, ni ká gbà pé a máa ń ní èrò àti ìṣarasíhùwà tí kò tọ́. Ìwé Mímọ́ rán wa létí pé gbogbo wa la ti ṣẹ̀, tí a “sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Láfikún sí i, ìfòyemọ̀ lè jẹ́ ká rí i pé onítọ̀hún yẹn kọ́ ló fa ìṣòro wa. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà yẹ̀ wò.

Ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni tí Jèhófà fún un, Jónà ti dé ìlú Nínéfè láti wàásù nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn ará ìlú náà. Ìyọrísí iṣẹ́ náà máyọ̀ wá, gbogbo ìlú Nínéfè pátá ló ronú pìwà dà, wọ́n sì wá gba Ọlọ́run tòótọ́ gbọ́. (Jónà 3:5-10) Jèhófà rí i pé ẹ̀mí ìrònúpìwàdà wọn mú kí ìdáríjì tọ́ sí wọn, nítorí náà ó dá wọn sí. “Bí ó ti wù kí ó rí, kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú.” (Jónà 4:1) Bí Jónà ṣe hùwà padà sí àánú Jèhófà mà yani lẹ́nu o. Kí ló lè fa ìbínú Jónà sí Jèhófà? Àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé ọ̀ràn tara Jónà nìkan ló ń rò, bóyá ó gbà pé òun ti tẹ́ ní gbogbo àgbègbè náà. Kò rídìí tí Jèhófà fi ní láti ṣàánú. Pẹ̀lú inú rere, Jèhófà kọ́ Jónà ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan tó ràn án lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe èrò rẹ̀, kí ó sì rí i bí ojú àánú Ọlọ́run ṣe tayọ lọ́lá tó. (Jónà 4:7-11) Dájúdájú, ìṣarasíhùwà Jónà ló ń fẹ́ àtúnṣe, kì í ṣe ti Jèhófà.

Ǹjẹ́ àwa náà lè ṣe bákan náà yí ìṣarasíhùwà wa lórí ọ̀ràn kan padà nígbà míì? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Kí ló ní lọ́kàn? Lọ́nà kan, ó ń rọ̀ wá pé ká máa fòye báni lò, kí a sì máa fi iyì àti ọ̀wọ̀ wọ àwọn Kristẹni mìíràn. Èyí wé mọ́ gbígbà pé olúkúlùkù ló ní àǹfààní láti yan ohun tó wù ú. Pọ́ọ̀lù tún rán wa létí pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Fún ìdí yìí, kí aáwọ̀ tó di iṣu-ata-yán-an-yàn-an, ẹ wo bó ti bọ́gbọ́n mu tó láti rò ó wò bóyá ìṣarasíhùwà ti àwa fúnra wa ń fẹ́ àtúnṣe! A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti rí i dájú pé ìrònú tiwa bá ti Jèhófà mu, ká sì wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn yòókù tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní tòótọ́.—Aísáyà 55:8, 9.

Ọ̀nà Tí A Gbà Ṣe É

Fojú inú wo àwọn ọmọ kékeré méjì tí wọ́n ń du ohun ìṣeré kan mọ́ ara wọn lọ́wọ́, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń fà á kó sáà lè bọ́ sí òun lọ́wọ́. Wọ́n lè máa sọ̀kò ọ̀rọ̀ kòbákùngbé síra wọn bí wọ́n ti ń fà á mọ́ra wọn lọ́wọ́, kí ó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá di pé ọ̀kan lára wọn á wá juwọ́ sílẹ̀ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, tàbí kí ẹnì kan bá wọn dá sí i.

Àkọsílẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì sọ fún wa pé Ábúráhámù gbọ́ pé aáwọ̀ wà láàárín àwọn darandaran tirẹ̀ àtàwọn ti Lọ́ọ̀tì, ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ábúráhámù gbé ìgbésẹ̀, ó tọ Lọ́ọ̀tì lọ, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ máa bá a lọ láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn olùṣọ́ agbo ẹran mi àti àwọn olùṣọ́ agbo ẹran rẹ, nítorí arákùnrin ni wá.” Ábúráhámù pinnu pé òun ò ní jẹ́ kí èdè àìyedè kankan ba àárín àwọn jẹ́. Kí ló ná an? Ó ṣe tán láti yááfì àǹfààní yíyan ibi tó wù ú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n; ó múra tán láti fi nǹkan kan du ara rẹ̀. Ábúráhámù jẹ́ kí Lọ́ọ̀tì yan ibi tó fẹ́ kí agboolé òun àti agbo ẹran òun wà. Ìyẹn ni Lọ́ọ̀tì fi mú àgbègbè ẹlẹ́tùlójú ti Sódómù àti Gòmórà. Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì ya ara wọn, láìjà láìta.—Jẹ́nẹ́sísì 13:5-12.

Láti lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ǹjẹ́ a ti múra tán láti ní irú ẹ̀mí tí Ábúráhámù ní? Ìtàn Bíbélì yìí fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé nígbà táa bá ní aáwọ̀. Ábúráhámù jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ máa bá a lọ.” Ìfẹ́ àtọkànwá Ábúráhámù ni pé káwọn yanjú ọ̀ràn náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ó dájú pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tó fi hàn pé bí àlàáfíà yóò ṣe wà là ń fẹ́, yóò jẹ́ kí èdè àìyedè náà yanjú. Ábúráhámù wá fi kún un pé “nítorí arákùnrin ni wá.” Èé ṣe tó fi máa ba ìbátan pàtàkì yẹn jẹ́ nítorí kí ìfẹ́ inú rẹ̀ lè ṣẹ tàbí nítorí ìgbéraga? Ábúráhámù gbájú mọ́ ohun tó ṣe pàtàkì. Ó fi ọ̀wọ̀ wọ ara ẹ̀, kò sì fi ara ẹ̀ wọ́lẹ̀ bó ṣe ń ṣe èyí, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún fi ọ̀wọ̀ wọ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè wá di dandan pé kí ẹlòmíì wá bá wa dá sí i nígbà míì, ṣùgbọ́n ẹ wo bí ì bá ti dáa tó ká ní ó ṣeé yanjú láàárín ara wa! Jésù rọ̀ wá pé ká gbé ìgbésẹ̀ láti wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin wa, àní ká tiẹ̀ tọrọ àforíjì bó bá pọndandan. a (Mátíù 5:23, 24) Ó ń béèrè ìrẹra-ẹni-sílẹ̀ tàbí ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, Pétérù sì kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) Ìṣesí wa sí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run.—1 Jòhánù 4:20.

Láàárín ìjọ Kristẹni, wọ́n lè ní ká yááfì ẹ̀tọ́ kan kí àlàáfíà lè wà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí ló jẹ́ pé àárín ọdún márùn-ún sẹ́yìn ni wọ́n di ara ìdílé Ọlọ́run tí ń fi tọkàntọkàn sìn ín. Ẹ wo bí èyí ṣe ń mú ọkàn-àyà wa láyọ̀ tó! Ó dájú pé ìṣesí wa ń nípa lórí àwọn wọ̀nyí àtàwọn mìíràn nínú ìjọ. Èyí jẹ́ ìdí kan pàtàkì tó fi yẹ ká kíyè sára gidigidi nípa irú eré ìnàjú tí à ń ṣe, tàbí ìgbòkègbodò tí a fi ń pawọ́ dà, irú òde tí à ń lọ, tàbí irú iṣẹ́ tí à ń ṣe, ká máa rántí irú ojú táwọn ẹlòmíì lè máa fi wò wá. Ṣé èyíkéyìí nínú ìṣesí wa tàbí ọ̀rọ̀ wa kò lè mú kí ominú máa kọ àwọn kan, kí ó sì di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró. Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:23, 24) Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ohun tí à ń wá lójú méjèèjì ni bí ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ ẹgbẹ́ àwọn ará wa tó jẹ́ Kristẹni yóò ṣe máa pọ̀ sí i.—Sáàmù 133:1; Jòhánù 13:34, 35.

Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Lára Dá

Ọ̀rọ̀ lè ní ipa tó dára gan-an. “Àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni jẹ́ afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń mú àwọn egungun lára dá.” (Òwe 16:24) Ìtàn bí Gídíónì ṣe bomi paná wàhálà kan tó fẹ́ bẹ́ sílẹ̀ láàárín òun àtàwọn ọmọ Éfúráímù fi hàn pé òtítọ́ ni òwe yìí.

Nígbà tí ogun tí Gídíónì ń bá Mídíánì jà wá jó dórí kókó, ó ké sí ẹ̀yà Éfúráímù fún ìrànlọ́wọ́. Àmọ́, nígbà tí ogun náà parí, Éfúráímù wá kọjú sí Gídíónì, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tìbínú-tìbínú pé kò pe àwọn nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ìjà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé “wọ́n sì gbìyànjú kíkankíkan láti bẹ̀rẹ̀ aáwọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Gídíónì wá fèsì pé: “Kí ni mo ṣe nísinsìnyí ní ìfiwéra pẹ̀lú yín? Èéṣẹ́ Éfúráímù kò ha sàn ju ìkójọ èso àjàrà Abi-ésérì? Ẹ̀yin ni Ọlọ́run fi Órébù àti Séébù, àwọn ọmọ aládé Mídíánì, lé lọ́wọ́, kí sì ni mo tíì ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú yín?” (Àwọn Onídàájọ́ 8:1-3) Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí, tí ń múni fọwọ́ wọ́nú, tí Gídíónì sọ yìí ló bomi pa ogun afẹ̀jẹ̀wẹ̀ tí ì bá bẹ́ sílẹ̀ láàárín ẹ̀yà kan sí ìkejì. Ó jọ pé ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú àti ìgbéraga ló ń yọ àwọn ẹ̀yà Éfúráímù lẹ́nu. Àmọ́, Gídíónì kò tìtorí ìyẹn ṣíwọ́ sísapá láti yanjú ọ̀ràn náà ní ìtùnbí-ìnùbí. Ṣé àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Inú àwọn kan lè máa ru ṣùù, èyí sì lè jẹ́ kí wọ́n máa ṣe kèéta sí wa. Á dáa kí á mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, kí á sì gbìyànjú láti lóye èrò wọn. Ṣé kì í ṣe pé a wà lára àwọn tó ń dá kún ìṣòro wọn? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, kí ló dé tí a kò gbà pé a lọ́wọ́ nínú ìṣòro náà, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó dùn wá gan-an pé a ti dá kún ìṣòro náà. Ọ̀rọ̀ àròjinlẹ̀ táa bá sọ jáde wẹ́rẹ́ lè tún àárín wa ṣe. (Jákọ́bù 3:4) Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ làwọn kan tí inú ń bí kàn fẹ́ gbọ́ látẹnu wa. Bíbélì sọ pé “níbi tí igi kò bá sí, iná a kú.” (Òwe 26:20) Bẹ́ẹ̀ ni, táa bá ro ọ̀rọ̀ táa fẹ́ sọ jinlẹ̀ ká tó sọ ọ́, táa sì fi ẹ̀mí tó dáa sọ ọ́, ó lè “yí ìhónú padà,” kí ó sì tún nǹkan ṣe.—Òwe 15:1.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dá a lábàá pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Òótọ́ ni pé a kò lágbára lórí ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíì, ṣùgbọ́n a lè ṣe ipa tiwa láti mú kí àlàáfíà wà. Dípò ṣíṣe ohun tí àìpé àwa fúnra wa tàbí ti àwọn ẹlòmíràn fẹ́ tì wá ṣe, a lè gbégbèésẹ̀ nísinsìnyí láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tó mọ́gbọ́n dání. Yíyanjú aáwọ̀ lọ́nà tí Jèhófà sọ pé kí á gbà yanjú rẹ̀ yóò yọrí sí àlàáfíà àti ayọ̀ wa títí ayé.—Aísáyà 48:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Máa Dárí Jini Látọkàn Wá” àti “O Lè Jèrè Arákùnrin Rẹ,” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 1999.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ṣé a máa ń rinkinkin pé ìfẹ́ inú wa ló gbọ́dọ̀ di ṣíṣe?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ábúráhámù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa jíjuwọ́ sílẹ̀ kí aáwọ̀ lè yanjú