Ìgbà Tí Àìfọhùn Bá Túmọ̀ sí Àjọgbà
Ìgbà Tí Àìfọhùn Bá Túmọ̀ sí Àjọgbà
ÌWÉ Betrayal—German Churches and the Holocaust kò fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ nígbà tó jíròrò ipa tí ìsìn kó nínú ètò ìjọba Násì. Ìwé náà sọ pé: “Àwọn Kristẹni ló ṣe ìtìlẹ́yìn fún ìjọba yẹn jù, èyí tó sì pọ̀ jù lọ lára wọn ni ò dá wọn lẹ́kun bí wọ́n ṣe ń ṣe inúnibíni sí àwọn Júù. Àìfọhùn wọn lórí ọ̀ràn yìí nítumọ̀ tí ó ga ju sísọ̀rọ̀ lọ.”
Kí làwọn tó pera wọn ní Kristẹni rí nínú ètò ìjọba Násì tó jẹ́ kó wù wọ́n? Ìwé náà sọ pé ohun tí Hitler fi rí ọ̀pọ̀ nínú wọn mú ni bó ṣe sọ pé òun “fẹ́ sọ àwọn ará Jámánì di àwọn ọmọlúwàbí ènìyàn tí ń pa òfin mọ́.” Ìwé náà sọ pé: “Ó lòdì sí àwọn nǹkan tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, títí kan iṣẹ́ aṣẹ́wó, ìṣẹ́yún, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, àti ‘àwọn ohun ìríra’ tó ń hàn nínú àwọn iṣẹ́ ọnà òde òní, ó sì ń fún àwọn obìnrin tó bí ọmọ mẹ́rin, àwọn tó bí mẹ́fà, àtàwọn tó bí mẹ́jọ lẹ́bùn idẹ, fàdákà, àti wúrà, ó ń tipa bẹ́ẹ̀ fún wọn níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ táa mọ àwọn obìnrin mọ́ nìṣó gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ilé. Èròǹgbà tó gbé kalẹ̀ yìí pé káwọn èèyàn padà sí ẹsẹ àárọ̀, pà pọ̀ mọ́ ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lọ́nà ti ológun ni Hitler fẹ́ fi gbẹ̀san títẹ́ tí wọ́n tẹ́ orílẹ̀-èdè náà lógo níbi Àdéhùn tí wọ́n ṣe ní Versailles, ló mú kí Ètò Ìjọba Násì di ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá nífẹ̀ẹ́ sí, àní títí kan ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni tó wà ní Jámánì.”
Ẹgbẹ́ kan dá yàtọ̀ pátápátá. Ìwé Betrayal sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ láti kópa nínú ìwà ipá tàbí láti jagun.” Láìsí àní-àní, èyí wá ṣokùnfà àtakò líle koko tí wọ́n gbé dìde sí àwùjọ kékeré yìí, wọ́n sì ju ọ̀pọ̀ lára àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Síbẹ̀, ńṣe ni àwọn mìíràn tí wọ́n pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi dákẹ́ láìfọhùn. Ìwé náà tún sọ pé: “Àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì lápapọ̀ gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dípò kí wọ́n ṣàánú wọn, wọ́n fara mọ́ ìwà ìkà Hitler dípò fífara mọ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe lòdì sí ogun.” Ó dájú pé àìfọhùn wọn dá kún ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí lábẹ́ ìjọba Násì.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipa tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kó nínú ìṣèlú ìjọba Násì ń fa àríyànjiyàn gbígbóná janjan ṣáá, ìwé Betrayal pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní “ẹ̀sìn kan tó kọ̀ láti fara mọ́ tàbí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọba náà.”