Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A San Èrè fún Ìwákiri Ọlọ́jọ́ Pípẹ́

A San Èrè fún Ìwákiri Ọlọ́jọ́ Pípẹ́

A San Èrè fún Ìwákiri Ọlọ́jọ́ Pípẹ́

“JÈHÓFÀ? Ta ni Jèhófà?” Silvia, ọmọ ọdún mẹ́jọ rí orúkọ yẹn nínú Bíbélì Àméníà kan, tó jẹ́ ìṣúra ìdílé, tí ọmọbìnrin kékeré mìíràn fi hàn án. Ó béèrè káàkiri, àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni níbi tó ń gbé ní Yerevan, Àméníà, tó lè sọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ fún un—àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n, olùkọ́ rẹ̀ ò mọ̀ ọ́n, kódà àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò pàápàá ò mọ̀ ọ́n.

Silvia dàgbà, ó parí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ríṣẹ́, síbẹ̀ kò mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba, ó ní láti sá fi Àméníà sílẹ̀, nígbà tó sì ṣe díẹ̀, ó bá ara rẹ̀ ní Poland, tó ń gbé inú yàrá kékeré kan pẹ̀lú àwọn olùwá-ibi-ìsádi mìíràn. Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń gbé inú yàrá kan náà máa ń gba àwọn kan lálejò déédéé. Silvia wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Àwọn wo lálejò rẹ?” Ìdáhùn tó rí gbà ni pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n.”

Ìdùnnú sọ lọ́kàn Silvia nígbà tó gbọ́ orúkọ náà, Jèhófà. Níkẹyìn, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti irú Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó jẹ́. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tó fi Poland sílẹ̀. Ó fẹ́ fi Denmark, ní ìsọdá Òkun Baltic ṣe ìlú ààbò. Ìwọ̀nba ẹrù díẹ̀ ló kó, ṣùgbọ́n ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde wà lára wọn. Silvia rí àwọn àdírẹ́sì ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Watch Tower Society tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ẹ̀yìn ìtẹ̀jáde kan. Ọ̀kan lára àwọn ohun ìní rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ nìyẹn—èyí ló máa fi ọ̀nà ọ̀dọ̀ Jèhófà hàn án!

Wọ́n mú Silvia lọ sí ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Denmark, bó sì ṣe ń débẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kiri. Ó ti rí i nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àdírẹ́sì tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society ti Denmark wà ní ìlú kan tó ń jẹ́ Holbæk. Àmọ́, ibo nìyẹn wà? Wọ́n fi ọkọ̀ ojú irin gbé Silvia lọ sí ibùdó mìíràn, bí wọ́n sì ti ń lọ síbẹ̀, ọkọ̀ ojú irin náà gba Holbæk kọjá! Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìdùnnú tún sọ lọ́kàn rẹ̀.

Ní ọjọ́ kan tí oòrùn ń ràn láìpẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Silvia wọ ọkọ̀ ojú irin náà padà sí Holbæk, ó sì rìn láti ibùdókọ̀ lọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà. Ó rántí pé: “Nígbà tí mo wọ inú ọgbà náà, mo jókòó sórí bẹ́ǹṣì kan, mo sì sọ fún ara mi pé, ‘Párádísè nìyí!’” Wọ́n fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí i káàbọ̀ ní ẹ̀ka náà, ó sì ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tirẹ̀ níkẹyìn.

Àmọ́ wọ́n tún gbé e lọ sí àwọn ibùdó bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn. Gbogbo ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó ń lọ ló ti ń wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, tó sì ń tún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ọdún méjì, ẹ̀kọ́ tó ti kọ́ ti wọ̀ ọ́ lọ́kàn dépò pé ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó ṣe batisí, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ní ọdún 1998, ìjọba Denmark gbà á láyè láti fi ibẹ̀ ṣe ìlú ààbò rẹ̀.

Silvia ti di ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n báyìí, ó sì ń sìn ní ibi tó rán an létíi Párádísè, ìyẹn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Denmark. Ó wá ń sọ nísinsìnyí pé: “Kí ni kí n sọ? Mo ti ń wá Jèhófà látìgbà tí mo ti wà lọ́mọbìnrin kékeré. Mo ti wá rí i báyìí. Ohun tó ti wà ní góńgó ẹ̀mí mi ni pé kí n lo gbogbo ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, èmi sì nìyí ní Bẹ́tẹ́lì. Àdúrà mi ni pé kí ibí yìí lè jẹ́ ilé mi fún ọ̀pọ̀ ọdún!”