Jèhófà Máa Ń San Èrè fún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Adúróṣinṣin
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà Máa Ń San Èrè fún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Adúróṣinṣin
GẸ́GẸ́ BÍ VERNON DUNCOMBE ṢE SỌ Ọ́
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìpápánu alẹ́ ọjọ́ yẹn ni, mo sì ṣáná sí sìgá gẹ́gẹ́ bí ìṣe mi. Ni mo bá béèrè lọ́wọ́ Aileen, ìyàwó mi pé: “N gbọ́, ìpàdé alẹ́ òní ti rí?”
Ó KỌ́KỌ́ dákẹ́ lọ sii, kó tó wá sọ pé: “Wọ́n ka lẹ́tà kan tí wọ́n fi kéde àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn, orúkọ rẹ sì wà lára wọn. Ìwọ ni yóò máa bójú tó àwọn ohun èlò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́. Gbólóhùn tó gbẹ̀yìn lẹ́tà náà kà pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni lára àwọn arákùnrin táa ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn yìí bá ń mu sìgá, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ lẹ́tà sí Society láti fi sọ pé àwọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ yìí o.’” a Ṣe ni mo mí kanlẹ̀ hìn-ìn, tí mo gbin kìn-ìn, tí mo sọ pé, “Hẹ̀n-ẹ́n! Ìyẹn ni ohun tí lẹ́tà náà wí.”
Mo wayín pọ̀, mo sì rún sìgá náà sínú àwo eérú tó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ mi. “Èmi ò mọ̀dí tí wọ́n fi yanṣẹ́ yìí fún mí o. Àmọ́ mi ò kọṣẹ́ kankan rí, mi ò sì ní in lọ́kàn pé kí n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí.” Mo pinnu pé n ò ní mu sìgá mọ́ láé. Ìpinnu yẹn ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àti gẹ́gẹ́ bí olórin. Ẹ jẹ́ kí n kúkú sọ ìtàn àwọn ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kí n ṣe ìpinnu yìí fún yín.
Ìdílé Tí Mo Dàgbà Sí
Ìlú Toronto, ní Kánádà ni wọ́n ti bí mi, ní September 21, 1914, èmi sì ni àrẹ̀mọ Vernon àti Lila, àwọn òbí mi ọ̀wọ́n tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́kára, tí wọ́n ń gbọ́ bùkátà ìdílé tó ní ọmọkùnrin mẹ́rin àti ọmọbìnrin méjì. Ẹni tí wọ́n bí tẹ̀ lé mi ni Yorke, àwọn tó sì tẹ̀ lé e ni Orlando, Douglas, Aileen, àti Coral. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré ni mí nígbà tí màmá mi gbé gòjé lé mi lọ́wọ́, tó ṣètò pé kí n lọ máa kọ́ ẹ̀kọ́ nípa orin ní Harris School of Music. Nǹkan ò rọgbọ, ṣùgbọ́n bàbá àti màmá mi sáà ń rún un mọ́ kí wọ́n lè rówó san owó ọkọ̀ àti owó iléèwé mi. Lẹ́yìn náà, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlànà àti ìṣètò orin kíkọ ní Royal Conservatory of Music
ní Toronto, nígbà tí mo sì pé ọmọ ọdún méjìlá, mo lọ́wọ́ nínú ìdíje orin àṣekálùú kan, tó wáyé ní Gbọ̀ngàn Massey, tó jẹ́ gbọ̀ngàn orin kíkọ tó gbajúmọ̀ gan-an láàárín ìlú. Èmi ni mo jáwé olúborí, wọ́n sì fún mi ní àgbà gòjé kan tí ń bẹ nínú àpò kan tí wọ́n fi awọ ọ̀nì ṣe.Bí àkókò ti ń lọ, mo tún kọ́ bí a ti ń tẹ dùrù àti bí a ti ń ta gòjé olóhùn kíkẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹgbẹ́ wa máa lọ ń ṣeré níbi àwọn òde àríyá kéékèèké ní alaalẹ́ Friday àti Sátidé, a sì tún máa ń ṣeré ní agbo ijó àwọn ọmọléèwé. Ìgbà kan táa lọ síbi irú àwọn agbo ijó yẹn ni mo ti kọ́kọ́ pàdé Aileen. Lọ́dún tí mo lò kẹ́yìn ní iléèwé girama, ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ olórin ni mo ń bá kọrin jákèjádò ìlú. Lẹ́yìn tí mo jáde iléèwé girama, Ẹgbẹ́ Olórin Ferde Mowry ní kí n wá wọ ẹgbẹ́ àwọn, iṣẹ́ yìí mówó wọlé gan-an, ọ̀dọ̀ wọn ni mo sì wà títí di ọdún 1943.
Bí Mo Ṣe Mọ Jèhófà
Ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní fẹ́ bẹ́ sílẹ̀ gẹ́ẹ́ làwọn òbí mi kọ́kọ́ gbọ́ nípa òtítọ́ Bíbélì, ilé ìtajà kékeré kan ni bàbá mi ń bá tajà ní àgbègbè ìṣòwò ìlú Toronto nígbà yẹn. Níbi tí wọ́n ti ń jẹun ọ̀sán, ó máa ń fetí kọ́ ọ̀rọ̀ táwọn òṣìṣẹ́ méjì kan tí wọ́n jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (ìyẹn lorúkọ táa fi ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún) máa ń bá ara wọn sọ, ó sì máa ń wá sọ ohun tó gbọ́ fún màmá mi nígbà tó bá délé lálẹ́. Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ìyẹn ní 1927, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọpọ̀ ńlá kan ní Toronto, ní Pápá Ìṣeré tó wà ní Ibi Ìpàtẹ Ilẹ̀ Kánádà. Títì méjì péré ló la ilé wa àti ọ̀nà àbáwọlé tí ń bẹ ní ìwọ̀ oòrùn ibi ìpàtẹ yẹn, wọ́n sì fi èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó wá láti Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ̀ sílé wa.
Lẹ́yìn ìyẹn, Ada Bletsoe, tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, bẹ̀rẹ̀ sí bẹ màmá mi wò lemọ́lemọ́, ó sì máa ń fún màmá mi ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dé gbẹ̀yìn. Lọ́jọ́ kan, ó sọ pé: “Ìyáàfin Duncombe, ó ti ṣe díẹ̀ báyìí tí mo ti ń fún ọ ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ka ìkankan nínú rẹ̀ rí?” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ mẹ́fà ni màmá mi ń tọ́, ó pinnu pé òun máa bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìwé ìròyìn náà látìgbà yẹn lọ, kò sì ṣíwọ́ kíkà wọ́n. Àmọ́ o, kò séyìí tó kàn mí pẹ̀lú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyẹn. Bí mo ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ yege níléèwé ló ká èmi lára ní tèmi, orin kíkọ tún ni ohun kejì tó gbà mí lọ́kàn.
June 1935 ni èmi àti Aileen ṣègbéyàwó nínú ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà kan. Látìgbà tí mo ti fi United Church sílẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, mi ò ṣe ẹ̀sìn kankan mọ́; nítorí náà, mo kọ ọ́ sínú ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó mi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì di Ẹlẹ́rìí nígbà náà.
Ìrètí wa ni pé níjọ́ ọjọ́ kan a óò bímọ, a ó sì fẹ́ láti jẹ́ òbí rere. Nítorí èyí, a wá bẹ̀rẹ̀ sí ka Májẹ̀mú Tuntun pa pọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa la dáwọ́ lé yìí, síbẹ̀, àwọn nǹkan míì dí wa lọ́wọ́. A tún gbìyànjú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, àmọ́ ibì kan náà ló tún já sí. Nígbà tó wá dìgbà Kérésìmesì ọdún 1935, ẹ̀bùn kan táa rí gbà ni ìwé kan tí wọ́n fi ọ̀rá wé, orúkọ ìwé náà ni Duru Ọlọrun. Ìyàwó mi sọ pé: “Ó ga o, ẹ̀bùn Kérésì tí màmá rẹ fi ránṣẹ́ yìí mà tún yàtọ̀ o.” Síbẹ̀síbẹ̀, tí mo bá lọ síbi iṣẹ́ tán, á bẹ̀rẹ̀ sí kà á, ó sì ń gbádùn ohun tó ń kà nínú rẹ̀. Mi ò tètè mọ̀ pé ó ń gbádùn rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ní ti ìfẹ́ wa láti di onídìílé, ìyẹn ò bọ́ sí i. Ọmọbìnrin wa táa bí ní February 1, 1937, kò dúró gbáyé. Áà, ó mà kó ìbànújẹ́ bá wa o!
Ní àkókò yìí, ògbóṣáṣá ni ìdílé mi nínú iṣẹ́ ìwàásù, mo sì gbọ́ pé bàbá mi nìkan ni akéde Ìjọba náà nínú ìdílé wa tí kò tíì rí ẹnikẹ́ni tí yóò forúkọ sílẹ̀ fún ìwé ìròyìn Consolation (tí à ń pè ní Jí! báyìí). Èyí sì ni góńgó tí wọ́n ń lé lóṣù náà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì ka ìkankan rí lára àwọn ìtẹ̀jáde Society, àánú bàbá mi ṣe mí, mo sì sọ pé: “Ó yá, Dádì, ẹ forúkọ mi sí i; kí ẹ̀yìn náà lè rí bí àwọn yòókù.” Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn dé, ẹgbẹ́ olórin wa sì kó kúrò láàárín ìlú láti lọ ṣeré ní ibi ìgbafẹ́ kan. Ìwé ìròyìn Consolation ń dé ọ̀dọ̀ mi nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́. Ìgbà ìwọ́wé dé, ẹgbẹ́ olórin wa sì kó padà wá sí Toronto. Ni àwọn ìwé ìròyìn náà bá tún bẹ̀rẹ̀ sí dé sí àdírẹ́sì wa tuntun, mi ò sì tíì já ìkankan wò rárá kúrò nínú bébà tí wọ́n fi dì í wá.
Nígbà kan táa wà nínú ìsinmi Kérésìmesì, mo wo òkìtì ìwé ìròyìn náà tó wà nílẹ̀, mo sì wá ronú pé bó bá ṣe pé owó mi ni mo fi rà wọ́n, ṣebí màá tiẹ̀ gbìyànjú àtika mélòó kan lára wọn, kí n mọ ohun tó wà nínú wọn. Èyí àkọ́kọ́ tí mo já ṣe mí ní háà. Ńṣe ló tú àṣírí ìwà jìbìtì àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn olóṣèlú ìgbà yẹn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn olórin ẹgbẹ́ mi sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo ń kà. Ṣùgbọ́n, wọ́n ní kò Mátíù 24:45.
dá àwọn lójú pé òótọ́ lohun tí mo ń sọ, ìyẹn ló wá jẹ́ kí n túbọ̀ jára mọ́ kíka àwọn ìwé ìròyìn náà kí n lè rí ẹ̀rí fi ti ohun tí mo ń sọ lẹ́yìn. Àṣé èmi náà ti bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí nípa Jèhófà nìyẹn láìmọ̀. Látìgbà yẹn sì rèé, mi ò tíì ṣíwọ́ kíka àwọn ìtẹ̀jáde àtàtà wọ̀nyí tí ń ṣàlàyé Bíbélì, tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń tẹ̀ jáde.—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ kì í jẹ́ kí n ráyè láàárín ọ̀sẹ̀, kò pẹ́ tí èmi àti Aileen bẹ̀rẹ̀ sí lọ sáwọn ìpàdé ọjọ́ Sunday. Báa ti dé ìpàdé lọ́jọ́ Sunday kan lọ́dún 1938, àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà kí wa, ọ̀kan sì sọ pé: “Tiẹ̀ gbọ́ ná, Arákùnrin Ọ̀dọ́, ǹjẹ́ o ti mú ìdúró rẹ níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà? Amágẹ́dọ́nì mà ti dé tán!” Mo mọ̀ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́, mo sì gbà gbọ́ dájú pé èyí ni ètò àjọ rẹ̀. Mo fẹ́ di ara ètò àjọ náà, fún ìdí yìí, ní October 15, 1938, mo ṣe batisí. Nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ni Aileen ṣe batisí. Mo láyọ̀ láti sọ pé gbogbo mẹ́ńbà ìdílé mi ló ya ara wọn sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà.
Ẹ wo bí ayọ̀ mi ti kún tó pé mo ń bá àwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́! Kò pẹ́ tí ọkàn mi fi balẹ̀ bíi ti tòlótòló láàárín wọn. Nígbà tí mi ò bá lè lọ sípàdé, mo máa ń hára gàgà láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Alẹ́ tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ yẹn jẹ́ àkókò ìyípadà ńlá nínú iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà.
Àkókò Ìyípadà Ńláǹlà fún Wa
Ìyípadà pàtàkì míì tún dé bá wa ní May 1, 1943. Ibi àpéjọpọ̀ ńlá àkọ́kọ́ tí a máa lọ, èyíinì ni Àpéjọ ti Ayé Tuntun Lábẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, táa ṣe ni September 1942, ní Cleveland, Ohio, la wà. Níbẹ̀, nígbà tí eruku ṣì ń sọ lálá nígbà ogun àgbáyé àjàkú-akátá náà, ogun àjààgbulà náà, a gbọ́ tí Arákùnrin Knorr, tí í ṣe ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn, fi ìgboyà sọ àsọyé tó wọni lọ́kàn ṣinṣin náà, “Àlàáfíà—Ǹjẹ́ Ó Lè Wà Pẹ́?” A rántí dáadáa bó ṣe fi hàn, látinú Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún, pé sáà àlàáfíà á dé lẹ́yìn ogun náà, nígbà tí a óò láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù ńlá kan parí.
Ohun tó nípa lórí wa jù lọ ni àsọyé tí Arákùnrin Knorr sọ ṣáájú, tó pe àkọlé rẹ̀ ní, “Jẹ́fútà àti Ẹ̀jẹ́ Rẹ̀.” Ni ìpè bá dún pé a ń fẹ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà púpọ̀ sí i o! Èmi àti Aileen wo ara wa lójú, a sì sọ ní ìfohùnṣọ̀kan (pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn ní àkókò yẹn) pé: “Àwa lọ̀rọ̀ yìí ń bá wí o!” Ojú ẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé báa ṣe máa tẹ́rí gba iṣẹ́ tó túbọ̀ ṣe pàtàkì.
Láti July 4, 1940, ni wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kánádà. Nígbà táa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní May 1, 1943, ó ṣì lòdì sófin láti jẹ́rìí nípa Jèhófà, kí a sì máa fi àwọn ìwé Society lọni nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. A ń bá iṣẹ́ wa lọ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kìkì ẹ̀dà Bíbélì King James wa là ń gbé dání. Ọjọ́ díẹ̀ péré lẹ́yìn táa dé ibi àkọ́kọ́ tí wọ́n ní ká ti lọ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìlú Parry Sound, Ontario, ni ẹ̀ka iléeṣẹ́ rán Stewart Mann, tí í ṣe aṣáájú ọ̀nà onírìírí, pé kí ó wá bá wa ṣiṣẹ́ nínú pápá. Ẹ wo irú ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí èyí jẹ́! Adùn-únbárìn ni Arákùnrin Mann, ẹ̀rín sì ni lọ́jọ́ gbogbo. A rí ohun púpọ̀ kọ́ lára rẹ̀, a sì gbádùn rẹ̀ gan-an ni. A ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ díẹ̀ nígbà tí Society tún yan iṣẹ́ míì fún wa, tí wọ́n ní ká máa lọ sílùú Hamilton. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n fẹ́ fagbára mú mi wọnú iṣẹ́ ológun, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí mi ti kọjá ti ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ológun. Kíkọ̀ tí mo kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun ló fà á tí wọ́n fi mú mi ní December 31, 1943. Nígbà tí wọ́n gbé ẹjọ́ náà dé kóòtù, wọn ò dúró gbẹ́jọ́ rárá, ńṣe ni wọ́n rán mi lọ sí àgọ́ àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sin ìlú dípò ṣíṣiṣẹ́ ológun, ibẹ̀ sì ni mo wà títí di August 1945.
Bí wọ́n ṣe tú mi sílẹ̀ báyìí lèmi àti Aileen tún tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n ní ká lọ ṣe ní Cornwall, Ontario. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn la tún gbéra ó di ẹkùn ilẹ̀ Quebec, pẹ̀lú àkànṣe ìwé àṣẹ láti kóòtù àwọn ọlọ́pàá, èyí tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní Ọ́fíìsì Society gbé lé wa lọ́wọ́. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Duplessis ní Quebec, nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni
tó burú jáì sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ láàárín ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, mo máa ń lọ sí kóòtù mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ran àwọn ará lọ́wọ́. Àkókò wọ̀nyẹn jẹ́ àkókò amóríyá, ó sì jẹ́ àkókò tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun.Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ tó wáyé ní Cleveland ní 1946, wọ́n fún wa níṣẹ́ bíbójútó àwọn àyíká àti àgbègbè kan, iṣẹ́ yìí sì gbé èmi àti ìyàwó mi láti etíkun Kánádà kan dé èkejì. Ńṣe ni àkókò ń sáré tete. Ní 1948, wọ́n pè wá fún kíláàsì kọkànlá ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Méjì lára àwọn olùkọ́ni wa ni Arákùnrin Albert Schroeder àti Maxwell Friend, kíláàsì wa sì ní akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínláàádọ́fà [108] nínú, àwọn ogójì ẹni àmì òróró sì wà lára wa. Ẹ wo bó ti jẹ́ ìrírí kíkọyọyọ, tó sì ń mérè wá tó, láti ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó ti ń sin Jèhófà láti ọjọ́ pípẹ́ lárọ̀ọ́wọ́tó wa!
Lọ́jọ́ kan, Arákùnrin Knorr wá bẹ̀ wá wò láti Brooklyn. Nínú àsọyé rẹ̀, ó ní kí èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ èdè Japanese. Gbogbo àwa méjìdínláàádọ́fà pátá la yọ̀ǹda ara wa! Ó wá kù sọ́wọ́ ààrẹ láti yan àwọn tí yóò gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà. Mo gbà pé Jèhófà ló darí yíyàn náà, nítorí pé yíyàn náà yọrí sí rere. Ọ̀pọ̀ lára èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí wọ́n yàn, tó sì wá ní àǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ní Japan ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ táa yàn wọ́n sí di báa ti ń sọ̀rọ̀ yìí—wọ́n ti darúgbó o, ṣùgbọ́n wọ́n ṣì wà níbẹ̀. Àwọn kan, bíi Llyod àti Melba Barry, gba iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn. Lloyd jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso títí ó fi kú lọ́dún tó kọjá. A bá gbogbo wọn yọ̀ nítorí èrè tí Jèhófà ti san.
Ọjọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege dé, wọ́n sì ní Jàmáíkà ni a ó lọ. Ṣùgbọ́n, wọ́n ní kí a padà sí Kánádà nítorí àwọn ẹjọ́ tó ṣì wà ní kóòtù ní Quebec.
Iṣẹ́ Orin Kíkọ Tún Dé O!
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo fi iṣẹ́ orin kíkọ sílẹ̀ nítorí iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, ó jọ pé orin ò fi mí sílẹ̀. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ààrẹ Society, Nathan Knorr, àti akọ̀wé rẹ̀, Milton Henschel, wá sí àgbègbè Maple Leaf Gardens ní Toronto. Àsọyé Arákùnrin Knorr, tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Ọjọ́ Ti Lọ Ju Bóo Ṣe Rò Lọ!” ta olúkúlùkù jí. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n ní kí n wá darí ẹgbẹ́ akọrin ní àpéjọpọ̀. Àwọn orin kan látinú ìwé orin Kingdom Service Song Book (1944), tí àwọn ará mọ̀-ọ́n kọ dáadáa, la ṣètò pé kí á kọ lọ́nà dídùn yùngbà-yungba. Ó jọ pé àwọn ará gbádùn rẹ̀. Nígbà táa parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán Sátidé, a bẹ̀rẹ̀ sí fi ètò táa wéwèé fún ọjọ́ Sunday dánra wò. Mo tajú kán rí Arákùnrin Henschel tó ń gba òdìkejì gbọ̀ngàn ìṣeré náà bọ̀ lọ́dọ̀ wa, ni mo bá ní kí ẹgbẹ́ akọrin dánu dúró kí n lè lọ pàdé rẹ̀. Ó béèrè pé, “Àwọn olórin mélòó ló wà nínú ẹgbẹ́ akọrin yín tí ń bẹ níhìn-ín?” Mo dá a lóhùn pé: “Bí ẹsẹ̀ gbogbo wa bá pé, a óò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó márùndínlógójì.” Ó wá fèsì pé: “Kò burú, ẹ óò tó ìlọ́po méjì iye yẹn ní New York, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún tí ń bọ̀.”
Àmọ́ kí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn tó dé, wọ́n ti pè mí wá sí Brooklyn. Nítorí ipò àwọn nǹkan, kò kọ́kọ́ ṣeé ṣe fún Aileen láti bá mi wá. Ilé tuntun tó wà ní òpópónà 124 Columbia Heights kò tíì parí nígbà yẹn, nítorí náà inú iyàrá kótópó kan nínú ilé àkọ́kọ́ ni mò ń sùn, pẹ̀lú àwọn arákùnrin ẹni àmì òróró méjì—àwọn ni bàbá àgbàlagbà Arákùnrin Payne àti Karl Klein, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tí màá bá a pàdé. Ǹjẹ́ iyàrá yẹn ò há jù? Ó há o. Síbẹ̀síbẹ̀, a ń gbé pa pọ̀ láìjà láìta. Àwọn arákùnrin àgbàlagbà wọ̀nyẹn ní àmúmọ́ra, wọ́n sì ní sùúrù. N kì í sì í fẹ́ kọjá àyè mi! Ó jẹ́ ẹ̀kọ́ ńlá nípa ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run lè ṣe. Wíwà lọ́dọ̀ Arákùnrin Klein àti bíbá a ṣiṣẹ́ pọ̀ mà ṣe mí lóore o! Ó ṣèèyàn púpọ̀, ó sì ń ranni lọ́wọ́ gidigidi. Àjọṣe wa wọ̀ gan-an, a sì ti jọ ń ṣọ̀rẹ́ báyìí fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún.
Mo ní àǹfààní láti bá wọn ṣiṣẹ́ nídìí orin nígbà àwọn àpéjọpọ̀ táa ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee lọ́dún 1950, 1953, 1955, àti 1958, èmi àti Al Kavelin ni a sì jọ bójú tó ẹgbẹ́ akọrin tó kọrin ní àpéjọpọ̀ ọdún 1963 táa ṣe ní pápá ìṣeré Rose Bowl, ní Pasadena, California. Nígbà àpéjọpọ̀ 1953 táa ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee, ètò orin kíkọ wáyé lọ́jọ́ Sunday kí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tó bẹ̀rẹ̀. Erich Frost mú Edith Shemionik (tó di Weigand lẹ́yìn náà) wá, ẹni tó jẹ́ olóhùn tín-ínrín, ó sì fẹnu kọ orin tó fọwọ́ ara rẹ̀ kọ, èyíinì ni orin “Ẹ Tẹsiwaju, Ẹyin Ẹlẹrii!” bí a ti ń lùlù táa sì ń ta gìtá sí i. Lẹ́yìn náà ni orí wá wú, báa ti ń gbọ́ orin àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa olóhùn iyọ̀ láti ilẹ̀ Áfíríkà, fún ìgbà àkọ́kọ́. Míṣọ́nnárì nì, Harry Arnott, ló mú kásẹ́ẹ̀tì kan tí wọ́n kọ orin aládùn yìí sí wá láti Àríwá Ròdéṣíà (táa ń pè ní Zambia báyìí) kí á lè gbádùn rẹ̀. Ṣe ni ohùn wọn gba gbogbo pápá ìṣeré náà kan.
Ètò Ìgbohùnsílẹ̀ Tó Wáyé Lórí Ìwé Orin 1966
Ǹjẹ́ o rántí ìwé orin aláwọ̀ osùn náà, “Ẹ Mã Kọrin Ki Ẹ si Mã Kọrin Didun Ninu Ọkan Nyin”? Nígbà tó ku díẹ̀ kí iṣẹ́ parí lórí ìwé orin yìí, Arákùnrin Knorr sọ pé: “A ó ṣe àwo lórí àwọn orin wọ̀nyí. Mo fẹ́ kí o kó ẹgbẹ́ àwọn olórin kéréje jọ, kí wọ́n kàn lo gòjé mélòó kan àti kàkàkí bíi méjì sí mẹ́ta. Èmi ò ní fẹ́ kí ẹnikẹ́ni wá ‘fun kàkàkí ara rẹ̀’ níbẹ̀ o, ìyẹn ni pé kí ẹnì kan wá máa gbé ògo ara rẹ̀ yọ!” Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n ní ká fi ṣe yàrá ìgbohùnsílẹ̀, àmọ́ ominú ń kọ wá pé ó máa ní ìṣòro nínú. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí ògiri ibẹ̀ tí a kò fi tìmùtìmù tẹ́, àti ilẹ̀ rẹ̀ táa tẹ́ ègé amọ̀ pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ sí, tí a to àwọn àga onírin tó ṣeé ká sórí rẹ̀, bá bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ìró máa dún ní àdúntúndún? Ta ló lè bá wa wá ojútùú sí ìṣòro kí ìró kàn máa dún láìnítumọ̀? Ẹnì kan dá a lábàá pé: “Tommy Mitchell ni kí ẹ pè! Iyàrá Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ló ti ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ìròyìn ABC.” A ránṣẹ́ sí Arákùnrin Mitchell, tayọ̀tayọ̀ ló sì fi fẹ́ láti ṣèrànwọ́.
Àárọ̀ ọjọ́ Sátidé àkọ́kọ́ tí a ó gbohùn sílẹ̀ dé wẹ́rẹ́, báa sì ṣe ń pe orúkọ àwọn olórin lọ́kọ̀ọ̀kan, mo rí arákùnrin kan tó gbé àpò kàkàkí dání. Mo rántí ìkìlọ̀ Arákùnrin Knorr pé: “Mi ò ní fẹ́ kí ẹnikẹ́ni wá ‘fun kàkàkí ara rẹ̀’ níbẹ̀ o!” Kí ni mo wá lè ṣe báyìí o? Mo ń wo arákùnrin náà bó ṣe gbé kàkàkí rẹ̀ jáde nínú àpò, tó bẹ̀rẹ̀ sí tò ó pọ̀, tó sì ń gbára dì. Tom Mitchell ni arákùnrin ọ̀hún, dídún tí kàkàkí ọ̀hún sì kọ́kọ́ dún báyìí, àgbọ́máleèlọ ni. Ó mú kí kàkàkí náà máa dún bíi gòjé! Mo wá ń rò ó lọ́kàn ara mi pé, ‘a gbọ́dọ̀ lo arákùnrin yìí o!’ Arákùnrin Knorr kò lòdì sí i rárá.
Nínú ẹgbẹ́ akọrin yẹn, a ní àwọn àgbà olórin tó tún jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́. Wọn kì í ṣe oníjàgídíjàgan rárá! Iṣẹ́ ìgbohùnsílẹ̀ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá, àmọ́ kò sẹ́ni tó ń ráhùn. Ìgbà tíṣẹ́ parí, tí kálukú fẹ́ máa lọ, ńṣe ni omi ń dà lójú wa; ẹ̀mí àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ sì ń bá a lọ láàárín àwa táa ṣiṣẹ́ náà. Gbogbo wa pátá la gbádùn àǹfààní yẹn, ọpẹ́ sì ni fún Jèhófà pé iṣẹ́ náà lójú.
Àwọn Àfikún Àǹfààní Tí Ń Mérè Wá
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, mo ṣì ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ni mo ti lò nínú iṣẹ́ àyíká àti ti àgbègbè—gbogbo ọdún yẹn ni mo sì gbádùn gan-an. Lẹ́yìn èyí ni mo fi ọdún márùn-ún bójú tó Gbọ̀ngàn Àpéjọ Norval ní Ontario. Ńṣe ni ọwọ́ èmi àti Aileen dí fọ́fọ́ nítorí pé kò sí òpin ọ̀sẹ̀ tí kì í sí àpéjọ àyíká àti àpéjọpọ̀ àgbègbè fún àwọn tí ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Ní ọdún 1979 sí 1980, àwọn tí ń yàwòrán ilé àtàwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lo Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí bí wọ́n ti ń wéwèé iṣẹ́ lórí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tí Society fẹ́ kọ́ sí Halton Hills. Lẹ́yìn iṣẹ́ wa ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ yẹn, iṣẹ́ mìíràn tí wọ́n yàn fún mi tún jẹ́ kí n túbọ̀ lọ́wọ́ sí iṣẹ́ orin kíkọ ní Brooklyn, láti 1982 sí 1984.
Ìyàwó mi ọ̀wọ́n kú ní June 17, 1994, ní ọjọ́ méje péré lẹ́yìn àjọ̀dún kọkàndínlọ́gọ́ta ìgbéyàwó wa. A ti jọ lo ọdún mọ́kànléláàádọ́ta nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà àfọkànṣe.
Bí mo ti ń ronú lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí tí mo ti ní nínú ìgbésí ayé, mo rántí bí Bíbélì ti jẹ́ atọ́nà tó wúlò gidigidi. Nígbà míì, mo máa ń lo Bíbélì Aileen, inú mi sì máa ń dùn gan-an bí mo ti ń rí àwọn ohun tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn—àwọn ẹsẹ kan lódindi, àwọn gbólóhùn pàtó kan, àtàwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tó fàlà sí. Gẹ́gẹ́ bíi ti Aileen, èmi náà ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ní ìtumọ̀ pàtàkì sí mi. Ọ̀kan irú rẹ̀ ni Sáàmù kẹtàdínlógóje [137], tó gba àdúrà amóríwú yìí sí Jèhófà, pé: “Kí èmi má mọ háàpù ta mọ́ láyé mi, bí mo bá gbàgbé ìwọ, Jerúsálẹ́mù! Kí n má mọ orin-ín kọ mọ́ láyé mi, bí mi ò bá rántí rẹ mọ́, tí mi ò sì ronú nípa rẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bí ayọ̀ mi gíga jù lọ!” (Sáàmù 137:5, 6, Today’s English Version) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ràn orin, ayọ̀ mi gíga jù lọ ń wá látinú fífi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà, ẹni tó ti jẹ́ kí n gbó, kí n tọ́, tó sì fi ìgbésí ayé aláyọ̀ san mí lẹ́san.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ile-Iṣọ Na ti February 1, 1974, ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé látìgbà yẹn lọ, ẹnikẹ́ni tó bá ń mu sìgá gbọ́dọ̀ jáwọ́ kí a tó lè batisí rẹ̀, kí ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi àti Aileen ní 1947
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwa rèé nígbà kan táa bẹ̀rẹ̀ sí gbohùn sílẹ̀