Ǹjẹ́ O Mọ Bí a Ṣe Ń dúró De Nǹkan?
Ǹjẹ́ O Mọ Bí a Ṣe Ń dúró De Nǹkan?
ǸJẸ́ o lè fojú inú wo bí àkókò táwọn èèyàn wulẹ̀ fi ń dúró lọ́dọọdún ti pọ̀ tó? Wọ́n a dúró lórí ìlà nílé ìtajà tàbí nílé epo. Wọ́n a dúró títí wọ́n fi máa gbé oúnjẹ wọn dé nílé àrójẹ. Wọ́n a dúró láti rí dókítà tàbí olùtọ́jú eyín. Wọ́n a dúró de bọ́ọ̀sì àti ọkọ̀ ojú irin. Dájúdájú, á yà wá lẹ́nu gan-an táa bá mọ iye àkókò téèyàn ń lò nínú ìgbésí ayé rẹ̀ láti dúró kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àwọn kan fojú díwọ̀n, àwọn ará Jámánì nìkan ń pàdánù ohun tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ wákàtí lọ́dún nídìí sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ ọkọ̀ lásán! Ẹnì kan ṣírò rẹ̀ pé iye wákàtí yìí dọ́gba pẹ̀lú iye ọdún tí a retí pé kí àwọn bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ènìyàn lò láyé.
Dídúró lè tánni ní sùúrù. Láyé òde òní, kò sígbà tó dà bí ẹni pé àkókò táa ní tó láti ṣe gbogbo nǹkan, tí a bá sì ń ronú lórí àwọn nǹkan mìíràn tó yẹ ká ṣe, dídúró lè di àdánwò gidi fún wa. Òǹkọ̀wé nì, Alexander Rose, fìgbà kan sọ pé: “Ìdajì ohun tó ń máyé súni ni dídúró.”
Òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà nì, Benjamin Franklin, gbà pé dídúró de nǹkan lè náni lówó gọbọi. Ní ohun tó lé ní àádọ́ta lé rúgba [250] ọdún sẹ́yìn, ó sọ pé: “Àkókò wọ́n ju owó lọ.” Ìdí nìyẹn táwọn oníṣòwò kì í fi í fàkókò ṣòfò lórí àwọn nǹkan tí kò ní láárí nígbà tíṣẹ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan títà táa fàkókò díẹ̀ ṣe lè mú èrè púpọ̀ sí i wá. Àwọn iléeṣẹ́ okòwò tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn ní tààrà máa ń gbìyànjú láti tètè dá àwọn èèyàn lóhùn—wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan bí oúnjẹ àsáréṣe, wíwakọ̀ wọnú ọgbà báńkì, ká sì parí gbogbo ohun táa bá wá láìbọ́ọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀, àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀—nítorí wọ́n mọ̀ pé ara ohun táwọn fi lè mú inú àwọn oníbàárà dùn ni káwọn dín iye àkókò tí wọ́n fi ń dúró kù.
Fífi Ìgbésí Ayé Wa Ṣòfò
Akéwì ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ọ̀rúndún kọkàndínlógún nì, Ralph Waldo Emerson, fìgbà kan ṣàròyé pé: “Ẹ wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò téèyàn fi ń ṣòfò lára ọjọ́
ayé rẹ̀ nídìí dídúró!” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí pàápàá, òǹkọ̀wé Lance Morrow ṣàròyé lórí bí dídúró ṣe lè jẹ́ kí nǹkan tojú súni, kí ó sì fa àìfararọ. Àmọ́, ó wá sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀nà àyínìke tí dídúró lè gbà túbọ̀ fayé súni.” Kí nìyẹn? “Mímọ̀ pé ohun tó níye lórí jù lọ téèyàn ní, ìyẹn àkókò, tó jẹ́ ìpín kan nínú ìgbésí ayé ẹni, ti di ohun tí a pàdánù, tí a kò sì lè rí gbà padà mọ́.” Ó bani nínú jẹ́, àmọ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Àkókò táa pàdánù nítorí pé a ń dúró jẹ́ èyí tí a pàdánù títí láé.Àmọ́ ṣá o, tí kì í bá ṣe pé ìgbésí ayé wa ti kúrú jù ni, a kì bá máa janpata nípa dídúró. Ṣùgbọ́n ìgbésí ayé kúrú. Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, onísáàmù inú Bíbélì sọ pé: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá, síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́; nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.” (Sáàmù 90:10) Ibikíbi tó wù kí a wà, irú ènìyàn tó sì wù kí a jẹ́, ìgbésí ayé wa—ìyẹn ọjọ́, wákàtí, ìṣẹ́jú tí a ó lò láti ìgbà tí a ti bí wa—mọ níwọ̀n. Síbẹ̀, a ò lè yẹra fún àwọn ipò tó ti di dandan fún wa láti fi díẹ̀ lára àkókò ṣíṣeyebíye bẹ́ẹ̀ ṣòfò lórí dídúró de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí àwọn ènìyàn.
Kíkọ́ Bí A Ṣe Ń Dúró De Nǹkan
Ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló ti wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí awakọ̀ ti ń gbìyànjú pé kí òun ṣáà sáré kọjá ọkọ̀ tó wà níwájú òun. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé kò sí nǹkan kan tó ń lé e léré—kì í kúkú ṣe pé awakọ̀ náà ní àdéhùn kankan tó jẹ́ kánjúkánjú. Síbẹ̀ kò lè fara da dídúró, pé kí awakọ̀ mìíràn máa pinnu fún òun bí ìrìn òun ṣe máa yá tó. Àìnísùúrù rẹ̀ fi hàn pé kò tíì kọ́ bí a ṣe ń dúró de nǹkan. Kíkọ́ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, mímọ bí a ṣe ń dúró de nǹkan jẹ́ ẹ̀kọ́ kan tí a gbọ́dọ̀ kọ́. Kì í ṣe àbímọ́ni. Àwọn ọmọ ọwọ́ máa ń wá àfiyèsí kíákíá nígbà tí ebi bá ń pa wọ́n tàbí nígbà tí ara bá ni wọ́n. Ìgbà tí wọ́n bá wá ń dàgbà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń mọ̀ pé àwọn ìgbà mìíràn wà táwọn ní láti dúró kí ọwọ́ wọ́n tó lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́. Láìṣe àní-àní, níwọ̀n bí dídúró ti jẹ́ apá tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé, mímọ bí a ṣe ń fi sùúrù dúró nígbà tí ó bá pọndandan jẹ́ àmì pé ẹnì kan dàgbà dénú.
Ká sọ tòótọ́ o, àwọn ipò kánjúkánjú kan wà táwọn èèyàn ti lè rí ìdí tí a ò fi lè ní sùúrù. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ọkọ ìyàwó tó ń sáré gbé aya rẹ̀ lọ sí ọsibítù nítorí pé ó fẹ́ bí ọmọ wọn tuntun kò ní fẹ́ kí ohunkóhun dá òun dúró rárá, bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn. Àwọn áńgẹ́lì tó wá sọ fún Lọ́ọ̀tì pé kó kúrò ní Sódómù kò ṣe tán láti dúró rárá nígbà tí Lọ́ọ̀tì ń jáfara. Ìparun ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ẹ̀mí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ sì wà nínú ewu. (Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16) Àmọ́, ẹ̀mí kì í sábà sí nínú ewu ní ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbà tó pọndandan fún àwọn ènìyàn láti dúró. Ní irú àwọn àkókò yẹn, nǹkan ì bá túbọ̀ rọni lọ́rùn ká sọ pé olúkúlùkù kọ́ bí a ṣe ń ní sùúrù—bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìtóótun ẹnì kan tàbí àìfọkànsí ohun tó ń ṣe ló fa ìdádúró náà. Síwájú sí i, yóò túbọ̀ rọrùn láti ní sùúrù bí olúkúlùkù bá kọ́ bí a ṣe ń lo àkókò tí a fi ń dúró lọ́nà tó ṣeni láǹfààní. Àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 5 fúnni ní àwọn ìmọ̀ràn mélòó kan lórí bí dídúró kò ṣe ní jẹ́ ohun tí ń roni lójú, ṣùgbọ́n tó tilẹ̀ lè jẹ́ ohun tó mérè wá pàápàá.
A kò lè gbójú fo kókó náà dá pé ẹ̀mí àìnísùúrù lè fi ìwà ìgbéraga ẹnì kan hàn, pé òun ṣe pàtàkì ju kí á dá òun dúró lọ. Fún ẹnikẹ́ni tó bá ní irú ìwà bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí láti inú Bíbélì yẹ fún àgbéyẹ̀wò: “Onísùúrù sàn ju onírera ní ẹ̀mí.” (Oníwàásù 7:8) Ẹ̀mí ìrera tàbí ìgbéraga jẹ́ àbùkù ńlá, òwe inú Bíbélì sì sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Òwe 16:5) Kíkọ́ bí a ṣe ń ní sùúrù—ìyẹn kíkọ́ bí a ṣe ń dúró—lè wá béèrè pé kí a yẹ ara wa wò dáadáa, kí a sì tún wo bí a ṣe ń bá àwọn tó yí wa ká lò.
Sùúrù Yóò Lérè
Dídúró sábà máa ń rọrùn nígbà tí a bá ní ẹ̀rí ìdánilójú pé ohun tí a ń dúró fún tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí a sì mọ̀ pé bópẹ́bóyá yóò tẹ̀ wá lọ́wọ́. Lórí ọ̀ràn yìí, ó dára láti máa ronú lórí kókó náà pé gbogbo àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Ọlọ́run ló ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí àgbàyanu rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, a sọ fún wa nínú sáàmù kan tó ní ìmísí Ọlọ́run pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Àpọ́sítélì Jòhánù tún ìlérí yìí sọ nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (Sáàmù 37:29; 1 Jòhánù 2:17) Ó ṣe kedere pé, bí a bá lè wà láàyè títí láé, dídúró ò ní jẹ́ ìṣòro rárá. Àmọ́, a ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí wà láàyè títí láé báyìí. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu láti máa sọ̀rọ̀ nípa ìyè àìnípẹ̀kun?
Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, rántí pé Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pẹ̀lú ìrètí pé kí wọ́n wà láàyè títí láé. Kìkì nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ ló jẹ́ kí wọ́n pàdánù ìfojúsọ́nà yẹn fún ara wọn àti àwọn ọmọ wọn—títí kan àwa pẹ̀lú. Àmọ́, kíá lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ̀ ni Ọlọ́run kéde ète rẹ̀ láti yí àbájáde àìgbọràn wọn padà. Ó ṣèlérí “irú-ọmọ” kan tí ń bọ̀, tó wá lọ jẹ́ Jésù Kristi.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Róòmù 5:18.
Yálà àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yóò jàǹfààní nínú ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ ni o, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìyẹn kù sọ́wọ́ wa láti pinnu. Yóò gba sùúrù. Kí ó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ bí a ṣe ń ní irú sùúrù yìí, Bíbélì gbà wá níyànjú láti ronú lórí àpẹẹrẹ àgbẹ̀ kan. Ó gbin irúgbìn rẹ̀, kò sì sí ohun tó lè ṣe ju pé kí ó fi sùúrù dúró—kí ó máa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti dáàbò bo ọ̀gbìn rẹ̀—títí di àkókò ìkórè. Lẹ́yìn náà, ó jèrè sùúrù rẹ̀, ó sì rí èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. (Jákọ́bù 5:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àpẹẹrẹ sùúrù mìíràn. Ó rán wa létí àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin ayé ìgbàanì. Wọ́n ń wọ̀nà fún ìmúṣẹ àwọn ète Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n ní láti dúró de àkókò tí Ọlọ́run yàn kalẹ̀. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti fara wé àwọn wọ̀nyí, “àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”—Hébérù 6:11, 12.
Dájúdájú, dídúró jẹ́ ohun kan tí ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé. Àmọ́ kò wá yẹ kó jẹ́ ohun tí yóò máa fi gbogbo ìgbà kó ìdààmú bá wa. Fún àwọn tó ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run, ó lè jẹ́ orísun ìdùnnú fún wọn. Wọ́n lè lo àkókò tí wọ́n fi ń dúró láti máa mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run gún régé sí i, kí wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń fi ìgbàgbọ́ wọn hàn. Àti nípasẹ̀ àdúrà, ìkẹ́kọ̀ọ́, àti àṣàrò, wọ́n lè ní ìgbọ́kànlé tí kò lè mì pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí rẹ̀ ni yóò ní ìmúṣẹ ní àkókò rẹ̀.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
DÍN ÀÌFARARỌ TÓ WÀ NÍNÚ DÍDÚRÓ DE NǸKAN KÙ!
Wéwèé ṣáájú! Bí o bá mọ̀ pé ó máa di dandan láti dúró, ṣètò láti kàwé, láti kọ̀wé, láti hun nǹkan, tàbí kí o ṣe àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tó gbámúṣé.
Lo àkókò yẹn láti ṣàṣàrò, ohun kan tó máa ń ṣòro láti ṣe nínú ayé kánjúkánjú tí a ń gbé yìí.
Kó àwọn ìwé díẹ̀ tí o lè kà sítòsí tẹlifóònù kí o lè máa rí nǹkan kà nígbà tí o bá ń dúró de ẹni tí o fẹ́ bá sọ̀rọ̀; o lè ka ojú ìwé bíi mélòó kan láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún tàbí mẹ́wàá.
Nígbà tí ìwọ àtàwọn èèyàn bá jọ ń dúró, lo àǹfààní náà, tó bá ṣeé ṣe, láti bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ẹlòmíràn jíròrò, kí o sì bá wọn ṣàjọpín èrò tó ń gbéni ró.
Fi àjákọ kan tàbí ìwé tóo lè kà sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ nítorí àwọn àkókò tóo bá máa dúró láìròtẹ́lẹ̀.
Di ojú rẹ, sinmi, tàbí kí o gbàdúrà.
DÍDÚRÓ LÁÌJẸ́ KÍ Ó SÚNI WULẸ̀ JẸ́ Ọ̀RÀN ÌṢARASÍHÙWÀ ẸNI ÀTI RÍRONÚ NÍPA RẸ̀ TẸ́LẸ̀.