Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ogún Wa Ṣíṣeyebíye—Kí Ló Túmọ̀ Sí Fún ọ?

Ogún Wa Ṣíṣeyebíye—Kí Ló Túmọ̀ Sí Fún ọ?

Ogún Wa Ṣíṣeyebíye—Kí Ló Túmọ̀ Sí Fún ọ?

“Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.”—MÁTÍÙ 25:34.

1. Kí ni onírúurú nǹkan táwọn èèyàn ti jogún?

 KÒ SẸ́NI tí kò rí nǹkan jogún. Àwọn kan lè máa gbé ìgbésí ayé ìdẹ̀ra nítorí ọrọ̀ tí wọ́n jogún. Ní ti àwọn míì, ìgbésí ayé òṣì ni wọ́n jogún bá. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, nítorí ohun tí ojú àwọn ìran àtijọ́ kan ti rí tàbí tí etí wọ́n ti gbọ́, ìkórìíra burúkú tí wọ́n ní fún ẹ̀yà mìíràn ni ogún tí wọ́n fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n o, ohun kan wà tí gbogbo wa jùmọ̀ ní. Gbogbo wa ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́. Ikú ni ogún yẹn máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.—Oníwàásù 9:2, 10; Róòmù 5:12.

2, 3. Ogún wo ni Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, kí sì ni ìdí tí wọ́n kò fi rí i gbà?

2 Ọ̀tọ̀ pátápátá ni ogún tí Jèhófà, Baba wa ọ̀run, onífẹ̀ẹ́, nawọ́ rẹ̀ sí aráyé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀—ogún ọ̀hún ni ìyè ayérayé pẹ̀lú ìjẹ́pípé nínú Párádísè. Ẹni pípé ni àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run fi pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé fún aráyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. (Sáàmù 115:16) Ó pèsè ọgbà Édẹ́nì gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ohun tí gbogbo àgbáyé yóò dà, ó sì fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní iṣẹ́ kan tó pinmirin, tó sì gbádùn mọ́ni. Ó ní kí wọ́n máa bímọ, kí wọ́n máa bójú tó ilẹ̀ ayé àti ọ̀kan-kò-jọ̀kan ohun ọ̀gbìn àti ẹranko tó wà nínú rẹ̀, kí wọ́n sì máa fẹ Párádísè náà títí yóò fi kárí ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:8, 9, 15) Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn yóò ṣe nínú iṣẹ́ yìí. Ẹ wo ohun àgbàyanu tí àwọn ọmọ wọn ì bá jogún!

3 Àmọ́, bí wọn yóò bá gbádùn gbogbo èyí, Ádámù àti Éfà àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì ṣègbọràn sí i, ṣùgbọ́n Ádámù àti Éfà kò mọyì ohun tí Ọlọ́run fi fún wọn, wọ́n sì ṣàìgbọràn sí àṣẹ rẹ̀. Wọ́n pàdánù ilé wọn tó jẹ́ Párádísè àti àwọn àǹfààní ológo tí Ọlọ́run nawọ́ rẹ̀ sí wọn. Nítorí náà, wọn kò lè fi nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ọmọ wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1-24.

4. Báwo ni ọwọ́ wa ṣe lè tẹ ogún tí Ádámù pàdánù?

4 Nínú ojú àánú rẹ̀, Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ kí ọwọ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà lè tẹ ogún tí Ádámù pàdánù. Báwo? Nígbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run, Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ lélẹ̀ fún àtọmọdọ́mọ Ádámù. Ọ̀nà yìí ni Kristi gba ra gbogbo wọn padà. Ṣùgbọ́n ogún náà kò lè ṣàdédé di tiwọn láìṣiṣẹ́ fún un. Wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìdúró rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì lè jèrè èyí nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ìtóye ẹbọ Jésù tí ń ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀, àti nípa fífi ìgbàgbọ́ yẹn hàn nípa ìgbọràn. (Jòhánù 3:16, 36; 1 Tímótì 2:5, 6; Hébérù 2:9; 5:9) Ǹjẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ ń fi hàn pé o mọrírì ìpèsè yẹn?

Ogún Tí Ábúráhámù Fi Sílẹ̀ Sẹ́yìn

5. Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun mọrírì àjọṣe òun pẹ̀lú Jèhófà?

5 Bí Jèhófà ti ń mú ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé ṣẹ, ó bá Ábúráhámù lò lọ́nà àkànṣe. Ó ní kí ọkùnrin olóòótọ́ yẹn ṣí kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ tí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò fi hàn án. Ábúráhámù ṣègbọràn tinútinú. Lẹ́yìn tí Ábúráhámù débẹ̀, Jèhófà sọ pé kì í ṣe Ábúráhámù tìkára rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà, bí kò ṣe àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 2, 7) Báwo ni Ábúráhámù ṣe ṣe? Ó múra tán láti sin Jèhófà níbikíbi àti lọ́nàkọnà tí Ọlọ́run bá darí rẹ̀ sí, kí àtọmọdọ́mọ rẹ̀ lè rí ogún yẹn gbà. Ábúráhámù sin Jèhófà ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tirẹ̀ fún ọgọ́rùn-ún ọdún, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 12:4; 25:8-10) Ǹjẹ́ ìwọ ì bá ṣe bẹ́ẹ̀? Jèhófà sọ pé “ọ̀rẹ́” òun ni Ábúráhámù.—Aísáyà 41:8.

6. (a) Kí ni Ábúráhámù fi hàn nípa bó ṣe múra tán láti fi ọmọ rẹ̀ rúbọ? (b) Ogún ṣíṣeyebíye wo ni Ábúráhámù fi sílẹ̀ fún àtọmọdọ́mọ rẹ̀?

6 Kó tó di pé Ábúráhámù wá bí Ísákì, ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ọ̀pọ̀ ọdún ló fi dúró láìrọ́mọ bí. Ìgbà tọ́mọ ọ̀hún tún dàgbà di géńdé ni Jèhófà tún pàṣẹ fún Ábúráhámù pé kó lọ fi ọ̀dọ́mọkùnrin náà rúbọ. Ábúráhámù kò mọ̀ pé ohun tí òun fẹ́ ṣe yóò jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò ṣe, ìyẹn ni fífi tí yóò fi Ọmọ rẹ̀ ṣe ìràpadà; síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣègbọràn, ó sì ti dáwọ́ lé àti fi Ísákì rúbọ, kó tó di pé áńgẹ́lì Jèhófà dá a lẹ́kun. (Jẹ́nẹ́sísì 22:9-14) Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé ipasẹ̀ Ísákì ni àwọn ìlérí tí òun ṣe fún Ábúráhámù yóò gbà nímùúṣẹ. Fún ìdí yìí, ó hàn kedere pé Ábúráhámù nígbàgbọ́ pé, bó bá di kàráǹgídá, Ọlọ́run lè mú Ísákì padà wá látinú ipò òkú, bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ṣáájú ìgbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 17:15-18; Hébérù 11:17-19) Nítorí pé Ábúráhámù ò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ̀ pàápàá lélẹ̀, Jèhófà kéde pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18) Èyí ló fi hàn pé ìlà ìdílé Ábúráhámù ni Irú-Ọmọ tí Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta, ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dógún mẹ́nu kàn, ìyẹn Mèsáyà olùdáǹdè náà, yóò gbà wá. Ogún ṣíṣeyebíye mà lèyí o!

7. Báwo ni Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ṣe fi hàn pé àwọn mọrírì ogún àwọn?

7 Ábúráhámù kò mọ ìtumọ̀ gbogbo ohun tí Jèhófà ń ṣe nígbà yẹn; bẹ́ẹ̀ náà ni Ísákì ọmọ rẹ̀ àti Jékọ́bù ọmọ ọmọ rẹ̀, tó di “ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀” kò mọ̀ ọ́n. Àmọ́ gbogbo wọn ló fọkàn tán Jèhófà. Wọn kò sọ ara wọn di ọmọ onílẹ̀ nínú èyíkéyìí lára àwọn ìlú ńlá tí ń dá ìjọba ara wọn ṣe ní ilẹ̀ náà, nítorí pé ohun tó sàn jù ni wọ́n ń wá—èyíinì ni “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 11:8-10, 13-16) Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ló mọrírì bí ohun tí wọ́n jogún nípasẹ̀ Ábúráhámù ti ṣeyebíye tó.

Àwọn Kan Tó Tẹ́ńbẹ́lú Ogún Náà

8. Báwo ni Ísọ̀ ṣe fi hàn pé òun kò mọyì bí ogún tí òun ní ti ṣeyebíye tó?

8 Ísọ̀, tó jẹ́ àrẹ̀mọ fún Ísákì, kò náání ogún ìbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí. Kò ka àwọn nǹkan ọlọ́wọ̀ sí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lọ́jọ́ kan tí ebi ń pa Ísọ̀, ńṣe ló ta ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù, arákùnrin rẹ̀. Kí ló fi gbà? Ó fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, ìyẹn, búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì! (Jẹ́nẹ́sísì 25:29-34; Hébérù 12:14-17) Orílẹ̀-èdè tí a ó tipasẹ̀ rẹ̀ mú àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ yóò wá látọ̀dọ̀ Jékọ́bù, ẹni tí Ọlọ́run yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ísírẹ́lì. Àwọn àǹfààní wo ni ogún pàtàkì yẹn ṣí sílẹ̀ fún wọn?

9. Nítorí ogún tẹ̀mí wọn, ìdáǹdè wo ni àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù, ìyẹn Ísírẹ́lì, rí?

9 Nígbà kan tí ìyàn ń jà, Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ ṣí lọ sí Íjíbítì. Ibẹ̀ ni wọ́n ti bí sí i, tí wọ́n sì di ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, àmọ́ wọ́n tún di ẹrú. Ṣùgbọ́n, Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá. Nígbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run, ó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè, ó sì sọ fún wọn pé òun máa mú wọn wọ “ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,” ìyẹn ni ilẹ̀ tó ṣèlérí fún Ábúráhámù.—Ẹ́kísódù 3:7, 8; Jẹ́nẹ́sísì 15:18-21.

10. Ní Òkè Sínáì, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ wo ló tún ṣẹlẹ̀ nípa ogún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

10 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà kó wọn jọ sí Òkè Sínáì. Ó wí fún wọn níbẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi. Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.” (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn èèyàn náà fínnúfíndọ̀ gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà wá fún wọn ní Òfin rẹ̀—kò bá orílẹ̀-èdè èyíkéyìí ṣe irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ rí.—Sáàmù 147:19, 20.

11. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun iyebíye tí ń bẹ nínú ogún tẹ̀mí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní?

11 Ẹ wo irú ogún tẹ̀mí tí orílẹ̀-èdè tuntun yẹn ní! Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ni wọ́n ń jọ́sìn. Ó ti dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì ti fojú ara wọn rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń múni kún fún ẹ̀rù nígbà tí a fún wọn ní Òfin ní Òkè Sínáì. Ogún wọn tún gbé pẹ́ẹ́lí sí i nígbà tí wọ́n tipasẹ̀ àwọn wòlíì gba àfikún “àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.” (Róòmù 3:1, 2) Jèhófà tìkára rẹ̀ ló pè wọ́n ní ẹlẹ́rìí òun. (Aísáyà 43:10-12) Orílẹ̀-èdè wọn ni Irú-Ọmọ náà tí í ṣe Mèsáyà yóò ti wá. Òfin náà tọ́ka sí i, yóò jẹ́ kí wọ́n dá a mọ̀, yóò sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe nílò rẹ̀ tó. (Gálátíà 3:19, 24) Kò tán síbẹ̀ o, wọn yóò tún ní àǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́, ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Irú-Ọmọ yẹn tí í ṣe Mèsáyà.—Róòmù 9:4, 5.

12. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, kí ni wọ́n pàdánù? Èé ṣe?

12 Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run awíbẹ́ẹ̀-ṣebẹ́ẹ̀, Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí gbẹẹrẹgbẹ. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣàlàyé lẹ́yìn náà, nítorí àìnígbàgbọ́ wọn, ilẹ̀ yẹn kò já sí “ibi ìsinmi” ní ti gidi. Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, wọn ò wọnú “ìsinmi Ọlọ́run” nítorí pé wọn ò mọ ète ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ṣíṣẹ̀dá Ádámù àti Éfà, wọn ò sì ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú rẹ̀.—Hébérù 4:3-10.

13. Nítorí àìmọyì ogún tẹ̀mí tí wọ́n ní, kí ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lódindi pàdánù?

13 Láti ara Ísírẹ́lì àbínibí nìkan ni à bá ti yan ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn tí yóò bá Mèsáyà náà jọba nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́. Ṣùgbọ́n wọn ò mọyì ogún ṣíṣeyebíye tí wọ́n ní. Kìkì àṣẹ́kù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àbínibí ló tẹ́wọ́ gba Mèsáyà náà nígbà tó dé. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìwọ̀nba kéréje lára wọn ló di ara ìjọba àwọn àlùfáà táa ṣèlérí. A gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ Ísírẹ́lì àbínibí, a sì “fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mátíù 21:43) Orílẹ̀-èdè wo nìyẹn?

Ogún Kan ní Ọ̀run

14, 15. (a) Lẹ́yìn ikú Jésù, báwo làwọn orílẹ̀-èdè ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bù kún ara wọn nípasẹ̀ “irú-ọmọ” Ábúráhámù? (b) Ogún wo ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” rí gbà?

14 Orílẹ̀-èdè tí a fi Ìjọba náà fún ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” èyíinì ni Ísírẹ́lì tẹ̀mí, tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi tí a fi ẹ̀mí bí. (Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-3) Àwọn kan lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wọ̀nyí jẹ́ Júù àbínibí, ṣùgbọ́n látinú àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọ́n ti wá. Lọ́nà yẹn ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù, pé nípasẹ̀ “irú-ọmọ” rẹ̀ ni a ó bù kún gbogbo orílẹ̀-èdè fi bẹ̀rẹ̀ sí nímùúṣẹ. (Ìṣe 3:25, 26; Gálátíà 3:8, 9) Nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́ yẹn, Jèhófà Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì sọ wọ́n di ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, wọ́n di arákùnrin Jésù Kristi. Nípa báyìí, àwọn náà di apá onípò kejì “irú-ọmọ” yẹn.—Gálátíà 3:28, 29.

15 Ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù bá àwọn Júù tí yóò di mẹ́ńbà orílẹ̀-èdè tuntun yẹn sọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú tuntun náà, tí ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀ yóò fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n bá ní nínú ẹbọ tó mú kí májẹ̀mú yìí lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni yóò jẹ́ kí a sọ àwọn táa mú wọnú májẹ̀mú yẹn di “pípé títí lọ fáàbàdà.” (Hébérù 10:14-18) A lè ‘polongo wọn ní olódodo,’ kí wọ́n sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (1 Kọ́ríńtì 6:11) Bí a bá wò ó lọ́nà yìí, wọn kò yàtọ̀ sí bí Ádámù ṣe rí kí ó tó di pé ó dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe párádísè orí ilẹ̀ ayé ni àwọn wọ̀nyí yóò máa gbé. Jésù sọ pé òun ń lọ pèsè ibì kan sílẹ̀ fún wọn ní ọ̀run. (Jòhánù 14:2, 3) Wọ́n ní láti mójú kúrò nínú ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n bàa lè ní ‘ogún tí a fi pa mọ́ dè wọ́n ní ọ̀run.’ (1 Pétérù 1:4) Kí ni wọn óò máa ṣe tí wọ́n bá dọ́hùn-ún? Jésù ṣàlàyé pé: “Èmi . . . bá yín dá májẹ̀mú . . . fún ìjọba kan.”—Lúùkù 22:29.

16. Iṣẹ́ ìsìn àgbàyanu wo ní ń bẹ níwájú fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?

16 Láti ọ̀run, ara nǹkan tí àwọn tí yóò bá Kristi jọba yóò ṣe ni pé, wọn yóò ṣèrànwọ́ láti mú gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ọ̀tẹ̀ sí ipò ọba aláṣẹ Jèhófà kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 2:26, 27) Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó jẹ́ onípò kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù nípa tẹ̀mí, wọn yóò nípìn-ín nínú mímú ìbùkún ìwàláàyè pípé wá fún àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. (Róòmù 8:17-21) Ogún tiwọn yìí mà tún kàmàmà o!—Éfésù 1:16-18.

17. Kí làwọn nǹkan tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń gbádùn lára ogún wọn nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé?

17 Àmọ́ o, kì í ṣe kìkì ẹ̀yìnwá ọ̀la ni gbogbo ohun tó jẹ́ ogún àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù yóò bọ́ sí. Jésù ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà débi tó jẹ́ pé kò tún sí ẹlòmíì tó lè fi irú òye yẹn yé wọn. (Mátíù 11:27; Jòhánù 17:3, 26) Nínú ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ, ó kọ́ wọn ní ohun tí ‘gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà’ túmọ̀ sí, ó sì kọ́ wọn ní ohun tí ṣíṣègbọràn sí Jèhófà ní nínú. (Hébérù 2:13; 5:7-9) Jésù fi ìmọ̀ òtítọ́ nípa ète Ọlọ́run jíǹkí wọn, ó sì mú un dá wọn lójú pé ẹ̀mí mímọ́ yóò túbọ̀ máa fi òye ọ̀hún yé wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (Jòhánù 14:24-26) Ó tẹ ìjẹ́pàtàkì Ìjọba Ọlọ́run mọ́ èrò inú àti ọkàn-àyà wọn. (Mátíù 6:10, 33) Jésù tún fún wọn ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní Jerúsálẹ́mù, Jùdíà, Samáríà, àti títí dé àwọn apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.—Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 1:8.

Ogún Ṣíṣeyebíye fún Ogunlọ́gọ̀ Ńlá

18. Ọ̀nà wo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò bù kún ara wọn nípasẹ̀ “irú-ọmọ” Ábúráhámù gbà ń nímùúṣẹ lónìí?

18 Ó ṣeé ṣe kí iye Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn, “agbo kékeré” ti àwọn ajogún Ìjọba náà, ti pé. (Lúùkù 12:32) Láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún báyìí ni Jèhófà ti darí àfiyèsí sí ìkójọpọ̀ ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn èèyàn mìíràn látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nípa báyìí, ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù pé nípasẹ̀ “irú-ọmọ” rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà bù kún ara wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ lọ́nà gbígbòòrò. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ fún wa láti rí i pé àwọn ẹni ìbùkún wọ̀nyí pẹ̀lú ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀jẹ́wọ́ pé ìgbàlà wọ́n sinmi lórí níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run. (Ìṣípayá 7:9, 10) Ǹjẹ́ o ti tẹ́wọ́ gba ìkésíni onínúure látọ̀dọ̀ Jèhófà láti wá di ara àwùjọ aláyọ̀ yìí?

19. Ogún wo làwọn tí à ń bù kún báyìí látinú àwọn orílẹ̀-èdè ń retí?

19 Ogún ṣíṣeyebíye wo ni Jèhófà ti fún àwọn tí kò sí lára agbo kékeré? Rárá, kì í ṣe ogún kan ní ọ̀run. Ó jẹ́ ogún tí Ádámù ì bá ti fi ṣọwọ́ sí àtọmọdọ́mọ rẹ̀—èyíinì ni àǹfààní ìyè ayérayé pẹ̀lú ìjẹ́pípé nínú Párádísè tí yóò kárí ayé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Yóò jẹ́ ayé kan níbi tí ‘ikú kì yóò ti sí mọ́, tí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora kì yóò ti sí mọ́.’ (Ìṣípayá 21:4) Nítorí náà, ìwọ ni Ọ̀rọ̀ ìmísí Ọlọ́run ń bá wí nígbà tó sọ pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere; máa gbé ilẹ̀ ayé, kí o sì máa fi ìṣòtítọ́ báni lò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá. Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:3, 4, 10, 11, 29.

20. Báwo ni “àwọn àgùntàn mìíràn” ṣe ń gbádùn apá púpọ̀ lára ogún tẹ̀mí táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní?

20 “Àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù ní ogún kan ní ilẹ̀ ayé tó jẹ́ apá kan Ìjọba ti ọ̀run náà. (Jòhánù 10:16a) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní sí ní ọ̀run, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára ogún tẹ̀mí tí àwọn ẹni àmì òróró ń gbádùn ni wọn yóò máa fi ṣọwọ́ sí wọn. Nípasẹ̀ àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró, ìyẹn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ni àwọn àgùntàn mìíràn ti rí ìlàlóye gbà nípa àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 24:45-47; 25:34) Lápapọ̀, àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn mọ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, wọ́n sì jùmọ̀ ń sìn ín. (Jòhánù 17:20, 21) Wọ́n jùmọ̀ ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìtóye ẹbọ Jésù tí ń ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n jùmọ̀ ń sìn gẹ́gẹ́ bí agbo kan lábẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn kan, ìyẹn ni Jésù Kristi. (Jòhánù 10:16b) Gbogbo wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ àwọn ará tí ń bẹ kárí ayé, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n jùmọ̀ ní àǹfààní jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Àní sẹ́, bí o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́, tí o sì ti ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, gbogbo nǹkan wọ̀nyí wà lára ogún tẹ̀mí tóo ní.

21, 22. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè fi hàn pé a mọyì ogún tẹ̀mí wa?

21 Báwo ni ogún tẹ̀mí yìí ṣe ṣeyebíye tó lójú rẹ? Ǹjẹ́ o mọyì rẹ̀ dáadáa dé ibi tí wàá fi sọ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run di ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ? Láti fi hàn pé èyí lohun pàtàkì jù lọ, ǹjẹ́ o ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti èyí tí ètò àjọ rẹ̀ ń fún wa pé ká máa wá sí gbogbo ìpàdé tí ìjọ Kristẹni ń ṣe déédéé? (Hébérù 10:24, 25) Ǹjẹ́ ogún yẹn ṣeyebíye sí ọ débi pé o lè máa bá a lọ ní sísin Ọlọ́run nígbà ìṣòro? Ǹjẹ́ ìmọrírì rẹ pọ̀ débi pé ó ń fún ọ lókun láti máa dènà àdánwò èyíkéyìí tó lè mú ọ máa tọ ipa ọ̀nà tí wàá fi pàdánù rẹ̀?

22 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa mọyì ogún tẹ̀mí tí Ọlọ́run ti fi fún wa. Bí a ṣe tẹjú mọ́ Párádísè tí ń bọ̀, ẹ jẹ́ ká máa nípìn-ín kíkún nínú àwọn àǹfààní tẹ̀mí tí Jèhófà ń fi jíǹkí wa báyìí. Nípa jíjẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà wà ní góńgó ẹ̀mí wa ní tòótọ́, a ń fi hàn gbangba pé ojú ribiribi la fi ń wo ogún tí Ọlọ́run fi fún wa. Ǹjẹ́ kí a wà lára àwọn tí ń polongo pé: “Ṣe ni èmi yóò gbé ọ ga, ìwọ Ọlọ́run mi Ọba, ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún orúkọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Sáàmù 145:1.

Báwo Lo Ṣe Máa Ṣàlàyé?

• Ká ní Ádámù ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run ni, ogún wo ni ì bá ti fi lé wa lọ́wọ́?

• Ojú wo làwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù fi ń wo ogún tí ń bẹ fún wọn?

• Kí ni ogún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹni àmì òróró Kristi ní nínú?

• Kí ni ogún àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, báwo sì ni wọ́n ṣe lè fi hàn pé àwọn mọrírì rẹ̀ gan-an?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù rí ìlérí táa ṣe nípa ogún ṣíṣeyebíye gbà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ǹjẹ́ o mọrírì ogún tẹ̀mí tóo ni?