‘Wọ́n Ń sọ̀rọ̀ Nípa Ìwà Rere Àti Ìfẹ́’
‘Wọ́n Ń sọ̀rọ̀ Nípa Ìwà Rere Àti Ìfẹ́’
LẸ́NU àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, kò sí ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ tí wọn ò tíì sọ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tán ní ilẹ̀ Faransé. Ńṣe ni àwọn alátakò wọn ń yí irọ́ pọ̀ mọ́ òótọ́, tí wọ́n ń fẹ́ kí wọ́n gbojúbi lọ́dọ̀ àwọn aráàlú. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1999, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ilẹ̀ Faransé pín mílíọ̀nù méjìlá ẹ̀dà ìwé ìléwọ́ tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, People of France, You Are Being Deceived! [Ẹ̀yin Ará Ilẹ̀ Faransé, Irọ́ Ni Wọ́n Ń Pa Fún Yín!] Nínú ìwé ìléwọ́ yìí, wọ́n ní àwọn kórìíra ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́ tí wọ́n ń sọ sáwọn.
Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n pín ìwé ìléwọ́ yìí, Ọ̀gbẹ́ni Jean Bonhomme, tí í ṣe oníṣègùn òyìnbó, tó tún jẹ́ ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin tẹ́lẹ̀ rí, kọ lẹ́tà ẹ̀hónú sí ìwé ìròyìn kan ládùúgbò náà. Ó kọ̀wé pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sílé mi. Wọ́n máa ń wá bá mi sọ̀rọ̀ nípa ìwà rere àti ìfẹ́ kárí ayé. . . . Wọn kì í já wọlé onílé. Ohùn pẹ̀lẹ́ ni wọ́n fi ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń fi sùúrù tẹ́tí sí iyèméjì tí mò ń ṣe.”
Ọ̀gbẹ́ni Bonhomme tún sọ nípa ojú ìwòye tẹ̀mí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní, pé: “Kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti ri ara wọn bọnú ọ̀ràn ti ayé kò pa ẹnikẹ́ni lára. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àìmọ̀kan àwọn olóṣèlú kan lohun náà gan-an tó lè dá họ́wùhọ́wù ńlá sílẹ̀ láàárín àwọn aráàlú, kí ó sì jẹ́ kí ìgboro dàrú.”