Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́
Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́
OBÌNRIN ará Brazil kan kígbe pé: “Ọlọ́run ti gbàgbé mi!” Èrò rẹ̀ ni pé ìgbésí ayé òun kò lè nítumọ̀ kankan mọ́ lẹ́yìn tí ọkọ òun ti kú ikú òjijì. Ǹjẹ́ o tíì gbìyànjú pé kí o tu ẹni tí ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò bí èyí nínú rí tàbí ẹni tó ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́?
Ìbànújẹ́ tí dorí àwọn kan kodò débi pé wọ́n ti gbẹ̀mí ara wọn—ọ̀dọ́ sì pọ̀ lára wọn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn Folha de S. Paulo sọ, ìwádìí kan ní Brazil fi hàn pé, “ìpara-ẹni láàárín àwọn ọ̀dọ́ ti fi ìpín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè.” Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Walter, a ọ̀dọ́kùnrin kan láti São Paulo yẹ̀ wò. Kò lóbìí, kò nílé, kò ní àkókò tó máa fi gbọ́ tara ẹ̀, kò sì lọ́rẹ̀ẹ́ tó lè finú hàn. Kí ìyà ńlá yìí lè dópin, Walter pinnu láti ti orí afárá bẹ́ sómi.
Obìnrin anìkàntọ́mọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edna ti ní ọmọ méjì nígbà tó pàdé ọkùnrin mìíràn. Lẹ́yìn oṣù méjì péré, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé pa pọ̀ nínú ilé ìyá ọkùnrin náà, ìyá yìí sì rèé, ẹlẹ́mìí èṣù ni, ó sì ń mu jẹ̀jẹ̀rẹ̀ nínú ọtí. Edna bí ọmọ mìíràn, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí mu ọtí ní àmupara, bó ṣe di ẹni tí ìbànújẹ́ ń sorí ẹ̀ kọdò nìyẹn, tó sì gbìyànjú àtipa ara rẹ̀. Níkẹyìn, wọ́n kó àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
Àwọn arúgbó náà ńkọ́? Maria jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn àríyá, tó sì mọ̀rọ̀ sọ bí nǹkan míì. Àmọ́, bó ṣe ń dàgbà sí i ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn nípa iṣẹ́ nọ́ọ̀sì tó ń ṣe, ó ń bẹ̀rù pé òun yóò máa ṣe àwọn àṣìṣe kan. Èyí mú kó sorí kọ́. Lẹ́yìn tó gbìyànjú láti wá oògùn lò fúnra rẹ̀, ló bá wá oníṣègùn òyìnbó lọ, ó sì jọ pé ìtọ́jú tó gbà ṣèrànwọ́ gan-an. Àmọ́, bíṣẹ́ ṣe bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tó di ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ni ìsoríkọ́ náà tún padà wá, ti ọ̀tẹ̀ yìí wá le débi pé kò gbóògùn mọ́. Maria wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú àtipa ara rẹ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n José Alberto Del Porto ti Yunifásítì São Paulo sọ pé: “Àwọn bíi mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tíbànújẹ́ máa ń sorí wọn kọdò ló máa ń gbìyànjú àtipa ara wọn.” Dókítà David Satcher tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn oníṣègùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ròyìn pé: “Ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé àwọn tó pa ara wọn pọ̀ ju àwọn táwọn ẹlòmíràn pa lọ, àmọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí ń bani nínú jẹ́ gbáà ni.”
Nígbà míì, ó jọ pé ẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ làwọn èèyàn tí ń gbìyànjú àtipa ara wọn ń bẹ̀. Ó sì dájú pé àwọn mẹ́ńbà ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ máa ń fẹ́ ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe fún ẹni tó ti sọ̀rètí nù. Àmọ́ ṣá o, wọn ò ní
ran ẹni náà lọ́wọ́ bí wọ́n bá ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi: “Yéé ká gúọ́gúọ́ kiri,” “Àìmọye èèyàn ni ìṣòro tiwọn ju tìẹ lọ” tàbí, “Gbogbo wa la níṣòro táà ń bá yí.” Dípò ìyẹn, o ò ṣe kúkú ṣe bí ọ̀rẹ́ gidi, kóo sì jẹ́ ẹni tí ń fetí sílẹ̀ dáadáa? Àní, gbìyànjú láti ran ẹni tíbànújẹ́ ń sorí ẹ̀ kọdò lọ́wọ́ kí ayé yéé sú wọn.Voltaire, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, kọ̀wé pé: “Ẹni tí ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò lónìí, tó wá tìtorí ìyẹn para ẹ̀, ì bá yàn láti wà láàyè ká ló dúró fún ọ̀sẹ̀ kan sí i.” Tóò, báwo làwọn tó ti bọ́hùn ṣe lè mọ̀ pé ó dáa kéèyàn wà láàyè?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Iye àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbà tó ń para wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Báwo lo ṣe lè ran ẹni tó ti sọ̀rètí nù lọ́wọ́?