Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ Kristẹni—Kì Í Ṣe Ọ̀rọ̀ Ẹnu Lásán

Ìfẹ́ Kristẹni—Kì Í Ṣe Ọ̀rọ̀ Ẹnu Lásán

Ìfẹ́ Kristẹni—Kì Í Ṣe Ọ̀rọ̀ Ẹnu Lásán

NÍGBÀ tí iná jó ilé àwọn Bartholomew ní Trinidad, gbogbo ohun tí ìdílé náà ní pátá ló ṣègbé àyàfi ẹ̀mí wọn. Ìbátan wọn kan tó ń gbé nítòsí ló gbà wọ́n sílé, àmọ́ ọ̀ràn náà ò parí síbẹ̀.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Olive Bartholomew, àwọn mẹ́ńbà ìjọ tó ń dara pọ̀ mọ́—àtàwọn tó wà láwọn ìjọ àgbègbè tó yí wọn ká—bẹ̀rẹ̀ sí dá nǹkan jọ tí wọn ó fi tún ilé tí òun àti ìdílé rẹ̀ pàdánù kọ́. Wọ́n gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí yóò bójú tó iṣẹ́ títún ilé náà kọ́, iṣẹ́ sì bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Nǹkan bí ogún Ẹlẹ́rìí àtàwọn aládùúgbò bíi mélòó kan ló wà níbẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ pàápàá dara pọ̀ mọ́ wọn, àwọn mìíràn sì wà tí wọ́n ń ṣètò ìpápánu.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Sunday Guardian ti Trinidad ṣe ròyìn rẹ̀, Olive sọ pé: “Inú ìdílé mi dùn gidigidi. Wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí o, àmọ́ ẹnu ṣì ń ya ọkọ mi sí ohun tó ń rí.”

Ní ṣíṣe àkópọ̀ gbogbo ìsapá wọn, alábòójútó iṣẹ́ ìkọ́lé náà tẹnu mọ́ ọn pé irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ojúlówó àmì tí a fi ń dá ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Ó sọ pé: “Kì í ṣe pé a kàn máa ń lọ láti ilé dé ilé láti sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ nìkan. A ń tiraka láti fi ohun tí a ń wàásù rẹ̀ ṣe ìwà hù.”—Jòhánù 13:34, 35.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Olive Bartholomew àti ọkọ rẹ̀