Jòsáyà Onírẹ̀lẹ̀ Rí Ojú Rere Jèhófà
Jòsáyà Onírẹ̀lẹ̀ Rí Ojú Rere Jèhófà
Ẹ̀RÙ ní láti ba Jòsáyà, ọmọ ọdún márùn-ún, tó jẹ ọmọ ọba Júdà. Jẹ́dídà ìyá rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀. Ó yẹ kí Jẹ́dídà sọkún nítorí pé Mánásè Ọba tó jẹ́ baba àgbà fún Jòsáyà ti kú.—2 Àwọn Ọba 21:18.
Ámọ́nì, tó jẹ́ baba Jòsáyà ló máa wá jọba Júdà báyìí. (2 Kíróníkà 33:20) Àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ámọ́nì pa á ní ọdún méjì lẹ́yìn náà (659 ṣáájú Sànmánì Tiwa). Àwọn èèyàn pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, wọ́n sì fi Jòsáyà ọ̀dọ́mọdé jọba. (2 Àwọn Ọba 21:24; 2 Kíróníkà 33:25) Àtìgbà tí Ámọ́nì ti wà lórí àlééfà, ló ti mọ́ Jòsáyà lára láti máa gbọ́ òórùn tùràrí tó gba Jerúsálẹ́mù kan nítorí ọ̀pọ̀ pẹpẹ tó wà lórí òrùlé táwọn èèyàn ń lò láti júbà fún àwọn ọlọ́run èké. Wọ́n tún máa ń rí àwọn àlùfáà kèfèrí tí wọ́n máa ń rìn lọ sókè lọ sódò, àtàwọn tó wá bọ òrìṣà—kódà àwọn kan tí wọ́n pera wọn ní olùjọsìn Jèhófà—tí wọ́n ń fi òrìṣà Málíkámù búra.—Sefanáyà 1:1, 5.
Jòsáyà mọ̀ pé ohun tó burú jáì ni Ámọ́nì ṣe nígbà tó ń jọ́sìn àwọn èké ọlọ́run. Ọ̀dọ́mọdé ọba Júdà yìí tún wá túbọ̀ lóye àwọn ìkéde tí Sefanáyà, wòlíì Ọlọ́run ṣe. Nígbà tí Jòsáyà pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (ní 652 ṣááju Sànmánì Tiwa), ó ti ń lo ọdún kẹjọ rẹ̀ lọ lórí oyè, ó sì pinnu láti ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Sefanáyà sọ. Àtìgbà tí Jòsáyà ti wà ní ọmọdékùnrin ló ti ń wá Jèhófà.—2 Kíróníkà 33:21, 22; 34:3.
Jòsáyà Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ní Pẹrẹu!
Ọdún mẹ́rin kọjá, Jòsáyà sì dáwọ́ lé rírẹ́yìn ìsìn èké ní Júdà òun Jerúsálẹ́mù (648 ṣááju Sànmánì Tiwa). Ó pa àwọn òrìṣà run, ó gé àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀, ó sì wó àwọn pẹpẹ tùràrí tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn Báálì. Ó lọ ère àwọn ọlọ́run èké di ekuru lẹ́búlẹ́bú tí wọ́n wá fọ́n sórí sàréè àwọn tó ń rúbọ sí wọn. Ó sọ àwọn pẹpẹ tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn àìmọ́ di ẹlẹ́gbin, ó sì wó wọn.—2 Àwọn Ọba 23:8-14.
Iṣẹ́ àfọ̀mọ́ tí Jòsáyà dáwọ́ lé yìí ti tẹ̀ síwájú gan-an nígbà tí Jeremáyà, ọmọ àlùfáà Léfì kan, wá sí Jerúsálẹ́mù (647 ṣááju Sànmánì Tiwa). Jèhófà Ọlọ́run ti yan Jeremáyà ọ̀dọ́mọdé gẹ́gẹ́ bí wòlíì rẹ̀, ẹ sì wo bó ṣe fi gbogbo agbára rẹ̀ polongo iṣẹ́ tí Jèhófà rán an lòdì sí ìsìn èké! Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ẹgbẹ́ ni Jeremáyà àti Jòsáyà. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo àfọ̀mọ́ tí Jòsáyà fi ìgboyà ṣe àti ìkéde tí Jeremáyà ṣe láìbẹ̀rù, kíá làwọn èèyàn náà tún padà sínú ìjọsìn èké.—Jeremáyà 1:1-10.
Àwárí Kan Tó Ṣeyebíye!
Ọdún bíi márùn-ún tún kọjá. Jòsáyà tó ti di ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ti ń ṣàkóso fún nǹkan bí ọdún méjìdínlógún. Ó ké sí Ṣáfánì, akọ̀wé; Maaseáyà, ìjòyè ìlú náà; àti Jóà tó ń ṣàkọsílẹ̀. Ọba pàṣẹ fún Ṣáfánì pé: ‘Sọ fún Hilikáyà, àlùfáà àgbà, pé kí ó kó owó tí àwọn olùṣọ́nà tẹ́ńpìlì kó jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn náà kí ó sì fi í lé ọwọ́ àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ náà, kí wọ́n lè tún ilé Jèhófà ṣe.’—2 Àwọn Ọba 22:3-6; 2 Kíróníkà 34:8.
Láti òwúrọ̀ kùtù hàì ni àwọn tó ń tún tẹ́ńpìlì náà ṣe ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Ó dájú pé Jòsáyà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé àwọn òṣìṣẹ́ náà ń tún ibi tí àwọn kan lára àwọn baba ńlá rẹ̀ tó jẹ́ ẹni ibi ti bàjẹ́ nínú ilé Ọlọ́run ṣe. Bí iṣẹ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, Ṣáfánì mú ìròyìn kan wá. Àmọ́, kí rèé lọ́wọ́ rẹ̀ yìí? Họ́wù, àkájọ kan ló gbé dání! Ó ṣàlàyé pé 2 Kíróníkà 34:12-18) Àwárí ńlá mà lèyí o—ó sì dájú pé ojúlówó ẹ̀dà Òfin náà ni!
Hilikáyà, Àlùfáà Àgbà ti rí “ìwé òfin Jèhófà láti ọwọ́ Mósè.” (Jòsáyà wá ń hára gàgà láti gbọ́ gbogbo ohun tó wà nínú ìwé náà. Bí Ṣáfánì ṣe ń kà á ni ọba náà ń gbìyànjú àtirí bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àṣẹ náà ṣe kan òun àtàwọn ènìyàn náà. Ohun tó múnú rẹ̀ dùn jù lọ ni bí ìwé náà ṣe tẹnu mọ́ ìjọsìn tòótọ́, tó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti ìkólọ sígbèkùn tí yóò wá sórí wọn bí àwọn ènìyàn náà bá lọ́wọ́ nínú ìsìn èké. Wàyí o, bí Jòsáyà ṣe rí i pé kì í ṣe gbogbo àṣẹ Ọlọ́run làwọn pa mọ́, ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó sì pàṣẹ fún Hilikáyà, Ṣáfánì, àti àwọn mìíràn pé: ‘Ẹ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí; nítorí pé títóbi ni ìhónú Jèhófà tí a mú gbaná jẹ sí wa nítorí pé àwọn baba ńlá wa kò fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí.’—2 Àwọn Ọba 22:11-13; 2 Kíróníkà 34:19-21.
A Sọ Ohun Tí Jèhófà Wí
Àwọn ìránṣẹ́ Jòsáyà lọ sọ́dọ̀ Húlídà, wòlíì obìnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì mú ìròyìn kan padà wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Húlídà ti sọ ohun tí Jèhófà wí, tí ó fi hàn pé àwọn ìyọnu àjálù tó wà nínú ìwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà yóò já lu orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà náà. Àmọ́, nítorí pé Jòsáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run, òun kò ní rí àjálù náà. Wọn óò kó o jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n ó sì gbé e lọ sínú itẹ́ tirẹ̀ ní àlàáfíà.—2 Àwọn Ọba 22:14-20; 2 Kíróníkà 34:22-28.
Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Húlídà rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nígbà tó jẹ́ pé ojú ogun ni Jòsáyà kú sí? (2 Àwọn Ọba 23:28-30) Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé “àlàáfíà” tí wọ́n fi kó o jọ sínú itẹ́ tirẹ̀ yàtọ̀ sí “ìyọnu àjálù” tó ń bọ̀ wá já lu Júdà. (2 Àwọn Ọba 22:20; 2 Kíróníkà 34:28) Jòsáyà kú kí ìyọnu àjálù náà tó ṣẹlẹ̀ ní 609 sí 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì pa á run. Àti pé ‘kíkóni jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá ẹni’ kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò lè kú ikú oró. A lo irú gbólóhùn kan náà yìí láti fi tọ́ka sí ikú oró àti ikú tí kì í ṣe ti oró.—Diutarónómì 31:16; 1 Àwọn Ọba 2:10; 22:34, 40.
Ìjọsìn Tòótọ́ Tẹ̀ Síwájú
Jòsáyà kó gbogbo àwọn ènìyàn Jerúsálẹ́mù jọ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì ka “gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé májẹ̀mú náà” tí wọ́n rí nínú ilé Jèhófà sí wọn létí. Ó wá dá májẹ̀mú “láti tọ Jèhófà lẹ́yìn, àti láti fi gbogbo ọkàn-àyà àti gbogbo ọkàn pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀, nípa mímú ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí tí a kọ sínú ìwé yìí ṣẹ.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì mú ìdúró wọn nínú májẹ̀mú náà.—2 Àwọn Ọba 23:1-3.
Jòsáyà Ọba wá gbé ìgbésẹ̀ mìíràn láti gbógun ti ìbọ̀rìṣà, ó sì hàn gbangba pé ìgbésẹ̀ kejì yìí lágbára ju ti ìṣáájú lọ. Gbogbo àwọn àlùfáà àwọn ọlọ́run àjèjì tó wà ní Júdà ni iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn. Àwọn àlùfáà ọmọ Léfì tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn àìmọ́ pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti sìn nídìí pẹpẹ Jèhófà, ó sì sọ gbogbo àwọn ibi gíga tí wọ́n kọ́ lákòókò tí Sólómọ́nì Ọba wà lórí ìtẹ́ di ibi tí kò yẹ fún ìjọsìn mọ́. Àfọ̀mọ́ náà tún nasẹ̀ dé ìpínlẹ̀ tí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì wà tẹ́lẹ̀, èyí tí àwọn ará Ásíríà ti kọ́kọ́ ṣẹ́gun (740 ṣááju Sànmánì Tiwa).
Ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tí “ènìyàn Ọlọ́run kan” tí a kò dárúkọ rẹ̀ ti sọ ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún ṣáájú, Jòsáyà dáná sun eegun àwọn àlùfáà Báálì lórí pẹpẹ tí Ọba Jèróbóámù Kìíní tẹ́ sí Bẹ́tẹ́lì. Ó mú gbogbo àwọn ibi gíga kúrò níbẹ̀ àti kúrò láwọn ìlú ńlá mìíràn, ó sì fi àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rúbọ lórí pẹpẹ tí àwọn fúnra wọn tí máa ń rúbọ.—1 Àwọn Ọba 13:1-4; 2 Àwọn Ọba 23:4-20.
Wọ́n Ṣe Ìrékọjá Kíkọyọyọ
Ìgbésẹ̀ tí Jòsáyà gbé láti gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ ní ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá. Níwọ̀n ìgbà tí ọba náà bá wà láàyè, yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àwọn ènìyàn náà “kò yà kúrò nínú títọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn lẹ́yìn.” (2 Kíróníkà 34:33) Báwo sì ni Jòsáyà ṣe lè gbàgbé ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kejìdínlógún ìṣàkóso rẹ̀?
Ọba pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ ṣe ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé májẹ̀mú [tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí].” (2 Àwọn Ọba 23:21) Inú Jòsáyà dùn láti rí báwọn ènìyàn náà ṣe dáhùn lọ́nà rere. Òun alára fi ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] àwọn ẹran Ìrékọjá àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] màlúù ṣe ìtìlẹyìn fún àṣeyẹ yìí. Ìrékọjá yìí mà kọyọyọ o! Ní ti ohun tí wọ́n fi rúbọ, bí wọ́n ṣe ṣètò rẹ̀ dáradára, àti ní ti iye àwọn olùjọ́sìn, ó ju Ìrékọjá èyíkéyìí lọ tí wọ́n tíì ṣe láti ìgbà ayé wòlíì Sámúẹ́lì.—2 Àwọn Ọba 23:22, 23; 2 Kíróníkà 35:1-19.
Ìdárò Ikú Rẹ̀ Ga
Jòsáyà ṣàkóso bí ọba rere fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n yòókù tó lò lórí ìtẹ́ (659 sí 629 ṣááju Sànmánì Tiwa). Ní apá ìparí ìṣàkóso rẹ̀, ó gbọ́ pé Fáráò Nékò fẹ́ gba Júdà kọjá láti lọ dábùú àwọn ọmọ ogun Bábílónì, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣèrànwọ́ fún ọba Ásíríà ní Kákémíṣì lẹ́bàá Odò Yúfírétì. Fún àwọn ìdí kan tí a kò mọ̀, Jòsáyà jáde lọ bá ará Íjíbítì náà jà. Nẹ́kò rán àwọn ońṣẹ́ sí i pé: “Fà sẹ́yìn fún ire ara rẹ nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, má sì jẹ́ kí ó run ọ́.” Ṣùgbọ́n Jòsáyà dọ́gbọ́n para dà, ó sì gbìyànjú láti dá àwọn ará Íjíbítì padà ní Mẹ́gídò.—2 Kíróníkà 35:20-22.
Ó mà ṣe fún ọba Júdà o! Àwọn ọ̀tá ta á lọ́fà, ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbé mi sọ̀ kalẹ̀, nítorí mo ti gbọgbẹ́ gidigidi.” Wọ́n gbé Jòsáyà kúrò nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n gbé e sínú òmíràn, wọ́n sì kọrí sí Jerúsálẹ́mù. Níbẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé bí wọn ṣe ń bọ̀ ní ìlú ńlá náà ni Jòsáyà mí èémí àmíkẹ́yìn. Àkọsílẹ̀ onímìísí náà sọ pé: “Bí ó ṣe kú nìyẹn, tí a sì sin ín sí itẹ́ àwọn baba ńlá rẹ̀; gbogbo Júdà àti Jerúsálẹ́mù sì ń ṣọ̀fọ̀ Jòsáyà.” Jeremáyà pàápàá sun rárà fún un, wọ́n sì ń fi orúkọ ọba náà kọ àwọn orin arò níbi àwọn àṣeyẹ pàtàkì lẹ́yìn ìyẹn.—2 Kíróníkà 35:23-25.
Lóòótọ́, àṣìṣe ńlá ni Jòsáyà Ọba ṣe nígbà tó lọ bá àwọn ará Íjíbítì jagun. (Sáàmù 130:3) Síbẹ̀síbẹ̀, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ fún ìjọsìn tòótọ́ jẹ́ kí ó rí ojú rere Ọlọ́run. Ẹ ò rí bí ìgbésí ayé Jòsáyà ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń fi ojú rere hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùfọkànsìn tí wọ́n ní ọkàn-àyà rírẹlẹ̀!—Òwe 3:34; Jákọ́bù 4:6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Jòsáyà Ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé fi taratara wá Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Jòsáyà pa àwọn ibi gíga run, ó sì gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ