Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkéde Ìjọba Ọlọ́run ní Àwọn Erékùṣù Fíjì

Kíkéde Ìjọba Ọlọ́run ní Àwọn Erékùṣù Fíjì

Àwa Jẹ́ Irú Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́

Kíkéde Ìjọba Ọlọ́run ní Àwọn Erékùṣù Fíjì

NÍGBÀ kan rí, Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa ojú ọ̀nà méjì. Ọ̀kan gbòòrò, ṣùgbọ́n ikú lòpin ẹ̀. Èkejì há, àmọ́ ìyè ló yọrí sí ní tirẹ̀. (Mátíù 7:13, 14) Jèhófà Ọlọ́run ṣètò pé kí a wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní gbogbo ayé kó lè ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti yan ọ̀nà tó tọ́. (Mátíù 24:14) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn èèyàn níbi gbogbo ń fetí sí ìhìn rere Ìjọba náà, àwọn kan sì ń yan ìyè nípa dídi “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) A fẹ́ kí ẹ kà nípa bí àwọn kan ṣe yan ìyè ní Fíjì àtàwọn erékùṣù míì tó wà nítòsí rẹ̀ ní Gúúsù Pàsífíìkì.

Wọ́n Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Mere ṣì wà níléèwé nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìhìn rere Ìjọba náà lọ́dún 1964. Nítorí ibi àdádó tó wà, ní erékùṣù kan tó jìn, kò fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀. Àmọ́ nígbà tó wá yá ṣá, ó jèrè ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì. Nígbà yẹn, ó ti fẹ́ ọkùnrin kan tó jẹ́ olóyè ní abúlé rẹ̀. Nítorí ìpinnu Mere láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì, ọkọ rẹ̀ àtàwọn ìbátan rẹ̀ fojú Mere rí màbo, àwọn ará abúlé sì ń pẹ̀gàn rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe batisí ní 1991.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ọkàn Josua, ọkọ Mere, bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, àní ó ń jókòó tì wọ́n nígbà tí Mere bá ń bá àwọn ọmọ wọn jíròrò látinú Bíbélì. Ni Josua bá pa Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì tì. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí olóyè, òun ṣì ni alága ìpàdé abúlé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn ará abúlé wá bẹ̀rẹ̀ sí ka Josua sí ọ̀dàlẹ̀, nítorí pé Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìgbésí ayé àwọn ará abúlé ní Fíjì. Nítorí náà, pásítọ̀ àdúgbò yẹn sọ fún Josua pé kó padà sínú ẹ̀sìn rẹ̀ àtijọ́.

Josua fi ìgboyà sọ fún un pé òun àti ìdílé òun ti yan ohun tí àwọn fẹ́, àwọn sì ti pinnu láti sin Jèhófà Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Nínú ìpàdé abúlé kan tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà, baálẹ̀ pàṣẹ pé kí Josua àti ìdílé rẹ̀ káńgárá wọn, kí wọ́n sì fi abúlé náà sílẹ̀. Ọjọ́ méje péré ni wọ́n fún wọn láti fi jáde kúrò ní erékùṣù náà àti kúrò ní ilé wọn, ilẹ̀ wọn, kí wọ́n sì fi ohun ọ̀gbìn wọn sílẹ̀—àní, gbogbo ohun tí wọ́n ní láyé wọn.

Kíá làwọn ará nípa tẹ̀mí, láti erékùṣù mìíràn, gba ọ̀ràn Josua àti ìdílé rẹ̀ kanrí, wọ́n bá wọn wá ibi tí wọn ó máa gbé àti ilẹ̀ tí wọn ó fi dáko. Josua àti àkọ́bí rẹ̀ ọkùnrin ti ṣe batisí báyìí, ọmọkùnrin rẹ̀ mìíràn sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere náà tí kò tíì ṣèrìbọmi. Láìpẹ́ yìí ni Mere forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé (olùpòkìkí Ìjọba náà alákòókò kíkún). Ìpinnu wọn láti sin Jèhófà yọrí sí pípàdánù ipò àti àwọn nǹkan ìní ti ara, ṣùgbọ́n bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, bíńtín ni wọ́n ka nǹkan wọ̀nyí sí ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí wọ́n ti jèrè.—Fílípì 3:8.

Yíyàn Kan Tó Wé Mọ́ Ẹ̀rí Ọkàn

Yíyàn láti tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn téèyàn ti fi Bíbélì kọ́ ń béèrè ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Bọ́ràn ṣe rí gan-an nìyẹn fún Suraang, ọ̀dọ́bìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí, tó ń gbé ní Tarawa, tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Kiribati. Suraang sọ pé kí wọ́n jọ̀ọ́ yọ̀ǹda òun tí iṣẹ́ bá ti kan apá kan lára iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi nọ́ọ̀sì ní ọsibítù. Àmọ́ wọn ò gbà fún un, wọ́n sì tìtorí èyí rán an lọ síbi tí yóò ti lọ máa bójú tó ibùdó ìṣègùn kékeré kan ní erékùṣù kan tó wà ní àdádó, níbi tí kò ti ní fojú gán-án-ní àwọn mẹ́ńbà ẹ̀sìn rẹ̀.

Ní erékùṣù yẹn, àṣà wọn ni pé kí ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọ rú ẹbọ sí “ẹbọra” àdúgbò náà. Àwọn èèyàn náà gbà pé ẹni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ á lọ sí i. Níwọ̀n bí Suraang kò ti gbà pé kí wọ́n ṣe ààtò ìbọ̀rìṣà yìí fún òun àti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àwọn ará abúlé ń retí ìgbà tí ẹbọra tí inú ń bí náà yóò wá lu òun tàbí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pa. Nígbà tí nǹkan kan ò ṣe Suraang, ọ̀pọ̀ àǹfààní wá ṣí sílẹ̀ fún un láti jẹ́rìí fún wọn dáadáa.

Àmọ́ ìdánwò Suraang kò tíì tán o. Àwọn ọkùnrin kan ní erékùṣù yẹn gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ fa ojú àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó bá wá sí àdúgbò yẹn mọ́ra, láti lè bá wọn ṣèṣekúṣe. Ṣùgbọ́n Suraang dènà gbogbo ìlọ̀kulọ̀ tí wọ́n fẹ́ máa fi lọ̀ ọ́, ó dúró ṣinṣin nínú ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run. Kódà, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wákàtí mẹ́rìnlélógún ló gbọ́dọ̀ fi wà lárọ̀ọ́wọ́tó, nítorí a kì í bàá mọ̀ bí ẹnì kan bá ń fẹ́ ìtọ́jú.

Ṣáájú àkókò àpèjẹ kan tí wọ́n fi yẹ́ Suraang sí nígbà tó ń múra àtifi erékùṣù náà sílẹ̀, àwọn àgbààgbà abúlé náà sọ pé òun ni ojúlówó míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ bẹ àwọn wò. Nítorí ìdúróṣinṣin rẹ̀ fún àwọn ìlànà Bíbélì, àwọn mìíràn ní erékùṣù náà ti ń fìfẹ́ hàn sí ìhìn Ìjọba náà.

Àwọn Ìpèníjà Tó Ṣeé Fojú Rí

Nítorí ibi àdádó tí àwọn abúlé kan wà, àwọn èèyàn Jèhófà ní láti tiraka gan-an kí ó lè ṣeé ṣe fún wọn láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, kí wọ́n sì lè pésẹ̀ sáwọn ìpàdé Kristẹni. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin—ọkùnrin kan àti obìnrin mẹ́ta—tó ti ṣe batisí, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n máa ń rin ìrìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ní tàlọ-tàbọ̀ nítorí àtipésẹ̀ sáwọn ìpàdé. Odò mẹ́ta ni wọ́n ń là kọjá nígbà tí wọ́n bá ń lọ àti nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀. Nígbà tí odò bá kún, arákùnrin náà ló máa kọ́kọ́ wẹ̀ kọjá, ó máa ń gbé ìkòkò ìdáná ńlá kan tí wọ́n kó àwọn àpò, ìwé, àti aṣọ tí wọ́n máa wọ̀ nípàdé sí. Á tún wá wẹ̀ padà láti lọ ran àwọn arábìnrin mẹ́ta wọ̀nyẹn lọ́wọ́.

Àwùjọ kékeré mìíràn, tó máa ń lọ sípàdé ní erékùṣù àdádó kan táa ń pè ní Nonouti ní Kiribati, ń kojú àwọn ìṣòro mìíràn. Ilé tí wọ́n ń lò kò gbà ju èèyàn méje sí mẹ́jọ péré lọ. Ńṣe làwọn yòókù tó bá wá máa ń jókòó síta, tí wọ́n á sì máa yọjú wo inú ilé lára àwọn ògiri táa fi wáyà oníhò wínníwínní ṣe. Ojútáyé gbáà ni ibi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé jẹ́ fáwọn ará abúlé, bí wọ́n ti ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ láti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọn gàgàrà-gàgàrà. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé àwọn èèyàn ló ṣeyebíye lójú Ọlọ́run ní tòótọ́, kì í ṣe ilé. (Hágáì 2:7) Àgbàlagbà ni arábìnrin kan ṣoṣo tó ti ṣe batisí ní erékùṣù náà, kò sì lè rin ọ̀nà jíjìn. Ṣùgbọ́n, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan, tó jẹ́ akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi ló ń ràn án lọ́wọ́, tó ń fi ọmọlanke tì í kiri. Wọ́n mà mọrírì òtítọ́ o!

Àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún [2,100], tí wọ́n ń sìn ní àwọn erékùṣù Fíjì ti pinnu láti máa bá a nìṣó ní kíkéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó sì dá wọn lójú pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ṣì ń bọ̀ wá di “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ọsirélíà

Fíjì