Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Láìpẹ́ Ayé Téèyàn Ò Ti Ní Bọ́hùn Mọ́ Yóò Dé

Láìpẹ́ Ayé Téèyàn Ò Ti Ní Bọ́hùn Mọ́ Yóò Dé

Láìpẹ́ Ayé Téèyàn Ò Ti Ní Bọ́hùn Mọ́ Yóò Dé

HÍLÀHÍLO inú ìgbésí ayé túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn ohun tó sì ń mú kéèyàn bọ́hùn pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní. Nígbà tí gbogbo rẹ̀ bá tojú súni, ó lè ṣòro láti ṣàkóso bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára wa. Àní sẹ́, àwọn tí ìyè wù pàápàá lè di aláìláyọ̀, kí ọ̀ràn ara wọn sú wọn pátápátá! Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Ní ayé ìgbàanì, wòlíì Mósè rẹ̀wẹ̀sì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi sọ fún Ọlọ́run pé: “Jọ̀wọ́ kúkú pa mí dànù, bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, má sì ṣe jẹ́ kí n fojú rí ìyọnu àjálù mi.” (Númérì 11:15) Nígbà tí Èlíjà ń sá fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó kígbe pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn [ìwàláàyè] mi kúrò.” (1 Àwọn Ọba 19:4) Wòlíì Jónà sì sọ pé: “Jèhófà, jọ̀wọ́, gba ọkàn mi kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí, kí n kú sàn ju kí n wà láàyè.” (Jónà 4:3) Àmọ́, kò sí ẹni tó pa ara rẹ̀ nínú Mósè, Èlíjà, àti Jónà. Gbogbo wọn ló mọ àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.” (Ẹ́kísódù 20:13) Nítorí ìgbàgbọ́ lílágbára tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run, wọ́n mọ̀ pé nínú ipòkípò téèyàn bá wà, ìrètí ṣì ń bẹ, àti pé ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Àwọn ìṣòro táa wá ń dojú kọ lónìí ńkọ́? Yàtọ̀ sí másùnmáwo tàbí àwọn ìṣòro ti ara táa máa ń ní, àwọn ìgbà mìíràn wà táa ní láti fojú winá ìwà ìkà látọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ńbà ìdílé, àwọn aládùúgbò, tàbí àwọn ẹlẹgbẹ́ wa. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n kún “fún gbogbo àìṣòdodo, ìwà burúkú, ojúkòkòrò, ìwà búburú, wọ́n kún fún ìlara, ìṣìkàpànìyàn, gbọ́nmi-si omi-ò-to, ẹ̀tàn, inú burúkú, wọ́n jẹ́ asọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́, àwọn asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, olùkórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, onírera, ajọra-ẹni-lójú, olùhùmọ̀ ohun aṣeniléṣe, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìní òye, olùyẹ àdéhùn, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìláàánú.” (Róòmù 1:28-31) Wíwà láàárín irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ lè máyé súni. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́?

Mímúratán Láti Fetí Sílẹ̀

Ìpọ́njú àti ìjìyà lè da orí èèyàn rú. Ọlọ́gbọ́n ọkùnrin náà sọ pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ fọ̀rọ̀ ẹni tó ń sọ pé òun fẹ́ pa ara òun ṣeré rárá. Àwọn ìṣòro tó ní, yálà ní ti ìmí ẹ̀dùn ni o, tàbí ti ara, bóyá ti èrò orí ni o, tàbí ti ẹ̀mí, lè jẹ́ ohun tó máa gba àfiyèsí kánjúkánjú. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìtọ́jú tí àwọn amọṣẹ́dunjú ń fúnni máa ń yàtọ̀ síra, ìpinnu ara ẹni sì pọndandan lórí ọ̀ràn irú ìtọ́jú tó yẹ láti gbà.—Gálátíà 6:5.

Ohun yòówù tó lè mú kí ẹnì kan máa ronú àtipa ara rẹ̀, rírí ẹnì kan tó lóye, tó ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn, tó sì tún ní sùúrù tí ó lè finú hàn lè yí ọ̀ràn náà padà. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ṣe tán láti fetí sílẹ̀ lè ṣèrànwọ́. Ní àfikún sí ìgbatẹnirò àti inúure, àwọn èrò tí ń gbéni ró látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣèrànwọ́ gan-an fún àwọn tó ti sọ̀rètí nù.

Ìrànlọ́wọ́ Tẹ̀mí fún Àwọn Tó Sorí Kọ́

Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí bí Bíbélì kíkà ṣe lè fúnni níṣìírí tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé táa fi ń wo ìdààmú ọpọlọ, síbẹ̀ ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọyì ìwàláàyè. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé ẹni; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníwàásù 3:12, 13) Yàtọ̀ sí iṣẹ́ tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ tó sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé nítumọ̀, àwọn nǹkan tí kì í sábàá gba àfiyèsí wa—bí afẹ́fẹ́ atunilára, ìmọ́lẹ̀ oòrùn, òdòdó, àwọn igi, àti àwọn ẹyẹ—jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa láti gbádùn.

Ohun tó tiẹ̀ wá fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ ni ìdánilójú tí Bíbélì fúnni pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ bìkítà nípa wa. (Jòhánù 3:16; 1 Pétérù 5:6, 7) Onísáàmù sọ ọ́ lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà, ẹni tí ń bá wa gbé ẹrù lójoojúmọ́, Ọlọ́run tòótọ́ ìgbàlà wa.” (Sáàmù 68:19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rò pé a ò já mọ́ nǹkankan àti pé a ò tóótun, síbẹ̀ Ọlọ́run ké sí wa pé kí a máa gbàdúrà sí òun. Kí ó dá wa lójú ṣáká pé kò sí ẹni tó fi ìrẹ̀lẹ̀ àti òtítọ́ inú béèrè fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí a óò ta nù.

Kò sẹ́ni tó lè retí pé òun lè wà nínú ayé táa wà yìí láìní ìṣòro kankan. (Jóòbù 14:1) Ṣùgbọ́n òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé pípa ara ẹni kì í ṣe ọ̀nà tó tọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wọn. Ronú nípa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ran onítúbú tó ti gbékútà lọ́wọ́, ẹni tó jẹ́ pé bó “ti jí lójú oorun, tí ó sì rí i pé àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì . . . fẹ́ pa ara rẹ̀, ó lérò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sá lọ.” Lójú ẹsẹ̀, onítúbú náà ti parí èrò sí pé pípa ara ẹni sàn ju kíkú ikú ẹ̀sín tàbí jíjoró kú nítorí ìkùnà rẹ̀. Àpọ́sítélì náà kígbe pé: “Má ṣe ara rẹ lọ́ṣẹ́, nítorí pé gbogbo wa wà níhìn-ín!” Pọ́ọ̀lù kò fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ sórí gbólóhùn yẹn. Àní òun àti Sílà tu onítúbú náà nínú, wọ́n sì dáhùn ìbéèrè tó béèrè pé: “Ẹ̀yin ọ̀gá, kí ni kí n ṣe láti rí ìgbàlà?” Wọ́n dáhùn pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, ìwọ yóò sì rí ìgbàlà, ìwọ àti agbo ilé rẹ.” Wọ́n wá sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún òun àti agbo ilé rẹ̀, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé “òun àti àwọn tirẹ̀ ni a sì batisí láìjáfara.” Onítúbú náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ yọ̀ gidigidi, ìgbésí ayé sì ní ìtumọ̀ tuntun sí wọn.—Ìṣe 16:27-35.

Ẹ wo bó ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó lóde òní láti mọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló ń fa ìwà ibi! Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ẹ̀mí búburú kan, “tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì,” ló “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Àmọ́ àkókò rẹ̀ ti ń tán lọ. (Ìṣípayá 12:9, 12) Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò fòpin sí gbogbo wàhálà tí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti mú wá sórí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé. Nígbà náà ni ayé tuntun òdodo tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò mú àwọn ohun tó ń fa àìnírètí àti ìpara ẹni kúrò títí láé.—2 Pétérù 3:13.

Ìtùnú fún Àwọn Tó Ń Wá Ìrànlọ́wọ́

Kódà nísinsìnyí pàápàá, àwọn tó sorí kọ́ lè rí ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́. (Róòmù 15:4) Onísáàmù náà Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” (Sáàmù 51:17) Lóòótọ́, a máa ń bá àwọn àdánwò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ pàdé, àìpé sì máa ń dà wá láàmú. Àmọ́, gbígba ìmọ̀ pípéye Baba wa ọ̀run tó jẹ́ onínúure, tó nífẹ̀ẹ́, tó sì tún ń gba tẹni rò yóò fún wa ní ìdánilójú pé a ṣeyebíye lójú rẹ̀. Ọlọ́run lè di Ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti Ẹni pàtàkì tó ń fún wa nítọ̀ọ́ni. Bí a bá mú àjọṣe tó dán mọ́rán dàgbà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, kò ní já wa kulẹ̀ láé. Ẹlẹ́dàá wa sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17.

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ti ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, ìsoríkọ́ tí kò gbóògùn ti sọ Mara di aláìlera nígbà tí jàǹbá ọkọ̀ pa ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí. a Jìnnìjìnnì bá a, ó sì gbìyànjú àtipa ara rẹ̀. Àmọ́, nísinsìnyí, ojoojúmọ́ ló máa ń jí láàárọ̀ kùtù hàì, tó máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé rẹ̀. Ó máa ń gbádùn gbígbọ́ orin àti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ìrètí pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà” ti mú lára oró tí ikú òjijì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n dá a kúrò, ó sì ti fún ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run lókun. (Ìṣe 24:15) Níwọ̀n bí Mara ò ti ní in lọ́kàn pé òun ó dà bí áńgẹ́lì ní ọ̀run, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 37:11 ti wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”

Obìnrin ará Brazil mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sandra, ṣiṣẹ́ àṣekára kí òun lè jẹ́ ìyá àtàtà fún àwọn ọmọ òun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ó sọ pé: “Ọwọ́ mi dí gan-an débi pé mi ò tiẹ̀ ronú nípa gbígbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ rárá nígbà tí baba mi kú lójijì, tó sì jẹ́ pé àárín àkókò kan náà ni mo rí i pé ọkọ mi ń yan obìnrin kan lálè.” Bí Sandra ṣe bọ́hùn nìyẹn, tó sì gbìyànjú àtipa ara rẹ̀. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti bọ́ nínú ìṣòro rẹ̀? Ìmọrírì tó ní fún àwọn nǹkan tẹ̀mí ni. Ó sọ pé: “Ní alaalẹ́ kí n tó lọ sùn, mo máa ń ka Bíbélì, mo si máa ń gbìyànjú àtifi ara mi sípò àwọn tí mo ń ka ìtàn wọn. Mo tún máa ń ka àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àwọn ìtàn ìgbésí ayé ni mo máa ń gbádùn jù lọ nítorí pé wọ́n máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti forí ti àwọn ìṣòro ìgbésí ayé tèmi.” Nítorí ó mọ̀ pé Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ó ti kọ́ bí a ṣe ń sọ ohun náà gan-an tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn ẹni jáde nínú àdúrà.

Ọjọ́ Ọ̀la Tí A Kò Ti Ní Bọ́hùn Mọ́ Ń Bọ̀

Ẹ ò rí i pé ìtùnú ńlá ló jẹ́ láti mọ̀ pé ìrora ènìyàn kò ní máa bá lọ bẹ́ẹ̀! Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, àwọn ọmọdé àtàgbà tí wọ́n ń fojú winá ìwà ipá, àwọn tí wọ́n ń rẹ́ jẹ, tàbí àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀tanú sí yóò yọ̀. Báa ṣe sọ ọ́ nínú sáàmù kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, Jésù Kristi, Ọba tí Jèhófà yàn, “yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́.” Láfikún sí i, “yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.” Àní “yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.”—Sáàmù 72:12-14.

Àkókò tí àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn yóò ní ìmúṣẹ ti sún mọ́lé. Ǹjẹ́ èrò àtigbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀ wù ọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kóo kún fún ìdùnnú, kí o sì fojú ribiribi wo ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Tóo bá sì ń ṣàjọpín àwọn ìlérí tí ń tuni nínú wọ̀nyí látinú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ẹlòmíràn, o lè mú ayọ̀ ńlá wá sínú ìgbésí ayé àwọn tó ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ nínú ayé tí kò sí ojú àánú àti ìfẹ́ yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú wa láyọ̀ lóde òní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé o ń wọ̀nà fún ayé tí a kò ti ní bọ́hùn mọ́?