“Wákàtí Náà Ti Dé!”
“Wákàtí Náà Ti Dé!”
“Wákàtí [rẹ̀] ti dé fún [un] láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba.”—JÒHÁNÙ 13:1.
1. Bí Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Tiwa ti sún mọ́lé, ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wo ló gbòde kan ní Jerúsálẹ́mù, èé sì ti ṣe?
NÍGBÀ batisí Jésù lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, ó bẹ̀rẹ̀ sí tọ ipa ọ̀nà kan tí yóò já sí “wákàtí” ikú rẹ̀, àjíǹde rẹ̀, àti ìṣelógo rẹ̀. Ìgbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Tiwa ti dé báyìí. Kìkì ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ló ti kọjá látìgbà tí Sànhẹ́dírìn, tí í ṣe ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù ti gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù. Nígbà tí Jésù gbọ́ nípa ohun tí wọ́n ń gbìmọ̀ láti ṣe, bóyá látẹnu Nikodémù, mẹ́ńbà Sànhẹ́dírìn tó ń bá a ṣọ̀rẹ́, ó fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, ó sì lọ sí àgbègbè àrọko tó wà ní ìsọdá Odò Jọ́dánì. Bí Àjọyọ̀ Ìrékọjá ti ń sún mọ́lé, ńṣe làwọn èèyàn ń ti ìgbèríko wọ́ wá sí Jerúsálẹ́mù, ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nípa Jésù sì gba gbogbo ìlú kan. Àwọn èèyàn ń bi ara wọn pé: “Kí ni èrò yín? Pé òun kì yóò wá sí àjọyọ̀ náà rárá ni bí?” Àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí tún dá tiwọn kún inú-fu-ẹ̀dọ̀-fu náà, nípa pípàṣẹ pé kí ẹnikẹ́ni tó bá rí Jésù wá sọ ibi tó wà fáwọn.—Jòhánù 11:47-57.
2. Kí ni Màríà ṣe tó fẹ́ fa àríyànjiyàn, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tó fi gbèjà rẹ̀ fi hàn pé Jésù mọ kí ni nípa “wákàtí rẹ̀”?
2 Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù Nísàn, ìyẹn ọjọ́ mẹ́fà ṣáájú Ìrékọjá, Jésù tún padà dé sí àgbègbè Jerúsálẹ́mù. Ó wá sí Bẹ́tánì—ìlú ìbílẹ̀ Màtá, Màríà, àti Lásárù tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n—ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta sí Jerúsálẹ́mù. Alẹ́ ọjọ́ Friday ni, ibẹ̀ sì ni Jésù ti ṣe Sábáàtì. Alẹ́ ọjọ́ kejì ni Màríà ń da òróró onílọ́fínńdà tó níye lórí gan-an sí i lára, táwọn ọmọlẹ́yìn sì bẹ̀rẹ̀ sí ta kò ó. Jésù dáhùn pé: “Jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́, kí ó lè pa ààtò àkíyèsí yìí mọ́ nítorí ọjọ́ ìsìnkú mi. Nítorí ẹ̀yin ní àwọn òtòṣì nígbà gbogbo pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kì yóò ní nígbà gbogbo.” (Jòhánù 12:1-8; Mátíù 26:6-13) Jésù mọ̀ pé “wákàtí òun ti dé fún òun láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 13:1) Ní ọjọ́ márùn-ún sí i, yóò “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Máàkù 10:45) Nítorí náà, Jésù kò fi nǹkan falẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń ṣe àti ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni. Ẹ wo àpẹẹrẹ gíga lọ́lá tí èyí jẹ́ fún wa báa ti ń fi ìháragàgà dúró de òpin ètò àwọn nǹkan yìí! Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e gan-an yẹ̀ wò.
Ọjọ́ Tí Jésù Fi Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Wọlé
3. (a) Báwo ni Jésù ṣe wọ Jerúsálẹ́mù ní Sunday, ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Nísàn, kí sì ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó yí i ká ṣe? (b) Kí ni ìdáhùn tí Jésù fún àwọn Farisí tí ń ṣàròyé nípa ogunlọ́gọ̀ náà?
3 Sunday, ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Nísàn, ni Jésù fi ayọ̀ ìṣẹ́gun wọ Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe ń sún mọ́ ìlú ńlá náà—tó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ìmúṣẹ Sekaráyà orí kẹsàn-án, ẹsẹ kẹsàn-án—ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó yí i ká tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sójú ọ̀nà, àwọn míì sì gé ẹ̀ka igi, wọ́n tẹ́ ẹ sílẹ̀. Wọ́n ń kígbe pé: “Alábùkún ni Ẹni tí ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!” Àwọn Farisí kan tó wà láàárín ogunlọ́gọ̀ náà fẹ́ kí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí. Àmọ́, Jésù fèsì pé: “Mo sọ fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá dákẹ́, àwọn òkúta yóò ké jáde.”—Lúùkù 19:38-40; Mátíù 21:6-9.
4. Èé ṣe tí arukutu fi sọ ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Jésù wọ ìlú náà?
4 Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ nínú ogunlọ́gọ̀ náà rí Jésù nígbà tó jí Lásárù dìde. Wàyí o, wọn ò yéé sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa iṣẹ́ ìyanu yẹn. Nítorí náà, bí Jésù ṣe wọ Jerúsálẹ́mù báyìí, ṣe ni arukutu sọ ní gbogbo ìlú yẹn. Àwọn èèyàn wá ń béèrè pé: “Ta ni èyí?” Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà sì ń sọ pé: “Èyí ni wòlíì náà Jésù, láti Násárétì ti Gálílì!” Nígbà táwọn Farisí rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n figbe ta pé: “Ayé ti wọ́ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”—Mátíù 21:10, 11; Jòhánù 12:17-19.
5. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wọ tẹ́ńpìlì lọ?
5 Gẹ́gẹ́ bí ìṣe Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà, nígbà tó wá sí Jerúsálẹ́mù, tẹ́ńpìlì ló gbà lọ tààrà láti kọ́ni. Àwọn afọ́jú àti arọ wá bá a níbẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn. Nígbà táwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé òfin rí èyí, tí wọ́n sì gbọ́ bí àwọn ọmọdékùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì ti ń ké jáde pé, “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!” inú bẹ̀rẹ̀ sí bí wọn. Wọ́n fi ẹ̀hónú sọ pé: “Ìwọ ha gbọ́ ohun tí àwọn wọ̀nyí ń sọ?” Jésù dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ kò tíì ka èyí rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde’?” Bí Jésù ti ń bá a nìṣó ní kíkọ́ni, ó fara balẹ̀ wo gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì.—Mátíù 21:15, 16; Máàkù 11:11.
6. Báwo ni ọ̀nà tí Jésù gbà wọ̀lú lọ́tẹ̀ yìí ṣe yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, èé sì ti ṣe?
6 Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńláǹlà wà nínú bí Jésù ṣe wọ̀lú lọ́tẹ̀ yìí àti bó ṣe wọ̀lú ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn! Nígbà yẹn, Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn ló wá ṣe ní Jerúsálẹ́mù, ó sì wá “kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ní bòókẹ́lẹ́.” (Jòhánù 7:10) Ó sì máa ń wá ọ̀nà àtisá lọ, tó bá di pé ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ló yan fanda-fanda wọ ìlú tí wọ́n ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé bí wọ́n bá rí i kí wọ́n mú un! Kì í tún ṣe àṣà Jésù láti máa polongo ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà. (Aísáyà 42:2; Máàkù 1:40-44) Kì í fẹ́ káwọn èèyàn máa kígbe òun kiri tàbí kí àsọdùn ìròyìn alátẹnudẹ́nu máa jà ràn-ìn nípa òun. Àmọ́, nígbà tí àwọn ogunlọ́gọ̀ wá ń polongo ní gbangba báyìí pé òun ni Ọba àti Olùgbàlà—èyíinì ni Mèsáyà náà—ńṣe ló tún kọ̀ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó ń sọ fún un pé kó pa wọ́n lẹ́nu mọ́! Kí ló fa ìyípadà yìí? Nítorí pé “wákàtí náà ti dé tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo,” gẹ́gẹ́ bí Jésù ti kéde lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e gan-an.—Jòhánù 12:23.
Ìgbésẹ̀ Àìṣojo—Lẹ́yìn Náà Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Ń Gbẹ̀mí Là
7, 8. Báwo ni àwọn ìgbésẹ̀ Jésù ní ọjọ́ kẹwàá oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ṣe jọ ohun tó ṣe nínú tẹ́ńpìlì nígbà Ìrékọjá ọdún 30 Sànmánì Tiwa?
7 Gbàrà tó wọ tẹ́ńpìlì ní Monday, ọjọ́ kẹwàá oṣù Nísàn, ńṣe ni Jésù gbégbèésẹ̀ lórí ohun tó rí ní ọ̀sán ọjọ́ tó ṣáájú. Ó bẹ̀rẹ̀ sí “lé àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà; kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé nǹkan èlò la tẹ́ńpìlì kọjá.” Ó bá àwọn oníwà àìtọ́ náà wí, pé: “A kò ha kọ ọ́ pé, ‘Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’? Ṣùgbọ́n ẹ ti sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”—Máàkù 11:15-17.
8 Ìgbésẹ̀ tí Jésù gbé yìí jọ ohun tó ṣe ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, nígbà tó wá sí tẹ́ńpìlì nígbà Ìrékọjá ọdún 30 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ ìbáwí ti ọ̀tẹ̀ yìí múná ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Lọ́tẹ̀ yìí, “ọlọ́ṣà” ló pe àwọn oníṣòwò tó wà nínú tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 19:45, 46; Jòhánù 2:13-16) Ohun tí wọ́n sì jẹ́ nìyẹn lóòótọ́, nítorí pé ńṣe ni wọ́n ń ṣáwó lé àwọn èèyàn tó wá ra àwọn ẹran fún ìrúbọ. Àwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé òfin, àtàwọn sàràkí-sàràkí láàárín àwọn èèyàn náà gbọ́ ohun tí Jésù ń ṣe, nítorí náà wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti ṣekú pa á. Àmọ́ wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè rẹ́yìn Jésù, níwọ̀n bí gbogbo àwọn èèyàn ti ń wọ́ tọ̀ ọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, nítorí pé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ń ṣe wọ́n ní háà.—Máàkù 11:18; Lúùkù 19:47, 48.
9. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ni, kí ló sì sọ pé kí àwọn tó ń fetí sí òun nínú tẹ́ńpìlì ṣe?
9 Bí Jésù ti ń bá a nìṣó ní kíkọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, ó polongo pé: “Wákàtí náà ti dé tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó mọ̀ pé ọjọ́ díẹ̀ péré ló kù tí òun yóò fi wà láyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Lẹ́yìn tó sọ bí hóró àlìkámà kan ṣe ní láti kú kí ó tó lè sèso—ó ń fi èyí wé bí òun yóò ṣe kú, tí òun yóò sì di ọ̀nà táwọn èèyàn yóò fi rí ìyè àìnípẹ̀kun—Jésù wá sọ fún àwọn tó ń fetí sí i, pé: “Bí ẹnikẹ́ni yóò bá ṣe ìránṣẹ́ fún mi, kí ó tọ̀ mí lẹ́yìn, níbi tí mo bá sì wà, ibẹ̀ ni òjíṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú. Bí ẹnikẹ́ni yóò bá ṣèránṣẹ́ fún mi, Baba yóò bọlá fún un.”—Jòhánù 12:23-26.
10. Ojú wo ni Jésù fi wo ikú oró tó ń dúró dè é?
10 Bí Jésù ti ń ronú lórí ikú oró tí òun yóò kú ní ọjọ́ mẹ́rin péré sí i, ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wàyí o, ọkàn mi dààmú, kí ni èmi yóò sì sọ? Baba, gbà mí là kúrò nínú wákàtí yìí.” Àmọ́ ohun tó ń dúró de Jésù kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí nìyí tí mo fi wá sí wákàtí yìí.” Láìsí àní-àní, Jésù fara mọ́ gbogbo ètò tí Ọlọ́run ṣe. Ó ti pinnu láti jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run darí àwọn ìgbésẹ̀ òun títí dójú ikú ìrúbọ tóun máa tó kú. (Jòhánù 12:27) Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ fún wa—àpẹẹrẹ ìtẹríba ní kíkún fún ìfẹ́ Ọlọ́run!
11. Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fi kọ́ ogunlọ́gọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ ohùn kan látọ̀run?
11 Nítorí pé ó ká a lára gan-an pé ikú òun lè ba orúkọ rere Bàbá òun jẹ́, Jésù gbàdúrà pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún ogunlọ́gọ̀ tó kóra jọ pọ̀ ní tẹ́ńpìlì nígbà tí ohùn kan dún látọ̀run, tó polongo pé: “Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.” Olùkọ́ Ńlá náà lo àǹfààní yìí láti sọ fún ogunlọ́gọ̀ náà nípa ìdí tí wọ́n fi gbọ́ ohùn náà, àti ohun tí yóò jẹ́ ìyọrísí ikú òun, àti ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́. (Jòhánù 12:28-36) Jésù ti ṣe gudugudu méje láàárín ọjọ́ méjì tó ti kọjá yìí. Àmọ́ ọjọ́ mánigbàgbé ṣì ń bẹ níwájú.
Ọjọ́ Ìdálẹ́bi
12. Báwo làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe gbìyànjú láti dẹkùn mú Jésù ní Tuesday, ọjọ́ kọkànlá oṣù Nísàn, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
12 Ní Tuesday, ọjọ́ kọkànlá oṣù Nísàn, Jésù tún padà lọ sínú tẹ́ńpìlì láti lọ kọ́ni. Àwùjọ àwọn abínú-ẹni kóra jọ síbẹ̀. Àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà tọ́ka sí àwọn nǹkan tí Jésù ṣe lọ́jọ́ tó ṣáájú, wọ́n sì bi í pé: “Ọlá àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ta ní sì fún ọ ní ọlá àṣẹ yìí?” Èsì tí Àgbà Olùkọ́ yìí fún wọn mú ẹnu wọn wọhò, ó sì ṣe àpèjúwe mẹ́ta tó múná dóko—méjì lára àpèjúwe náà jẹ́ nípa ọgbà àjàrà, ọ̀kan sì jẹ́ nípa ayẹyẹ ìgbéyàwó—àpèjúwe wọ̀nyí sì tú àwọn alátakò yìí fó, ó fi hàn pé olubi gbáà ni wọ́n. Ọ̀rọ̀ tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọ̀nyí gbọ́ bí wọn nínú gan-an ni, wọ́n sì fẹ́ mú Jésù. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù àwọn ogunlọ́gọ̀ wọ̀nyí tún ń bà wọ́n, torí pé wòlíì ni wọ́n ka Jésù sí. Nítorí náà, wọ́n fẹ́ wá bí àwọn ṣe lè dọ́gbọ́n sún un sọ ohun tí wọ́n á fi lè sọ pé, ó yá, ẹ mú un. Àmọ́ ńṣe ni àwọn ìdáhùn Jésù mú wọn wọ̀ ṣin-in.—Mátíù 21:23-22:46.
13. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ nípa àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí?
13 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Òfin Ọlọ́run làwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí sọ pé àwọn fi ń kọ́ni, Jésù wá rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín, ni kí ẹ ṣe kí ẹ sì pa mọ́, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣe wọn, nítorí wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe.” (Mátíù 23:1-3) Ìdálẹ́bi ìtagbangba yìí mà gbóná o! Ṣùgbọ́n wọ́n ṣì máa gbọ́ dẹndẹ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Jésù. Ọjọ́ tó máa wọ tẹ́ńpìlì gbẹ̀yìn rèé, ó sì fi àìṣojo tú àṣírí wọn lóríṣiríṣi—ṣe ni ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń dún bí ààrá.
14, 15. Àwọn ìfibú mímúná janjan wo ni Jésù kéde lé àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí lórí?
14 Ẹ̀ẹ̀mẹfà ni Jésù polongo pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè!” Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣàlàyé, alágàbàgebè ni wọ́n nítorí pé wọ́n sé Ìjọba ọ̀run pa níwájú àwọn ènìyàn, wọn ò sì jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ wọlé ráyè wọlé. Àwọn alágàbàgebè wọ̀nyí ń la òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ kọjá láti sọ ẹnì kan di aláwọ̀ṣe, tí wọn yóò sì wá sọ ọ́ di ẹni tí yóò dojú kọ ìparun ayérayé. Wọ́n ò ka “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́,” ṣùgbọ́n wọ́n ń darí gbogbo àfiyèsí sórí sísan ìdá mẹ́wàá. Ohun tí wọ́n ń ṣe kò yàtọ̀ sí fífọ “òde ife àti àwopọ̀kọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún ìpiyẹ́ àti àìmọníwọ̀n,” ní ti pé wọ́n ti jẹrà nínú, àní wọ́n ti dómùkẹ̀, bí wọ́n tiẹ̀ dà bí olùfọkànsìn lóde. Síwájú sí i, wọ́n múra tán láti kọ́ sàréè àwọn wòlíì, kí wọ́n sì ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́, kí wọ́n lè pe àfiyèsí sí iṣẹ́ ọrẹ àánú tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ni “ọmọ àwọn tí wọ́n ṣìkà pa àwọn wòlíì.”—Mátíù 23:13-15, 23-31.
15 Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn alátakò rẹ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan nípa tẹ̀mí, ó sọ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú afinimọ̀nà.” Wọ́n jẹ́ afọ́jú ní ti ìwà rere nítorí pé wúrà inú tẹ́ńpìlì ṣe pàtàkì lójú wọn ju bí ibi ìjọsìn yẹn ti ṣe pàtàkì tó nípa tẹ̀mí. Jésù ṣì ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sì wá fi wọ́n bú lọ́nà tó múná jù lọ. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ejò, ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ ó ṣe sá kúrò nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?” Dájúdájú, ohun tí Jésù ń sọ fún wọn ni pé, nítorí ìwà burúkú wọn, ńṣe ni wọn yóò ṣègbé títí láé. (Mátíù 23:16-22, 33) Ǹjẹ́ kí àwa náà fi ìgboyà pòkìkí ìhìn Ìjọba náà, kódà tó bá kan títú ẹ̀sìn èké fó.
16. Bí wọ́n ṣe jókòó sórí Òkè Ólífì, àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì wo ni Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
16 Jésù wá fi tẹ́ńpìlì sílẹ̀ wàyí. Nígbà tó fẹ́ máa di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gun Òkè Ólífì lọ. Bí wọ́n ṣe jókòó síbẹ̀, Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun tẹ́ńpìlì àti àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan. Ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nasẹ̀ dé àkókò wa yìí. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù tún sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ mọ̀ pé ọjọ́ méjì sí i, ìrékọjá yóò wáyé, a ó sì fa Ọmọ ènìyàn léni lọ́wọ́ láti kàn án mọ́gi.”—Mátíù 24:1-14; 26:1, 2.
Jésù ‘Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tirẹ̀ Títí Dé Òpin’
17. (a) Nígbà Ìrékọjá lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni Jésù kọ́ àwọn méjìlá náà? (b) Àjọ̀dún wo ni Jésù dá sílẹ̀ lẹ́yìn tó lé Júdásì Ísíkáríótù jáde?
17 Láàárín ọjọ́ méjì tó tẹ̀ lé e—ìyẹn ọjọ́ kejìlá àti ìkẹtàlá oṣù Nísàn—Jésù kò jáde sí gbangba ní tẹ́ńpìlì. Àwọn aṣáájú ìsìn ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á, kò sì fẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tí kò ní jẹ́ kóun àtàwọn àpọ́sítélì òun jùmọ̀ ṣe Ìrékọjá. Bí oòrùn ṣe ń wọ̀ lọ́jọ́ Thursday ni ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn bẹ̀rẹ̀—èyí ni ọjọ́ ìkẹyìn tí Jésù lò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wà pa pọ̀ nínú ilé kan ní Jerúsálẹ́mù, níbi táa ṣètò pé kí wọ́n ti ṣe Ìrékọjá. Bí wọ́n ṣe ń gbádùn Ìrékọjá pa pọ̀, ó wẹ ẹsẹ̀ àwọn méjìlá náà láti kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tó dáa nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Lẹ́yìn tó lé Júdásì Ísíkáríótù jáde, ẹni tó ti gbà láti da Ọ̀gá rẹ̀ nítorí ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà—owó orí ẹrú kan lásán, ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Mósè—ni Jésù tó wá dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀.—Ẹ́kísódù 21:32; Mátíù 26:14, 15, 26-29; Jòhánù 13:2-30.
18. Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni Jésù tún fi tìfẹ́tìfẹ́ kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́, báwo ló sì ṣe múra wọn sílẹ̀ fún àtilọ rẹ̀ tó ti dé tán?
18 Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ Ìṣe Ìrántí, àwọn àpọ́sítélì wá bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn kíkankíkan nípa ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. Kàkà tí Jésù ì bá fi jágbe mọ́ wọn, ńṣe ló tún ń fi sùúrù kọ́ wọn nípa ìjẹ́pàtàkì ṣíṣèránṣẹ́ fáwọn ẹlòmíì. Nítorí pé ó mọrírì bí wọ́n ti dúró ti òun gbágbáágbá nígbà tóun wà nínú àdánwò, òun fúnra rẹ̀ wá bá wọn dá májẹ̀mú fún ìjọba kan. (Lúùkù 22:24-30) Jésù tún pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ti nífẹ̀ẹ́ wọn. (Jòhánù 13:34) Gbogbo bí Jésù ṣe dúró pẹ́ díẹ̀ nínú iyàrá yẹn ló ń fi tìfẹ́tìfẹ́ múra wọn sílẹ̀ fún àtilọ rẹ̀ tó ti dé tán. Ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀rẹ́ làwọn lọ́jọ́kọ́jọ́, ó fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n lo ìgbàgbọ́, ó sì ṣèlérí fún wọn pé wọ́n á rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. (Jòhánù 14:1-17; 15:15) Kí wọ́n tó fi ilé náà sílẹ̀, Jésù rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Bàbá rẹ̀ pé: “Wákàtí náà ti dé; ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo.” Ní tòótọ́, Jésù ti múra àwọn àpọ́sítélì sílẹ̀ fún àtilọ rẹ̀, ó sì dájú pé ó ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ títí dé òpin.’—Jòhánù 13:1; 17:1.
19. Èé ṣe tí làásìgbò fi dé bá Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì?
19 Ó jọ pé ó ti kọjá ààjìn òru pátápátá kó tó di pé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ dé ọgbà Gẹtisémánì. Kì í kúkú ṣòní kì í ṣàná lòun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti jọ ń lọ síbẹ̀. (Jòhánù 18:1, 2) Wákàtí ló kù tí wọ́n ń kà báyìí, kó tó di pé wọn ó pa Jésù gẹ́gẹ́ bí òkúùgbẹ́ ọ̀daràn. Làásìgbò tó dé bá a nítorí ríronú nípa ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí i àti bí èyí ṣe lè kó ẹ̀gàn bá Bàbá rẹ̀ kọjá sísọ, àní ó pọ̀ débi pé nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, òógùn tó ń kán lára rẹ̀ dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀. (Lúùkù 22:41-44) Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Wákàtí náà ti dé! . . . Wò ó! Afinihàn mi ti sún mọ́ tòsí.” Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ni Júdásì Ísíkáríótù dé, tòun ti ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n mú ògùṣọ̀ àti fìtílà àtàwọn ohun ìjà lọ́wọ́. Jésù ni wọ́n wá mú. Kò sì ní kí wọ́n máà mú òun. Ó ṣàlàyé pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?”—Máàkù 14:41-43; Mátíù 26:48-54.
A Ti Ṣe Ọmọ Ènìyàn Lógo!
20. (a) Àwọn ìwà ìkà bíburú jáì wo ni wọ́n hù sí Jésù lẹ́yìn tí wọ́n mú un? (b) Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ kí Jésù tó kú, kí ló dé tó kígbe pé: “A ti ṣe é parí”?
20 Lẹ́yìn tí wọ́n mú Jésù, àwọn ẹlẹ́rìí èké fẹ̀sùn kàn án, àwọn adájọ́ tí ń ṣègbè sọ pé ó jẹ̀bi, Pọ́ńtíù Pílátù sì dá ẹjọ́ ikú fún un, ni àwọn àlùfáà àtàwọn èèyànkéèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣẹ̀sín, àwọn ọmọ ogun wá ń sín in jẹ, wọ́n sì ń dá a lóró. (Máàkù 14:53-65; 15:1, 15; Jòhánù 19:1-3) Nígbà tó fi máa di ọ̀sán Friday, wọ́n ti kan Jésù mọ́ òpó igi oró, ó sì ń jẹ̀rora burúkú-burúkú bí ọ̀ọ̀rìn rẹ̀ ti mú kí ojú ibi tí wọ́n kan ìṣó mọ́ ọn lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ fà ya. (Jòhánù 19:17, 18) Nígbà tó di nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán, Jésù kígbe pé: “A ti ṣe é parí!” Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ti parí gbogbo ohun tó wá ṣe láyé. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́, ó tẹ orí ba, ó sì kú. (Jòhánù 19:28, 30; Mátíù 27:45, 46; Lúùkù 23:46) Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn náà, Jèhófà jí Ọmọ rẹ̀ dìde. (Máàkù 16:1-6) Ogójì ọjọ́ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, Jésù gòkè re ọ̀run, a sì ṣe é lógo.—Jòhánù 17:5; Ìṣe 1:3, 9-12; Fílípì 2:8-11.
21. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù?
21 Báwo la ṣe lè máa ‘tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí’? (1 Pétérù 2:21) Gẹ́gẹ́ bí tirẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa forí-fọrùn ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, a ò sì gbọ́dọ̀ fòyà, a ò gbọ́dọ̀ ṣojo rárá bí a ti ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 4:29-31; Fílípì 1:14) A ò gbọ́dọ̀ gbàgbéra rárá níbi tí ọjọ́ dé yìí o, a ò sì gbọ́dọ̀ gbàgbé àtimáa ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà. (Máàkù 13:28-33; Hébérù 10:24, 25) A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti òtítọ́ náà pé à ń gbé ní “àkókò òpin” máa darí gbogbo ìgbésẹ̀ wa pátá.—Dáníẹ́lì 12:4.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ipa wo ni mímọ̀ tí Jésù mọ̀ pé ikú òun ti sún mọ́lé ní lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù?
• Kí ló fi hàn pé Jésù ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ títí dé òpin’?
• Kí ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ní àwọn wákàtí díẹ̀ tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn nípa rẹ̀?
• Báwo la ṣe lè fara wé Kristi Jésù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jésù “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin”