Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé—Ṣé Ibi Ìdánniwò Fún Lílọ Gbé Níbòmíràn Ni?

Ayé—Ṣé Ibi Ìdánniwò Fún Lílọ Gbé Níbòmíràn Ni?

Ayé—Ṣé Ibi Ìdánniwò Fún Lílọ Gbé Níbòmíràn Ni?

Ẹ WO bí ara ti tù ú tó! Ó ti yege ìdánwò. Akẹ́kọ̀ọ́ tó ti fi odindi ọ̀sẹ̀ méjì ṣe ìdánwò, tí ẹ̀mí rẹ̀ sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ gba èsì tó múnú rẹ̀ dùn níkẹyìn. Ní báyìí, ó ti wá làǹfààní àtiṣe iṣẹ́ tó ti ń wù ú ṣe tipẹ́.

Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe ń wo ìgbésí ayé lórí ilẹ̀ ayé nìyẹn. Wọ́n fojú wò ó pé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú ìdánwò tí gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ là kọjá ni. Àwọn tó bá “yege ìdánwò” á wá lọ síbì kan tó tún dára jù, ìyẹn ni irú Ìwàláàyè Kan Lẹ́yìn Ikú. Ka sọ tòótọ́, ìbànújẹ́ ńlá ni yóò jẹ́, tó bá lọ jẹ́ pe ìgbésí ayé ìsinsìnyí, tí ọ̀pọ̀ kàn wà láyé bí aláìsí—nìkan ni èyí tó dára jù lọ tí aráyé lè máa gbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ní àlàáfíà, tó sì tún rí jájẹ dáadáa fún èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, síbẹ̀ ó sọ nínú Bíbélì pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, Ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.”—Jóòbù 14:1.

Ní gbígbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka ohun tó jẹ́ ìrònú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ògo ti ọ̀run ni àyànmọ́ tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ènìyàn. . . . A lè rí i pé kí ọwọ́ ṣáà ti tẹ ìgbádùn tó wà lọ́run ni ohun tó jẹ́ olórí ayọ̀ ènìyàn.” Ìwádìí kan tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kristi ṣe ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé, ìpín mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà gbọ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀run làwọ́n máa lọ lẹ́yìn tí àwọ́n bá kú.

Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni náà tún nírètí láti fi ayé sílẹ̀ lọ síbì kan tó dára jù lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Mùsùlùmí nírètí láti lọ sí àlùjánnà lọ́run. Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ya ìsìn Ilẹ̀ Mímọ́ ti Búdà ní China àti Japan gbà gbọ́ pé táwọn bá ṣáà ti lè máa pe “Amitabha” láìdábọ̀, ìyẹn orúkọ Búdà tó ni Ìmọ́lẹ̀ Àìlópin, wọ́n á tún àwọn bí ní Ilẹ̀ Mímọ́ náà, tàbí ní Ìwọ̀ Oòrùn Párádísè, níbi tí àwọn á ti máa gbé nínú ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́.

Ó dùn mọ́ni nínú pé Bíbélì, ìwé tí wọ́n tíì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè mìíràn jù lọ, tó sì jẹ́ pé òun ni wọ́n tíì pín kiri jù lọ láyé, kò sọ̀rọ̀ nípa ayé gẹ́gẹ́ bí ibì kan tí èèyàn ti lè sá kúrò, pé ó jẹ́ àtẹ̀gùn tí a ń gùn bọ́ sí ibòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Nínú Bíbélì ni a tún ti lè rí ọ̀rọ̀ Jésù tó lókìkí yẹn: “Alabukún-fun li awọn ọlọkàntutù: nitori nwọn o jogún aiye.”—Mátíù 5:5, Bibeli Mimọ.

Èrò àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò pé ayé lọjà, túmọ̀ sí pé, ikú jẹ́ ojú ọ̀nà tó lọ sí ìgbésí ayé onígbẹdẹmukẹ lẹ́yìn ikú. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìbùkún ni ikú jẹ́ nígbà náà. Àmọ́ ènìyàn mélòó ló jẹ́ fojú wo ikú gẹ́gẹ́ bí ìbùkún, ǹjẹ́ kì í ṣe ọ̀nà bi ẹ̀mí wọn ṣe máa gùn sí i ni wọ́n máa ń wá? Ìrírí fi hàn pé, nígbà táwọn èèyàn bá ń gbádùn ìlera ara tó dára, tọ́kàn wọ́n sì balẹ̀ dé ààyè kan, wọ́n kì í fẹ́ kú.

Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí pé ìgbésí ayé lórí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ibi àti ìjìyà, ọ̀pọ̀ ló ṣì ń fojú wò ó pé ọ̀run nìkan ṣoṣo ni ibi téèyàn ti lè rí àlàáfíà àti ayọ̀ tòótọ́. Àmọ́, ṣé ibi àlàáfíà àti ayọ̀ ni ọ̀run wulẹ̀ jẹ́ ni, tó bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìwà ibi àti àìsíṣọ̀kan? Àbí kẹ̀, ṣé ibì kan lájùlé ọ̀run nìkan ni ìwàláàyè lẹ́yìn ikú máa wà ni? Àwọn ìdáhùn tí Bíbélì fúnni lè yà ọ́ lẹ́nu. Jọ̀wọ́, máa kà á nìṣó.