Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayọ̀ Tí Kò Lópin—Ṣé Lọ́run Ni Àbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?

Ayọ̀ Tí Kò Lópin—Ṣé Lọ́run Ni Àbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?

Ayọ̀ Tí Kò Lópin—Ṣé Lọ́run Ni Àbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?

ṢÉ IBI tóò ń gbé ni olórí ohun tó ń fún ẹ láyọ̀? Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ènìyàn ló máa gbà láìjanpata pé, àwọn ohun tó ń fún èèyàn láyọ̀ jù ni kéèyàn ní ìlera tó dáa, kí ìgbésí ayé ẹ̀ ní ète nínú, kí àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán sì wà láàárín òun àtàwọn ẹlòmíràn. Òwe kan nínú Bíbélì sọ ọ́ báyìí pé: “Oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.”—Òwe 15:17.

Ṣùgbọ́n o, ó báni nínú jẹ́ pé, ó ti pẹ́ tí ilé ayé wa ti kún fún ìkórìíra, ìwà ipá, àti oríṣiríṣi àwọn ìwà burúkú mìíràn. Ọ̀run ní tiẹ̀ ńkọ́, tàbí ilẹ̀-àkóso ẹ̀mí, ìyẹn ibi tí ọ̀pọ̀ ń retí láti lọ lẹ́yìn tí wọ́n bá kú? Ṣé pé kò sígbà kankan tí rògbòdìyàn ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ rí, ṣé pé ibẹ̀ ti fìgbà gbogbo jẹ́ ibi alálàáfíà tó sì tòrò minimini gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀pọ̀ ní lọ́kàn?

Bíbélì kọ́ni pé, ọ̀run ni Ọlọ́run ń gbé, òun àtàwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí a ń pè ní áńgẹ́lì. (Mátíù 18:10; Ìṣípayá 5:11) Àwọn wọ̀nyí ni a ń pè ní ‘àwọn ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run.’ (Jóòbù 38:4, 7) Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ènìyàn, àwọn áńgẹ́lì náà lómìnira ìwà híhù; wọ́n kì í ṣe ẹ̀rọ. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, àwọn náà lè yàn láti ṣe ohun tó dára tàbí ohun tó burú. Ṣé àwọn áńgẹ́lì lè yàn láti ṣe ohun tó burú ni? Ó lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn kan láti gbọ́ pé, ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, àwọn áńgẹ́lì kan tí iye wọn pọ̀ díẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run—àní wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run!—Júúdà 6.

Àwọn Ọlọ̀tẹ̀ ní Ọ̀run

Ẹ̀ṣẹ̀ fara hàn nínú ilẹ̀ ọba ẹ̀mí nítorí ìṣọ̀tẹ̀ áńgẹ́lì kan, ẹni táa wá mọ̀ lẹ́yìn náà sí Sátánì (Alátakò) àti Èṣù (Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́). Áńgẹ́lì yìí, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ onígbọràn, mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti ṣe ohun tó burú látinú òmìnira ìfẹ́ inú ara rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wá ní ipa búburú lórí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù, débi pé, ọ̀pọ̀ lára wọ́n ló dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ní àkókò Nóà, kí Ìkún Omi tó dé.—Jẹ́nẹ́sísì 6:2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; 2 Pétérù 2:4.

Wọn ò lé àwọn áńgẹ́lì tó yẹsẹ̀ wọ̀nyí jáde kúrò lọ́run ní wàrà-ǹṣe-ṣà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a fàyè gbà wọ́n láti máa lọ káàkiri síbẹ̀ àní fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún pàápàá—àmọ́ o, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wọn ò ní ààlà. a Bó ti wù kó rí, nígbà tí àyè tí Ọlọ́run fi gba àwọn ẹni ibi yìí dópin, a fi wọ́n “sọ̀kò sísàlẹ̀” láti ọ̀run, tí a ó sì wá pa wọn run níkẹyìn. Lẹ́yìn náà ni ohùn kan láti ọ̀run wá wí pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!” (Ìṣípayá 12:7-12) Ó hàn gbangba pé àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ yọ̀ gidigidi pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ọ̀run di ibi tó bọ́ lọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì adájọ̀gbọ̀nsílẹ̀ yẹn!

Nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ọ̀pọ̀ kò mọ̀ nípa rẹ̀ yìí, ó hàn gbangba pé, kò sọ́gbọ́n tí àlàáfíà tòótọ́ fi lè wà nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀dá onílàákàyè bá ti ṣàìka àwọn òfin Ọlọ́run àti àwọn ìlànà rẹ̀ sí. (Aísáyà 57:20, 21; Jeremáyà 14:19, 20) Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, tí gbogbo èèyàn bá ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run, àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ á wà níbi gbogbo. (Sáàmù 119:165; Aísáyà 48:17, 18) Nítorí náà, bí gbogbo ènìyàn bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ṣègbọràn sí i tí wọ́n tún fẹ́ràn ara wọn, ǹjẹ́ ayé kò ní jẹ́ ibi aláyọ̀, tó dùn mọ́ni láti gbé? Bíbélì dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ ni!

Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó tìtorí ìmọtara ẹni nìkan tí wọn sọ pé àwọn ò ní yí ọ̀nà búburú àwọn padà? Ṣé títí ayé ni wọ́n ó máa bá a lọ láti máa dí àlàáfíà àwọn tó fẹ́ fi òótọ́ inú ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ ni? Rárá o, Ọlọ́run rí sí àwọn áńgẹ́lì búburú ní ọ̀run, yóò sì tún rí sí àwọn ènìyàn búburú tó wà lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín pẹ̀lú.

Ilẹ́ Ayé Kan Tí A Gbá Mọ́ Tónítóní

Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ilẹ̀ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.” (Aísáyà 66:1) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ ẹni gíga jù lọ ní ìjẹ́mímọ́, kò ní gbà kí “àpótí ìtìsẹ̀” òun di èyí tí ìwà ibi kó èérí bá títí lọ kánrin. (Aísáyà 6:1-3; Ìṣípayá 4:8) Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe palẹ̀ àwọn ẹ̀mí búburú mọ́ kúrò ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa gbá àwọn ènìyàn búburú mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí àwọn àyọkà Bíbélì tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ti fi hàn:

“Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, Ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 37:9.

“Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”—Òwe 2:21, 22.

“Ó jẹ́ òdodo níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti san ìpọ́njú padà fún àwọn tí ń pọ́n yín lójú, ṣùgbọ́n, fún ẹ̀yin tí ń ní ìpọ́njú, ìtura pa pọ̀ pẹ̀lú wa nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa. Àwọn wọ̀nyí gan-an yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun láti iwájú Olúwa àti láti inú ògo okun rẹ̀.”—2 Tẹsalóníkà 1:6-9.

“Ayé [gbogbo àwọn ènìyàn búburú] ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.

Ṣé Ayé Yóò Máa Wà Lálàáfíà Nìṣó?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fi yé wa yékéyéké pé àyè tí Ọlọ́run fi gba àwọn ẹni ibi yóò wá sópin rẹ̀, báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé, táa bá ti lè mú ìwà ibi kúrò lẹ́ẹ̀kan yìí, kò tún ní padà wáyé mọ́? Ó ṣe tán, kò pẹ́ rárá tó tún fi yọjú lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ó sì wá le débi tí Ọlọ́run fi ní láti dojú ètò tí aráyé gbé kalẹ̀ dé nípa dídà wọ́n lédè rú.—Jẹ́nẹ́sísì 11:1-8.

Ìdí pàtàkì tọ́kàn wa fi balẹ̀ pé ìwà ibi kò tún ní wáyé lẹ́ẹ̀kan sí i mọ́ ni pé, èèyàn kọ́ ni yóò tún máa ṣàkóso ayé gẹ́gẹ́ bó ti rí kété lẹ́yìn Ìkún Omi. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run ni yóò máa ṣàkóso rẹ̀. Bó ti ń ṣàkóso láti ọ̀run wá, Ìjọba yìí yóò jẹ́ àkóso kan ṣoṣo tí ayé yóò ní. (Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14) Yóò gbégbèésẹ̀ lẹ́yẹ-ò-sọkà láti mú ènìyàn èyíkéyìí tó bá gbìdánwò láti tún mú ìwà ibi padà wá kúrò. (Aísáyà 65:20) Àní, yóò pa ẹni náà gan an tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ìwà búburú run nígbẹ̀yìngbẹ́yín—Sátánì Èṣù—pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì búburú tó tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.—Róòmù 16:20.

Ìyẹn nìkan kọ́ o, kò tún ní sí ìdí fún ìran ènìyàn láti ṣàníyàn nípa oúnjẹ, aṣọ, ibùgbé, àti rírí iṣẹ́ ṣe—àìní àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ń sún àwọn kan lónìí sínú gbígbé ìgbésí ayé ìwà ọ̀daràn. Ó dájú pé gbogbo ilẹ̀ ayé pátá ní a óò sọ di Párádísè eléso tí gbogbo ènìyàn yóò sì ní ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan láti jẹ.—Aísáyà 65:21-23; Lúùkù 23:43.

Èyí tó tún wa ṣe pàtàkì jù ni pé, Ìjọba yẹn yóò kọ́ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé alálàáfíà, bákan náà, yóò mú kí wọ́n dé òtéńté ìjẹ́pípé ti ẹ̀dá ènìyàn. (Jòhánù 17:3; Róòmù 8:21) Lẹ́yìn ìyẹn, aráyé kò tún ní máa bá àwọn àìlera àti àwọn ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀yá ìjà mọ́, èyí yóò tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run ní kíkún ṣeé ṣe kó sì tún gbádùn mọ́ni, gẹ́gẹ́ bí i ti ọkùnrin pípé náà, Jésù. (Aísáyà 11:3) Láìsí tàbí-tàbí, Jésù jẹ́ adúró ṣinṣin sí Ọlọ́run àní lójú ìdẹwò àti ìfìyàjẹni lílekoko—àwọn nǹkan táà ní gbúròó mọ́ nínú Párádísè.—Hébérù 7:26.

Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ń Lọ sí Ọ̀run

Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ òǹkàwé Bíbélì ló mọ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù náà dáadáa pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ní ń bẹ. . . . Nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 14:2, 3) Ǹjẹ́ èyí kò wá tako èrò wíwàláàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé?

Àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kò tako ara wọn. Ká sọ tòótọ́ ńṣe ní ọ̀kan tún ti èkejì lẹ́yìn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Bíbélì sọ pé kìkì àwọn Kristẹni olóòótọ́ díẹ̀ tí wọ́n níye—tí iye wọn ọ̀hún sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ní a jí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí láti lọ gbé ní ọ̀run. Èé ṣe táa fi fún wọn ní èrè àgbàyanu yìí? Nítorí pé wọ́n para pọ̀ di agbo náà tí Jòhánù rí nínú ìran kan, àwọn tí wọ́n ‘wá sí ìyè, tí wọ́n sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Kristi fún ẹgbẹ̀rún ọdún.’ (Ìṣípayá 14:1, 3; 20:4-6) Táa bá fi wọ́n wéra pẹ̀lú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tó wà lórí ilẹ̀ ayé, “agbo kékeré” ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] náà jẹ́ ní tòótọ́. (Lúùkù 12:32) Láfikún sí i, nítorí pé wọ́n ti nírìírí àwọn ìṣòro tó wọ́pọ̀ láàárín ìràn ènìyàn, àwọn náà, bíi ti Jésù yóò lè ‘bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa’ bí wọ́n ti ń mójú tó mímú aráyé àti ilẹ̀ ayé wa padà bọ̀ sípò.—Hébérù 4:15.

Ayé—Ilé Ènìyàn Títí Lọ Gbére

Nípa pípèsè ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà [144,000] jọ ní nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, ẹ̀rí sì fi hàn pé ẹgbẹ́ yìí ti pé nísinsìnyí. (Ìṣe 2:1-4; Gálátíà 4:4-7) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] nìkan ni ẹbọ Jésù wà fún, “ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:2) Nítorí náà, gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù ló ní ìrètí ìyè ayérayé. (Jòhánù 3:16) Gbogbo àwọn tó ń sùn nínú sàréè ṣùgbọ́n tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run ni yóò jí dìde, kì í ṣe sí ọ̀run o, àmọ́ sí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé mímọ́ tónítóní. (Oníwàásù 9:5; Jòhánù 11:11-13, 25; Ìṣe 24:15) Kí ni ohun tó ń dúró dè wọ́n níbẹ̀?

Ìṣípayá 21:1-4 dáhùn, ó sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Fojú inú wò ó ná—pé ènìyàn bọ́ lọ́wọ́ ikú, tí ìrora àti igbe ẹkún tó máa ń bá a rìn sì pòórá títí ayé! Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ète tí Jèhófà ní fún ilẹ̀ ayé àti ìran ènìyàn níbẹ̀rẹ̀ yóò di èyí tó ní ìmúṣẹ rẹ̀ ológo.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28.

Yíyàn Tí A Ní—Ìyè Tàbí Ikú

A kò fún Ádámù àti Éfà ní yíyàn láti lọ sí ọ̀run. Yíyàn tí wọ́n ní kò ju pé kí wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run kí wọ́n sì wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tàbí kí wọ́n ṣàìgbọràn sí i kí wọ́n sì kú. Ó bani nínú jẹ́ pé, àìgbọràn ni wọ́n yàn, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n padà sínú “ekuru” ilẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:2-5, 19) Kò fìgbà kankan rí jẹ́ ète Ọlọ́run fún ìdílé aráyé láti kú kí wọ́n sì wá gba inú sàréè lọ sí ọ̀run láti lọ kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Ọlọ́run dá ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì láti máa gbé ní ọ̀run; àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí kì í ṣe ẹ̀dá ènìyàn tó ti kú tí wọ́n sì wá jí dìde sí ìwàláàyè ní ọ̀run.—Sáàmù 104:1, 4; Dáníẹ́lì 7:10.

Kí lohun táa gbọ́dọ̀ ṣe táa bá fẹ́ gba ìbùkún gbígbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì mímọ́. Jésù sọ nínú àdúrà pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi”—Jòhánù 17:3.

Fífi ìmọ̀ yẹn sílò ni ìgbésẹ̀ mìíràn sí ayọ̀ ayérayé nínú Párádísè. (Jákọ́bù 1:22-24) Àwọn tó ń gbé níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń retí àtifi ojú ara wọn rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ amúniláyọ̀ bí irú èyí tó wà ní Aísáyà 11:9, tó sọ pé: “Wọn [ìran aráyé] kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìjíròrò nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé, wo ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, ojú ìwé 70 sí 79.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29