“Ewúrẹ́ Olóòfà Ẹwà Ti Orí Òkè Ńlá”
“Ewúrẹ́ Olóòfà Ẹwà Ti Orí Òkè Ńlá”
Ọ̀PỌ̀ jù lọ nínú wa ni kò jẹ́ júwe ewúrẹ́ pé ó jẹ́ olóòfà ẹwà. Gbogbo ohun táa lè ronú kàn nípa ewúrẹ́ ni pé ó jẹ́ ẹranko tó máa ń jẹ oríṣiríṣi nǹkan tó bá rí, ó sì wúlò nítorí ẹran rẹ̀ máa ń dùn, àti pé ó máa ń pèsè wàrà aṣaralóore fún wa—àmọ́, ekukáká la fi lè pè é ní olóòfà ẹwà.
Bó ti wù kó rí, Bíbélì ṣàpèjúwe aya kan gẹ́gẹ́ bí “egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá.” (Òwe 5:18, 19) Sólómọ́nì, òǹkọ̀wé ìwé Òwe, jẹ́ ẹni tó ṣàkíyèsí àwọn ẹranko ìgbẹ́ Ísírẹ́lì lọ́nà tó jinlẹ̀, nítorí náà, kò sí àní-àní pé ó ní ìdí tó ṣe gúnmọ́ fún lílo àpèjúwe yìí. (1 Àwọn Ọba 4:30-33) Bíi ti Dáfídì, bàbá rẹ̀, òun náà ti lè kíyè sí àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá tí wọ́n sábà máà ń jẹ̀ lágbègbè Ẹ́ń-gédì, ní tòsí etí Òkun Òkú.
Àwọn agbo ewúrẹ́ kéékèèké orí òkè ńlá tí wọ́n ń gbé tòsí Aṣálẹ̀ Jùdíà máà ń wá síbi ìsun Ẹ́ń-gédì déédéé. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni orísun tó ṣeé gbára lé fún omi ní àgbègbè tó jẹ́ aṣálẹ̀ yìí, fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni Ẹ́ń-gédì ti jẹ́ ibi àyànláàyò tí a ti ń fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè lómi mu. Ká sòótọ́, orúkọ náà, Ẹ́ń-gédì ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “orísun omi ọmọ ewúrẹ́,” èyí tó jẹ́rìí sí bí àwọn ọ̀dọ́ ewúrẹ́ ṣe máa ń wà lágbègbè yìí nígbà gbogbo. Dáfídì Ọba rí ààbò níhìn-ín kúrò lọ́wọ́ inúnibíni Sọ́ọ̀lù Ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní láti gbé bí ìsáǹsá “lórí àwọn àpáta dídán borokoto ti àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá.”—1 Sámúẹ́lì 24:1, 2.
Ní Ẹ́ń-gédì, o ṣì lè máa wo abo ewúrẹ́ ẹgàn, tàbí ewúrẹ́ orí òkè ńlá, tó ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ jẹ̀ lọ síhà a
ìsàlẹ̀ àfonífojì olókùúta, bó ti ń tẹ̀ lé akọ ewúrẹ́ kan lọ síbi omi. Lẹ́yìn náà, o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ìfiwéra tó wà láàárín abo ewúrẹ́ orí òkè ńlá àti aya adúróṣinṣin kan. Ìwà jẹ́jẹ́ tó ní àti ìṣesí ẹlẹ́wà rẹ̀ tún sọ nípa àwọn ànímọ́ rere ti abo. Ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ náà “olóòfà ẹwà” ń tọ́ka sí ọlá àti ìrísí ẹlẹ́wà ti ewúrẹ́ orí òkè ńlá náà.Abo ewúrẹ́ orí òkè máa ń rọ́kú, bákan náà ó máa ń ta kébékébé. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún Jóòbù ní kedere, ewúrẹ́ orí òkè máa ń bímọ sínú àpáta gàǹgà, ní àwọn ibi olókùúta, láwọn ibi tí kò ṣeé dé tí oúnjẹ ti lè ṣòro láti rí, tí ìdíwọ̀n ooru ara sì lè gbóná kọjá ààlà. (Jóòbù 39:1) Síbẹ̀, lójú gbogbo àwọn ìṣòro wọ̀nyí, ó máa ń bìkítà fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì máà ń kọ́ wọn láti gun òkè kí wọ́n sì máa ta pírípírí bíi tirẹ̀ láàárín àwọn àpáta. Ewúrẹ́ orí òkè ńlá tún máa ń fi taápọntaápọn dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn apanijẹ. Alákìíyèsí kan rí ewúrẹ́ orí òkè ńlá kan tó ń bá ẹyẹ idì kan jà fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, nígbà tí ọmọ ewúrẹ́ náà sì ká gúlútú sábẹ́ rẹ̀ fún ààbò.
Lábẹ́ àwọn àyíká ipò tí kò fi bẹ́ẹ̀ bára dé ni àwọn aya àti ìyá tó jẹ́ Kristẹni ti sábà ń tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà. Bíi ti ewúrẹ́ orí òkè ńlá, wọ́n ń fi ìfarajìn àti àìmọtara-ẹni-nìkan bójú tó ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún wọn yìí. Wọ́n sì ń fi tìgboyàtìgboyà tiraka láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ewu tẹ̀mí. Nítorí náà, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí bíbu àwọn obìnrin kù pẹ̀lú àfiwé yìí, ńṣe ni Sólómọ́nì ní ti gidi ń pe àfiyèsí sí ọlá àti ẹwà obìnrin kan, ìyẹn àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tó ń tàn jáde àní nínú àwọn àyíká tó le koko jù lọ pàápàá.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, The New Brown-Driver-Briggs-Gesenius Hebrew and English Lexicon ti sọ, nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ Hébérù náà chen tí a pè ní “olóòfà ẹwà,” túmọ̀ sí ‘ọlá tàbí ẹwà ara àti ìrísí.’
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]
Aya àti ìyá kan tó jẹ́ Kristẹni ń fi àwọn ànímọ́ tẹ̀mí rírẹwà hàn nígbà tó bá ń mú àwọn ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún un ṣẹ