O Ha Jẹ́ Olóye Bí?
O Ha Jẹ́ Olóye Bí?
NÍ YÍYAN àwọn onídàájọ́ fún Ísírẹ́lì, Mósè tiraka láti wá “àwọn ọkùnrin ọlọ́gbọ́n àti olóye àti onírìírí.” (Diutarónómì 1:13) Kì í ṣe ìrírí tí wọ́n ní nítorí bọ́jọ́ orí wọ́n ṣe tó nìkan la fi díwọ̀n wọn. Ọgbọ́n àti òye tún ṣe kókó.
Olóye ènìyàn máa ń lo ìfòyemọ̀ nínú ọ̀rọ̀ ẹnu àti nínú ìwà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary ti sọ ọ́, ènìyàn kan tí ó jẹ́ olóye tún “jẹ́ ẹni tó dáńgájíá nínú dídákẹ́ jẹ́ẹ́ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání.” Òótọ́ ni, “ìgbà sísọ̀rọ̀” wà, bẹ́ẹ̀ ni “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” náà sì wà, ènìyàn kan tó jẹ́ olóye sì mọrírì ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn. (Oníwàásù 3:7) Lọ́pọ̀ ìgbà, ìdí rere wà fún dídákẹ́ jẹ́ẹ́ láìfọhùn, nítorí Bíbélì sọ pe: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.”—Òwe 10:19.
Àwọn Kristẹni máa ń ṣọ́ra láti jẹ́ olóye nínú bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn lò. Kì í ṣe ẹnì tó máa ń sọ̀rọ̀ jù tàbí tí ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu rẹ̀ jù lọ ló sábà máa ń jẹ́ ẹni tó ṣe pàtàkì jù tàbí ẹni tó jẹ́ pé a ò lè ṣe ohunkóhun láìjẹ́ pé a rí i. Rántí pé Mósè jẹ́ “alágbára nínú ọ̀rọ̀ . . . rẹ̀,” àmọ́ kò ṣeé ṣe fún-un láti darí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ́nà tó gbéṣẹ́, àfìgbà tí ó tóó ní sùúrù, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Ìṣe 7:22) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tí ó ní àṣẹ níkàáwọ́ lórí àwọn ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ dìídì tiraka láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu.—Òwe 11:2.
Àwọn tí Jésù fa “gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀” lé lọ́wọ́ ni a pè ní “olóòótọ́ àti olóye” nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 24:45-47) Wọn kì í fi ìkùgbù ṣáájú Jèhófà nítorí ìfẹ́ ọkàn tí a kò kó níjàánu; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í lọ́tìkọ̀ nígbà tí ìdarísọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá mú àwọn ọ̀ràn kan ṣe kedere. Wọ́n mọ ìgbà tó yẹ láti sọ̀rọ̀ àti ìgbà tó yẹ láti dúró ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún òye kíkún sí i. Ì bá dára kó má jẹ́ pé ńṣe ni gbogbo Kristẹni kàn ń ṣàfarawé ìgbàgbọ́ wọn nìkan, ṣùgbọ́n kí àwọn náà jẹ́ olóye, bíi ti ẹgbẹ́ ẹrú náà.—Hébérù 13:7.