Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ríra Àkókò Padà Láti Kàwé Àti Láti Kẹ́kọ̀ọ́

Ríra Àkókò Padà Láti Kàwé Àti Láti Kẹ́kọ̀ọ́

Ríra Àkókò Padà Láti Kàwé Àti Láti Kẹ́kọ̀ọ́

“[Ẹ ra] àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.”—ÉFÉSÙ 5:16.

1. Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu fún wa láti wéwèé àkókò wa, kí sì ni ọ̀nà táa gba ń lo àkókò wa lè fi hàn nípa wa?

 ATI máa ń sọ ọ́ pé “tóo bá ti mọ iye àkókò tóo fẹ́ lò, o ò ní fàkókò ṣòfò.” Ẹni tó bá ń pinnu iye àkókò pàtó tó fẹ́ lo lórí ohun tó yẹ ní ṣíṣe yóò máa fi àkókò rẹ̀ ṣe ohun tó ní láárí. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo ló ní wákàtí tí a yàn kalẹ̀ fún un, ìgbà wà fún ohun gbogbo lábẹ́ ọ̀run.” (Oníwàásù 3:1, Moffatt) Iye àkókò kan náà ló wà níkàáwọ́ gbogbo wa; bá ṣe wá ń lò ó kù sọ́wọ́ wa. Ọ̀nà táa gba yan àwọn ohun àkọ́múṣe wa àti báa ṣe pín àkókò wa fi ohun tó jẹ́ ipò kìíní ní ọkàn-àyà wa hàn dé ìwọ̀n gíga kan.—Mátíù 6:21.

2. (a) Nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, kí ni Jésù sọ nípa àìní wa nípa tẹ̀mí? (b) Kí ni àwon àyẹ̀wò ara ẹni tó yẹ ní ṣíṣe?

2 Ó di dandan fún wa láti lo àkókò fún oúnjẹ jíjẹ àti oorun sísùn nítorí ara wa nílò àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí ńkọ́? A mọ̀ pé ó yẹ kí a tẹ́ àwọn náà lọ́rùn pẹ̀lú. Nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, Jésù là á mọ́lẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ìdí nìyẹn tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fi ń rán wa létí ìjẹ́pàtàkì Bíbélì kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo ìgbà. (Mátíù 24:45) O lè gbà pé ohun táa ń wí yìí ṣe pàtàkì lóòótọ́, àmọ́ o lè wá ronú pé kò sọ́gbọ́n tóo fi lè ráyè kẹ́kọ̀ọ́ tàbí kóo ka Bíbélì. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ọ̀nà táa lè gbà àti ọgbọ́n táa lè dá láti túbọ̀ ráyè fún kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fún dídákẹ́kọ̀ọ́, àti fún ṣíṣàṣàrò nínú ìgbésí ayé wa yẹ̀ wò.

Wíwá Àkókò fún Bíbélì Kíkà àti Ìkẹ́kọ̀ọ́

3, 4. (a) Kí ni ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa lórí bí a ṣe ń lo àkókò wa, kí sì ni èyí ní nínú? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó gbà wá nímọ̀ràn pé ká ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara wa’?

3 Nítorí àkókò tí a ń gbé, gbogbo wa lá gbọ́dọ̀ kọbi ara sí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú. Ní tìtorí èyí, ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” (Éfésù 5:15-17) Láìsí àní-àní, ìmọ̀ràn yìí kárí gbogbo apá ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, títí kan wíwá àkókò fún àdúrà gbígbà, kíkẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí ìpàdé, àti níní ìpín kíkún bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú wíwàásù “ìhìn rere ìjọba náà.”—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

4 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ló dà bí ẹni pé ó ṣòro fún nínú ìgbésí ayé wọn láti wá àyè fún Bíbélì kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Ó hàn gbangba pé a ò lè fi wákàtí kan péré kún ìgbésí ayé wa, nítorí náà ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ní láti túmọ̀ sí ohun tó yàtọ̀ pátápátá. Lédè Gíríìkì, gbólóhùn náà “ríra àkókò tí ó rọgbọ padà” túmọ̀ sí rírà á lọ́wọ́ àwọn nǹkan mìíràn. Nínú ìwé atúmọ̀ èdè Expository Dictionary rẹ̀, W. E. Vine túmọ̀ rẹ̀ sí “ṣíṣàì fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àǹfààní èyíkéyìí táa bá ní, fífi àǹfààní kọ̀ọ̀kan ṣe ohun tó dára jù lọ nítorí pé àkókò kò dúró dẹnì kan.” Láti inú kí ni tàbí ibo la ti lè ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?

A Gbọ́dọ̀ Ṣètò Àwọn Ohun Àkọ́múṣe

5. Èé ṣe tó fi yẹ ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” báwo ló sì ṣe yẹ ká ṣe é?

5 Ní àfikún sí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe, a tún ní ọ̀pọ̀ nǹkan tẹ̀mí táa tún ní láti bójú tó. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, a ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Nítorí ìdí èyí, Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Èyí túmọ̀ sí pé a ní láti ṣètò àwọn ohun àkọ́múṣe. Àwọn nǹkan tẹ̀mí gbọ́dọ̀ máa ṣáájú àwọn nǹkan ti ara. (Mátíù 6:31-33) Síbẹ̀, a tún ní láti lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì láti kájú àwọn ohun tó jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún wa nípa tẹ̀mí. Báwo la ṣe ń pín àkókò wa sórí onírúurú apá tí ìgbésí ayé wa ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni? Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ròyìn pé nínú “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” tó yẹ kí Kristẹni kan máa bójú tó, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà dà bí èyí tí a ti fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.

6. Kí ni ríra àkókò tí ó rọgbọ padà lè ní nínú nígbà tó bá kan iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí iṣẹ́ ilé?

6 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, ríra àkókò tí ó rọgbọ padà wé mọ́ “ṣíṣàì fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àǹfààní èyíkéyìí táa bá ní” àti “fífi àǹfààní kọ̀ọ̀kan ṣe ohun tó dára jù lọ.” Nítorí náà, bí Bíbélì kíkà wa àti ọ̀nà tí a gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ kò bá kúnjú ìwọ̀n, yóò dára ká yẹ ara wa wò dáradára láti mọ bí a ṣe ń lo àkókò wa. Bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa bá jẹ́ èyí tó ká wa lọ́wọ́ kò, tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti agbára wa, a ní láti mú ọ̀ràn náà tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà. (Sáàmù 55:22) Ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àwọn àtúnṣe kan tó máa jẹ́ ká rí àyè fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà, títí kan kíkẹ́kọ̀ọ́ àti kíka Bíbélì. A ti máa ń gbọ́ pé iṣẹ́ obìnrin kì í tán. Nítorí náà, àwọn Kristẹni arábìnrin gbọ́dọ̀ ṣètò ohun àkọ́múṣe wọn, kí wọ́n sì ṣètò àkókò pàtó fún Bíbélì kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko.

7, 8. (a) Láti inú àwọn ìgbòkègbodò wo la ti lè ra àkókò padà láti kàwé àti láti kẹ́kọ̀ọ́? (b) Kí ni ète eré ìtura, báwo sì ni rírántí èyí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣètò àwọn ohun àkọ́múṣe wa?

7 Lápapọ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ wa lè ra àkókò padà fún kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa pípa àwọn ohun tí kò fí bẹ́ẹ̀ ní láárí tì. A lè bi ara wa pé, ‘Báwo ni àkókò tí mò fi ń ka àwọn ìwé ìròyìn ayé, èyí tí mo fi ń wo tẹlifíṣọ̀n, èyí tí mo fi ń fetí sí orin, tàbí tí mo ń lò nídìí eré àṣedárayá orí fídíò ṣe pọ̀ tó? Ṣe kì í ṣe pé àkókò tí mò ń lò nídìí kọ̀ǹpútà pọ̀ ju èyí tí mo fi ń ka Bíbélì?’ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” (Éfésù 5:17) Ó dà bí ẹni pé àìfi ọgbọ́n lo tẹlifíṣọ̀n ni ìdí pàtàkì tí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ò fi lè ya àkókò tí ó tó sọ́tọ̀ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà.—Sáàmù 101:3; 119:37, 47, 48.

8 Àwọn kan lè sọ pé àwọn ò lè máa fi gbogbo ìgbà kẹ́kọ̀ọ́ o jàre, pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣeré ìtura. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yí, ì bá tún dára táa bá lè gbé iye àkókò táa fi ń najú yẹ̀ wò, ká wá fi wéra pẹ̀lú àkókò táa dìídì fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí táa fi ń ka Bíbélì. Ohun táa máa rí lè yà wá lẹ́nu gan-an. Lóòótọ́, eré ìtura àti eré ìnàjú pọndandan, àmọ́ a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n gbà àkókò ju bó ṣe yẹ lọ. Ète wọn ni láti tù wá lára fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí mìíràn. Ọ̀pọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n àti àwọn eré àṣedárayá fídíò ló máa ń tánni lókun, nígbà tó sì jẹ́ pé ńṣe ni kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ máa ń tuni lára tó sì ń fúnni lókun.— Sáàmù 19:7, 8.

Bí Àwọn Kan Ṣe Wá Àyè fún Kíkẹ́kọ̀ọ́

9. Kí ni àwọn àǹfààní tó wà nínú títẹ̀lé ìmọ̀ràn táa fúnni nínú ìwé kékeré Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—1999?

9 Ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé kékeré Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti ọdún 1999 sọ pé: “Yóò ṣàǹfààní jù lọ bí ẹ bá ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ àti àlàyé rẹ̀ láti inú ìwé pẹlẹbẹ yìí ní òwúrọ̀. Ìwọ yóò nímọ̀lára bí ẹni pé Jèhófà, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá, ń fi àwọn ìtọ́ni rẹ̀ jí ọ. Lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, a sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń jàǹfààní láti inú àwọn ìtọ́ni Jèhófà ní òròòwúrọ̀: ‘Ó [Jèhófà] ń jí mi ní òròòwúrọ̀; ó ń jí etí mi láti gbọ́, bí àwọn tí a kọ́.’ Irú àwọn ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí Jésù ní ‘ahọ́n àwọn tí a ń kọ́’ kí ó lè ‘mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.’ (Aísá. 30:20; 50:4; Mát. 11:28-30) Jíjẹ́ ẹni tí a jí sí ìmọ̀ràn tó bá àkókò mu láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní òròòwúrọ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tìrẹ yóò sì tún fún ọ ní ‘ahọ́n àwọn tí a kọ́’ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.” a

10. Báwo ni àwọn kan ṣe wá àyè fún Bíbélì kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́, àǹfààní wo ni wọ́n sì ti rí níbẹ̀?

10 Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí nípa kíka ọ̀rọ̀ ẹsẹ-ìwé ojoojúmọ́ àti àlàyé rẹ̀, àti nípa kíka Bíbélì tàbí kí wọ́n jí kẹ́kọ̀ọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀. Ní ilẹ̀ Faransé, aṣáájú ọ̀nà tòótọ́ kan tètè máa ń jí lárààárọ̀, ó sì máa ń fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ka Bíbélì. Kí ló ti ràn án lọ́wọ́ láti ṣe èyí láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá? Obìnrin náà sọ pé: “Ó máa ń wù mí kà ṣáá ni, mo sì ń tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìwé kíkà mi láìjẹ́ kí ohunkóhun dí mi lọ́wọ́!” Àkókò tó wù ká yàn, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí a máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa. René Mica, tó ti wà nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ohun tó lé ní ogójì ọdún ní Yúróòpù àti ní Àríwá Áfíríkà, sọ pé: “Láti ọdún 1950 ni mo ti fi ṣe góńgó mi pé kí n máa parí Bíbélì lọ́dọọdún, mo sì ti ṣe èyí fún ìgbà mọ́kàndínláàádọ́ta báyìí. Mo rò pé èyí ṣe pàtàkì kí àjọṣe dídánmọ́rán tí mo ní pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá mi má bàá yingin. Ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ìdájọ́ òdodo Jèhófà àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù sí i, ó sì ti jẹ́ orísun okun kíkàmàmà fún mi.” b

“Ìpèsè Oúnjẹ . . . ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu”

11, 12. (a) “Ìpèsè oúnjẹ” tẹ̀mí wo ni “olóòótọ́ ìríjú náà” ti fún wa? (b) Báwo la ti ṣe fún wa ní “ìpèsè oúnjẹ náà” ni àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?

11 Bí jíjẹun déédéé ṣe ń ṣàlékún ìlera ara, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà déédéé fún kíkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà máa ń ṣàlékún ìlera tẹ̀mí. Nínú Ìhìn Rere ti Lúùkù, a ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye, tí ọ̀gá rẹ̀ yóò yàn sípò lórí ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti máa fún wọn ní ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?” (Lúùkù 12:42) Láti ohun tí ó lé ní ọgọ́fà ọdún báyìí ni wọ́n ti ń fún wa ní “ìpèsè oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nípa tẹ̀mí láti inú Ilé Ìṣọ́, àti láti inú àwọn ìwé àti ìtẹ̀jáde mìíràn tí a gbé ka Bíbélì.

12 Kíyè sí gbólóhùn náà, “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Ní àkókò tí ó bá a mu wẹ́kú, “Olùkọ́ni Atóbilọ́lá” wa, Jèhófà, ti tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ àti ẹgbẹ́ ẹrú náà, tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ́nà lórí ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àti ìwà híhù. Ṣe ló dà bí ẹni pé a ti gbọ́ ohùn kan lápapọ̀ tó ń sọ fún wa pé: “‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:20, 21) Ìyẹn nìkan kọ́ o, nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá fara balẹ̀ ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì gbogbo, wọ́n sábà máa ń mọ̀ pé àwọn gan-an la darí àwọn èrò tó wà níbẹ̀ sí. Dájúdájú, àwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run àti àwọn ìdarí rẹ̀ yóò wá ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún wa, tí yóò fi mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti dènà ìdẹwò tàbí kí a lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.

Kọ́ Bí A ṣe Ń Jẹun Lọ́nà Tó Dáa

13. Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà ṣàìjẹun lọ́nà tó dáa nípa tẹ̀mí?

13 Ká tó lè jàǹfààní látinú irú “ìpèsè oúnjẹ” tí wọ́n ń fún wa ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa jẹun lọ́nà tó dáa. Ó ṣe pàtàkì láti ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Bíbélì kíkà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kí a sì máa tẹ̀ lé e. Ǹjẹ́ o máa ń jẹun lọ́nà tó dáa nípa tẹ̀mí kí o sì ní àwọn àkókò tóo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé lọ́nà tó jinlẹ̀? Tàbí ṣe lo máa ń yẹ àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ti wọ́n fara balẹ̀ pèsè fún wa wò gààràgà, ká kúkú sọ pé tí o kò ní fara balẹ̀ jẹ ẹ́, tàbí kí o má tilẹ̀ jẹ àwọn kán níbẹ̀ rárá? Ṣíṣàìjẹun lọ́nà tó dáa nípa tẹ̀mí ti mú kí àwọn kan di aláìlera nínú ìgbàgbọ́—ó ti mú kí wọ́n ṣubú pàápàá.—1 Tímótì 1:19; 4:15, 16.

14. Èé ṣe tó fi ṣàǹfààní láti fara balẹ̀ ka kókó ẹ̀kọ́ tó lè jẹ́ èyí táa ti mọ̀ tẹ́lẹ̀?

14 Àwọn kan lè ronú pé àwọn ti mọ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́, àti pé kì í ṣe gbogbo àpilẹ̀kọ ló ń sọ ohun tó jẹ́ tuntun. Nítorí náà, kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti lílọ sí àwọn ìpàdé ò fi bẹ́ẹ̀ pọndandan mọ́. Ṣùgbọ́n Bíbélì fi hàn pé ó yẹ kí wọ́n máa rán wa létí àwọn ohun táa ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. (Sáàmù 119:95, 99; 2 Pétérù 3:1; Júúdà 5) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó mọ oúnjẹ se dáadáa ṣe ń fi àwọn èròjà kan náà se ọ̀pọ̀ oúnjẹ tí adùn wọ́n yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ṣe ń pèsè àwọn oúnjẹ amáralókun nípa tẹ̀mí ní onírúurú ọ̀nà. Kódà nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó ẹ̀kọ́ táa ti mọ̀ bí ẹní mowó tẹ́lẹ̀, àwọn kókó tó dára tún lè wà níbẹ̀ tá ò ní fẹ pàdánù. Òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ohun tí a bá jèrè látinú àkójọ ọ̀rọ̀ kan sinmi lórí bí àkókò táa lò àti ìsapá táa ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.

Àwọn Àǹfààní Tẹ̀mí Látinú Kíkàwé àti Kíkẹ́kọ̀ọ́

15. Báwo ni kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sunwọ̀n sí i?

15 Àwọn àǹfààní táa ń rí látinú kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kò lóǹkà. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti kúnjú ìwọ̀n àwọn ojúṣe tó mú kí a jẹ́ Kristẹni ní ti gidi, ìyẹn ni pé kí ẹni kọ̀ọ̀kan wa lè di “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Báa bá ṣe túbọ̀ ń ka Bíbélì tí a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkàn wa yóò túbọ̀ máa kún fún àwọn èrò Ọlọ́run. Nígbà náà, bíi ti Pọ́ọ̀lù, yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa ‘bá àwọn ènìyàn fọ̀rọ̀ wérọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́, ká máa ṣàlàyé, ká sì máa fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka’ àwọn òtítọ́ àgbàyanu ète Jèhófà. (Ìṣe 17:2, 3) Ìkọ́ni wa yóò sunwọ̀n sí i, àwọn ìjíròrò wa, àsọyé táa ń sọ, àti àwọn ìmọ̀ràn táa ń fúnni yóò túbọ̀ máa gbéni ró nípa tẹ̀mí.—Òwe 1:5.

16. Àwọn ọ̀nà tó jẹ́ ti ara ẹni wo la fi ń jàǹfààní látinú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?

16 Láfikún sí i, àkókò táa bá lò láti ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú ìgbésí ayé wa bá àwọn ọ̀nà Jèhófà mu ní kíkún. (Sáàmù 25:4; 119:9, 10; Òwe 6:20-23) Yóò fún àwọn ànímọ́ tẹ̀mí wa bí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìdúróṣinṣin, àti ayọ̀ lókun. (Diutarónómì 17:19, 20; Ìṣípayá 1:3) Nígbà tí a bá ń fi ìmọ̀ tí a jèrè láti inú kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílò, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yóò máa ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìgbésí ayé wa, tí yóò yọrí sí ọ̀pọ̀ yanturu èso tí ẹ̀mí nínú ohun gbogbo táa bá ń ṣe.—Gálátíà 5:22, 23.

17. Báwo ni bí iye ìgbà táa fi ń ka Bíbélì àti èyí táa fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ ṣe pọ̀ tó àti bó ṣe kúnjú ìwọ̀n tó ṣe nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà?

17 Ní pàtàkì jù lọ, àkókò táa rà padà lọ́wọ́ àwọn ìgbòkègbodò mìíràn láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ yóò mú èrè ńlá wá ní ti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ òun lè “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ [Ọlọ́run] nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kólósè 1:9, 10) Bákan náà, kí a “lè máa rin lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà,” a ní láti “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí.” Ní kedere, ohun ti jíjèrè ìbùkún àti ojú rere Jèhófà sinmi lè lórí jù lọ ni bí iye ìgbà táa fi ń ka Bíbélì àti èyí táa fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó àti bó ṣe kúnjú ìwọ̀n tó.

18. Kí ni àwọn ìbùkún tó lè jẹ́ tiwa bí a bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 17:3?

18 “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ìyẹn ni ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò jù lọ láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọyì ìjẹ́pàtàkì kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò sì sí ohun tí kò fi yẹ kí àwa náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe bẹ́ẹ̀. Ìrètí táa ní láti wà láàyè títí láé sinmi lórí bí a ṣe ń dàgbà nínú ìmọ̀ Jèhófà àti ti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. Ìwọ tiẹ̀ ronú nípa ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná. Títúbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà kò lè dópin láé—ayérayé yóò sì tún wà fún wa láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀!—Oníwàásù 3:11; Róòmù 11:33.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kà Á àti Bí Wọ́n Ṣe Ń Jàǹfààní,” tí a tẹ̀ jáde nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti May 1, 1995, ojú ìwé 20 sí 21.

Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò

• Kí ni ọ̀nà táa gbà ń lo àkókò wa fi hàn?

• Inú àwọn ìgbòkègbodò wo la ti lè ra àkókò padà fún kíkà Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?

• Èé ṣe tó fi yẹ ká fiyè sí ọ̀nà tí a ń gbà jẹun nípa tẹ̀mí?

• Àwọn àǹfààní wo la ń rí látinú kíka Ìwé Mímọ́ àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Kíkà Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Mímú kí àwọn ìgbòkègbodò tí ń mọ́wọ́ ẹni dí nínú ìgbésí ayé wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì pẹ̀lú àwọn ìlépa tẹ̀mí ń mú èrè ńlá wá