Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àpẹẹrẹ Ìṣọ̀kan”

“Àpẹẹrẹ Ìṣọ̀kan”

“Àpẹẹrẹ Ìṣọ̀kan”

ÌYẸN ni àkọlé ọ̀rọ̀ olóòtú kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn kan ní ìlú Indaiatuba, São Paulo, Brazil. Àwọn wo ló fi àpẹẹrẹ yẹn lélẹ̀ ná? Òǹkọ̀wé náà ṣàlàyé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń wéwèé láti kọ́ ‘Gbọ̀ngàn Ìjọba’ tuntun kan, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń pe tẹ́ńpìlì tàbí gbọ̀ngàn àpéjọ wọn, ló fi àpẹẹrẹ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó hàn gbangba gbàǹgbà láìṣeé gbójú fò, tó sì ṣeé mú lò lélẹ̀.

Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń hàn kedere ní irú àkókò bẹ́ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ó mà wúni lórí o, láti rí àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n ń fi tinútinú ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti kọ́ ibì kan tí wọ́n ti lè máa pàdé pọ̀ láti jọ́sìn Ọlọ́run.”

Bákan náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ láwọn apá ibòmíràn. Ọ̀rọ̀ olóòtú náà fi kún un pé, “Láfikún sí kíkẹ́kọ̀ọ́ àti gbígbàdúrà, ète wọn ni láti mú kí àwọn onímukúmu-ọtí àti àwọn ajoògùnyó jáwọ́ nínú ìwà yẹn àti láti fi ọ̀nà ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ han àwọn ènìyàn. Ọ̀nà wo ni wọ́n ń gbà ṣe èyí? Àwọn Ẹlẹ́rìí mọ̀ pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti fífi àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò máa ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwàkiwà. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń ṣakitiyan láti fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Olóòtú yìí parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé, “láìsí tàbí ṣùgbọ́n, àpẹẹrẹ” wọn jẹ́ “ọ̀kan tó yẹ ká tẹ̀ lé láìjáfara.”

Gbogbo ènìyàn ló ní àǹfààní láti wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì sí ọ̀rọ̀ gbígba owó igbá níbẹ̀. A fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí ọ láti ṣèbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nítòsí rẹ.