Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Lójú àṣẹ Bíbélì nípa ọ̀nà tó tọ́ láti lo ẹ̀jẹ̀, ojú wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tó ní lílo ẹ̀jẹ̀ ara ẹni nínú?

Dípò gbígbé ìpinnu ka kìkì ohun tí ẹnì kan fara mọ́ tàbí lé orí àbá ìṣègùn kan, ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbé ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò dáadáa. Ó jẹ́ ọ̀ràn àárín òun àti Jèhófà.

Jèhófà tó ni ẹ̀mí wa pàṣẹ pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Nínú òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ìgbàanì, ó fi ààlà sí ìlò ẹ̀jẹ̀ nítorí pé ó dúró fún ìwàláàyè. Ó pàṣẹ pé: “Ọkàn [tàbí ìwàláàyè] ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀, èmi tìkára mi sì ti fi sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.” Tí ẹnì kan bá wá pa ẹran fún jíjẹ ńkọ́? Ọlọ́run sọ pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde, kí ó sì fi ekuru bò ó.” a (Léfítíkù 17:11, 13) Léraléra ni Jèhófà pa àṣẹ yìí. (Diutarónómì 12:16, 24; 15:23) Ìwé Júù náà, Soncino Chumash sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ gbé pa mọ́ àmọ́ a ní láti sọ ọ́ di aláìwúlò nípa dídà á sórí ilẹ̀.” Kò sí ọmọ Ísírẹ́lì kankan tó gbọ́dọ̀ fa ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá mìíràn, tí ìwàláàyè rẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí ó tọ́jú rẹ̀ pa mọ́, kó sì wá lò ó.

Jíjẹ́ tó jẹ́ dandan gbọ̀n fúnni láti pa Òfin Mósè mọ́ dópin nígbà tí Mèsáyà náà kú. Síbẹ̀síbẹ̀, ojú tí Ọlọ́run fi wo ẹ̀jẹ̀ pé ó jẹ́ mímọ́ kò yí padà. Bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sì ṣe darí àwọn àpọ́sítélì, wọ́n pàṣẹ pé kí àwọn Kristẹni ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ Wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àṣẹ yẹn rárá. Bí yíyẹra fún ìṣekúṣe tàbí ìbọ̀rìṣà ti jẹ́ ìwà rere tó ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ lòun náà ti ṣe pàtàkì. (Ìṣe 15:28, 29; 21:25) Nígbà tí fífi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ àti ìfàjẹ̀sínilára di èyí tó gbòde kan ní ọ̀rúndún ogún, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lòdì sí àṣà yìí. b

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, dókítà kan lè rọ aláìsàn kan pé kó fà lára ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ pa mọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ ṣáájú iṣẹ́ abẹ, (Títọ́jú ẹ̀jẹ̀ ara ẹni pa mọ́ ṣáájú iṣẹ́ abẹ, táwọn oníṣègùn ń pè ní PAD), tó fi jẹ́ pé bí ọ̀ràn bá dójú ẹ̀, dókítà lè fa ẹ̀jẹ̀ aláìsàn náà tó ti fi pa mọ́ sí i lára padà. Bó ti wù kó rí, irú gbígba ẹ̀jẹ̀, títọ́jú rẹ̀ pa mọ́ àti fífà á síni lára bẹ́ẹ̀ tako ohun tí Léfítíkù àti Diutarónómì sọ ní tààràtà. A kò gbọ́dọ̀ tọ́jú ẹ̀jẹ̀ pa mọ́; a ní láti dà á nù ni—kí ó padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, Òfin Mósè kọ́ ni à ń lò nísinsìnyí. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà tí Ọlọ́run là sílẹ̀ nínú rẹ̀, wọ́n sì pinnu láti ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ Nítorí náà, a kì í fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kì í tójú ẹ̀jẹ̀ ara wa tó yẹ ká ‘dà jáde’ pa mọ́ fún fífà sára. Àṣà yẹn kò bá òfin Ọlọ́run mu.

Àwọn ìtọ́jú tàbí àwọn àyẹ̀wò mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan kò fi bẹ́ẹ̀ tako àwọn ìlànà tí Ọlọ́run là sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ti gbà kí wọ́n fa díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ wọn fún àyẹ̀wò, tí wọ́n sì wá da ẹ̀jẹ̀ yẹn nù lẹ́yìn náà. Wọ́n tún lè dámọ̀ràn àwọn ìtọ́jú tó tún díjú díẹ̀, èyí tó mú lílo ẹ̀jẹ̀ ẹni dání.

Fún àpẹẹrẹ, lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe irú àwọn iṣẹ́ abẹ kan, wọ́n lè darí ìṣàn ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ kúrò nínú ara, èyí tí a mọ̀ sí hemodilution. Wọ́n á wá lú ẹ̀jẹ̀ tó kù lára aláìsàn náà. Lẹ́yìn náà, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n ti mú kó máa ṣàn yí po nínú ibòmíràn yìí ni wọ́n á wá dá padà sí i lára, nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ á fẹ́rẹ̀ẹ́ padà sí bó ṣe yẹ kó wà gan-an. Bákan náà, wọ́n tún lè gba ẹ̀jẹ̀ tó ń dà lójú ọgbẹ́, kí wọ́n sẹ́ ẹ, kí wọ́n bàa lè dá àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ aláìsàn náà padà sí ara rẹ̀; eléyìí ni wọ́n ń pè ní ṣíṣàìjẹ́-kí- sẹ́ẹ̀lì-ṣòfò. Nínú ìlànà kan tó tún yàtọ̀, wọ́n lè darí ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ẹ̀rọ kan tí yóò máa ṣe iṣẹ́ tí àwọn ẹ̀ya ara (bí ọkàn àyà, ẹ̀dọ̀fóró, tàbí kíndìnrín) sábà máa ń ṣe fúngbà díẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá dá ẹ̀jẹ̀ inú ẹ̀rọ náà padà sára aláìsàn náà. Nínú àwọn ìtọ́jú mìíràn, wọ́n máa ń darí ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ẹ̀rọ kan tó máa ń ya nǹkan sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ (centrifuge) kí wọ́n lè mú àwọn tí kò bá dára níbẹ̀ tàbí to ti bàjẹ́ kúrò. Ó sì lè jẹ́ góńgó wọn ni láti ya díẹ̀ sọ́tọ̀ lára ẹ̀yà inú ẹ̀jẹ̀ láti lọ lò ó ní apá ibòmíràn nínú ara. Àwọn àyẹ̀wò kan sì tún wà nínú èyí tí wọn yóò ti fa ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ kí wọ́n lè lẹ nǹkan mọ́ ọn tàbí kí wọ́n fi oògùn sí i, tí wọ́n á sì wá dá a padà sára aláìsàn náà.

Kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn àyẹ̀wò yìí lè yàtọ̀ síra, ó sì dájú pé àwọn ọgbọ́n ìṣègùn, ìtọ́jú, àti àwọn àyẹ̀wò tuntun yóò ṣì yọjú. Kì í ṣe ẹrù iṣẹ́ tiwa láti máa wá tú ìyàtọ̀ tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ ká sì wá mú ìpinnu kan jáde. Kristẹni kan gbọ́dọ̀ fúnra rẹ̀ pinnu ọ̀nà tó bá fẹ́ kí wọ́n gbà lo ẹ̀jẹ̀ òun lásìkò iṣẹ́ abẹ, àyẹ̀wò ìṣègùn, tàbí ìtọ́jú lọ́ọ́lọ́ọ́ kan. Kí ó ti béèrè àlàyé lórí àwọn ohun tí wọ́n lè fẹ́ ṣe lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lákòókò tí ìtọ́jú bá ń lọ lọ́wọ́ lọ́dọ̀ dókítà tàbí oníṣègùn náà ṣáájú. Lẹ́yìn náà kí ó pinnu bí ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ bá ṣe gbà fún un. (Wo àpótí.)

Kí àwọn Kristẹni fi ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run sọ́kàn àti ojúṣe wọn ‘láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn, gbogbo ọkàn wọn, gbogbo okun wọn àti gbogbo èrò inú wọn.’ (Lúùkù 10:27) Láìdà bí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú ribiribi wo àjọṣe dídánmọ́rán tó wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run. Olùfúnni-ní-ìyè rọ gbogbo ènìyàn láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀. A kà á pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ [Jésù Kristi] àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa.”—Éfésù 1:7.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀jọ̀gbọ́n Frank H. Gorman kọ̀wé pé: “Dída ẹ̀jẹ̀ jáde ní a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwà ọ̀wọ̀ kan tó ń fi hàn pé èèyàn bọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè ẹran náà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, ẹni tó ṣẹ̀dá ìwàláàyè tó sì tún ń bá a lọ ní títọ́jú rẹ̀.”

b Ile-Iṣọ Na July 1, 1951 [Gẹ̀ẹ́sì] dáhùn àwọn ìbéèrè ṣíṣe pàtàkì nípa kókó ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣàlàyé ìdí tí fífa ẹ̀jẹ̀ tí a fi tọrẹ síni lára kò fi bójú mu.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ YẸ KÍ O BI ARA RẸ

Bí wọn yóò bá darí ìṣàn díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ mí kúrò nínú ara mi gba ibòmíràn lọ, tó sì jẹ́ pé wọ́n tilẹ̀ lè dá ṣíṣàn tó ń ṣàn dúró fúngbà díẹ̀, ǹjẹ́ ẹ̀rí-ọkàn mi yóò gbà fún mí láti wò ó pé apá kan ara mi ni ẹ̀jẹ̀ yìí ṣì jẹ́ síbẹ̀, tí ìyẹn kò fi ní béèrè pé kí wọ́n “dà á jáde sórí ilẹ̀”?

Ṣé yóò kò ìdààmú bá ẹ̀rí-ọkàn mi tí a ti fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́ tó bá lọ jẹ́ pé lásìkò ìṣàyẹ̀wò tàbí nígbà ìtọ́jú kan, wọ́n fa díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ mi, wọ́n ṣàtúnṣe sí i, tí wọ́n sì wá darí rẹ̀ padà (tàbí pé wọ́n dà á padà) sínú ara mi?